Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 15


Ori 15

Ọgbà-àjàrà Olúwa (Isráẹ́lì) yíò di ahoro, a ó sì tú àwọn ènìyàn rẹ̀ ká—Ìbànújẹ́ yíò wá sórí wọn ní ipò ìṣubú-kúrò nínú òtítọ́ àti títúká wọn—Olúwa yíò gbé ọ̀págun sókè yíò sì kó Isráẹ́lì jọ—Fi Isaiah 5 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nígbànã ni èmi yíò kọ orin sí àyànfẹ́ ọ̀wọ́n mi orin àyànfẹ́ mi ọ̀wọ́n, níti ọgbà-àjàrà rẹ̀. Àyànfẹ́ ọ̀wọ́n mi ní ọgbà-àjàrà lórí òkè eléso.

2 Ó sì sọ ọgbà yí i ká, ó sì ṣa òkúta kúrò nínú rẹ̀, ó sì gbin àṣàyàn àjàrà sí inú rẹ̀, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sãrin rẹ̀, ó sì ṣe ìfúntí sínú rẹ̀ pẹ̀lú; ó sì wò pé kí ó so èso àjàrà jáde wá, ó sì mú èso àjàrà asodigbó jáde wá.

3 Àti nísisìyí, A! ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù, àti ẹ̀yin ọkùnrin Júdà, e ṣe ìdájọ́, mo bẹ̀ yín, lãrín mi àti ọgbà-àjàrà mi.

4 Kíni a bá ṣe sí ọgbà-àjàrà mi tí èmi kò ti ṣe nínú rẹ̀? Nítorí-èyi, nígbàtí mo wò pé ìbá mú èso àjàrà jáde wá ó mú èso àjàrà asodigbó jáde wá.

5 Njẹ́ nísisìyí ẹ wá ná; èmi yíò sọ fún yín ohun tí èmi yíò ṣe sí ọgbà-àjàrà mi—èmi yíò mú ọgbà rẹ̀ kúrò, a ó sì jẹ ẹ́ run; èmi yíò sì wó ògiri rẹ̀ lu ilẹ̀, a ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀;

6 Èmi yíò si sọ ọ́ di ahoro; a kì yíò tọ́ ẹ̀ka rẹ̀ bẹ̃ni a kì yíò wà á; ṣùgbọ́n ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yíò wá sókè níbẹ̀; èmi yíò sì pàṣẹ fún àwọ̀sánmà kí ó má rọ̀jò sórí rẹ̀.

7 Nítorí ọgbà-àjàrà Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni ará ilé Isráẹ́lì, àti àwọn ọkùnrin Júdà ni igi-gbíngbìn tí ó wù ú; ó sì retí ìdájọ́, sì kíyèsĩ i, ìnilára; ó retí òdodo, ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, igbe.

8 Ègbé ni fún àwọn tí ó ní ilé kún ilé, títí àyè kò fi sí mọ́, kí wọ́n bà lè nìkan wà ní ãrin ilẹ̀ ayé!

9 Ní etí mi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun sọ pé, nítõtọ́ ọ̀pọ̀ ilé ni yíò di ahoro, àti ìlú nla àti dídára láìsí olùgbé.

10 Bẹ̃ni, ìwọ̀n ákérì mẹ́wã ọgbà-àjàrà yíò mú òṣùwọ̀n bátì kan wá, àti òṣùwọ̀n irúgbìn hómérì kan yíò mú òṣùwọ̀n éfà kan wá.

11 Ègbé ni fún àwọn tí ndìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí wọ́n lè má lépa ọtí líle, tí wọ́n wà nínú rẹ̀ títí di alẹ́, tí ọtí-wáínì sì mú ara wọn gbóná!

12 Àti hárpù, àti fíólì, tábrẹ́tì, àti fèrè, àti ọtí-wáínì wà nínú àsè wọn; ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, bẹ̃ni wọn kò ro iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

13 Nítorínã, àwọn ènìyàn mi lọ sí ìgbèkun, nítorí tí wọn kò ní òye; àwọn ọlọ́lá wọn sì di rírù, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn gbẹ fún òrùngbẹ.

