Àwọn Àwùjọ Alágberó
Bí iye tí ó tó nínú àwọn aládugbò wa bá tiraka láti tọ́ ìgbé ayé wa sọ́nà nípa òtítọ́ Ọlọ́run, àwọn ìwà rere tí a nílò ní gbogbo àwùjọ yío wà.
Irú akọrin rírẹwà tí ó nkọrin Olùgbàlà dídára.
Ní 2015 Àjọ Ìṣọkan Àwọn Orílẹ̀ Èdè fi ọwọ́ sí ohun tí a pè ní “Ètò fún Ìdàgbàsókè Alágberó Títí ti 2030.” Wọ́n ṣe àpèjúwe rẹ̀ bí “ìwé àfọwọ́kọ kan tí wọ́n ṣe àbápín fún àlàáfíà àti ìlọsíwájú fún àwọn ènìyàn àti ìpín ilẹ̀, nísisìyí àti dé ọjọ́ iwájú.” Ètò fún Ìdàgbàsókè Tí ó Seé Gbéró ní àwọn àfojúsùn mẹ́tàdínlógún nínú tí yío jẹ́ síṣeyọrí ní ọdún 2030, bí àìsí ìṣẹ́, àìsí ẹbi rárá, ẹ̀kọ́ dídára, ìmúdọ́gba ẹ̀yà, omi mímọ́ àti ìmọ́tótó, àti iṣẹ́ tó bójúmu.1
Àgbèkalẹ̀ ti idàgbàsókè alágberó títí jẹ́ ohun kan tí ó dùnmọ́ni tí ó sì ṣe pàtàkì. Paapaa ní ìyára díẹ̀ síi, síbẹ̀síbẹ̀, ni ìbéèrè gbígbòrò jù ti àwọn àwùjọ alágberó. Kíni àwọn ìpìlẹ́ tí ó ṣe àtìlẹhìn àwùjọ tí ó ní ìtara, ọ̀kan tí ó ṣe ìgbádùn ayọ̀, ìlọsíwájú, aláàfíà, àti ìlera láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀? A ní àkọsílẹ̀ inú ìwé-mímọ́ fún ó kéré jù méjì irú àwọn àwùjọ bẹ́ẹ̀ tí ó ní ìdàgbàsókè. Kíni a le kọ́ láti ọ̀dọ̀ wọn?
Ní ìgba àtijọ́, baba-nlá àti wòlíì náà Enọ́kù wàásù òdodo àti ó “kọ́ ìlú kan tí a pè ní Ìlú Ìwà-mímọ́, àní Síonì.”2 A rohìn rẹ̀ pé “Olúwa sì pè àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Síónì, nitorí wọ́n wà ní ọkàn kan àti inú kan, wọ́n sì gbé nínú òdodo; kò sì sí òtòṣì kankan ní àárín wọn.”3
“Olúwa sì bùkún ilẹ̀ náà, a sì bùkún fún wọn ní orí àwọn òkè náà, àti ní orí àwọn ibi gíga, wọ́n sì gbilẹ̀.”4
Àwọn ènìyàn sẹ́ntíúrì ìkínní- àti ìkejì ní Western Hemisphere tí a mọ̀ sí àwọn ará Néfì àti àwọn ará Lámánì pèsè àpẹrẹ tí ó tayọ miràn níti àwùjọ tí ó gbilẹ̀ kan. Títẹ̀lé iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó lápẹrẹ ti Olùgbàlà tó jínde ní ààrin wọn, “wọ́n rìn ní ti àwọn òfin ti wọn ti gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ati Ọlọ́run wọn, ní títẹ̀síwájú nínú ààwẹ̀ àti adura gbígbà, àti nínú pípàdé papọ̀ nígbà kugbà láti gbàdúrà àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. …
“Ko sì sí ìlara, tabi ìjà, tabi ìrúkèrúdò, tàbí ìwà àgbèrè, tabi irọ pípa, tabi ìpànìyàn, tabi irúkírú ìwà ìfẹ́kúfẹ̃; àti pé dájúdájú kò sí irú àwọn ènìyàn tí ó le láyọ̀ jù wọ́n lọ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn tí a ti dá nípa ọwọ́ Ọlọ́run.”5
