Jẹ́kí Ọlọ́run Borí
Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé yín? Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ alágbára pàtàkì jùlọ nínú ayé yín?
Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, bí ìmoore mi ti tó fún àwọn ọ̀rọ̀ ìyanilẹ́nu ìpàdé àpapọ̀ yí àti fún ànfàní mi láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín nísisìyí.
Nítorí púpọ̀ ju àwọn ọdún mẹrindinlogoji tí mo ti jẹ́ Àpóstélì, ẹ̀kọ́ ìkójọ Israel ti kápá àfojúsí mi.1 Ohungbogbo nípa rẹ̀ ti wọ̀ mí lára, pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti orúkọ2 Abraham, Isaac, àti Jacob; ìgbé ayé wọn àti àwọn ìyàwó wọn; májẹ̀mú tí Ọlọ́run ṣe pẹ̀lú wọn tí ó lọ nínú ìran wọn;3 ìfọ́nká àwọn ẹ̀yà méjìlá; oríṣiríṣi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìkójọ́ ní ọjọ́ wa.
Mo ti kọ́ ìkójọ náà, gbàdúra rẹ̀, ṣe àpèjẹ lórí gbogbo ìwé mímọ́ tó bamu, mo ti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa láti mú ìmọ̀ mi pọ̀ sí.
Nítorínáà rírónú lórí ìdùnní mi a darí mi lọ sínú òye titun. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé Hébérù méjì, mo kọ́ pé ọ̀kan lára ìtumọ̀ ti Hébérù ọ̀rọ̀ náà Ísráẹ́lì ni “ jẹ́kí Ọlọ́run borí.”4 Báyi, orúkọ Ísráẹ́lì gan an tọ́kasí ẹnìkan tì ò nfẹ́ láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ìgbé ayé ọkùnrin tàbí obìnrin. Èròngbà yẹn ru ẹ̀mí mi sókè!
Ọ̀rọ̀ náà nfẹ́ ṣe kókó sí títúmọ̀ ti Israel.5 Gbogbo wa ní agbára láti yàn. A lè yàn láti jẹ́ ti Ísráẹ́lì, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. A lè yàn láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ìgbé ayé wa, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. A lè yàn láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ okun alágbára jùlọ nínú ìgbé ayé wa, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
Fún àkokò kan, ẹ jẹ́kí a tún kókó àmì ìyípadà sọ nínú ìgbé ayé Jákọ́bù, ọmọ-ọmọ Ábráhámù. Ní ibi tí a ti fún Jákọ́bù lórúkọ Peniel (èyí tí ó túmọ̀ sí “ojú Ọlọ́run”),6 Jákọ́bù jà pẹ̀lú ìpènijà líle. A dán agbára láti yàn rẹ̀ wò. Nínú ìjà yí, Jákọ́bù jẹ́wọ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ síi. Ó júwe pé òun nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé rẹ̀. Ní ìdáhùn, Ọlọ́run yí orúkọ Jákọ́bù padà sí Israel,7 ó túmọ̀ sí “ jẹ́kí Ọlọ́run Borí.” Ọlọ́run nígbànáà ṣe ìlérí fún Ísráẹ́lì pé gbogbo àwọn ìbùkún tí a ti polongo lórí Abraham ni yíò jẹ́ tirẹ̀ bákannáà.8
Ní bíbáni-nínújẹ́, àwọn àtẹ̀lé já májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Wọ́n sọ òkúta lu àwọn wòlíì wọn kò sì fẹ́ jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé wọn. Ní òpin, Ọlọ́run fọ́n wọn ká lọ sí ìgun mẹ́rin ilẹ̀-ayé. Pẹ̀lú àánú, Ó ṣe ìlérí lẹ́hìnnáà láti kó wọn jọ́, bí à ti ròhìn látẹnu Ísáíàh: “Fún akokò díẹ̀ ni mo ti gbàgbé yín [Israel]; ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú nlá ni èmi ó kó yín jọ.”10
Pẹ̀lú ìtumọ̀ ti Hébérù Ísráẹ́lì nínú, a ri pé ìkójọ Ísráẹ́lì gbà àfikún ìtumọ̀. Olúwa nkó àwọn ẹnití ó nfẹ́ jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé wọn jọ́. Olúwa nkó àwọn ẹnití yíò yàn láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ agbára pàtàkì jùlọ nínú ayé wọn jọ́.
