Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 4


Orí 4

Álmà ri ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn ẹnití a yí lọ́kàn padà bọmi—Àìṣedẽdé wọ inú ìjọ, ìfàsẹ́hìn sì dé bá ìjọ—A yan Néfáíhà gẹ́gẹ́bí onídàjọ́ àgbà—Álmà, gẹ́gẹ́bí olórí àlùfã, ṣe ìfọkànsìn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ní ìwọ̀n ọdún 86–83 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kẹfà nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, kò sí ìjà tàbí ogun ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà;

2 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn nã ní ìpọ́njú, bẹ̃ni, ìpọ́njú nlá lórí ìpàdánù àwọn arákùnrin nwọn, àti pẹ̀lú fún ìpàdánù àwọn agbo-ẹran nwọn àti àwọn ọ̀wọ́-ẹran nwọn, àti fún ìpàdánù àwọn pápá ọkà nwọn, èyítí àwọn ará Lámánì tẹ̀ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ nwọn, tí wọ́n sì parun.

3 Báyĩ sì ni ìpọ́njú nwọn pọ̀ tó, tí ó jẹ́ wípé gbogbo ènìyàn ni ó níláti ṣọ̀fọ̀; nwọ́n sì gbàgbọ́ wípé ìdájọ́ Ọlọ́run ni a rán lé nwọn lórí nítorí àìṣedẽdé nwọn àti ìwà ìríra nwọn; nítorínã nwọ́n sì tají sí ìrántí iṣẹ́ ẹ̀sìn nwọn.

4 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dá ìjọ sílẹ̀ síi; bẹ̃ni, ọ̀pọ̀ ni a sì rìbọmi nínú omi Sídónì, a sì dà nwọ́n pọ̀ mọ́ ìjọ-Ọlọ́run; bẹ̃ni, a rì nwọn bọmi láti ọwọ́ Álmà, èyítí a ti yà sí mímọ́ sí ipò olórí àlùfã lórí àwọn ènìyàn ìjọ nã, láti ọwọ́ bàbá rẹ̀, Álmà.

5 Ó sì ṣe, ní ọdún keje nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹ̃dẹ́gbẹ̀ta ènìyàn da ara pọ̀ mọ́ ìjọ Ọlọ́run tí a sì rì nwọn bọmi. Báyĩ sì ni ọdún keje nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ dé òpin lórí àwọn ènìyàn Nífáì; àlãfíà sì wà ní gbogbo ìgbà nã.

6 Ó sì ṣe, ní ọdún kẹjọ ti ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àwọn ará ìjọ nã bẹ̀rẹ̀síi ṣe ìgbéraga nítorí ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí nwọ́n ní, àti aṣọ dáradára nwọn àti aṣọ olówó-iyebíye nwọn, àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbo-ẹran àti ọ̀wọ́-ẹran nwọn, àti wúrà nwọn àti fàdákà nwọn, àti onírurú ohun iyebíye, èyítí nwọ́n ti ní nípa ìtẹpámọ́ṣẹ́, nínú ohun wọ̀nyí ni nwọ́n sì rú ara nwọn sókè ní ìgbéraga, nítorítí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí wọ aṣọ olówó-iyebíye.

7 Nísisìyí èyí ni ohun tí ó fa ìpọ́njú fún Álmà, bẹ̃ni, àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí Álmà ti yà sọ́tọ̀ láti jẹ́ olùkọ́ni, àti àlùfã, àti àwọn àgbàgbà lórí ìjọ nã; bẹ̃ni, púpọ̀ nínú nwọn kẹ́dùn nítorí àìṣedẽdé tí nwọ́n rí tí ó ti bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn wọn.

8 Nítorítí nwọ́n ṣàkíyèsí pẹ̀lú ìbànújẹ́ pé àwọn ènìyàn ìjọ nã bẹ̀rẹ̀sí gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga ojú nwọn, àti láti gbe ọkàn nwọn le ọrọ̀ àti ohun asán ayé, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pẹ̀gàn ara nwọn, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe inúnibíni sí àwọn tí nwọn kò gbàgbọ́ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti ìdùnnú nwọn.

9 Àti báyĩ, ní ọdún kẹjọ nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, ìjà púpọ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín àwọn ènìyàn ìjọ nã; bẹ̃ni, ìlara, ìjà, pẹ̀lú àrankàn, àti inúnibĩni, àti ìgbéraga, ni ó wà pẹ̀lú, àní tí ó tayọ ìgbéraga àwọn tí nwọn kì íṣe ará ìjọ ti Ọlọ́run.

