Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Jẹ́ kí Sùúrù Ṣe Àṣepé Iṣẹ́ Rẹ̀, ẹ sì Ka Gbogbo Rẹ̀ Sí Ayọ̀!
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ẹ Jẹ́ kí Sùúrù Ṣe Àṣepé Iṣẹ́ Rẹ̀, ẹ sì Ka Gbogbo Rẹ̀ Sí Ayọ̀!

Nígbàtí a bá lo sùúrù, ìgbàgbọ́ wa npọ̀si. Bí ìgbàgbọ́ wa ti npọ̀si, bẹ́ẹ̀ náà ni ayọ̀ wa.

Ní ọdún méjì sẹ́hìn, àbúrò mi ọkùnrin tó kéré jùlọ, Chad, gbésẹ̀ la ìbòjú kọjá. Ìpapòdà rẹ̀ sí òdìkejì fi ihò kan sí inú ọkàn ìyàwó àbúrò mi, Stephanie, àwọn ọmọ wọn kékèké méjì, Brayden àti Bella; bẹ́ẹ̀ náà sì ni ará ìyókù nínú ẹbí. A rí ìtùnú nínú àwọn ọ̀rọ̀ Alàgbà Neil L. Anderson nínú ìpàdé gbogbogbò ti ọ̀sẹ̀ tó ṣaájú ikú Chad pé: “Nínú koto àwọn àdánwò ilẹ̀ ayé, fi sùúrù sún síwájú, àti pé agbára ìwòsàn ti Olùgbàlà yío mú ìmọ́lẹ̀, òye, alàáfíà, àti ìrètí wá fún ọ” (“Tí a Palára,,” Liahona, Nov. 2018, 85).

Chad Jaggi àti ẹbí

A ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì; a mọ̀ pé a ó tún darapọ̀ mọ́ Chad lẹ́ẹ̀kansíi, ṣùgbọ́n pípàdánù àfojúrí wíwà rẹ̀ dunni! Ọpọ̀lọpọ̀ ní ó ti pàdánù àwọn olùfẹ́. Ó lè le láti ní sùúrù kí a sì dúró fún àkókò náà tí a ó tún darapọ̀ mọ́ wọn.

Ní ọdún lẹ́hìn tí ó kú, a ní ìmọ̀lára bí ẹnipé ìkũkù ti òkùnkùn kan bò wá mọ́lè. A wá ààbò nínú ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ wa, gbígba àdúrà pẹ̀lú ìtara, àti lílọ sí tẹ́mpìlì léraléra síi. Àwọn ìlà láti inú orin ìsìn yi gbé àwọn ìmọ̀lára wa ní àkókò náà: “Ojúmọ́ ọjọ́ ti nmọ́, ayé ti njí, àwọn ikũku ti òkunkùn òru ti nsá lọ” (“Ojúmọ́ Ọjọ́ Ti Nmọ́,” Àwọn Orin, orin 52).

Ẹbí wa ṣe ìpinnu pé 2020 yío jẹ́ ọdún kan fún ìtúnṣe okun! A nṣe àṣàrò ẹ̀kọ́ Wá, Tẹ̀lé Mi wa nínú ìwé Jákọ́bù ti Májẹ̀mú Titun ní ìhà òpin Oṣù kọkànlá 2019 nígbàtí àkòrí kan fi ara rẹ̀ hàn sí wa. Jákọ́bù orí 1 ẹsẹ 2 kà pé, “Ẹyin ará mi, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀ nígbàtí ẹ̀yin bá ṣubú sínú àwọn ìpọ́njú púpọ̀” (Ìyírọ̀padà ti Joseph Smith, Jákọ́bù 1:2 [nínú Jákọ́bù 1:2àkọsílẹ̀-ìsàlẹ̀ a]). Nínú ìfẹ́ inú wa láti ṣí ọdún tuntun, dẹ́kéèdì titun, pẹ̀lú ayọ̀, a pinnu pé ní 2020 a ó “ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.” A ní ìmọ̀lára tí ó le tóbẹ́ẹ̀ nípa rẹ̀ tí ó jẹ́ pé ní Kérésìmesì tí ó kọjá a ṣe ẹ̀bùn àwọn T-sẹ́ẹ̀tì fún àwọn ọmọ òbí wa tí ó sọ pẹ̀lú àwọn lẹ́tà títóbi pé, “Ka Gbogbo Rẹ̀ Sí Ayọ̀.” Dájúdájú ọdún 2020 yío jẹ́ ọdún ayọ̀ àti dídun inú.