Fún àwọn sẹ́ntúrì, àwọn wòlíì ti sọtẹ́lẹ̀ nípa ìkójọ yí,11 àti pé ó nṣẹlẹ̀ gan nísisìyí! Bí ìṣaájú pàtàkì sí Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa o jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì jùlọ nínú ayé!
Ìkójọ ìṣíwájú-mílẹ́níà yí ni ságà olúkúlùkù ní mímú ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ti ẹ̀mí àwọn mílíọ́nù ènìyàn gbòrò. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, tàbí “májẹ̀mú Ísráẹ́lì ọjọ́-ìkẹhìn,”12 a ti gba àṣẹ láti ti Olúwa lẹ́hìn pẹ̀lú iṣẹ́ pàtàkì yí.13
Nígbàtí a bá sọ̀rọ̀ ìkójọ Ísráẹ́lì ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú, a ntọ́kasí, bẹ́ẹ̀ni, sí ìránṣẹ́ ìhìnrere, tẹ́mpìlì, àti iṣẹ́ ìtàn ẹbí. Bákannáà a ntọ́ka sí gbígbé ìgbàgbọ́ wa àti ẹ̀rí ga nínú ọkàn àwọn ẹnití à ngbé, ṣiṣẹ́, àti sìn pẹ̀lú. Ìgbàkugbà tí a bá ṣe ohunkan láti ran ẹnìkan lọ́wọ́—ní ẹ̀gbẹ́kẹ́gbẹ́ ti ìbòjú—láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, à nṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ.
Láìpẹ́, ìyàwó ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ọmọkùnrin wa ntiraka níti ẹ̀mí. Èmi ó pè é ní “Jill.” Pẹ̀lú ààwẹ̀, àdúrà, àti àwọn ìbùkún oyè-àlùfáà, Baba Jill nkú lọ. Ẹ̀rù mú u dání pé òun yíò sọ baba àti ẹ̀rí rẹ̀ méjèèjì nù.
Ní ìrọ̀lẹ́ jíjìn kan, ìyàwó mi, Arábìnrin Wendy Nelson, wí fún mi nípa ipò Jill. Ní òwúrọ̀ tó tẹ̀le Wendy ní ìmọ̀lára láti pín ìdáhùn mi pẹ̀lú Jill pé ìjà ti ẹ̀mí rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kan! Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ àìlóye.
Lẹ́hìnnáà Jill gba fún Wendy pé ní àkọ́kọ́ òun banújẹ́ nípa ìdáhùn mi. Ó wípé, “Mò nretí kí Baba-baba ṣèlérí iṣẹ́ ìyanu baba mi fún mi. Mo nronú ìdí tí ọ̀rọ̀ náà ko fi lóye ni ọ̀kan tí ó ní ìmọ̀lára láti fi dandan sọ.”
Lẹ́hìn tí baba Jill kọjá lọ, ọ̀rọ̀ náà àìlóye ṣì nwá sínú rẹ. Ó ṣí ọkàn rẹ̀ sí ìmọ̀ àní jíjinlẹ̀ si pé àìlóye túmọ̀ sí “àìrítòsí.” Àti pé ríronú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí nyí. Jill nígbànáà wípé “Àìlóye mú mi dúró, ronú, àti wòsàn. Ọ̀rọ̀ náà kún inú mi pẹ̀lú aláfíà nísisìnyí. Ó rán mi létí láti mú ìrísí mi gbòrò àti láti wá ayérayé. Ó rán mi létí pé ètò àtọ̀runwá kan wà àti pé baba mi ṣì wà láàyè àti pé ó nṣètọ́jú mi.. Àìlóye ti darí mi sí Ọlọ́run.”
