Àwa Yóò Dán Wọn Wò Báyi
Ìsisìyí ni àkokò láti múrasílẹ̀ àti láti dán arawa wò ní ìfẹ́ àti agbára láti ṣe ohun gbogbo eyikeyi tí Olúwa Ọlọ́run wa yíò pàṣẹ fún wa.
Mo gbàdúrà fún àtìlẹhìn Ẹ̀mí Mímọ́ fún gbogbo wa bí a ti npín àwọn èrò àti ìmọ̀lára tí ó ti wá sí inú àti ọkàn mi ní mímúrasílẹ̀ fún ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yí.
Pàtàkì àwọn Ìdánwò
Fún àwọn díkédì méjì ṣíwájú ìpè mi sí ìgbà-kíkún iṣẹ́-ìsìn Ìjọ, mo ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́bí olùkọ́ni unifásitì àti alabojuto. Kókó ojúṣe mi bí olùkọ́ kan ni láti ran àwọn akẹkọ lọ́wọ́ láti kọ́ bí wọ́n ṣe lè kẹkọ fúnrawọn. Àti pé nkan pàtàkì tí iṣẹ́ mi ní ṣíṣẹ̀dá, kíkà, àti fífún èsì nípa iṣẹ́ ọmọ ilé-ìwé lórí àwọn ìdánwò. Bí ẹ ṣe lè ti mọ̀ látinú ìrírí araẹni, àwọn ìdánwò gan kìí ṣe ara ètò ẹ̀kọ́ tí àwọn akẹkọ́ fẹ́ràn jùlọ!
Ṣùgbọ́n àwọn ìdánwò ìgbàkọ̀ọ̀kan ṣe pàtàkì gidi sí kíkọ́ ẹ̀kọ́. Ìdánwò kan tó múnádóko nràn wá lọ́wọ́ láti fi ohun tí a nílò láti mọ̀ wé ohun tí a mọ̀ dájúdájú nípa kókó ẹ̀kọ́ kan; bákannáà ó pèsè òṣùwọ̀n kan ní ìlòdi sí èyí tí a lè gbé ìkẹkọ wa àti ìdàgbàsókè yèwò.
Bákannáà, àwọn ìdánwò ní ilé-ìwé ayé ikú jẹ́ ohun èlò pàtàkì sí ìlọsíwájú ayérayé wa. Bákannáà, ó dùnmọ́ni pé, a kò rí ọ̀rọ̀ náà ìdánwò ní ìgbà kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìwé-mímọ́ ti Iṣẹ́ Òṣùwọn ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ bí ridi, wadi, àti dánwo ni a lò láti júwe onírurú àwọn ìlànà tótọ́ ti ìmọ̀ ẹ̀mí wa nípa, òye ti, àti ìfọkànsìn wa sí ètò ìdùnnú ayérayé ti Baba wa Ọ̀run àti okun wa láti wá àwọn ìbùkún Ètùtù Olùgbàlà.
Ẹni tí ó dá ètò ìgbàlà sílẹ̀ júwe èrèdí ti àdánwò ayé ikú gan ní lílo àwọn ọ̀rọ̀ ridi, wadi, àti dánwò nínú iwé mímọ́ àtijọ́ àti òde-òní. “A ó sì dán wọn wò ní báyí,” láti ríi bóyá wọn yíó ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wọn yíó paláṣẹ fún wọn.”1
Yẹ ẹ̀bẹ̀ yí wò látẹnu Dáfídì Olórin:
“Wadi mi, Olúwa, kí o sì ridi mi; dán inú mi àti ọkàn mi wò.