Ó dára, àwa nìyí—dípò bẹ́ẹ̀ 2020 mú àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19, àìsinmi abẹ́lé, àti àwọn ìpèníjà ọrọ̀ ajé wá sí àgbáyé. O le jẹ́ pé Baba wa Ọrun nfún wa ní àkókò láti ronú kí a sì ṣe àgbéyẹ̀wò òye wa nípa sùúrù àti ìpinnu àtinúwá wa láti yan àyọ̀.

Ìwé ti Jákọ́bù ti ní ìtumọ̀ tuntun kan síwa láti ìgbà náà. Jákọ́bù ori 1 ẹsẹ 3 àti 4 tèsíwájú:

“Ní mímọ̀ èyí, pé ìdánwò ìgbàgbọ́ yín nṣiṣẹ́ sùúrù.

“Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù ṣe iṣẹ́ àṣepé rẹ̀, kí ẹ̀yin ó lè jẹ́ pípé àti àìlábùkú, kí ó má sì ku ohun kan.”

Nínú àwọn akitiyan wa láti rí ayọ̀ ní ààrin àwọn àdánwò wa, a ti gbàgbé pé níní sùúrù jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí jíjẹ́kí àwọn àdánwò wọnnì ṣiṣẹ́ fún rere wa.

Ọba Benjamin kọ́ni láti gbé ènìyàn ẹlẹ́ran ara kúrò kí a sì di “ènìyàn mímí kan nípasẹ̀ ètùtù Krísti Olúwa, tí ó sì [dà] bí ọmọdé, onítẹríba, oníwà-tútù, onírẹ̀lẹ̀, onísùúrù, kíkún fún ìfẹ́, tí ó fẹ́ láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ohun gbogbo” (Mòsíàh 3:19).

Orí kẹfà ti Wàásù Ìhìnrere Mi tí ó nkọ́ni ní kókó ìhùwàsí Krístì pé kí a ṣe ìbámú: “Sùúrù ni okun láti farada ìdádúró, wàhálà, àtàkò, tàbí ìjìyà láì bínú, bíbàjẹ́, tàbí ní ìtara. Ó jẹ́ agbára láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kí a sì tẹ́wọ́gba àkókò Rẹ̀. Nígbàtí ẹ bá ní sùúrù, ẹ di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ abẹ́ mọ́lẹ̀ tí a sì lè dojúkọ ìpọ́njú jẹ́jẹ́ àti pẹ̀lú ìrètí” (Wàásù Ìhìnrere Mi: Ìtọ́nisọ́nà kan sí Iṣẹ́-ìsìn Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, rev. ed. [2019], 126).

Iṣẹ́ àṣepé ti sùúrù bákannáà le jẹ́ síṣe àpẹrẹ nínú ìgbé ayé ọ̀kan lára àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì ní ìbẹ̀rẹ̀, Símónì ará Kánnà. Àwọn Zealot ni àwọn ẹgbẹ́ olómìnira Ará Júù kan tí wọ́n tako òfin Ará Rómù gidigidi. Ẹgbẹ́ Zealot náà polongo ìdàlúrú tako àwọn Rómù, àwọn Ará Júù tí wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn, àti àwọn Sadusí nípa jíjá àwọn nkan gbà fún ìpèsè àti lílepa àwọn ìṣe miran láti ṣe àtìlẹ́hìn fún èrò wọn (wo Encyclopedia Britannica, “Zealot,” britannica.com). Símónì ará Kánnà jẹ́ Zealot kan (wo Luku 6:15). Fi ojú inú wo Símónì ní gbígbìyànjú láti rọ Olùgbàlà sí gbígbé àwọn ohun ìjà, ṣíwájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan, tàbí dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù. Jésù kọ́ni:

“Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù: nítorí wọn yíò jogún ayé. …

“Alábùkún-fún ni àwọn alãnú, nítorí wọn yíò rí ãnú gbà. …

“Alábùkún-fún ni àwọn onílàjà: nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n” (Máttéù 5:5, 7, 9).

Símonì le ti gbà mọ́ra kí ó sì polongo èrò inú rẹ̀ pẹ̀lú agbára àti ìfẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ìwé mímọ́ sọ pé nípasẹ̀ ipá àti àpẹrẹ ti Olùgbàlà, ìfojúsùn rẹ̀ yípadà. Jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn rẹ̀ sí Krístì di kókó ìfojúsùn sí àwọn akitiyan ìgbé ayé rẹ̀.