Mo ní ìgberaga lórí ìyàwó-ọmọ-ọmọ wa iyebíye gan. Ní ìgbà ìrora-ọkàn yí nínú ayé rẹ̀, Jill ọ̀wọ́ nkọ́ láti gba ìfẹ́ Ọlọ́run fún baba rẹ̀ mọ́ra, pẹ̀lú ìrìsí ayérayé fún ayé ararẹ̀. Nípasẹ̀ yíyàn láti jẹ́kí Ọlọ́run Borí, ó nrí àláfíà.
Bí àwa ó bá fàyè gbàá, àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà tí títúmọ̀ Hébérù ti Ísráẹ́lì yí lè fi rànwálọ́wọ́. Ẹ ronú bí àdúrà wa lórí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa—àti fún àwọn ìlàkàkà ara wa láti kó Isráẹ́lì jọ—ṣe nyípadà pẹ̀lú èròngbà yí nínú. À ngbàdúra léraléra pé kí a darí wa àti àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere sí àwọn tí ó múrasílẹ̀ láti gba àwọn òtítọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì. Ó yà mí lẹ́nu, ẹni tí a ó darí wa sí nígbàtí a bá bẹ̀bẹ̀ láti rí àwọn tí ó nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé wọn?
A lè dárí wa sí àwọn kan tí kò gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tàbí Jésù Krístì rárá ṣùgbọ́n tí wọ́n nyára sí kíkọ́ nípa Wọn àti ètò ìdùnnú Wọn. Àwọn ẹlòmíràn ni a ti lè “bí sínú májẹ̀mú”14 ṣùgbọ́n tí wọ́n ti rìn kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Nísisìyí wọ́n lè ṣetán láti ronúpìwàdà, padà, àti kí wọ́n jẹ́ Kí Ọlọ́run Borí. A lè ṣe àtìlẹhìn nípa kíkí wọn káàbọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ àti ọkàn ṣíṣí. Àti pé kí àwọn kan tí a lè darí wa sí lè ní ìmọ̀lára nígbàgbogbo pé ohunkan wa tí ó ti sọnù nínú ayé wọn. Àwọn, náà, nlọ́ra fún odidi àti ayọ̀ tí ó nwá sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé wọn.
Àpapọ̀ ìhìnrere láti kó àwọn olùfọ́nká Ísráẹ́lì jọ gbòrò. Ààyè wa fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa tí yíò gbá ìhìnrere Jésù Krístì mọ́ra ní kíkún. Olùyípadà kọ̀ọ̀kan ndi àwọn ọmọ májẹ̀mú Ọlọ́run kan,15 bóyá nípasẹ̀ ìbí tàbí nípasẹ̀ àgbàtọ́. Ẹnìkọ̀ọ̀kan di ajogún kíkún sí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí sí àwọn olotitọ ọmọ Ísráẹ́lì!16
Ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa ní agbára àtọ̀runwá nítorí ẹnìkọ̀ọ̀kan wá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Ẹnìkọ̀ọ̀kan báradọ́gba ní ojú Rẹ̀. Àbábọ̀ ti òtítọ́ yí jinlẹ gidi. Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fetísílẹ̀ sí ohun tí mo fẹ́ sọ. Ọlọ́run kò nifẹ ẹ̀yà kan ju òmíràn lọ. Ẹ̀kọ́ Rẹ̀ lórí ọ̀ràn yí dáyéké. Ó pe gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀, “dúdú àti funfun, tí ó wà nínú ìdè àti ní òmìnira, akọ àti abo.”17
Mo mu dáa yín lójú pé a kò pinnú àwọ̀ ti ara yín nípa dídúró yín níwájú Ọlọ́run . Ojúrere tàbí àìní-ojúrere pẹ̀lú Ọlọ́run dá lórí ìfọkànsìn wa sí Ọlọ́run àti àwọn òfin Rẹ̀ àti pé kìí ṣe àwọ̀ ara yín.
Mo banújẹ́ pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa dúdú ní gbogbo ayé nfarada ìrora ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ẹ̀tanú. Ní òní mo pe àwọn ọmọ ìjọ̀ níbigbogbo láti jẹ́ àpẹrẹ nípa pípa àwọn ìwà àti ìṣe ẹ̀tànú ti. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti gbé ọ̀wọ̀ ga fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.