Àwọn àwùjọ nínú àwọn àpẹrẹ méjì wọ̀nyí ni a gbéró nípa àwọn ìbùkún ti ọ̀run tí ó ndàgbà jáde láti inú àwòkọ́ṣe ìfarajì wọn sí àwọn òfin nlá méjì náà: “Kí ìwọ kí ó fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti pẹ̀lú gbogbo inú rẹ, àti pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ,” àti “Kí ìwọ kí ó fẹ́ aládugbò rẹ bí ara rẹ.”6 Wọ́n ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run nínú ìgbé ayé wọn bíi ẹnìkọ̀ọ̀kan, wọ́n sì bójútó àláàfíà ara wọn níti ara àti níti ẹ̀mí. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, ìwọ̀nyí ni àwọn àwùjọ níbití “olukúlùkù ènìyàn ti nwá ànfààní fún aládùúgbò rẹ̀, àti tí wọ́n nṣe ohun gbogbo pẹ̀lú fífi ojú ṣe ọ̀kan sí ògo Ọlọ́run.”7
Láìlóríre, Alàgbà Quentin L. Cook ṣe àkíyèsí ní òwúrọ̀ yí nípa, àwùjọ dáradára tí a ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú 4 Néfì ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì kò faradà kọjá sẹ́ntíúrì kejì rẹ̀. Kò sí ìfọwọ́sọ̀yà fún síṣe gbéró, àti pé àwùjọ kan tí ngbèrú le kùnà ní àkókò kan bí ó bá pa àwọn kókó ìwà rere tì, èyítí ó gbé àlàáfíà àti ìlọsíwájú rẹ̀ dúró. Nínú ọ̀rọ̀ yí, ní kíkọ ara sí àwọn àdánwò èṣù, àwọn ènìyàn náà “bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìpínyà sí àwọn ẹgbẹ́; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ àwọn ìjọ fun ara wọn fún èrè jíjẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sẹ́ ìjọ òtítọ́ ti Krístì.”8
“O sì ṣe nígbàtí ọ̀ọ́dúnrún ọdún ti kọjá lọ, àwọn ènìyàn méjèèjì Néfì àti àwọn ara Lámánì ti di ènìyàn búburú gidigidi ọ̀kan sì dàbíi òmíràn.”9
Ní ìparí sẹ́ntíúrì míràn, àwọn mílíọ́nù ti kú nínú ogun abẹ́lé àti pé orílẹ̀-èdè wọn tí ó ti fi ìgbàkan wà ní ìrẹ́pọ̀ ti di mímú kéré sí àwọn ẹ̀yà tí ngbógun.
Rírònú nípa èyí àti àwọn àpẹrẹ miràn ti àwọn àwùjọ tí ngbèrú tẹ́lẹ̀ tí wọ́n padà rì lẹ́hìnwá, mo rò pé kò léwu láti sọ pé nígbàtí àwọn ènìyàn bá yà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ìrònú pé wọn níláti jíhìn fún Un, àti dípò bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú “apá ẹran ara,” àjálù nsúnmọ́. Gbígbẹ́kẹ̀lé ọwọ́ ẹran-ara ni láti pa Olùdásílẹ̀ ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn ti àti iyi ènìyàn àti láti fúnní ní ààyò gígajù sí àwọn ọ̀rọ̀, agbára, àti ìyìn ayé (nígbàtí a bá nṣe ẹlẹ́yà àti inúnibíni àwọn ẹnití ó tẹ̀lé òṣùwọ̀n tó yàtọ̀). Níbáyìí, àwọn tí ó wà ní àwùjọ́ dídúró-gbọingbọin nwá “ìdàgbà nínú ìmọ̀ ògò ẹnití ó ṣẹ̀dá [wọn], tàbí nínú ìmọ̀ èyí tí ó jẹ́ òtítọ́ a`ti dáadáa.”10
Àwọn àgbékalẹ̀ ẹbí àti ẹ̀sìn ṣe kókó fún bíbùkún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn àdúgbò pẹ̀lú àwọn ìwà rere tí ngbé àwùjọ kan tí ó ní ìfaradà ró. Àwọn ìwàrere wọ̀nyí, fi gbòngbò múlẹ̀ nínú ìwé mímọ́, ojuṣe àti ìjihìn, àánú, ìgbéyàwó àti ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó, ìtẹríba fún àwọn ẹlòmíràn àti ohun ìní àwọn ẹlòmíràn, iṣẹ́ ìsìn, àti didan àti iyì iṣẹ́, láàrin àwọn míràn.
