Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 31


Orí 31

Álmà síwájú iṣẹ́-ìránṣẹ́ kan láti lọ gba àwọn ará Sórámù tí nwọ́n ti ṣubú kúrò nínú òtítọ́—Àwọn ará Sórámù sẹ́ Krístì, nwọ́n gbàgbọ́ nínú ìmọ̀ èkè pé àṣàyàn ni nwọn íṣe, nwọ́n sì njọ́sìn ní ipa àwọn àdúrà tí nwọ́n ti gbékalẹ̀ ṣãjú—Áwọn oníṣẹ́ Ọlọ́run kún fún Ẹ̀mí Mímọ́—Àwọn ìpọ́njú nwọn di gbígbémì nínú ayọ̀ Krístì. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn ikú Kòríhọ̀, tí Álmà sì ti gbọ́ ìròhìn pé àwọn ará Sórámù nyí ọ̀nà Olúwa po, àti pé Sórámù, ẹnití í ṣe olórí nwọn, ndarí ọkàn àwọn ènìyàn nã láti tẹríba fún àwọn ère tí kò lè sọ̀rọ̀, ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀sí kẹ́dùn nítorí ìwà àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã.

2 Nítorítí ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ nlá fún Álmà láti mọ̀ nípa ìwà àìṣedẽdé tí ó wà lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀; nítorínã ọkàn rẹ̀ kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìyapa àwọn ara Sórámù kúrò lára àwọn ará Nífáì.

3 Nísisìyí, àwọn ará Sórámù ti kó ara nwọn jọ sí orí ilẹ̀ kan tí nwọn npè ní Ántíónọ́mù, èyítí ó wà ní ìhà ìwọ-oòrùn ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí ó wà nítòsí ãlà etí-òkun, tí ó wà ní apá gũsù ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, èyítí ó fẹ́rẹ́ bá aginjù tí ó wà ní ìhà gũsù pa ãlà, aginjù èyítí àwọn ará Lámánì kún inú rẹ̀.

4 Nísisìyí, àwọn ará Nífáì bẹ̀rù púpọ̀ pé àwọn ará Sórámù yíò ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, àti pé yíò jẹ́ ipa àdánù nlá fún àwọn ará Nífáì.

5 Àti nísisìyí, bí ìwãsù ọ̀rọ̀ nã sì ṣe ní ipa nlá láti darí àwọn ènìyàn nã sí ipa ṣíṣe èyítí ó tọ́—bẹ̃ni, ó ti ní agbára tí ó tobi jùlọ lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã ju idà tàbí ohun míràn tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn rí—nítorínã Álmà rõ pé ó jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà pé kí àwọn kí ó lo agbára tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

6 Nítorínã ó mú Ámọ́nì, àti Áárọ́nì, àti Òmnérì; ó sì fi Hímnì sílẹ̀ ní ìjọ-onígbàgbọ́ ní Sarahẹ́múlà; ṣùgbọ́n àwọn mẹ́ta ìṣájú nnì ni ó mú pẹ̀lú rẹ̀, àti pẹ̀lú Ámúlẹ́kì àti Sísrọ́mù, tí nwọ́n wà ní Mẹ́lẹ́kì; ó sì mú méjì nínú àwọn ọmọkùrin rẹ̀ pẹ̀lú.

7 Nísisìyí, èyítí ó dàgbàjù nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ni kò mú lọ pẹ̀lú rẹ̀, orúkọ rẹ̀ ni í sì í ṣe Hẹ́lámánì; ṣùgbọ́n orúkọ àwọn tí ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ni Ṣíblọ́nì àti Kọ̀ríántọ́nì; èyí sì ni orúkọ àwọn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀ sãrin àwọn ará Sórámù, láti lọ wãsù ọ̀rọ̀ nã sí nwọn.

8 Nísisìyí, àwọn ará Sórámù jẹ́ olùyapa-kúrò lára àwọn ará Nífáì; nítorínã, nwọ́n ti gbọ́ ìwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí.

9 Ṣùgbọ́n nwọ́n ti ṣubú sínú àwọn àṣìṣe ńlá, nítorítí nwọn kò gbiyanju láti pa òfin Ọlọ́run mọ́, àti ìlànà rẹ̀, gẹ́gẹ́bí òfin Mósè.

10 Bẹ̃ni nwọn kò sì kíyèsí ìṣe ìjọ-onígbàgbọ́, láti tẹ̀síwájú nínú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run lójojúmọ́, kí nwọ́n má bã bọ́ sínú ìdánwò.

11 Bẹ̃ni, ní kúkúrú, nwọ́n yí ọ̀nà Olúwa po ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà; nítorínã, fún ìdí èyí, Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ sí orí ilẹ̀ nã láti lọ wãsù ọ̀rọ̀ nã sí nwọn.

