Orí 48
Amalikíà rú ọkàn àwọn ará Lámánì sókè sí àwọn ará Nífáì—Mórónì ṣe ìmúrasílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti jà ìjà-òmìnira ti àwọn Krìstìánì—Ó yọ̀ nínú ìtúsílẹ̀ àti òmìnira ó sì jẹ́ ẹni nlá nínú Ọlọ́run. Ní ìwọ̀n ọdún 72 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí ó sì ṣe, ní kété tí Amalikíà ti gba ìjọba nã ni ó bẹ̀rẹ̀sí rú ọkàn àwọn ará Lámánì sókè sí àwọn ará Nífáì; bẹ̃ni, ó sì yan àwọn ènìyàn láti bá àwọn ará Lámánì sọ̀rọ̀ láti àwọn ilé ìṣọ́ gíga nwọn, ní ìtako àwọn ará Nífáì.
2 Báyĩ ni ó sì ṣe rú ọkàn nwọn sókè sí àwọn ará Nífáì, tó bẹ̃ tí ó jẹ́ pé ní àkokò tí ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ fẹ́rẹ̀ dópin, tí ó sì ti mú ète rẹ̀ di ṣíṣe títí dé àkokò yĩ, bẹ̃ni, tí nwọ́n sì ti fi ṣe ọba lórí àwọn ará Lámánì, ó wá ọ̀nà pẹ̀lú láti jọba lórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ nã, àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì pẹ̀lú.
3 Nítorínã ó ti mú ète rẹ̀ di ṣíṣe, nítorítí ó ti sé àyà àwọn ará Lámánì le tí ó sì ti fọ́ ojú inú nwọn, tí ó sì ti rú ọkàn nwọn sókè ní ìbínú, tó bẹ̃ tí ó sì ti kó ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun jọ láti lọ bá àwọn ará Nífáì jagun.
4 Nítorítí ó ti pinnu láti borí àwọn ará Nífáì kí ó sì mú nwọn ní ìgbèkùn nítorí pípọ̀ tí àwọn ènìyàn rẹ̀ pọ̀.
5 Báyĩ sì ni ó yan àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun lãrín àwọn ará Sórámù, nítorítí nwọ́n ní ìmọ̀ nípa agbára àwọn ará Nífáì, àti ibi ìsádi nwọn, àti àwọn ibi àìlágbára inú ìlú-nlá nwọn; nítorínã ni ó ṣe yàn nwọ́n láti jẹ́ àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun lórí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.
6 Ó sì ṣe tí nwọ́n kó àgọ́ nwọn, tí nwọ́n sì tẹ̀síwájú sí ìhà ilẹ̀ Sarahẹ́múlà nínú aginjù.
7 Nísisìyí ni ó sì ṣe pé bí Amalikíà ṣe ngba agbára nípa ọ̀nà ẹ̀rú, ni Mórónì, ní ìdà kejì, ti nṣe ìmúrasílẹ̀ ọkàn àwọn ènìyàn nã láti jẹ́ olódodo sí Olúwa Ọlọ́run nwọn.
8 Bẹ̃ni, ó ti nfi okun fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, tí ó sì nmú kí nwọ́n kọ́ àwọn odi kékèké, tàbí àwọn ibi ìsádi; pẹ̀lú ìṣù amọ̀ yípo láti ká àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ mọ́, àti mímọ́ odi òkúta yípo gbogbo ìlú-nlá nwọn àti àwọn etí ilẹ̀ nwọn gbogbo; bẹ̃ni, yípo ilẹ̀ nã.
9 Àti ní gbogbo àwọn ibi ìsádi nwọn tí ó ṣe aláìlágbára jùlọ ni ó fi àwọn ọmọ ogun tí ó pọ̀ jùlọ sí; báyĩ sì ni ó dãbò bò tí ó sì fún ilẹ̀ nã ní ágbára èyítí àwọn ará Nífáì ní ní ìní.
10 Báyĩ ni ó sì nṣe ìmúrasílẹ̀ láti se àtìlẹhìn fun òmìnirá nwọn, àwọn ilẹ̀ nwọn, àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, àti àlãfíà nwọn, àti pé kí nwọ́n ó lè wà lãyè fún Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti pé kí nwọ́n lè gbé èyí nnì tí àwọn ọ̀tá nwọn npè ní ìjà-òmìnira àwọn Krìstìánì ró.
11 Mórónì sì jẹ́ ènìyàn tí ó ní ipá àti agbára; ó jẹ́ ẹnití ó ní òye pípé; bẹ̃ni, ẹnití kò ní inúdídùn sí ìtàjẹ̀sílẹ̀; ẹnití ọkàn rẹ̀ ní áyọ̀ nínú ìtúsílẹ̀ àti òmìnira orílẹ̀-èdè rẹ̀, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò nínú ìdè àti oko ẹrú;
12 Bẹ̃ni, ẹnití ọkàn rẹ̀ kún fún ọpẹ́ sí Ọlọ́run rẹ̀, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní àti ìbùkún tí ó ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹnití o ṣiṣẹ́ púpọ̀púpọ̀ fún àlãfíà àti àìléwu àwọn ènìyàn rẹ̀.
13 Bẹ̃ni, ó sì jẹ́ ẹnití ó dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, ó sì ti búrà nínú ìbúra láti dãbò bò àwọn ènìyàn rẹ̀, ẹ̀tọ́ rẹ̀ àti orílẹ̀-èdè rẹ̀, àti ẹ̀sìn rẹ̀, àní títí dé títa ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀.