Olóòtú gbogbogbò Gerard Baker kọ ìwé kan ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yi Ìròhìn Wall Street Náà ní bíbu ọlá fún bàbá rẹ̀, Frederick Baker, ní ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́run ọdún bàbá rẹ̀. Baker rò nípa àwọn ìdí fún ẹ̀mí gígùn bàbá rẹ̀ ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà ó fi àwọn èrò wọ̀nyí kún:
“Nígbàtí gbogbo wa le fẹ́ mọ àṣírí sí ẹ̀mí gígùn, mo máa nfi ìgbàgbogbo ní ìmọ̀lára pé aó ṣe dára jùlọ bí a bá fi àkókò wa jì láti rò nípa ohun tí ó nmú kí ìgbésí ayé dára, èyíkéyi ìwọ̀n tí a bá pín fún wa. Níhin, ó dá mi lójú pé mo mọ àṣírí ti bàbá mi.
“Òun wá láti inú àkókò nígbàtí a ṣètumọ̀ ìgbésí ayé nípàtàkì nípa iṣẹ́, kìí ṣe nípa ẹ̀tọ́; nípa àwọn ojúṣe àwùjọ, kìí ṣe àwọn ànfàní ara ẹni. Pàtàkì ìwúrí tí wọ́n gbàgbọ́ ní gbogbo sẹ́ntíúrì rẹ̀ ni ọgbọ́n ojuṣe—sí ẹbí, Ọlọ́run, orílẹ̀ èdè.
“Ní àkókò tí a ndárí láti ọwọ́ àwọn pàntí ti àwọn ẹbí dídàrú, bàbá mi jẹ́ olóòtọ́ ọkọ sí ìyàwó rẹ̀ fún ọdún 46, olójúṣe baba sí àwọn ọmọ mẹ́fà. Òun kìí wà ní àrọ́wọ́tó kí ó sì ṣe pàtàkì ju ìgbà tí àwọn òbí mi jìyà ìjàmbá tí kò ṣeé rò ti pípàdánù ọmọ kan. …
“Àti ní àkókò kan nígbàtí ìwádìí npọ̀ síi lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, bàbá mi ti gbé bíi olõtọ́, onígbàgbọ́ Àgùdà, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àìyẹsẹ̀ nínú àwọn ìlérí Krístì. Nítòótọ́, mo máa nrò nígbàmíràn pé ó ti pẹ́ láyé tó bẹ́ẹ̀ nítorípe ó gbaradì dáradára ju ẹnikẹ́ni tí mo ti bá pàdé rí láti kú.
“Mo ti jẹ́ olóríire ènìyàn—tí a bùkúnfún nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ rere, ẹbí tèmi tí ó kún fún ìyànu, àwọn àṣeyege ti inú ayé díẹ̀ tí èmi kò lẹtọ sí. Ṣùgbọ́n bákannáà ìmọ̀lára ìgbéraga àti ìmoore tí mo ní, ní fífi pamọ́ nípasẹ̀ ìgbéraga àti ìmoore tí mo ní fún ẹni náà tí, láìsí àníyàn tàbí eré ìtàgé, láìsí ìrètí èrè tàbí ìjẹ́wọ́ paapàá, ti tẹ̀síwájú—fún sẹ́ntíúrì kan báyi—pẹ̀lú àwọn iṣẹ́, àwọn ojúṣe àti, ní ìgbẹ̀hìn, àwọn ayọ̀ ìrọ̀rùn ti gbígbé ìgbé ayé oníwà rere.”11
Pàtàkì ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn tí a fiyèsí ti dínkù ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ní àwọn ọdún àìpẹ́. Àwọn ènìyàn tí iye wọn npọ̀ síi lérò pé ìgbàgbọ́ nínú àti ìfọkàntán sí Ọlọ́run kò nílò fún ìwà ìdúroṣinṣin nínú bóyá àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí àwọn àwùjọ ní àgbáyé òde òní.12 Mo rò pé gbogbo wa yío gbà pé àwọn wọnnì tí wọn kò jẹ́wọ́ ìgbágbọ́ nínú ẹ̀sìn le, wọn sì nfi ọ̀pọ̀ ìgbà jẹ́, àwọn oníwà