12 Nísisìyí, nígbàtí nwọ́n ti wá sínú ilẹ̀ nã, kíyèsĩ, sí ìyàlẹ́nu wọn ríi pé àwọn ará Sórámù ti kọ́ àwọn sínágọ́gù, tí nwọn sì máa kó ara nwọn nwọn, jọ ní ọjọ́ kan nínú ọ̀sẹ̀, èyítí nwọn npè ní ọjọ́ Olúwa; nwọ́n sì jọ́sìn ní ọ̀nà tí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kò rí irú rẹ̀ rí;

13 Nítorí nwọ́n ní ibi tí nwọ́n kọ́ ní ãrin sínágọ́gù nwọn, ibití Idìdedúró sí, èyítí ó ga tayọ orí; òkè orí èyítí kò gbà ju ẹyọ ẹnìkan lọ.

14 Nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́ láti jọ́sìn níláti jáde lọ, kí ó si dúró lórí rẹ̀, kí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjẽjì sí òkè-ọ̀run, kí ó sì kígbe ní ohùn rara, wípé:

15 Mímọ́ Ọlọ́run mímọ́; àwa gbàgbọ́ pé ìwọ ni Ọlọ́run, a sì gbàgbọ́ pé mímọ́ ni ìwọ í ṣe, àti pé ẹ̀mí ni ìwọ í ṣe ní ìgbà nnì, ẹ̀mí ni ìwọ sì í ṣe, àti pé ẹ̀mí ni ìwọ í ṣe títí láéláé.

16 Ọlọ́run mímọ́, àwa gbàgbọ́ pé ìwọ tí ṣe ìpínyà wa kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wa; àwa kò sì gba àṣà àwọn arákùnrin wa gbọ́, èyítí àwọn bàbá nwọn gbé fún wọn nínú ìwà òmùgọ̀ wọn; ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé ìwọ ti yàn wá láti jẹ́ ọmọ mímọ́ rẹ; àti pẹ̀lú ìwọ ti sọọ́ di mímọ̀ fún wa pé kì yíò sí Krístì kankan.

17 Ṣùgbọ́n ìwọ ni ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí láé; ìwọ sì ti yàn wá kí àwa lè di ẹni-ìgbàlà, nígbàtí a yan àwọn tí ó yí wa ká láti lè bọ́ sínú ọ̀run àpãdì nípa ìbínú rẹ; nítorí ìwà mímọ́ wa yĩ, A! Ọlọ́run, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ; àwa sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti yàn wá, kí àwa má lè tẹ̀lé àwọn àṣà aṣiwèrè àwọn arákùnrin wa, èyítí ó ndè nwọ́n mọ́lẹ̀ sí ìgbàgbọ́ nínú Krístì, èyítí ó ndarí ọkàn nwọn láti ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, Ọlọ́run wa.

18 Àwa sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, A! Ọlọ́run, pé àwa jẹ́ ẹnití a ti yàn àti àwọn ènìyàn mímọ́ Àmín.

19 Báyĩ ni ó ṣe lẹ́hìn tí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti gbọ́ àwọn àdúrà wọ̀nyí, ẹnu yà nwọ́n gidigidi rékọjá gbogbo ìwọ̀n.

20 Nítorí kíyèsĩ, olúkúlùkù nwọn ni ó kọjá lọ láti gba irú àdúrà kannã.

21 Nísisìyí nwọn npe orúkọ ibẹ̀ ní Rámiúpítọ́mù, èyítí ó túmọ̀ sí ibi-ìdúró mímọ́.

22 Nísisìyí, lórí ibi-ìdúró yĩ, olúkúlùkù nwọn gbe ohùn àdúrà irú kannã sókè sí Ọlọ́run, tí nwọn sì ndúpẹ́ pé ó yàn nwọ́n, àti pé ó darí wọn kúrò ní ipa àṣà àwọn arákùnrin nwọn, àti pé nwọn kò rí wọn mú pẹ̀lú ẹ̀tàn láti gbàgbọ́ nínú àwọn ohun tí nbọ̀wá, èyítí nwọn kò mọ́ ohunkóhun nípa rẹ̀.

23 Nísisìyí, lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn nã bá ti gbé ohùn ọpẹ́ sókè tán lọ́nà yĩ, nwọn padà sí ilé wọn, ti nwọn kò sí ní sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run wọn mọ́ títí nwọn ó fi tún péjọpọ̀ sí ibi-ìdúró mímọ́ nã, láti gbé ohùn ọpẹ́ sókè lọ́nà yĩ.

24 Nísisìyí nígbàtí Álmà rí eleyĩ, inú rẹ̀ bàjẹ́; nítorítí ó ríi pé ènìyàn búburú àti ẹni-ìlòdìsí ni nwọn íṣe; bẹ̃ni, ó rí i pé nwọn kó ọkàn wọn lé wúrà, àti lè fàdákà, àti lé onírurú ohun mèremère.

