Orí 35
Ìwãsù ọ̀rọ̀ nã pa ìwà-àrékérekè àwọn ará Sórámù run—Nwọ́n lé àwọn tí a ti yí lọ́kàn padà jáde, tí nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ámọ́nì ní Jẹ́ṣónì—Álmà kẹ́dùn ọkàn nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn nã. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Nísisìyĩ ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ámúlẹ́kì ti fi òpin sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ni nwọ́n kúrò lãrín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, tí nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì.
2 Bẹ̃ ni, àti àwọn arákùnrin ìyókù, lẹ́hìn tí nwọ́n ti wãsù ọ̀rọ̀ nã fún àwọn ará Sórámù, àwọn nã kọjá lọ sínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì.
3 Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí àwọn olórí àwọn ará Sórámu ti pèròpọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti fi wãsù fún nwọn, nwọ́n bínú nítorí ọ̀rọ̀ nã, nítorítí ó pa ìwà-àrekérekè nwọn run; nítorínã ni nwọ́n kò ṣe lè fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ nã.
4 Nwọ́n sì ránṣẹ́ nwọ́n sì pe gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ nã jọ, nwọ́n sì pèròpọ̀ pẹ̀lú nwọn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ tẹ́lẹ̀.
5 Nísisìyí, àwọn olórí nwọn àti àwọn àlùfã nwọn àti àwọn olùkọ́ni nwọn kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn nã mọ̀ nípa ìfẹ́-inú nwọn; nítorínã, nwọ́n ṣe ìwádĩ ní ìkọ̀kọ̀ nípa èrò ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn nã.
6 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n ti mọ́ èrò ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn nã, ni nwọ́n lé àwọn tí nwọn ní inú dídùn sí ọ̀rọ̀ Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã; wọn sì pọ̀; nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì.
7 Ó sì ṣe tí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe ìtọ́jú nwọn.
8 Nísisìyí àwọn ará Sórámù bínú sí àwọn ènìyàn Ámọ́nì tí nwọ́n wà ní Jẹ́ṣónì, àti pé olórí aláṣẹ àwọn ará Sórámù, ẹnití ó jẹ́ ènìyàn búburú púpọ̀, ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn Ámọ́nì pé òun fẹ́ kí nwọ́n lé gbogbo àwọn tí nwọn kọjá wá láti ọ̀dọ̀ nwọn sínú ilẹ̀ nwọn jáde.
9 Ó sì nsọ ọ̀rọ̀ ìdẹ́rùbani púpọ̀ nípa nwọn. Àti nísisìyí àwọn ènìyàn Ámọ́nì kò sì bẹ̀rù ọ̀rọ̀ nwọn; nítorínã nwọ́n kò lé nwọn jáde, ṣùgbọ́n nwọ́n gba gbogbo àwọn tálákà tí ó wà nínú àwọn ará Sórámù tí nwọ́n kọjá wá sọ́dọ̀ nwọn; nwọ́n sì bọ́ nwọn, nwọ́n sì fi aṣọ bò nwọ́n lára, nwọ́n sì fún nwọn ní ilẹ̀ fún ìní nwọn; nwọ́n sì fi fún nwọn gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti ṣe aláìní.
10 Nísisìyí, eleyĩ mú kí inú àwọn ará Sórámù rú sókè ní ìbínú sí àwọn ènìyàn Ámọ́nì, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n sì rú àwọn nã sókè ní ìbínú sí nwọn.
11 Báyĩ sì ni àwọn ará Sórámù àti àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìmúrasílẹ̀ fún àti jagun pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ámọ́nì, àti pẹ̀lú àwọn ará Nífáì nã.
12 Báyĩ sì ni ọdún kẹtàdínlógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin.
13 Àwọn ènìyàn Ámọ́nì sì jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, nwọ́n sì wọ inú ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì, nwọ́n sì fún àwọn ọmọ ogun àwọn ará Nífáì ní ãyè nínú ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, kí nwọ́n lè bá àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì àti ti àwọn ará Sórámù jà; báyĩ sì ni ogun bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Nífáì, ní ọdún kejìdínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́; a ó sì sọ nípa àwọn ogun tí nwọ́n jà lẹ́hìn èyí.
14 Álmà àti Ámọ́nì, àti àwọn arákùnrin nwọn, àti àwọn ọmọ Álmà méjì sì padà lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lẹ́hìn tí nwọ́n ti jẹ́ ohun èlò lọ́wọ́ Ọlọ́run láti mú púpọ̀ nínú àwọn ará Sórámù wá sí ìrònúpìwàdà; gbogbo àwọn tí nwọn sì rònúpìwàdà nwọn ni nwọ́n lé jáde kúrò nínú ilẹ̀ nwọn; ṣùgbọ́n nwọ́n ní ilẹ̀ fún ìní nwọn nínú orí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, nwọ́n sì ti gbé ohun-ìjà ogun láti dãbò bò ara nwọn, àti àwọn aya nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, àti ilẹ̀ nwọn gbogbo.
15 Nísisìyí, nítorípé Álmà kẹ́dùn fún ìwà-àìṣedẽdé àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni fún àwọn ogun, àti àwọn ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti àwọn ìjà tí ó wà lãrín nwọn; àti nítorípé ó níláti kéde ọ̀rọ̀ nã, tàbí pé a ti rán an láti kéde ọ̀rọ̀ nã, lãrín gbogbo ènìyàn nínú ìlú gbogbo; àti nítorípé ó ríi pé àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí sé ọkàn nwọn le, àti pé nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bínú nítorí àìṣegbé ọ̀rọ̀ nã, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi.
16 Nítorínã, ó mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ kóra nwọn jọ, pé kí òun lè fún olúkúlùkù nwọn ní ìmọ̀ràn tirẹ̀, lọ́tọ̃tọ̀, nípa àwọn ohun tĩ ṣe ti òdodo. A sì ní ìkọsílẹ̀ nípa àwọn òfin rẹ̀, èyítí ó fún nwọn gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti ara rẹ̀.