Bí a ti nṣe tí a sì npa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, Olùgbàlà le ràn wá lọ́wọ́ láti “di àtúnbí; bẹ́ẹ̀ni, bíbí nípa ti Ọlọ́run, yíyípadà láti ipò ti ara àti ìṣubú [kan], sí ipò ti ìṣòdodo, tí a ti rà padà láti ọwọ́ Ọlọ́run, ní dídi ọmọkùnrin àti àti ọmọbìnrin rẹ̀” (Mòsíà27:25).

Nínú gbogbo àwọn ìgbésẹ̀ pẹ̀lú ìtara ti ìbákẹ́gbẹ́, ẹ̀sìn, àti ti òṣèlú òde òní, ẹ jẹ́kí ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì jẹ́ ẹgbẹ́ wa tí ó tayọ jùlọ àti tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ jùlọ. “Nítorí níbití ìṣúra yín bá gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yíò wà pẹ̀lú” (Máttéù 6:21). Kí a máṣe gbàgbé pẹ̀lú, àní lẹ́hìn tí àwọn ọmọlẹ́hìn tòótọ́ ti “ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run,” wọ́n “[ṣì] nílò sùúrù” (Hèbérù 10:36).

Gẹ́gẹ́ bí dídán ìgbàgbọ́ wa wò ti nṣiṣẹ́ sùúrù nínú wa, nígbàtí a bá lo sùúrù, ìgbàgbọ́ wa nlékun síi. Bí ìgbàgbọ́ wa ti nlékún, bẹ́ẹ̀ ní ayọ̀ wa nṣe.

Ní Oṣu Kẹta tí ó kọjá, ọmọbìnrin wa kejì, Emma, bíi púpọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nínú ìjọ, wọ ibi ìyanisọ́tọ̀ lọ ní dandan. Púpọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wá sílé. Púpọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere dúró fún rírán lọ ìbòmíràn Púpọ̀ kò gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì wọn ṣaájú lílọ sí orí pápá iṣẹ́. Ẹ ṣeun, ẹ̀yin alàgbà àti arábìnrin. A nifẹ yín.

Emma àti ojúgbà rẹ̀ ní Netherlands ni a yọ lẹ́nu ní àwọn ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ díẹ̀—yọ lẹ́nu dé omijé ní ìgbà púpọ̀. Pẹ̀lú àwọn ànfàní kúkúrú nìkan fún àjọṣe àwọn tí wọ́n wà nínú ibẹ̀ àti yíyọjú síta tí ó ní òdiwọ̀n, gbígbé ọkàn lé Ọlọ́run lékún síi fún Emma. A gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí ìlà a sì béèrè bí a ti le ṣe ìrànwọ́. Ó sọ fún wa láti ṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí ó nkọ́ lórí ilà!

Ẹbí wa bẹ̀rẹ̀ sí ṣepọ̀ lóri ìlà, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ Emma ní Netherlands. A pè wọ́n láti darapọ̀ mọ́ àṣàro Wá Tẹ̀lé Mi ti ìgbòòrò-ẹbí wa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lórí ayélujára. Floor, Laura, Renske, Freek, Benjamin, Stal àti Muhammad gbogbo wọn ti di ọ̀rẹ́ wa. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ wa láti Netherlands ti wọlé “sínú níbi ẹnu ọ̀nà híhá náà” (3 Néfì 14:13). A nfi “tẹẹrẹ ọ̀nà, àti híhá náà, han àwọn ẹlòmíràn nípa èyí tí wọn yíò wọlé” (2 Nefì 31:9). Wọ́n jẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú Kristì. Ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan a “nka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀” bí a ti nṣiṣẹ́ papọ̀ nínú ìtẹ̀síwájú wa ní ojú ọ̀nà májẹ̀mú.

A “jẹ́kí sùúrù ṣe àsepé iṣẹ́ rẹ̀” (Jákọ́bù 1:4) nínú àìlágbára wa láti pàdé ní ojúkojú bí àwa ẹbí ní wọ́ọ̀dù fún ìgbà kan. Ṣùgbọ́n a kà sí ayọ̀, ìgbàgbọ́ àwọn ẹbí wa tí nlékún síi nípasẹ̀ àjọṣepọ̀ ìmọ̀ ẹrọ tuntun, àti Wá, Tẹ̀lé Mi àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Ààrẹ Russell M. Nelson ṣèlérí, “Ìtiraka yín léreléra nínú ìsapá yí—àní nínú àkokò wọnnì nígbàtí ẹ lè nímọ̀lára pé ẹ kò ṣàṣeyọrí nípàtàkì—yíò yí ìgbé ayé yín padà, ti ẹbí yín, àti ayé” (“Tẹ̀síwáju nínú Ìgbàgbọ́,” Liahona, May 2020, 114).