14 Nítorínã, ọ̀run àpãdì ti fún ara rẹ̀ ní àyè, ó sì la ẹnu rẹ̀ ní àìní ìwọ̀n; àti ògo wọn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, àti ọ̀ṣọ́ wọn, àti ẹni tí nyọ̀, yíò sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀.

15 Ènìyàn lásán ni a ó mú wá sílẹ̀, àti ènìyàn alágbára ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ojú agbéraga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀.

16 Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni a ó gbé ga ní ìdájọ́, àti Ọlọ́run ẹni-mímọ́ yíò jẹ́ mímọ́ nínú òdodo.

17 Nígbànã ni àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yíò ma jẹ gẹ́gẹ́bí ìṣe wọn, àti ibi ahoro àwọn tí ó sanra ni àwọn àlejò yíò ma jẹ.

18 Ègbé ni fún àwọn tí nfa ìwà búburú pẹ̀lú okùn ohun asán, àti ẹ̀ṣẹ̀ bí enipé pẹ̀lú okùn kẹ̀kẹ́;

19 Tí wọ́n wípé: Jẹ́ kí ó yára, mú iṣẹ́ rẹ̀ yára, kí àwa kí ó lè rí i; sì jẹ́ kí ìmọ̀ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì súnmọ́ ìhín kí ó sì wá, kí àwa kí o lè mọ̀ ọ́.

20 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n npe ibi ní rere, àti rere ní ibi, tí nfi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀, àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn, ti nfi ìkorò pe adùn, àti adùn pe ìkorò!

21 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n gbọ́n ní ojú ara wọn tí wọ́n sì mọ́ òye ní ojú ara wọn!

22 Ègbé ni fún àwọn tí ó ní ipá láti mu ọtí-wáínì, àti àwọn ọkùnrin alágbára láti ṣe àdàlú ọtí líle;

23 Àwọn ẹni tí ó dá àre fún ẹni-búburú nítorí èrè, tí wọ́n sì mú òdodo olódodo kúrò ní ọwọ́ rẹ̀!

24 Nítorínã, bí iná ti í jó àkékù koríko run, tí ọwọ́ iná sì í jó ìyàngbo, egbò wọn yíò dàbí rírà, ìtànná wọn yíò sì gòkè bí eruku; nítorí wọ́n ti ṣá òfin Olúwa àwọn Ọmọ-ogun tì, wọ́n sì ti gan ọ̀rọ̀ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì.

25 Nítorínã, ni ìbínú Olúwa fi ràn sí ènìyàn rẹ̀, ó sì ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí wọn, ó sì ti lù wọ́n; àwọn òkè sì wàrìrì, òkú wọn sì fàya ní ãrin ìgboro. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.

26 Yíò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnà, yíò sì kọ sí wọn láti òpin aiyé wá; sì kíyèsĩ i, wọn yíò yára wá kánkán; kò sí ẹnìkan tí yíò ṣe ãrẹ̀ tàbí kọsẹ̀ lãrín wọn.

27 Kò sí ẹni tí yíò tõgbé tàbí tí yíò sùn; bẹ̃ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yíò tú, bẹ̃ni okùn bàtà wọn kì yíò já;

28 Àwọn ẹni tí ọfà wọn yíò mú, tí gbogbo ọrun wọn sì tẹ̀, a ó ka pátákó ẹṣẹ̀ ẹṣin wọn bí òkúta àkọ̀, àti kẹ̀kẹ́ wọn bí ãjà, ohùn bíbú wọn bí ti kìnìún.

29 Wọn yíò bú ramúramù bí àwọn ọmọ kìnìún; bẹ̃ni, wọn yíò bú ramúramù, wọn yíò sì di ohun ọdẹ nã mú, wọn yíò sì gbé lọ ní àìléwu, kò sì sí ẹnìkan tí yíò gbà sílẹ̀.

30 Àti ní ọjọ́ nã wọn yíò bú ramúramù sí wọn bí bíbú òkun; bí wọ́n bá sì wo ilẹ̀ nã, kíyèsĩ i, òkùnkùn àti ìrora-ọkàn, ìmọ́lẹ̀ sì di òkùnkùn nínú àwòsánmà dúdú rẹ̀.

Tẹ̀