14 Nísisìyí a ti kọ́ àwọn ará Nífáì láti dãbò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, àní títí dé ìtàjẹ̀sílẹ̀ bí ó bá di ṣíṣe; bẹ̃ni, a sì tún kọ́ nwọn láti má kọ lu ẹnìkẹ́ni láéláé, bẹ̃ni, láti má gbé idà sókè sí ẹnìkẹ́ni láéláé àfi sí ẹnití í ṣe ọ̀tá, àfi fún pípa ẹ̀mí nwọn mọ́.
15 Eyĩ sì ni ìgbàgbọ́ nwọn, pé nípa ṣíṣe eleyĩ Ọlọ́run yíò mú nwọn ṣe rere lórí ilẹ̀ nã, tàbí kí a wípé, bí nwọ́n bá jẹ́ olódodo ní pípa òfin Ọlọ́run mọ́ pé òun yíò mú nwọn ṣe rere lórí ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, kìlọ̀ fún nwọn láti sá, tàbí láti múrasílẹ̀ fún ogun, ní ti ewu tí ó bá wà fún nwọn;
16 Àti pẹ̀lú, pé Ọlọ́run yíò sọọ́ di mímọ̀ fún nwọn ibi tí nwọn yíò lọ láti dábõbò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, àti nípa ṣíṣe eleyĩ, Olúwa yíò kó nwọn yọ; èyí sì ni ìgbàgbọ́ Mórónì, ọkàn rẹ̀ sì yọ̀ púpọ̀ nínú rẹ, kĩ ṣe nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ṣíṣe rere, nínú pipa àwọn ènìyàn rẹ mọ, nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́, bẹ̃ni, àti yíyẹra fún àìṣedẽdé.
17 Bẹ̃ni, lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún nyín, bí gbogbo ènìyàn bá wà, àti ti nwọn sì wà, àti ti nwọn yíò si wa bí Mórónì, kíyèsĩ, gbogbo àwọn agbára ọ̀run àpãdì yíò di aláìlágbára títí láéláé; bẹ̃ni, èṣù kì bá ti lágbára lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn.
18 Kíyèsĩ, ó jẹ́ ẹnití ó dàbí Ámọ́nì, ọmọ Mòsíà, bẹ̃ni, àti àwọn ọmọ Mòsíà yókù pẹ̀lú, bẹ̃ni, àti Álmà àti àwọn ọmọ rẹ̀, nítorítí gbogbo nwọn jẹ́ ẹni Ọlọ́run.
19 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kò ṣe aláì ṣiṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nã bí ti Mórónì; nítorítí nwọ́n wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nwọ́n sì ṣe ìrìbọmi fún gbogbo ẹni tí yíò bá tẹ́tísí ọ̀rọ̀ nwọn sí ti ìrònúpìwàdà.
20 Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe jáde lọ, àwọn ènìyàn nã sì rẹ ara nwọn sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi rí ojú rere Olúwa lọ́pọ̀lọpọ̀, báyĩ sì ni nwọ́n ṣe bọ́ lọ́wọ́ ogun àti ìjà lãrín ara nwọn, bẹ̃ni, àní fún ìwọ̀n ọdún mẹ́rin.
21 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí mo ti wí ní ìṣãjú, ní àkokò tí ọdún kọkàndínlógún fẹ́rẹ̀ dópin, bẹ̃ni, l’áìṣírò àlãfíà wà lãrín ara nwọn, a mú nwọn bá àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì jà pẹ̀lú ìlọ́ra.
22 Bẹ̃ni, ní kukuru, àwọn ogun nwọn pẹ̀lú àwọn ará Lámánì kò tán fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, l’áìṣírò nwọ́n ní ìlọ́ra púpọ̀ láti bá nwọn jà.
23 Nísisìyí, nwọ́n kẹ́dùn láti gbé ohun ìjà-ogun ti àwọn ará Lámánì, nítorítí nwọn kò ní inú dídùn sí ìtàjẹ̀sílẹ̀; bẹ̃ni, èyí nìkan sì kọ́—nwọn kẹ́dùn láti jẹ́ ipa tí a ó fi rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin nwọn jáde kúrò nínú ayé yĩ lọ sínú ayérayé, ní aimurasílẹ̀ láti bá Ọlọ́run nwọn pàdé.
24 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọn kò lè gbà láti fi ẹ̀mí nwọn lélẹ̀, kí àwọn tí ó fi ìgbà kan rí jẹ́ arákùnrin nwọn ó pa àwọn aya àti ọmọ nwọn nípasẹ̀ ìwà ìkà òun ìpãnle nwọn, bẹ̃ni, tí nwọ́n sì ti yapa kúrò nínú ìjọ nwọn, tí nwọ́n sì ti kúrò lọ́dọ̀ nwọn, tí nwọ́n sì ti lọ láti pa nwọ́n run nípa dídarapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì.
25 Bẹ̃ni, nwọn kò lè gbà kí àwọn arákùnrin nwọn yọ̀ lé ẹ̀jẹ̀ àwọn ará Nífáì, níwọ̀n ìgbàtí àwọn kan bá wà tí ó npa òfin Ọlọ́run mọ́, nítorípé ìlérí Olúwa ni pé, bí nwọ́n bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ nwọn yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã.