Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Tẹramọ́ Yíyípadà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Pa Ìyípadà Náà Mọ́

Nípasẹ̀ Jésù Krístì, a fún wa ní okun láti ṣe ìyípada pípẹ́. Bí a ṣe nyí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Òun ó mú àlékún bá agbára wa láti yípadà.

Ẹ̀yin arábìnrin, ó jẹ́ ayọ̀ kan láti wà pẹ̀lú yín!

Sísan owó ọja kan

Rònú nípa ẹnìkan tó nlọ sí ọjà kan láti ra ohun kan. Tí ó bá sanwó fún akápò ju oye tó yẹ fún ohunkan, akápò yíò fun ní ṣénjì.

Gbígb ṣénjì

Ọba Bẹ́njámìn kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Amẹ́ríkà àtijọ́ nípa àwọn ìbùkún nlá tí a ngbà láti ọwọ́ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Ó dá àwọn ọ̀run àti ayé àti gbogbo ẹwà tí a ngbádùn sílẹ̀.1 Nípasẹ̀ ìfẹ́ni Ètùtù Rẹ̀, Ó pèsè ọ̀nà fún wa láti ní ìràpadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.2 Bí a ti nfi ìmoore wa hàn sí I nípa fífi aápọn gbé ìgbé ayé àwọn òfin Rẹ̀, Òun lójúkannáà nbùkún wa, ní fífi wá sílẹ̀ nígbà gbogbo nínú gbèsè Rẹ̀.

Ó nfúnwa ní púpọ̀, púpọ̀ síi ju iye ohun tí a le dá padà fún Un láe. Nítorínáà, kinni a le fi fún Un, ẹnití ó san gbèsè àìdíyelé fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa? A lè fún Un ní ìyípada. A lè fún Un ní ìyípada wa. Ó le jẹ́ ìyípadà èrò, ìyípadà nínú ìwà bárakú, tàbí ìyípadà nínú ìhà ibi tí a kọrí sí. Ní ìpadàbọ̀ fún ìsanwó àìlónkà Rẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa, Olúwá bèèrè fún ìyípadàọkàn wa. Ìyípada tí Ó bèèrè lọ́wọ́ wa kìí ṣe fún èrè Rẹ̀ ṣùgbọ́n fún tiwa. Nítorínáà, láìdàbíi olùrajà ní ọjà tí yíò mú ṣénjì tí a fúnni padà,Olùgbàlà onínúre wa npè wá láti tẹramọ́ yíyípadà.

Lẹ́hìn gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ sísọ láti ẹnu Ọba Benjámínì, àwọn ènìyàn rẹ̀ kígbe sókè, ní kíkéde pé ọkàn wọn ti yípadà wí pe, “Nítorí Ẹ̀mí Olúwa Alèwílèṣe, tí ó ti ṣe ìyípadà nlá nínú wa, … àwa kò ní ẹ̀mí àti ṣe búburú mọ́, ṣùgbọ́n láti máa ṣe rere títí.”3 Àwọn ìwé mímọ́ kò sọ pé wọ́n di pípé lójúkannáà; bíkòṣepé, ìfẹ́ inú wọn láti yípadà fi ipá mú wọn láti gbé ìgbésẹ̀. Ìyípadà ọkàn wọn túmọ̀ sí bíbọ́ ẹran ara ọkùnrin tàbí ti obìnrin kúrò àti láti gbà sí Ẹ̀mí bí ẹ ti ntiraka láti dà bíi Jésù Krístì síi.

Ààrẹ Henry B. Eyring kọ́ni pé: “Ìyípadà ọkàn tòótọ́ dá lé fífi ìrọ̀rùn lépa nínú ìgbàgbọ́, pẹ̀lú akitiyan nlá àti ìrora díẹ̀. Nígbànáà Olúwa ni ẹni náà tí fúnni … ìyanu ti ìwẹ̀númọ́ àti ìyípadà.”4 Ní dída akitiyan wa pọ̀ pẹ̀lú agbára ti Olùgbàlà láti yí wa padà, a ndi ẹ̀dá tuntun.

Nígbàtí èmi kò tíi dàgbà, mo wo ara mi tí nrìn ní ipa ọ̀nà to lọ́ sókè, ní nínà dúró sí ìhà ìfojúsùn mi sí ìyè ayérayé. Ní ìgbàkigbà tí mo bá ṣe tàbí sọ ohun kan tí kò dára, mo nní ìmọ̀lára pé mo nyọ̀ lọ sísàlẹ̀ ipa ọ̀nà náà, láti tún bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò mi lákọtun lẹ́ẹ̀kansíi. Ó dàbí sísọ̀kalẹ̀ sí orí onígun mẹ́rin kan nínú eré àwọn ọmọdé Chutes and Ladders tí ó máa nyọni sísàlẹ̀ láti òkè ténté bọ́ọ̀dù padà sí ìbẹ̀rẹ̀ eré náà! Ó jẹ́ ohun ìrẹ̀wẹ̀sì! Ṣùgbọ́n bí mo ti bẹ̀rẹ̀sí ní òye ohun tí Néfì pè ní ẹ̀kọ́ Krístì5 àti bí mo ti le mú un lò ní ojoojúmọ́ nínú ìgbé ayé mi, mo rí ìrètí.

Ètò yípadà náà pẹ̀lú ìfaradà

Jésù Krístì ti fúnwa ní àwòrán àìlópin kan fún ìyípadà. Ó npè wá láti lo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, èyí tí ó nmísí wa láti ronúpìwàdà—”ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà èyí tí ó nmú ìyípadà ọkàn wá.”6 Bí a ti nronúpìwàdà tí à nyí ọkàn wa padà sí I, à njèrè ìfẹ́ inú títóbi si láti dá àti láti gbé ìgbé ayé májẹ̀mú mímọ́. A ni ìfaradà dé òpin nípa títẹ̀síwájú láti lo àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí nínú gbogbo ìgbé ayé wa àti pípe Olúwa láti yí wa padà. Fífi ara dà dé òpin túmọ̀ sí yíyípadà dé òpin. Ó ti yé mi nísisìyí pé èmi kò ní bẹ̀rẹ̀ lákọtun pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbìyànjú tó kùnà, ṣùgbọ́n pé pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbìyànjú, mo ntẹ̀síwájú ìgbésẹ̀ ìyípadà mi.

Àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ onímisí kan wà nínú àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó sọ pé, “Mo ṣìkẹ́ ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà mo sì nlépa láti ṣe àtúnṣe ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.”7 Mo gbàdúrà pé kí a ṣìkẹ́ ẹ̀bùn rírẹwà yí àti pé kí ó jẹ́ ifẹ́ inú wa ní lílépa ìyípadà. Nígbàmiràn àwọn àyípadà tí a nílò láti ṣe máa nní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wúwo. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a ntiraka láti tún ìwà wa ṣe láti mú ara wa wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àbùdá ti Jésù Krístì. Àwọn yíyàn wa ojojúmọ́ yio ṣe ìrànlọ́wọ́ tàbí ìfàsẹ́hìn fún ìtẹ̀síwájú wa. Àwọn àyípadà àmọ̀ọ̀mọ́ kékèké, ṣùgbọ́n dídúróṣinṣin, yío ràn wá lọ́wọ́ láti gbèrú. Ẹ máṣe di rírẹ̀wẹ̀sì. Ìyípadà jẹ́ ìlànà kan títí gbogbo ìgbé ayé. Mo ní ìmoore pé nínú àwọn ìtiraka wa láti yípadà, Olúwa ní sùúrù pẹ̀lú wa.

Nípasẹ̀ Jésù Krístì, a fún wa ní okun láti ṣe ìyípada pípẹ́. Bí a ṣe nyí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Òun ó mú àlékún bá agbára wa láti yípadà.

Ní àfikún sí agbára ìyínipadà ti Ètùtù Olùgbàlà wa, Ẹ̀mí Mímọ́ yio tì wá lẹ́hìn yío sì tọ́wa bí a ti nṣe akitiyan wa. Ó tilẹ̀ le ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú àwọn àyípadà tí a nílò láti ṣe. A le rí ìrànlọ́wọ́ àti ìgbani-níyànjú bákannáà nípasẹ̀ àwọn ìbùkún oyè àlùfáà, àdúrà, ààwẹ̀, àti lílọ sí tẹ́mpìlì.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn mọlẹ́bí tí a gbẹ́kẹ̀lé, àwọn olórí, àti àwọn ọ̀rẹ́ tí a ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí le ṣe ìrànwọ́ nínú àwọn akitiyan wa láti yípadà. Nígbàtí mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ, arákùnrin mi àgbà, Lee, àti èmi máa nlo àsìkò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa ní síṣeré nínú àwọn ẹ̀ka igi àdúgbò kan. A fẹ́ràn wíwà papọ̀ nínú àjùmọ̀ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa ní abẹ́ òjìji igi náà. Ní ọjọ́ kan, Lee ṣubú kúrò lórí igi náà ó sì kán apá rẹ̀. Níní apá kíkán kan mú kí ó le fún un láti gun igi náà fúnra ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ayé lórí igi lásán kò rí bákannáà láìsí òun níbẹ̀. Nítorínáà díẹ̀ nínú wa ṣe ààbò fún un látẹ́hìn nígbàtí àwọn miràn fa apá rẹ̀ tí ó dára, àti pé láìsí akitiyan púpọ̀ lọ títí, Lee padà wà nínú igi náà. Apá rẹ̀ ṣì kán síbẹ̀, ṣùgbọ́n ó wà pẹ̀lú wa lẹ́ẹ̀kansíi tí ó ngbádùn ìbáṣọ̀rẹ́ wa bi apá rẹ̀ ti nsan.

Mo ti fi ìgbà gbogbo ronú nípa ìrírí mi ní ti síṣeré nínú igi náà bíi jíjẹ́ irú iṣe ìdárayá kan nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì. Nínú òjìji àwọn ẹ̀ka ìhìnrere, a ngbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú wa. Àwọn kan le ti ṣubú kúrò ní ibi ààbò àwọn májẹ̀mú wọn kí wọn ó sì nílò ìrànlọ́wọ́ wa ní gígòkè padà sínú ààbò ti ìhìnrere. Ó le ṣòro fún wọn láti padà wá fúnra ara wọn. Njẹ́ a le fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fà wọ́n díẹ̀ níhĩn kí a sì tì wọ́n sókè díẹ̀ lọ́hũn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ gba ìwòsàn nígbàtí wọ́n ó máà gbádùn ìbáṣọ̀rẹ́ wa?

Bí o bá njìyà ìfarapa kan láti ìṣubú kan, jọ̀wọ́ fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ padà sí àwọn májẹ̀mú rẹ àti àwọn ìbùkún tí wọ́n fi lélẹ̀. Olùgbàlà le ràn yín lọ́wọ́ rí ìwòsàn àti láti yípadà nígbátí àwọn tó fẹ́ràn yín bá yí yín ká.

Ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan mo máa npàdé àwọn ọ̀rẹ́ tí èmi kò ti rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Nígbà míràn wọn sọ pé, “Iwọ kò tíì yípadà rárá!” Ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá gbọ́ bẹ́ẹ̀ mo máa nsúnrakì díẹ̀, nítoripé mo nírètí pé mo ti yípadá nínú àwọn ọdún. Mo nírètí pé mo ti yípadà láti àná! Mo nírètí pé mo ti ní àánú díẹ̀ síi, pé mo dínkù ní dídájọ́, áti pé mo ní ìyọ́nú síi. Mo nírètí pé mo nyára síi láti dáhùn sí àìní àwọn ẹlòmíràn, mo sì ní ìrètí pé mo kàn ní sùúrù kékeré díẹ̀ síi.

Mo fẹ́ràn rírìn ní orí òkè kan ní ẹ̀bá ilé mi. Ní ìgbà púpọ̀, mo nní òkúta kékeré kan nínú bàtà mi bí mo ti nrìn ní ipa ọ̀nà náà. Nígbẹ̀hìn, mo ndúró èmi ó sì gbọn bàtà mi nù Ṣùgbọ́n ó máa nyàmílẹ́nu bí ó ṣe pẹ́ tó tí mo fi ààyè gba ara mi láti rìn nínú ìrora kí ntó dúró láti mú ìnira náà kúrò.

Bí a ti nrin ìrìnàjò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, nígbàmíràn a ngbé àwọn òkúta nínú àwọn bàtà wa bíi àwọn ìwà bárakú tí kò dára, àwọn ẹ̀ṣẹ̀, tàbí àwọn ìhùwàsí burúkú. Bí a bá ṣe gbọ̀n wọ́n nù kíákíá kúrò nínú ìgbé ayé wa sí, bẹ́ẹ̀ ni ìrìn àjò wa ní ayé ikú yío ṣe jẹ́ aláyọ̀ sí.

Mímú ìyípadà ró ngba akitiyan. Èmi kò le ronú dídúró ní ojú ipa ọ̀nà náà àní láti fi òkúta kékeré tí ó nbíni nínú tí ó sì ndunni náà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mú kúrò padà sí inú bàtà mi. Èmi kò ní fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ rárá ju bí arẹwà labalábá kan yío ti yàn láti padà sí ibi ìbora rẹ̀ lọ.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé nítorí Jésù Krístì, a le yípadà. A le ṣe àtúnṣe àwọn ìwà bárakú wa, kí a tún àwọn èrò wa tò, kí a sì mú àwọn ìhùwàsí wa dára síi láti dà bí Rẹ̀ síi Àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, a lè pa ìyípadà náà mọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.