10 Báyĩ sì ni ọdún kẹjọ ìjọba àwọn onídàjọ́ parí; ìwà búburú ìjọ nã sì jẹ́ ohun-ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tí kì íṣe ará ìjọ nã; báyĩ sì ni ìjọ nã bẹ̀rẹ̀sí kùnà nínú ìtẹ̀síwájú rẹ̀.

11 Ó sì ṣe, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹẹ̀sán, Álmà rí ìwà búburú ìjọ nã, òun sì ríi tí àpẹrẹ ìjọ nã bẹ̀rẹ̀sí darí àwọn aláìgbàgbọ́ lati ìwà àìṣedẽdé kan sí òmíràn, tí ó sì mú ìparun bá àwọn ènìyàn nã.

12 Bẹ̃ni, òun rí àìdọ́gba tí ó tóbi lãrín àwọn ènìyàn nã, àwọn kan sí gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga nwọn, tí nwọn nkẹ́gàn àwọn míràn, tí nwọ́n sì nṣe ìkórira àwọn aláìní, àti àwọn tí ó wà ní ìhõhò, ati àwọn ti ebi npa, àti àwọn tí npòngbẹ, àti àwọn tí nwọ́n ṣàìsàn àti tí ìyà njẹ.

13 Nísisìyí, èyí fa ohun ìpohùnréré-ẹkún lãrín àwọn ènìyàn nã, bí àwọn kan ṣe nrẹ ara nwọn sílẹ̀, tí nwọ́n sì nṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ nwọn nípa fífúnni nínú ohun ìní nwọn fún àwọn tálákà àti àwọn aláìní, tí nwọn nbọ́ àwọn tí ebi npa, tí nwọ́n sì nfarada onírurú ìpọ́njú, nítorí Krístì, ẹnití mbọ̀wá gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀;

14 Tí nwọ́n sì nretí ọjọ́ nã, nípa èyítí nwọ́n rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; tí nwọ́n sì kún fún ayọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí àjĩnde òkú, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti agbára àti ìdásílẹ̀ Jésù Krístì kúrò lọ́wọ́ ìdè ikú.

15 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà, nígbàtí ó rí ìpọ́njú àwọn onírẹ̀lẹ̀-ọkàn tí nwọ́n jẹ́ olùtẹ̀lé Ọlọ́run, àti àwọn inúnibíni tí a dà lé nwọn lórí láti ọwọ́ àwọn èyítí ó ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn rẹ̀, tí ó sì rí gbogbo àìdọ́gba nwọn, ó sì bẹ̀rẹ̀sí banújẹ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃ Ẹ̀mí Olúwa kò jáa kulẹ̀.

16 Ó sì yan ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan, ẹniti ó wà lãrín àwọn àgbàgbà ìjọ nã, ó sì fún un ní agbára gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn, pé kí ó lè ní agbára láti fi òfin lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyítí a ti fún nwọn, kí o sì fi nwọ́n múlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn nã.

17 Nísisìyí, orúkọ ọkùnrin yíi ní Néfáíhà, a sì yàn án ní onídàjọ́ agba; òun sì jókõ lórí ìtẹ́ ìdájọ́ láti ṣe ìdájọ́ àti lati ṣe àkóso àwọn ènìyàn nã.

18 Nísisìyí, Álmà kò fún un ní ipò olórí àlùfã lórí ìjọ nã, ṣùgbọ́n ó fi ara rẹ̀ sí ipò olórí àlùfã; ṣùgbọ́n ó fi ìtẹ́ ìdájọ́ lé Néfáíhà lọ́wọ́.

19 Èyí ni ó sì ṣe, kí òun fúnrarẹ̀ lè kọjá lọ lãrín àwọn ènìyàn rẹ, tabi larin àwọn ènìyàn Nífáì, kí òun kí ó lè kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí nwọn, láti ta nwọ́n jí ní ìrántí iṣẹ́ ìsìn nwọ́n, àti kí ó lè já kulẹ̀, nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbogbo ìgbéraga àti ọgbọ́n àrékérekè àti gbogbo ìjà tí ó wà lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorítí kò rí ọ̀nà míràn tí ó fi lè gbà nwọ́n, àfi nípa jíjẹ́ ẹ̀rí ìgbàgbọ́ sí nwọn.

20 Báyĩ ni, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹẹ̀sán nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, lórí àwọn ará Nífáì, Álmà gbé ìtẹ́ ìdájọ́ sílẹ̀ lé Néfáíhà lọ́wọ́, ó sì fi ara rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún iṣẹ́ oyè-àlùfã gíga, èyítí íṣe ti ẹgbẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run, fún ẹ̀rí ọ̀rọ̀ nã, gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ti ìfihàn àti ti ìsọtẹ́lẹ̀.