“Nítorítí ìṣeun-ìfẹ́nbẹ rẹnbẹ níwájú mi: Èmi sì ti nrìn nínú òtìtọ́ rẹ̀.”2
Olúwa kéde ní 1833, “Nítorínáà, ẹ máṣe bẹ̀rù àwọn ọ̀tá yín, nítorí mo ti paṣẹ nínú ọkàn mi, ni Oluwa wí, pé èmi o dán yin wò nínú ohun gbogbo, bóyá ẹ̀yín yíò dúró nínú májẹ̀mú mi, àni sí ikú, kí a lè ríi yin ní ìkàyẹ.”3
Rírídi àti Dídánwò Òde-Oní
Ọdún 2020 ni a ti sàmì sí, ní apákan, nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé tí ó ti dán wa wò, wadi, àti ridi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà. Mo gbàdúrà pé àwa bí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ẹbí nkọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìyebíye tí àwọn ìrírí ìpènijà nìkan lè kọ́ wa. Bákannáà mo ní ìrètí pé gbogbo wa yíò dá “títóbi jùlọ Ọlọ́run” mọ̀ àti òtítọ́ pé “oùn yíò ya àwọn ìpọ́njú [wa] sí mímọ́ fún èrè [wa].”4
Àwọn kókó ìpìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ méjì lè tọ́wasọ́nà bí a ṣe ndojúkọ àwọn ipò rírí-ìdí àti dídánwò nínú ayé wa, eyikeyi tí wọ́n lè jẹ́: (1) ìpìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìmúrasílẹ̀, àti (2) títẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì.
Dídánwo àti Mímúrasílẹ̀
Gẹ́gẹ́bí ọmọẹ̀hìn Olùgbàlà, a pàṣẹ fún wa láti “múra ohun gbogbo tí ó yẹ sílẹ̀; kí a sì gbé ilé kan kalẹ̀, àní ilé àdúrà, ilé àwẹ̀, ilé ìgbàgbọ́, ilé ẹ̀kọ́, ilé ògo, ilé elétò, ilé Ọlọ́run.”5
Bákannáà a ṣe ìlérí fún wa pe, “A kò ní bẹ̀rù tí a bá múrasílẹ̀.
“Àti kí ẹ lè yọkúrò nínú agbára ọ̀tá, kí ẹ sì kó awọn ènìyàn mímọ́ jọ sí mi láìsí àbàwọ́n àti ní àìlẹ́ṣẹ̀.”6
Ìwé mímọ́ wọ̀nyí pèsè ìlànà pípé fún ṣíṣe ètò àti mímúra ayé àti ilé wa sílẹ̀ níti ara àti níti ẹ̀mí. Àwọn ìlàkàkà wa láti múrasílẹ̀ fún àwọn ìrírí ìdánwò ti ayé-ikú gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà ẹnití ó fi àfikún “pọ̀ ní ọgbọ́n àti ìdàgbà, àti ní ojúrere pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn”7—ìbámu tó dọ́gba níti ẹ̀kọ́, ti-ara, ti-ẹ̀mí, àti ṣíṣetán àwùjọ.
Ní ọ̀sán kan ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, Susan àti èmi wòyíka ibi tí à nko Oúnjẹ pamọ́ sí àti àwọn ìpèsè pàjáwìrì. Ní àkokò tí, COVID-19 ngbilẹ̀ si kíákíá, àti ti oríṣiríṣi ìsẹ́lẹ̀ ti da ilé wa ní Utah lamu. A ti ṣiṣẹ́ láti àwọn ọjọ́ ìṣíwájú sí ìgbeyàwó wa láti tẹ̀lé àmọ̀ràn ti wòlíì nípa mímúrasílẹ̀ fún àwọn ìpènijà àìrí, nítorínáà “wíwádí” ipò ti ṣíṣetán wa ní àárín àrùn àti ìsẹ́lẹ̀ tí ó dàbíi ohun rere àti ìgbà tó dára láti ṣe. A fẹ́ láti rí ìwọn wa lórí àwọn ìdánwò àìwífúnni wọ̀nyí.
A kẹkọ́ nlá gidi. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè, iṣẹ́ ìmúrasílẹ̀ wa bọ́ sí rẹ́gí. Ní àwọn agbègbè míràn, bákannáà, a nílò àtúnṣe nítorí a kò damọ̀ kí a sì ṣe àwọn àìní kan ní pàtó ní àwọn ọ̀nà ìbámu.
Bákannáà a rẹrin lọ́pọ̀lọpọ̀. Fún àpẹrẹ, a ri àwọn ohun èlò ní ìsàlẹ̀ ibi-ípamọ́ tí ó ti wà nínú ibi ìpamọ́ oúnjẹ fún àwọn díkédì. Lótitọ́, ẹ̀rú bà wá láti ṣí àti láti yẹ àwọn kan lára àwọn agolo náà wò fún ìjayà ti mímú àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé míràn wá! Ṣùgbọ́n inú yín gbọ́dọ̀ dun pé a kó àwọn ohun èlò eléwu sọnù dáadáa, àti pé a mú ewu ìlera sí ayé kúrò.