rere ènìyàn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò ní gbà pé èyí rí bẹ́ẹ̀ láìsí agbára àtọ̀runwá. Mo ntọ́ka sí Ìmọ́lẹ̀ Krístì. Olùgbàlà kéde pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tí ó ntànmọ́lẹ̀ sí olukúlùkù ènìyàn tí ó wá sí inú ayé.”13 Bóya a mọ̀ nípa rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo ọkùnrun, obìnrin, àti ọmọdé ti olukúlùkù ìgbàgbọ́, ibikíbi, àti àkókò ni a ti kún pẹ̀lú Ìmọ́lẹ̀ ti Krístì àti nítorínáà wọ́n ní ọgbọ́n títọ́ àti àìtọ́ tí a nfi ìgbà pùpọ̀ pè ní ẹ̀rí ọkàn.14
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbàtí jíjẹ́ ti ayé bá mú ìwà rere àwùjọ yapa kúrò lára ìjíhìn sí Ọlọ́run, ó ngé irúgbìn kúrò lára àwọn gbòngbò rẹ̀. Gbígbára lé àṣà àti ìṣe nìkan kò le tó láti gbé ìwà rere ró ní àwùjọ. Nígbàti ẹnìkan kò bá ní ọlọ́run tí ó ga ju òun fúnra rẹ̀ lọ, tí kò sì wá ohun rere kan tí ó tóbi ju síṣe ìtẹ́lọ́run fún àwọn ìpòngbẹ àti àwọn ohun fífẹ́ ti ara rẹ̀, àwọn àyọrísí yío farahàn ní àkókò rẹ̀.
Àwùjọ kan, fún àpẹrẹ, nínú èyítí ìfọwọ́sí ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ìdíwọ́ kanṣoṣo lóri ìṣe ìbálòpọ̀, jẹ́ àwùjọ nínú ìbàjẹ́. Panṣágà, ìwà ìbájẹ́, àwọn ìbímọ láìṣe ìgbéyàwó,15 ìmọ̀ọ́mọ̀ ba oyún jẹ́ ni díẹ̀ lára ṣùgbọ́n àwọn èso kíkorò tí ndàgbà láti inú ìwa àìdára tí wọ́n fi òntẹ̀ lù nípasẹ̀ rògbòdìyàn ìbálòpọ̀. Àwọn àyọrísí títẹ̀lé tó nṣiṣẹ́ tako àgbéró àwùjọ pípéye pẹ̀lú iye púpọ̀ síi ti àwọn ọmọ tí wọ́n ntọ́ nínú ìṣẹ́ àti láìsí ipa dídára ti àwọn baba, nígbàmíràn ní líla àwọn ìran púpọ̀ já; àwọn obìnrin tí wọ́n ndá gbé ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ àwọn ojúṣe pípín; àti àìnító ẹ̀kọ́ líle gidi bí àwọn ilé ìwé, bíi àwọn àgbékalẹ̀ miràn, ni a nfún ní iṣẹ́ ṣe láti ṣe ẹ̀san fún ìjákulẹ̀ inú ilé.16 Ní àfikún sí àwọn ẹ̀kọ́ àìsàn àwùjọ wọ̀nyí ni àwọn àpẹrẹ tí kò lónkà ti ìbànújẹ́ àti àìnírètí ti ẹnìkọ̀ọ̀kan—ìparun ọpọlọ àti ti ìmọ̀ara tí a fi ṣe ìbẹ̀wò sórí ẹnití ó jẹ̀bi àti aláìṣẹ̀.
Nefì kéde pé:
Ègbé ni fún ẹni náà tí ó fetísílẹ̀ sí ìlànà àwọn ènìyàn, tí ó sì sẹ́ agbára Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́! …
“… Ègbé ni fún gbogbo àwọn tí nwárìrì, tí wọ́n sì nbínú nítorí òtítọ́ Ọlọ́run!”17
Ní ìdàkejì, ọ̀rọ̀ ìdùnnú wa sí àwọn ọmọ wa àti sí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni pé “òtítọ́ ti Ọlọ́run” ntọ́ka sí ọ̀nà dídára síi kan, tàbí bí Paulù ti sọ, “ọ̀nà dídára kan jùlọ síi,”18 ọ̀nà kan sí ìdùnnú ti ara ẹni àti ànfààní agbègbè nísisìyí àti sí àlàáfíà àti ayọ̀ ayérayé lẹ́hìnwa.