Tbití a ti ndá àwọn májẹmú mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run—tẹ́mpìlì—wà ní títì. Ibití a ti npa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run—ilé—wà ní ṣíṣí! A ní ànfààní kan nílé láti ṣe àṣàrò àti láti ronú jinlẹ̀ lóríi ẹwà títayọ ti àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì. Àní ní àìsí wíwọlé sínú àlafo àfojúrí mímọ́ náà, “ọkàn wa … yío yọ̀ púpọ̀ ní àyọrísí àwọn ìbùkún èyítí yío di títú jáde” (Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 110:9).

Púpọ̀ ti pàdánù iṣẹ́; àwọn míràn ti pàdánù àwọn ànfààní. A láyọ̀, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú Ààrẹ Nelson, ẹnití ó sọ láìpẹ́ yi pé: “Àwọn àtinúwá ọrẹ ààwẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ ìjọ wa ti lé kún síi lódodo, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀dáwó àtinúwá sí àpò ẹgbẹ́ aláànú wa. … Ní àpapọ̀, àwa ó borí àkókò ìṣòro yí. Olúwa yío bùkún yín bí ẹ ti ntẹ̀síwájú láti bùkún àwọn ẹlòmíràn” (Russell M. Nelson’s Facebook page, post from Aug. 16, 2020, facebook.com/russell.m.nelson).

“Ẹ tújúká” ni àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, kìí ṣe ẹ bẹ̀rù (Matteu 14:27).

Nígbàmíràn a ndi aláìní-sùúrù nígbàtí a bá rò pé a “nṣe ohun gbogbo ní títọ́” àti pé síbẹ̀ a kò gba àwọn ìbùkún tí a fẹ́. Enọ́kù rìn pẹ̀lú Ọlọ́run fún ọgọ́run mẹ́ta àti ọgọ́ta ó lé márun ọdún kí òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ to di ṣíṣí nípò padà. Ọgọ́run mẹ́ta àti ọgọ́ta ó lé márun ọdún ti títiraka láti ṣe ohun gbogbo ní títọ́ àti pé nígbànáà ó ṣẹlẹ̀! (Wo Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:49.)

Kíkọjá lọ arákùnrin mi Chad ṣẹlẹ̀ ní àwọn oṣù díẹ̀ lẹ́hìn dídásílẹ̀ wa láti ìṣàkóso lórí Míṣọn Utah Ogden. Ó jẹ́ ohun ìyanu pé nígbàtí a ngbé ní Gúsù California, nínú gbogbo àwọn mísọ̀n irínwó ó lé mẹ́tàdínlógún tí àwa ìbá ti jẹ́ yíyàn sí ní ọdún 2015, a jẹ́ yíyàn sí àríwá Utah. Ilé mísọ̀n náà jẹ́ ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ní wíwakọ̀ sí ilé ti Chad. Àrùn jẹjẹrẹ Chad ni wọ́n rí nínú àyẹ̀wò lẹ́hìn tí a gba yíyàn-sí-iṣẹ́ mísọn wa tán. Àní nínú ipò dídánwò jùlọ, a mọ̀ pé Baba wa Ọrun nrántí wa Ó sì nrànwálọ́wọ́ láti ri ayọ̀.

Mo jẹ́ ẹ̀rí agbára tí nràpadà, tí nsọdimímọ́, tí nrẹnisílẹ̀, àti ti nkúnni fún ayọ̀ ti Olùgbàlà Jésù Krístì. Mo jẹ́rí pé nígbàtí a bá gbàdúrà sí Baba wa Ọrun ní orúkọ Jésù Krístì, Òun ó dá wa lóhùn. Mo jẹ̀rí pé bí a ṣe gbọ́, ti a fetísílẹ̀, tí a sì gbọ́ràn sí ohùn Olúwa àti wòlíì alààyè rẹ̀, Ààrẹ Russell M. Nelson a le “jẹ́ kí sùúrù ṣe iṣẹ́ àṣepé rẹ̀,” kí a sì “ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.