Àwọn ọmọ Ìjọ kan rò pé àwọn ètò àti ìpèsè pàjáwìrì, ìkópamọ́ oùnjẹ àti ohun-èlò wákàtí méjìléní-àádọ́rin kò gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì mọ́ nítorí àwọn Arákùnrin kò sọ̀rọ̀ nípa ìwọ̀nyí àti àwọn ìbámu ẹ̀kọ́ léráléra àti láìpẹ́ ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Ṣùgbọ́n ìkìlọ àtúnsọ láti múrasílẹ̀ ní a ti kéde látẹnu àwọn olórí Ìjọ fún àwọn ọdún púpọ̀ sẹ́hìn. Ìṣìsẹ̀ntẹ̀lé ti àmọ̀ràn wòlíì ní àkokò ndá mímọ́ kedere alágbára àti oye ìkìlọ aláruwò ju ìṣeré àdákọ tí a le mú jáde.
Bí àwọn àkokò ìpènija ṣe nfi àìlera nínú ìmúrasílẹ̀ ti ara wá, bẹ́ẹ̀ náà ni àìsàn ti ẹ̀mí àìronúsí àti ìtẹ̀lọ́rùn nfa àbájade ohun tó bùrú jùlọ sí wọn ní àsìkò àwọn àdánwò lílè. Fún àpẹrẹ, a kọ́ nínú òwe ti wúndíá mẹwa pé, jíjífara ìmúrasílẹ̀ ndarí sí àìyege ìdánwò. Rántí bí àwọn wundia marun aláìgbọ́n fi kùnà láti múrasílẹ̀ déédé fún ìdánwò tí a fún wọn ní ọjọ́ tí Ọkọ-ìyàwó mbọ̀.
“Àwọn tí ó ṣealáìgbọ́n mú fìtílà wọn, wọn kò mú òróró lọ́wọ́:
“Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n mú òróró nínú kólóbó pẹ̀lú fìtílà wọn. …
Ṣùgbọ́n laarin ọ̀gànjọ́ igbe ta sókè, wípé, Wòó, ọkọ ìyàwó mbọ̀; ẹ jáde lọ̀ pàdé rẹ̀.
“Nígbànáà ni gbogbo àwọn wundia wọnnì dìde, wọ́n sì tún fìtílà wọn ṣe.
“Àwọn aláìgbọ́n sì wí fún àwọn ọlọ́gbọ́n pé, Fún wa nínú òróró yín; nítorí fìtílà wa nkú lọ.
Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n dá wọn ní ohùn, wípé, Bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má ba ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin: ẹ kúkú tọ àwọn tí ntà lọ, kí ẹ sì ra fún ara yín.
Nígbà tí wọ́n sì lọ rà, ọkọ ìyàwó dé; àwọn tí ó sì múra tán bá a wọlé lọ sí ibi ìyàwó: a sì ti lẹ̀kùn.
“Ní ìkẹhìn ni àwọn wundia ìyókù sì dé, wọ́n wípé, Olúwa, Olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.”8
“Ṣùgbọ̀n ó dáhùn wípé, lóòtọ́ ni mo wí fún yín, Ẹ̀yin kò mọ̀ mi .”9
Ó kéréjù lórí ìdánwò yí, àwọn wundia marun aláìgbọ́n fi arawọn hàn bí àwọn olùgbọ́ nìkan kìí ṣe bí olùṣe ọ̀rọ̀ náà.10
Mo ní ọ̀rẹ́ kan ẹnití o jẹ́ aláápọn akẹkọ ní ilé-ìwé òfin. Ní ìgbà abala ìkàwé kan, Sam fi àkokò sílẹ̀ lójojúmọ́ láti ṣàyẹ̀wò, ṣàtúnkọ, àti láti kẹkọ nínú ìwé-àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú èyí tí ó ti forúkọ sílẹ̀. Ó tẹ̀lé irú ètò kannáà fún gbogbo kíláàsì rẹ ní òpin ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ àti oṣooṣù. Ọ̀nà rẹ̀ mú kí ó kọ́ òfin kìí ṣe kíkọ́sọ́rí ní àlàyé lásán. Bí àwọn ìdánwò ìparí ṣe nsúnmọ́, Sam ti múrasílẹ̀. Nítòótọ́, ó ri pé ìdánwò ìparí náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí kò munilómi nínú idanilẹkọ òfin rẹ̀. Ìmúrasílẹ̀ dáadáa àti ní àsìkò nṣíwájú rírí àṣeyege.