Òtítọ́ Ọlọ́run ntọ́kasí kókó àwọn òtítọ́ tí ó sàmì sí èrò ìdùnnú Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni pé Ọlọ́run wà láàyè; pé Òun ni Baba Ọrun ti àwọn ẹ̀mí wa; pé bíi ìfarahàn ìfẹ́ Rẹ̀, Ó ti fúnwa ní àwọn òfin tí ó darí sí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ kan pẹ̀lú Rẹ̀; pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run àti Olùràpadà wa; pé Ó jìyà Ó sì kú láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí ipò ti ìrònúpìwàdà wa; pé Ó jínde kúrò nínú òkú, ní mímú Àjínde gbogbo ènìyàn wá sí ìmúṣẹ; àti pé gbogbo wa a ó dúró níwájú Rẹ̀ láti jẹ́ dídá lẹ́jọ́, èyí ni pé, láti ṣírò fún ìgbésí ayé wa.19
Ọdún mẹ́san nínú ohun tí a pè ní “ìjọba àwọn onídajọ́,” wòlíì Almà fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ bíi onídájọ̀ àgbà láti fi àkókò kíkún sí iṣẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ lórí ìjọ. Èrò rẹ̀ ni láti ṣiṣẹ́ lórí ìgbéraga, inúnibíni, àti ojúkòkòrò tí ngbìlẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn náà àti nípàtàkì láàrin àwọn ọmọ ìjọ.20 Bí Alàgbà Stephen D. Nadauld ti wòye nígbàkan rí, “Ìpinnu ìmísí [Almà] ímisí kìí ṣe láti lo àkókò síi ní gbígbìyànjú láti ṣe àti láti lo àwọn àwọn òfin láti ṣe àtúnṣe ìhùwàsí àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, láti kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ náà kí ó sì mú kí òye wọn ní ti èrò ìràpadà darí wọn láti yí ìhùwàsí wọn padà.”21
Ohun púpọ̀ ni a le ṣe bíi aládugbò àti bíi àjùmọ̀ kẹ́gbẹ́ láti lọ́wọ́ sí síṣeé gbéró àti àṣeyọ́rí àwọn àwùjọ tí a ngbé nínú rẹ̀, àti pé dájúdájú iṣẹ́ ìsìn wa tí ó ṣe pàtàkì àti tí yío pẹ́ títí jùlọ ni láti kọ́ni kí a sì gbé ìgbé ayé ní9pa àwọn òtítọ́ náà tí ó wà nínú èrò nlá Ọlọ́run fún ìràpadà. Bí a ṣe sọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ orin náà:
Ìgbàgbọ́ àwọn bàbá wa, àwa yíó nífẹ́
Àti ọ̀rẹ́ àti ọ̀tá nínú gbogbo ìjà wa,
A ó sì wàásù rẹ, bákannáà, bí ìfẹ́ ti mọ̀ọ́ ṣe,
Nípa àwọn ọ̀rọ̀ rere àti ìgbé ayé ìwà rere.22
Bí iye tí ó tó lára wa àti iye tí ó tó nínú àwọn aládugbò wa bá tiraka láti ṣe ìpinnu wa kí a sì tọ́ ìgbé ayé wa nípa òtítọ́ Ọlọ́run sọ́ná, àwọn ìwà rere tí a nílò ní gbogbo àwùjọ yío wà.
Nínú ìfẹ́ Rẹ̀, Baba Ọ̀run fi Ọmọbíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo, Jésù Krístì funi, pé kí awa le ní ìyè àìlópin.23
“[Jésù Krístì] kò ṣe ohunkóhun láì jẹ́ fún èrè gbogbo ayé; nítorí ó fẹ́ aráyé, àní tí ó fi fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí òun lè mú gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nítorínáà, òun kò pàṣẹ fún ẹnikẹ́ni pé wọn kì yío ní ìpín nínú ìgbàlà rẹ̀.
“Kíyèsíi, njẹ́ ó kígbe sí ẹnikẹ́ni, wípé: Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi bi? Kíyèsíi, mo wí fún yín, Rárá; ṣùgbọ́n ó wípé: Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin ikangun ayé, ẹ ra wàrà àti oyin, láìsí owó àti láìsí iye.”24
Èyí ni a kéde, “pẹ̀lú ọ̀wọ̀ nínú ọkàn, nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,”25 àti ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.