Àwọn òfin Álmà sí ọmọ rẹ̀ Kọ̀ríántọ́nì.
Èyítí a kọ sí àwọn orí 39 títí ó fi dé 42 ní àkópọ̀.
Orí 39
Ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè jẹ́ ohun ìríra—Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Kòríántọ́nì dènà àwọn ará Sórámù láti gba ọ̀rọ̀ nã—Ìràpadà ti Krístì yíò gba àwọn olódodo tí ó ti wà ṣãjú rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo ní ohun díẹ̀ láti bá ọ sọ sí i ju èyítí mo bá arákùnrin rẹ sọ; nítorípé kíyèsĩ, njẹ́ ìwọ kò ha ṣe àkíyèsí ìdúró ṣinṣin arákùnrin rẹ, ìwà òdodo rẹ̀, àti àìsimi rẹ̀ ní pípa òfin Ọlọ́run mọ́ bí? Kíyèsĩ, njẹ́ òun kò ha ti fi ìlànà rere lélẹ̀ fún ọ bí?
2 Nítorítí ìwọ kò kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ mi gẹ́gẹ́bí ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe ṣe, lãrín àwọn ará Sórámù. Nísisìyí èyí ni ohun tí èmi ní ìlòdìsí ọ; ìwọ lọ yangàn nínú agbára rẹ àti ọgbọ́n rẹ.
3 Èyí nìkan sì kọ́, ọmọ mi. Ìwọ ṣe ohun èyítí ó burú lójú mi; nítorítí ìwọ kọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ sílẹ̀, tí o sì kọjá lọ sí ilẹ̀ Sírọ́nì, nínú ilẹ̀ àwọn ará Lámánì, tí o sì tọ obìnrin panṣágà nnì, Ísábẹ́lì lọ.
4 Bẹ̃ni, ó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn ṣáko; ṣùgbọ́n èyí kò tọ́ fún ọ láti ṣe, ọmọ mi. Ó yẹ kí ìwọ dojúkọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ nã èyítí a fi lé ọ lọ́wọ́.
5 Ìwọ kò ha mọ̀, ọmọ mi, pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ ohun ìríra níwájú Olúwa; bẹ̃ni, èyítí ó jẹ́ ohun ìríra tayọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, àfi ìtàjẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ tàbí sísẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́?
6 Nítorí kíyèsĩ, bí ìwọ bá sẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ lẹ́hìn tí ó ti ní ibùgbé nínú rẹ nígbàkan rí, tí ìwọ sì mọ̀ pé ò nsẹ́ ẹ, kíyèsĩ, èyĩ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì; bẹ̃ni, ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì pànìyàn láìkà ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ Ọlọ́run sí, kò rọrùn fún un láti gba ìdáríjì; bẹ̃ni, mo wí fún ọ, ìwọ ọmọ mí, pé kò rọrùn fún un láti gba ìdáríjì.
7 Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi fẹ́ nítorí Ọlọ́run, pé ìwọ ìbá má ti jẹ̀bi ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nlá yĩ. Èmi kò ní tẹnumọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nã, láti ni ọkàn rẹ lára, bí kò bá jẹ́ fún ànfãní rẹ.
8 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìwọ kò lè fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pamọ́ kúrò níwájú Ọlọ́run; àti pé àfi bí ìwọ bá ronúpìwàdà, nwọn yíò dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí takò ọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn.
9 Nísisìyí ọmọ mi, èmi fẹ́ kí o ronúpìwàdà kí o sì kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀, kí ìwọ má sì tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ ojú rẹ mọ́, ṣùgbọ́n dá ara rẹ dúró nínú àwọn ohun wọ̀nyí gbogbo; nítorí àfi bí ìwọ bá ṣe eleyĩ, ìwọ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run rárá. A!, rántí, kí o sì sọọ́ di síṣe, kí o sì dá ara rẹ dúró nínú àwọn ohun wọ̀nyí.
10 Èmi pàṣẹ fún ọ láti sọ ọ́ di síṣe láti bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ dámọ̀ràn nínú ohun tí ìwọ yíò bá ṣe; nítorí kíyèsĩ, ìwọ wà ní ìgbà èwe rẹ, ìwọ sì níláti gba ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Kí ìwọ kí ó sì gba ìmọ̀ràn nwọn.
11 Máṣe jẹ́ kí ohun asán tàbí aṣiwèrè kankan darí rẹ; máṣe jẹ́ kí èṣù tún darí ọkàn rẹ tọ àwọn panṣágà obìnrin nnì lọ. Kíyèsĩ, A! ọmọ mi, báwo ni àìṣedẽdé tí ìwọ mú bá àwọn ará Sórámù ti pọ̀ tó; nítorípé nígbàtí nwọ́n rí ìwà rẹ nwọn kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́.
12 Àti nísisìyí Ẹ̀mí Olúwa sọ fún mi pé: Pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ láti ṣe rere, kí nwọn má bã darí ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sínú ìparun; nítorínã mo pàṣẹ fún ọ, ọmọ mi, nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run, pé kí o dáwọ́ dúró nínú ìwà àìṣedẽdé rẹ;
13 Pé kí o yí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo iyè, agbára àti ipa rẹ; pé kí ìwọ máṣe darí ọkàn láti ṣe búburú mọ́; ṣùgbọ́n dípò èyí padà lọ bá nwọn, kí o sì jẹ́wọ́ àṣìṣe àti ìpanilára rẹ èyítí ìwọ ti ṣe.
14 Má lépa ọrọ̀ tàbí àwọn ohun asán ayé yĩ; nítorí kíyèsĩ, ìwọ kò lè kó nwọn pẹ̀lú rẹ.
15 Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi yíò sọ ohun díẹ̀ fún ọ nípa bíbọ̀ Krístì. Wõ, mo wí fún ọ, pé òun ni ẹnití nbọ̀wá dájúdájú láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ; bẹ̃ni, ó nbọ̀wá láti kéde ìró ayọ̀ ti ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
16 Àti nísisìyí, ọmọ mi, èyí ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ inú èyítí a pè ọ́ sì, láti kéde ìró ayọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yĩ, láti múra ọkàn nwọn sílẹ̀; tàbí pé kí ìgbàlà lè wá sí ọ́dọ̀ nwọn, kí nwọn lè múra ọkàn àwọn ọmọ nwọn sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nã ní àkokò tí yíò bá dé.
17 Àti nísisìyí èmi yíò tu ọkàn rẹ lára díẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yĩ. Kíyèsĩ, ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún ọ ìdí rẹ tí ohun wọ̀nyí ṣe níláti jẹ́ mímọ̀ ṣãjú bíbọ̀ rẹ. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ, njẹ́ ọkàn kan ní àkokò yĩ kò ha ní iye lórí lọ́wọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí ọkàn kan yíò ṣe rí ní àkokò tí yíò bá dé bí?
18 Njẹ́ kò ha tọ́ láti jẹ́ kí ìlànà ìràpadà nã di mímọ̀ sí àwọn ènìyàn yĩ àti sí àwọn ọmọ nwọn pẹ̀lú bí?
19 Njẹ́ kò ha rọrùn ní àkokò yĩ nã fún Olúwa láti rán ángẹ́lì rẹ̀ láti kéde àwọn ìró ayọ̀ yĩ fún wa àti fún àwọn ọmọ wa, tàbí bí yíò ti ṣe lẹ́hìn ìgbà nã tí yíò bá dé bí?