Ọ̀nà tí Sam gbà ṣe ẹ̀kọ́ òfin rẹ fi àmìn ọ̀kan lára àwọn ètò alakọbẹrẹ fún ìdàgbà àti ìlọsíwájú hàn. Ní báyìí Olúwa wípé: “Èmi ó fún àwọn ọmọ ènìyàn ní ìlà lórí ìlà, òye lórí òye, díẹ̀ nihin àti díẹ̀ lọ́hun; àti pé alábùkúnfún ni àwọn wọnnì tí wọ́n fetísí òye mi, tí wọ́n sì gbọ́ àmọ̀ràn mi, nítorí wọn yíò kọ́ ọgbọ́n; nítorí fún ẹni tí ó bá gbàá èmi ó fún wọn ní púpọ̀ si.”4
Mo pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti “kíyèsí ọ̀nà [wa]” “wadi [arawa], bóyá [a] wà nínú ìgbàgbọ́; [ àti] fi han [àwa] tìkárawa.” Kíni a kọ́ ní àwọn oṣù àìpẹ wọ̀nyí nípa àtúnṣe ìgbé-ayé àti ìhámọ́? Kíni a nílò láti ṣe kí a lè gbèrú nínú aye wa nìti ẹ̀mí, ti ara, ti àwùjọ, ti ẹ̀dùn ọkàn, àti ti ẹ̀kọ́? Ìsisìyí ni àkokò láti múrasílẹ̀ àti láti dán arawa wò ní ìfẹ́ àti agbára láti ṣe ohun gbogbo eyikeyi tí Olúwa Ọlọ́run wa yíò pàṣẹ fún wa.
Dídánwò àti Títẹ̀ Síwájú
Mo fi ìgbàkan lọ sí ibi ìsìnkú fún ìránṣẹ́ ìhìnrere kékeré kan ẹnití ó kú nínú ìjàmba kan. Baba ìránṣẹ́ ìhìnrere náà sọ̀rọ̀ nínú ìsìn ó sì júwe ìrora ọkàn ti ìyapa ikú àìròtẹ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ olólùfẹ́ ọmọ kan. O kéde lootọ́ pé oùn alára kò ní òye àwọn ìdí tàbí àsìkò fún irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi ó rántí ọkùnrin rere yí nìgbàgbogbo tí ó nkede bákanáà pé òun mọ̀ pé Ọlọ́run mọ ìdí àti àsìkò fún ìkọjá ọmọ rẹ̀—àti pé iyẹ̀n dára tó fún òun. Ó wí fún gbogbo ìjọ pé òun àti ẹbí òun, bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n banújẹ́, yío wà dáadáa; ẹ̀rí wọn dúró ṣinṣin àti gbọingbọin. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìkéde pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé bí ó ti kan ìhìnrere Jesu Krísti, gbogbo ẹbí wa wà nínú rẹ̀. Gbogbo wa wà nínú rẹ̀.”
Bíótilẹ̀jẹ́pé ìsọnù olùfẹ́ ọ̀wọ́n kan jẹ́ ìbanilọ́kànjẹ́ àti ìṣòro, àwọn akọni ọmọ ẹbí yí tí múrasílẹ̀ niti ẹ̀mí láti fi hàn pé wọn lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ayérayé nípasẹ̀ àwọn ohun tí wọ́n ti jìyà.14
Ìṣòdodo kìí ṣe àìlọ́gbọ́n tàbí ajáfáfá. Ṣùgbọ́n, ó jẹ́ gbígbẹ́kẹ̀lé àti gbígbé ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Jésù Krístì bí Olùgbàlà wa, lórí orúkọ Rẹ̀, àti nínú ìlérí Rẹ̀. Bí a ṣe “ntẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, níní ìmọ́lẹ̀ pípé ti ìrètí, àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,”15 a di alábùkúnfún pẹ̀lú ìwò ayérayé àti ìran tí ó tayọ kọjá agbára ayé ikú wa tó lópin. A ó ní okun láti “kórajọ papọ, kí a sì dúró níbi mímọ́”16 kí a “máṣe yẹsẹ̀, títí tí ọjọ́ Olúwa yíò dé.”
