Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè, Ìbátan, àti Ahọn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè, Ìbátan, àti Ahọn

A lè di, ara ìmúṣẹ ti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti ìlérí Rẹ̀ Olúwa ní ọ̀nà ti arawa—ara ìhìnrere tó nbùkún ayé.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, láìpẹ́ mo ṣe èdidì nínú tẹ́mpìlì, ní títẹ̀lé àwọn ìtọ́nisọ́nà COVID-19. Pẹ̀lú ìyàwó àti ọkọ, àwọn méjèèjì olóotọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere tó padàdé, ni àwọn òbí wọn àti gbogbo àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò. Èyí kò rọrùn. Ìyàwó ni ìkẹsan lára àwọn ọmọ mẹ́wa. Àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ mẹ́sẹ̀sán jóko lọ́gbọọgba, àgbà dé kékeré.

Ẹbí náà ti wá láti jẹ́ aladugbo rere níbikíbi tí wọ́n bá gbé. Bákannáà, ìletò kan kò ní ìkónimọ́ra—nítorípé, ìyá ìyàwó wípé, ẹbí wọn jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Ẹbí náà ṣe ohun gbogbo láti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ wọn ní ilé-ìwé, fọwọ́si kí wọ́n sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbọ́, ṣùgbọ́n kò já mọ́ nkankan. Ẹbí náà gbàdúrà wọ́n sì gbàdúrà kí ọkan kí ó rọ̀.

Ní àṣálẹ́ kan, ẹbí náà ní ìmọ̀lára pé àdúra wọn ti gbà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà àìròtẹ̀lẹ̀ ni. Ilé wọn gbiná ó sì jó kanlẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun míràn kan ṣẹlẹ̀. Iná yí mú ọkàn àwọn aladúgbo wọn rọlẹ̀.

Àwọn aladúgbò wọn àti ilé-ìwé ìbílẹ̀ kó aṣọ jọ, bàtà, àti awọn ohun lílò míràn nípasẹ̀ ẹbí, tí ó ti sọ ohun gbogbo nu. Inúrere ṣílẹ̀kùn fún òye Kìí ṣe ọ̀nà tí ẹbí nàá ti ní ìrètí tàbí rò pé àdúrà wọn yíò gbà. Bákannáà, wọ́n fi ooré hàn fún ohun tí wọ́n kọ́ nínú àwọn ìrirí líle àti àwọn ìdáhùn sí àìlerò sí àdúrà àtọkànwá.

Nítòótọ́, fún àwọn ọkàn olótítọ́ àti ojú láti rí, ìrọ́nú àánú Olúwa tí ó nfarahàn ní àárín àwọn ìpenijà ayé. Fi òdodo bá àwọn ìpènijà pàdé àti pé ìrúbọ nmú àwọn ìbùkún ọ̀run wá. Nínú ayé ikú yí, a lè sọ ohun nù tàbí dúró fún àwọn ohunkan fún ìgbà kan, ṣùgbọ́n ní òpin a ó rí ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ. 1 Iyẹn ni ìlérí Rẹ̀. 2

Ìkéde igbà ọdún wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ àfikún ìlérí pé “Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ọmọ Rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.” 3 Fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n, àti ènìyàn, 4 àwọn Ìlérí, àwọn májẹ̀mú Ọlọ́run npè wá láti wá ṣe àbápín ọ̀pọ̀ ayọ̀ àti inúrere Rẹ̀.

Ifẹ́ Ọlọ́run sí gbogbo ènìyàn ní a tẹnumọ́ nínú gbogbo ìwé-mímọ́. 5 Ìfẹ́ náà kó májẹ̀mú ti Abraham, ìkójọ àwọn olùfọ́nká ọmọ Rẹ̀, 6 àti ètò ìdùnnú Rẹ̀ papọ̀.

Nínú agbo-ilé ìgbàgbọ́ kò sí àwọn àjèjì, kò sí àlejò, 7 kò sí ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, 8 kò sí àwọn “ẹlòmíràn” níta. Gẹ́gẹ́bí “ọmọlàkejì pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́,” 9 a pè wá láti yí ayé padà fún rere, láti inú sí ìta, ẹnìkan, ẹbí kan, aladugbo kan ní ìgbà kan.

Èyí nṣẹlẹ̀ nígbàtí a bá gbé tí a sì npín ìhìnrere. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àkokò iṣẹ́ ìríjú yí, Wolíì Joseph gba ìfihàn alámì pé Baba Ọ̀run nfẹ́ kí ènìyàn gbogbo níbi gbogbo wá ìfẹ́ Ọlọ́run rí kí wọ́n sì ní ìrírí agbára Rẹ̀ láti dàgbà àti láti yípadà.

Ilé àwọn Smith

Ìfihàn náà ni a gbà nihin, níbí ilé igi ẹbí Smith ní Palmyra, New York. 10

Alàgbà àti Arábìnrin Gong nínú ilé Smith

A tun ilé àwọn Smith kọ́ ní orí ìpìnlẹ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀, a ṣetán ní 1998. Ilé olókè yàrá-ibùsùn kejì gba ìṣísẹ̀ 18- nípa 30- nípa 10-foot (5.5 nípa 9 nípa 3m) ní ti ààyè ibití Mórónì gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ológo látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ti wá sọ́dọ̀ Joseph kékeré ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́ Kọkànlélógún Oṣù Kẹsan,1823. 11

Ẹ rántí ohun tí Wòlíì Joseph tún sọ:

“[Mórónì] wípè … Ọlọ́run ní iṣẹ́ kan fún mi láti ṣe; àti pé a o gbọ́ orúkọ mi fún rere àti ibi ní àárín gbogbo orílẹ-èdè, ìbátan àti ahọ́n. …

“Ó wipé ìwé kan wà tí a kó pamọ́, … pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhìnrere àìlópin ni ó wà nínú rẹ̀.” 12

Nihin ni a dawọ́dúró. A njọ́sìn Ọlọ́run Baba Ayérayé àti Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì, kìí ṣe Wòlíì Joseph tàbí ọkùnrin tàbí obìnrin ayé ikú kankan.

Síbẹ̀síbẹ̀ ro bí Ọlọ́run ti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ó fún àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ ṣẹ. 13 Àwọn kan ní a tètè múṣẹ, àwọn kan lẹ́hìnwá, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ ni a múṣẹ. 14 Bí a ti nfetísílẹ̀ sí ẹ̀mí àsọtẹ́lẹ̀ Olúwa, a lè di, ara ìmúṣẹ ti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti ìlérí Rẹ̀, ní ọ̀nà ti arawa—ara ìhìnrere tó nbùkún ayé.

Ní 1823, Joseph jẹ́ ọ̀dọ́mọdé aláìmọ̀ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tí ó ngbé ní ìletò àìlajú kan ní orílẹ̀-èdè titun olómìnira. Àyàfi tí ó bá jẹ́ òtótọ́, báwo ni òun yíò ṣe ronú pé òun yíò jẹ́ ohun èlò nínú iṣẹ́ Ọlọ́run àti láti yí ọ̀rọ̀ padà nípasẹ̀ ẹ̀bùn Ọlọ́run àti agbára àwọn ìwé mímọ́ tí yíò di mímọ́ níbi gbogbo?

Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí ó jẹ́ òtítọ́, ẹ lè jẹ́ri àsọtẹ́lẹ̀ pé a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ àní bí a ti pè wá láti ṣèrànwọ́ láti mu wá sí ìmúṣẹ.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, kàákiri ayé, ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa tí wọ́n nkópa nínú ìpàdé àpàpọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020 wà ní àárín orílẹ̀-èdè, ìbátan, àhọ́n tí a sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀.

Ní òní, àwọn ọmọ ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ngbé ní ìgba-o-dín-mẹ́rin àwọn orílẹ̀-èdè àti ìgbèrìko, pẹ̀lú àwọn èèkan Ìjọ 3,446 ní àádọ́rin wọn. 15 Awa ṣojú okun gbogbo ìbú àti àringbùngbun ayé méjèèjì.

Ní 1823, tani yíò rònú pé ní 2020 àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta yíò wà pẹ̀lú míllíọ́nù ó lé àwọn ọmọ Ìjọ yí ní—United State, Mexico, àti Brazil?

Tàbí orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ogọrun ọmọ Ìjọ—mẹ́ta ní Àríwá Amẹ́ríkà, mẹ́rìnlá ní Àringbùgbun àti Gúsù Amẹ́ríkà, ọ̀kan ní Europe, mẹ́rin ní Asia, àti ọ̀kan ní Afríkà? 16

Ààrẹ Russell M. Nelson pe Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní “Iṣẹ́ ìyanu yíyanilẹ́nu kan.” Ó jẹ́ ẹ̀rí tí a jẹri, “Kí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n àti ènìyàn kí ó mọ̀.” 18 Ní òní, ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò wà ní àwọn èdè ọgọrun. Ààrẹ Nelson ti jẹri nípa Jésù Krístì àti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè mẹtalelàádóje, ò ṣì npọ̀si.

Bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún marun ẹ̀da àkọ́kọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí a tẹ̀ ní 1830, àwọn ẹ̀dà míllíọ́nù 192 ti gbogbo tàbí ara Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni a ti tẹ̀ jádé ní àwọn èdè méjìléláàdọ́fà. Àyípada-èdè Ìwé ti Mọ́mọ́nì wà káàkiri lórí díjítà bákannáà. Ìyírọ̀padà Ìwé ti Mọ́mọ́nì lọ́wọ́lọ́wọ́ wà pẹ̀lú àwọn èdè àgbáyé mẹ́tàlélógún tí à nsọ látẹnu àwọn àádọ́ta míllíọ́nù àwọn ènìyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, lápapọ̀ àwọn èdè àbínibí ti àwọn ọ̀kàn-lé-ní-bíllíọ́nùmẹ́rin ènìyàn.

Nípa ohun kékeré àti ìrọ̀rùn—nínú èyí tí a pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti kópa—ní àwọn ohun nlá tí nwá sí ìmúṣẹ.

Fún àpẹrẹ, ní ìpàdé àpapọ̀ èèkan ní Monreo, Utah, olùgbé 2,200, mo bèèrè pé àwọn melo ní ó ti sìn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́. Bí gbogbo ọwọ́ ní ó lọ sókè. Ní àwọn ọdún àìpẹ́, látinú èèkan kan, àwọn 564 ìránṣẹ́ ìhìnrere ti sìn ní gbogbo ìpínlẹ̀ àádọ́ta ní U.S. àti orílẹ̀-èdè mẹ́ta lé ní àádọ́ta—ní gbogbo ilẹ̀-ayé yàtọ̀ sí Antarctica.

Sísọ̀rọ̀ Antarctica, àní ní Ushuaia ní òkè gúsù ti Argentina, mo rí àsọtẹ́lẹ̀ tí ó nw´a sí ìmúṣẹ bí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa ti nṣe àbápín ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jesù Krístì ní ibìkan tí à npè ní “òpin ilẹ̀ ayé.” 20

Múràl tí a ṣe nípasẹ̀ ìwọn-ìwé àwọn Enìyàn Mímọ́

Múrà tí ó bo àtẹ̀jádé wa mẹ́rin ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ mọ́lẹ̀ 21 fi àyíká gbogbo ayé hàn nípa èso gbígbé ìhìnrere tí ó mbọ̀ wá sọ́dọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ níbigbogbo. Ìtàn Ìjọ ni ó dálé gbígbé nínú ẹ̀rí àti ìrìnàjò ìhìnrere ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú Mary Whimer, arábìnrin olóòótọ́ enití Mórónì fi àwo Ìwé ti Mọ́mọ́nì hàn. 22

Ìròhìn Titun Ìjọ

Ní Oṣù Ìkínní 2021 tí ó mbọ̀, ìwé ìròhìn Ìjọ àgbáyé titun mẹ́ta— Fríẹ́ndì, Fún Okun Ọ̀dọ́, àti Làìhónà—pe gbogbo ènìyàn làti wà pẹ̀lú kí wọn sì pín àwọn ìrírí àti ẹ̀rí nínú ìletò ìgbàgbọ́ ti gbogbo ayé. 23

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a ṣe nmú ìgbàgbọ́ wa nínú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì pọ̀si, tí à ngba àwọn ìbùkún tí a rí nínú gbígbé òtítọ́ ìmúpadabọ̀sípò ìhìnrere àti àwọn májẹ̀mú mímọ́, tí a nṣe àṣàrò, jíròrò, àti ṣe àbápín nípa Ìmúpadàbọ̀sípò tí ó nlọ lọ́wọ́, à nkópa nínú mímúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀.

À nyí arawa padà àti ayé nínú àwòṣe ìhìnrere tí ó nbùkún àwọn ìgbé ayé nibigbogbo.

Arábìnrin Áfríkà kan wípé, “Iṣẹ́-ìsìn oyè-àlùfáà ọkọ mi mú u ní sùúrù àti inú rere si. Mo sì ndi ìyàwó rere àti iyá si.”

Gbajúmọ̀ ìsisìyí kan oníṣòwò àgbáyé ní Àringbùngbun Amẹ́ríkà wípé ṣíwájú kí òun tó ṣàwárí ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Ọlọ́run, òun ngbé láìní-ìrètí ní àdúgbò. Nísisìyí òun àti ẹbí rẹ̀ ti rí ìdánimọ̀, èrèdí, àti okun.

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní Gúsù Amẹ́ríkà ntọ́jú àwọn adìyẹ ó sì ntà àwọn ẹyin wọn láti ṣèrànwọ́ láti ra fèrèsé fún ilé tí àwọn ẹbí rẹ̀ nkọ́. Ó kọ́kọ́ san idamẹwa rẹ̀. Òun ó rí fèrèsé ọ̀run ní ṣíṣí bí ọ̀rọ̀.

Ní Igun Mẹ́rin, ní gúsù-ìwọ̀oòrùn United States, ẹbí abínibí Amẹ́ríkà kan ntọ́ òdòdó kan tórẹwà láti dàgbà nínú aṣálẹ̀, àmì ìhìnrere ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni.

Ẹnikan tó kù nínú ìkorò ogun abẹ́lé, arákùnrin kan ní Gúsù-ìlàoòrùn Asia fi aìnírètí wípé ayé kò nítumọ̀. Ó rí ìrètí nínú àlá kan nínú èyí tí ẹlẹgbẹ́ kíláàsì rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti di tíréè oúnjẹ Olúwa mú tí ó sì jẹri nípa àwọn ìlànà ìgbàlà àt Ètùtù Jésù Krístì.

Baba Ọ̀run pè wá nibigbogbo láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀, láti kọ́ àti láti dàgbà nínú ẹ̀kọ́, iṣẹ́ ọlọ́lá, iṣẹ́-ìsìn ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni, àti àwọn àwòṣe ìnúrere àti ìdùnnú tí a rí nínú ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ.

Gẹ́gẹ́bí a ti nwá láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nígbàmíràn nípa ẹ̀bẹ̀ nínú òkùnkùn-biri, àdáwà gidi, àwọn àkokò àìní ìdánilójú, à kọ́ pé Òun mọ̀ wá dáradára Ó sì fẹ́ràn wa ju bí a ṣe mọ̀ tàbí fẹ́ràn ara wa.

Èyí ni ìdí tí a fi nílò ìrànlọ́wọ́ láti dá ìdáláre pípẹ́, ìbámu, ìdára, àti àláfíà nínú ilé àti ìletò wa. Òtítọ́ jùlọ, ìjìnlẹ̀ jùlọ, àlàyé òtítọ́ jùlọ, ibi, àti wíwà-pẹ̀lú wa nwá nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára ìràpadà ìfẹ́, wá oore-ọ̀fẹ́ àti iṣẹ́ ìyànu nípasẹ̀ Ètùtù Ọmọ Rẹ̀, àti gbígbé àwọn ìbáṣepọ̀ pípẹ́ kalẹ̀ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́.

Ẹ̀sìn ìwàrere àti ọgbọ́n ni a nílò ní òde-òní tí ó kún fún, aruwo, ìbàjẹ́ ayé. Báwo ni a tún ṣe lè yí, ìmísí padà kí a sì gbé ẹ̀mí ẹlẹ́ran-ara ga?

Gbígbin àwọn igi ní Haiti
Gbígbin àwọn igi ní Haiti
Gbígbin àwọn igi ní Haiti

Gbígbin àwọn igi ní Haiti ni ohun kan ní àárín àwọn àpẹrẹ ọgọrun àwọ́n ènìyàn tí wọ́n nwá papọ̀ láti ṣe rere. Ìletò ìbílẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọmọ Ìjọ 1,800, èyí tí wọ́n fúnni ní igi, kórapọ̀ láti gbin ẹgbẹ́run marundinlọgbọn igi. 25 Iṣẹ́ igi gbíngbìn ọ̀pọ̀-ọdún yí ti gbin àwọn igi 121,000 ó lé tẹ́lẹ̀. Ó nfojúsọ́nà sí gbígbin àwọn ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún mẹ́wa si.

Ìtiraka ìrẹ́pọ̀ yí npèsè iboji, ó ntọ́jú erùpẹ̀, ó nmú àgbàrá ọjọ́-ọ̀la kúrò Ó nmú àwọn ipò-àdúgbò rẹwà si, ó nkọ́ ìletò, ó ntẹ́ ìtọ́wò lọ́rùn, ó sì nṣìkẹ́ ẹ̀mí. Bí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ ará Haiti ẹnití yíò kórè èso látinú àwọn igi wọ̀nyí, wọn nwípé, “Ẹnikẹ́ni tí ebi npa.”

Ìpín ọgọrin ti olùgbé ayé ni wọ́n wà pẹ̀lú ẹ̀sìn. 26 Àwọn ìletò ẹlẹ́sìn nfèsì sí àwọn àìní kíákíá lẹ́hìn àjálù, bákannáà bí àwọn àìní líle fún oúnjẹ, ilé-lórí, ẹ̀kọ́, ìmọ̀wé, àti idanilẹkọ iṣẹ́. Káàkiri ayé, àwọn ọmọ ìjọ wa, ọ̀rẹ́, àti Ìjọ nran àwọn ìletò lọ́wọ́ láti ti àwọn asásalà lẹ́hìn àti láti pèsè omi, ìmọ́tótó, ohun-ìrìn-abirùn, àti ìtọ́jú ojú—ẹnìkan, abúlé kan, igi kan ní àkokò kan. 27 Níbigbogbo, a nwá láti jẹ́ obí rere àti ọmọ-ìlú rere, láti lọ́wọ́sí ipò-àdúgbò àti àwùjọ wa. 28

Ọlọ́run fún wa ní ìwà agbára láti yàn—àti ìwà ìṣirò. Olúwa kéde pé, “Èmi, Olúwa Ọlọ́run, fún yín ní òmìnira, nítorínáà ẹ di òmìnira nítòótọ́.” 29 Ní kíkéde “ìtúsílẹ̀ sí àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn,” 30 Olúwa ṣe ìlérí pé Ètùtù Rẹ̀ àti ipa-ọ̀nà ìhìnrere yíò já ìdè ti-ẹ̀mí àti ti ara. 31 Pẹ̀lú àánú, òmìnira ìràpadà yí nà sí àwọn ẹnití wọ́n ti kọjá lọ nínú ayé ikú.

Àwọn ọdún kan sẹ́hìn, àlùfáà kan ní àringbùngbun Amẹ́ríkà wí fún mi pé òun tí ṣe àṣàrò lórí “ìrìbọmi fún àwọn ẹni tókú” àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. “Ó kàn dàbí ẹnipé,” àlùfáà náà wí, “pé Ọlọ́run yíò fún gbogbo ènìyàn ní ànfàní láti gba ìrìbọmi, eyikeyi ìgbà tàbí ibi tí wọ́n ngbé, yàtọ̀ sí àwọn ọmọdé, tí wọ́n ‘wà ní ààyè nínú Krístì.’ 32 Àpóstélì Páùlù,” àlùfáà náà ṣe àkíyèsí, “ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn òkú tí wọ́n ndúró de ìrìbọmi àti ajinde.” 33 Àwọn ìrọ́pò ìlànà tẹ́mpìlì ṣe ìlérí pé “gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, àti èdè” tí ẹnìkan kò nílò “dúró bí ẹ̀rú sí òkú, ti àpáàdì, tàbí ti bojì.”

Bí a ṣe nwá Ọlọ́run rí, nígbàmíràn àwọn ìdáhùn àìrotẹ́lẹ̀ sí àdúrà wa nmú wa kúrò ní àdúgbò, ó nmú wá sá sí ìletò, ó nlé òkùnkùn kúrò nínú ọkàn wa, ó sì ntọ́ wa sọ́nà láti rí ààbò ti-ẹ̀mí àti wíwá pẹ̀lú nínú ìwàrere àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ àti gbígbé nínú ifẹ́.

Àwọn ohun nlá nbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun kékeré nígbàkugbà, ṣùgbọ́n àwọn iṣẹ́-ìyanu Ọlọ́run nfarahàn lójojúmọ́. Bí a ti fi ìmoore hàn fún ẹ̀bùn títayọ Ẹ̀mí Mímọ́, Ètùtù Jésù Krístì, àti ẹ̀kọ́ tí a fihàn, àwọn ìlànà, àti àwọn májẹ̀mú tí a rí nínú ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Rẹ̀, tí a pè ní orúkọ Rẹ.

Njẹ́ kí a fi ayọ̀ tẹ́wọ́gba ìpè Ọlọ́run láti gbà àti láti ṣèrànwọ́ mú ìlérí àti àwọn ìbùkún àsọtẹ́lẹ̀ Rẹ̀ ṣẹ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, àti ahọ́n, ni mo gbàdúrà ní orúkọ ọ̀wọ̀ àti mímọ́ Jésù Krístì, Amín.