Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 38


Àwọn òfin Álmà sí ọmọ rẹ̀ Ṣíblọ́nì.

Èyítí a kọ sí orí 38.

Orí 38

Nwọ́n ṣe inúnibíni sí Ṣíblọ́nì nítorí ìwà òdodo rẹ̀—Ìgbàlà nbẹ nínú Krístì, ẹnití í ṣe ìyè àti ìmọ́lẹ̀ ayé—Kó gbogbo ìwà rẹ ní ìjánu. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ọmọ mi, fi ètí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, nítorí èmi wí fún ọ, àní gẹ́gẹ́bí mo ti wí fún Hẹ́lámánì, pé níwọ̀n ìgbàtí ìwọ bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ìwọ yíò ṣe rere nínú ilẹ̀ nã; àti pé níwọ̀n ìgbàtí ìwọ kò bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ a ó ké ọ kúrò ní iwájú rẹ̀.

2 Àti nísisìyí, ọmọ mi, ó dámi lójú pé èmi yíò ní ayọ̀ púpọ̀ lórí rẹ, nítorí ìdúró ṣinṣin rẹ àti ìsòtítọ́ rẹ sí Ọlọ́run; nítorípé gẹ́gẹ́bí ìwọ ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, gẹ́gẹ́bẹ̃ ni èmi ṣe ní írètí pé ìwọ yíò tẹ̀síwájú ní pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́; nítorípé ìbùkún ní fún ẹnití ó bá forítĩ dé òpin.

3 Mo wí fún ọ́, ọmọ mi, pé èmi ti ní áyọ̀ púpọ̀ lórí rẹ síwájú, nítorí òtítọ́ rẹ àti ìgbọ́ran rẹ, àti ìpamọ́ra rẹ, àti ìfaradà rẹ lãrín àwọn ènìyàn tí íṣe ará Sórámù.

4 Nítorí mo mọ̀ pé ìwọ wà nínú ìdè; bẹ̃ni, èmi sì tún mọ̀ pé nwọ́n sọ ọ́ ní òkúta nítorí ọ̀rọ̀ nã; ìwọ sì faradà gbogbo nkan wọ̀nyí pẹ̀lú sũrù nítorípé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ; àti nísisìyí ìwọ mọ̀ pé Olúwa ni ó kó ọ yọ.

5 Àti nísisìyí, ọmọ mi, Ṣíblọ́nì, èmi fẹ́ kí o rántí, pé níwọ̀n bí o bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni yíò kó ọ yọ nínú àwọn àdánwò rẹ, àti àwọn wàhálà rẹ, àti àwọn ìpọ́njú rẹ, a ó sì gbé ọ sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.

6 Nísisìyí, ọmọ mi, èmi kò fẹ́ kí o rò wípé fúnra mi ni mo mọ́ ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Ọlọ́run èyítí ó wà nínú mi ni o sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ fún mi; nítorípé bí kò bá ṣe pé a ti bí mi nípa ti Ọlọ́run, èmi kì bá ti mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí.

7 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Olúwa nínú ãnú nlá rẹ̀ rán ángẹ́lì rẹ̀ láti sọ fún mi pé èmi gbọ́dọ̀ da ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ dúró; bẹ̃ni, èmi sì ti rí ángẹ́lì ni ojúkojú, òun sì bá mi sọ̀rọ̀, ohun rẹ̀ sì dà bí àrá, ó sì mi gbogbo ilẹ̀.

8 Ó sì ṣe tí èmi wà ní ipò ìrora àti ìbànújẹ́ ọkàn èyítí ó korò jùlọ fún ọ̀sán mẹta àti òru mẹ́ta; àti pé láìjẹ́wípé ó di ìgbà tí èmi kígbe pe Jésù Krístì Olúwa fún ãnú, ni èmi gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi kígbe pẽ, mo sì rí àlãfíà gbà sínú ọkàn mi.

9 Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi sọ eleyĩ fún ọ kí ìwọ kí ó lè kọ́ ọgbọ́n, kí ìwọ kí ó lè kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ mi pé kò sí ọ̀nà míràn tàbí ipa tí a fi lè gbà ènìyàn là, àfi nínú àti nípasẹ̀ Krístì nikan. Kíyèsĩ, òun ni ìyè àti ìmọ́lẹ̀ ayé. Kíyèsĩ, òun ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti òdodo.

10 Àti nísisìyí, bí ìwọ ti ṣe bẹ̀rẹ̀sí kọ́ni ní ọ̀rọ̀ nã, bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni èmi fẹ́ kí ó tẹ̀síwájú nínú kíkọ́ni; èmi sì fẹ́ kí o ní ìgbọ́ràn àti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ohun gbogbo.

11 Rí i pé ìwọ kò gbé ara rẹ sókè nínú ìgbéraga; bẹ̃ni, ríi pé ìwọ kò yangàn nínú ọgbọ́n ara rẹ, tàbí nínú agbára rẹ tí ó pọ̀.

12 Lo ìgboyà, ṣùgbọ́n máṣe jẹ gàba léni lórí; àti pẹ̀lú pé kí ó ríi pé ìwọ kó ara rẹ ní ìjánu nínú ohun gbogbo, kí ìwọ bá lè kún fún ìfẹ́; ríi pé o yẹra fún ìwà ọ̀lẹ.

13 Máṣe gbàdúrà bí àwọn ará Sórámù, nítorítí ìwọ ti ríi pé nwọn a máa gbàdúrà kí ènìyàn bá lè gbọ́ nwọn, kí nwọ́n sì yìn wọ́n fún ọgbọ́n nwọn.

14 Máṣe sọ wípé: A! Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé àwa dára ju àwọn arákùnrin wa; ṣùgbọ́n dípò èyí nnì sọ wípé: A! Olúwa, dáríjì mí ni ti àìpé mi, kí o sì rántí àwọn arákùnrin mi nínú ãnú—bẹ̃ni, fi àìpé rẹ han níwájú Ọlọ́run ni ìgbà gbogbo.

15 Kí Olúwa kí ó sì bùkúnfún ọkàn rẹ, kí ó sì gbà ọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn sínú ìjọba rẹ̀, láti wà ní ipò àlãfíà. Nísisìyí máa lọ, ọmọ mi, kí o sì kọ́ àwọn ènìyàn yĩ ní ọ̀rọ̀ nã. Mã wà ní ipò ironujinlẹ. Ọmọ mi, ó dìgbóṣe.