Nígbàtí mo nsìn bí ààrẹ ti Yunifásítì Brigham Young–Idaho, Alàgbà Jeffrey R. Holland wá sínú ọgbà ní Oṣù Kejìlá 1988 láti sọ̀rọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìfọkànsìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ wa. Susan àti èmi pe ẹgbẹ́ àwọn akẹkọ kan láti pàdé àti láti bẹ Alàgbà Holland wò ṣíwájú kí ó to fúnni ní ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí àkokò wa papọ̀ ṣe nsúnmọ́ ìparí, mo bèèrè lọ́wọ́ Alàgbà Holland, “Bí ó bá lè kọ́ àwọn akẹkọ wọ̀nyí ní ohun kan péré, kíni yíò jẹ́?”
Ó dáhùn pe:
“À njẹri ìṣípòpadà títóbi jùlọ síwájú ibi. A ó mú àárín àwọn ìjìnlẹ̀ àṣàyàn kúrò lọ́dọ̀ wa gẹ́gẹ́bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. A ó fa àárín ọ̀nà kúrò.
“Bí ẹ bá nrìn lórí omi nínú ìjì odò kan lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹ ó dé ibìkan. Ẹ̀yin ó kàn lọ síbikíbi tí ìjì bá gbée yín lọ ni. Lílọ sí odò, títẹ̀lé ìgbà, yíyíkúrò nínú ìjì kò ní ṣeé.
“A níláti ṣe àṣàyàn. Aìṣe àṣàyàn kan ni yíyàn àṣàyàn kan. Kọ́ láti yàn nísisìyí.”
Gbólóhùn Alàgbà Holland nípa púpọ̀si ibi ni àwọn wòlíì ti ri nípasẹ̀ àwọn ìṣe àwùjọ àti ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún méjìlélógún láti ìgbà tí ó ti dáhùn ìbèèrè mi. Yíyàkúrò àsọtẹ́lẹ gbígbòòrò ní àárín àwọn ọ̀nà Olúwa àti ayé, Alàgbà Hollánd kìlọ̀ pé àwọn ọjọ́ ìtura níní ẹsẹ̀ kan nínú Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò àti ẹsẹ̀ kan nínú ayé ti nparẹ́ kíákíá. Ìránṣẹ́ Olúwa yí ngba àwọn ọ̀dọ́ náà níyànjú láti yàn, múrasílẹ̀, àti lati da ọmọẹ̀hìn olùfọkànsìn Olùgbàlà. Ó nràn wọ́n lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ àti láti tẹ̀síwájú si àti láti ridi, wádi, àti dánwò nípasẹ̀ àwọn ìrírí ìgbé ayé wa.
Ìlérí àti Ẹ̀rí
Ètò fífi ara wa hàn ni ara ìpìlẹ̀ ètò ìdùnnú nla ti Baba Ọ̀run. Mo ṣe ìlérí pé bí a ti njìjọ múrasílẹ̀ tí a sì ntẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà, gbogbo wa lè gba ìwọ̀n kannáà lórí ìdánwò ìgbẹ̀hìn ti ayé ikú: “Káàbọ̀, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́: ìwọ ṣe olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi ó mú ọ ṣe olórí ohun púpọ̀: ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ Olúwa rẹ.”18
Mo jẹri pé Ọlọ́run Baba Ayérayé ni Baba wa. Jésù Krístì ni Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Nìkanṣoṣo àti alààyè, Olùgbàlà wa àti Olùràpadà. Nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni mo jẹ́ẹ̀rí ni orúkọ mímọ́ Olúwa Jésù Krístì, àmín.