25 Bẹ̃ni, ó sì ríi pẹ̀lú pé wọ́n nṣe ìgbéraga púpọ̀púpọ̀ nínú ọkàn nwọn.

26 Ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè sí ọ̀run, ó sì kígbe, wípé: A! báwo ni yíò ti pẹ́ tó, A! Olúwa, ìwọ yíò ha jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbé ìsàlẹ̀ yĩ nínú ara, láti wo irú ìwà búburú nlá báyĩ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn?

27 Kíyèsĩ, A! Ọlọ́run, nwọn nképè ọ́, ṣùgbọ́n ọkàn nwọn kún fún ìgbéraga. Kíyèsĩ, A! Ọlọ́run, nwọn nképè ọ́ pẹ̀lú ẹnu nwọn, ṣùgbọ́n ọkàn nwọn rú sókè sí ìgbéraga àní sí tílóbi, pẹle àwọn ohun asán ayé.

28 Kíyèsĩ, A! Ọlọ́run mi àwọn aṣọ olówó-iyebíye wọn, àti àwọn òrùka-ọwọ́ wọn, àti ẹ̀gbà-ọwọ́ wọn, àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà wọn, àti ohun mèremère wọn gbogbo tí nwọ́n fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ ọ́; sì wõ, ibití ọkàn wọn wà ni èyĩ, síbẹ̀ nwọ́n nképè ọ́ nwọn sì nwípé—Àwa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, A! Ọlọ́run, nítorípé ẹ̀yin ti ṣe wá ní ẹni-yíyàn níwájú nyin, nígbàtí àwọn míràn yíò ṣègbé.

29 Bẹ̃ni, nwọ́n sì nsọ wípé ìwọ ti sọọ́ di mímọ̀ fún nwọn pé kò lè sí Krístì kankan.

30 A! Olúwa Ọlọ́run, báwo ni yíò ti pẹ́ tó tí ìwọ yíò fi gbà kí irú ìwà búburú àti àìgbàgbọ́ bẹ̃ kí ó wà lãrín àwọn ènìyàn yĩ? A! Olúwa, ìwọ ìbá fún mi ní agbára, kí èmi lè faradà àwọn àìlera mi. Nítorítí aláìlera ni èmi íṣe, irú àwọn ìwà búburú lãrín àwọn ènìyàn yĩ sì jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún ọkàn mi.

31 A! Olúwa, ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀; ìwọ ìbá tu ọkàn mi nínú nípasẹ̀ Krístì. A! Olúwa, ìwọ ìbá gbà fún mi, kí èmi ní agbára láti lè jẹ́ kí èmi ó lè fi ìpamọ́ra gba àwọn ìpọ́njú wọ̀nyí tí yíò bá mi nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn yĩ.

32 A! Olúwa, ìwọ ìbá tu ọkàn mi nínú, kí ó sì fún mi ní àṣeyọrí, àti àwọn alájọṣiṣẹ́pọ̀ mi tí nwọ́n wà pẹ̀lú mi—bẹ̃ni, Ámọ́nì, àti Áárọ́nì, àti Òmnérì, àti Ámúlẹ́kì, àti Sísrọ́mù, àti àwọn ọmọ mi méjẽjì pẹ̀lú—bẹ̃ni, àní ìwọ ìbá tu gbogbo àwọn wọ̀nyí nínú, A! Olúwa. Bẹ̃ni, ìwọ ìbá tu ọkàn wọn nínú nípasẹ̀ Krístì.

33 Ìwọ ìbá fi fún nwọn, kí nwọn lè lágbára, kí nwọn lè faradà ìpọ́njú tí yíò bá nwọn nítorí ìwà àìṣedẽdé àwọn ènìyàn yĩ.

34 A! Olúwa, ìwọ ìbá fi fún wa kí àwa lè ní àṣeyọrí láti lè mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ nípasẹ̀ Krístì.

35 Kíyèsĩ, A! Olúwa, ẹ̀mí nwọn níyelórí, arákùnrin wa sì ni púpọ̀ nínú nwọn íṣe; nítorínã, fún wa, A! Olúwa, ní agbára àti ọgbọ́n tí àwa yíò fi tún mú àwọn wọ̀nyí, àwọn arákùnrin wa, wá sọ́dọ̀ rẹ.

36 Nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí Álmà ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Sì wò ó, bí ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí nwọn, nwọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.

37 Lẹ́hìn èyí, nwọ́n sì pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara nwọn, láìṣe àníyàn nípa ohun tí nwọn yíò jẹ, tabí tí nwọn yíò mu, tàbí tí nwọn yíò fi bora.

38 Olúwa sì pèsè fún nwọn tí ebi kò pa nwọ́n, bẹ̃ sì ni òrùngbẹ kò gbẹ nwọ́n; bẹ̃ni, ó sì tún fún nwọn lágbára láti má rí ìpọ́njú kankan, àfi kí nwọn gbé nwọn mì nínú ayọ̀ Krístì. Nísisìyí èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Álmà; ó sì rí bẹ̃ nítorípé ó gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́.