Ìbèère fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, láìka ẹ̀yà sí, ni ọ̀kannáà. Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé yín? Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ agbára pàtàkì jùlọ nínú ayé yín? Ṣe ẹ ó fàyè gba àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, òfin Rẹ̀, àti májẹ̀mú Rẹ̀ láti fún wa lágbára ohun tí ẹ ó ṣe lójojúmọ́? Ṣe ẹ ó fàyè gba ohùn Rẹ̀ láti jẹ́ ìṣíwájú lórí ẹlòmíràn kankan? Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́ kí ohunkóhun tí Ó nílò kí ẹ ṣe jẹ́ ìṣíwájú lórí gbogbo àwọn ìlépa míràn? Ṣé ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ̀ ó gbé tiyín mì?19
Ẹ ronú bí irú ìfẹ́ náà ti lè bùkún yín. Bí ẹ kò bá ṣègbeyàwó tí ẹ sì wá ojúgbà ayérayé, ìfẹ́-inú yín láti jẹ́ “ti Ísráẹ́lì” yíò ràn yín lọ́wọ́ láti pinnu ẹnití wọn ó bá dọrẹ àti báwo.
Bí ẹ bá gbéyàwó sí ojúgbà kan tí ó ti já àwọn májẹ̀mú ọkùnrin tàbí obìnrin náà, ìfẹ́ yín láti jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé yín yíò fàyè gbà àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run láti dúróúṣinṣin. Olùgbàlà yíò wo ọkàn ìròbìnújẹ́ yín sàn. Àwọn ọ̀run yíò ṣí bí ẹ ti nwá láti mọ̀ bí ẹ ó ti tẹ̀síwájú. Ẹ kò nílò láti rìnkiri tàbí ní ìyàlẹ́nu.
Bí ẹ bá ní àwọn ìbèère àtinúwá nípa ìhìnrere tàbí Ìjọ, bí ẹ ti yàn láti jẹ́kí Ọlọ́run borí, a ó darí yín láti rí àti láti ní ìmọ̀ àwọn òtítọ́ ayérayé, tí yíò tọ́ yín sọ́nà nínú ìgbé ayé yín àti láti ràn yín lọ́wọ́ láti dúró gbọingbọin lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
Nígbàtí ẹ bá ní ìdojúkọ pẹ̀lú àdánwò—àní bí àdánwò bá wá nígbàtí ó ti rẹ̀ yín tàbí tí ẹ ní ìmọ̀làra àdáwà tàbí àìní ìmọ wa—ronú ìgbòya tí ẹ lè ní bí ẹ ti yàn láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín bí ẹ ti mbẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ láti fún yín lókun.
Nígbàtí ìfẹ́ títóbi jùlọ wa bá jẹ́kí Ọlọ́run borí, láti jẹ́ ara Ísráẹ́lì, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu di rírọrùn si. Nítorínáà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀ràn di àìsí-ọ̀ràn! Ẹ mọ̀ bí ẹ ṣe lè tún ara yín ṣe dáradára jùlọ̀. Ẹ mọ ohun tí ẹ ó wò àti tí ẹ ó kà, ibi tí ẹ ó ti lo àkokò, àti pẹ̀lú ẹnití ẹ ó darapọ̀ mọ́. Ẹ mọ ohun tí ẹ fẹ́ láti ṣe àṣeyege. Ẹ mọ irú ẹni tí ẹ fẹ́ dà lódodo.
Nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ó gba méjèèjì ìgbàgbọ́ àti ìgboyà láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí. Ó gba ìtẹramọ́, iṣẹ́ ti-ẹ̀mí líle láti ronúpìwàdà àti láti gbé ènìyàn àdánidá sílẹ̀ nípa Ètùtù Jésù Krístì.19 Ó gba ìtiraka ojojúmọ́, lèraléra láti gbèrú àwọn ìwà-araẹni láti ṣe àṣàrò ìhìnrere, láti kọ́ si nípa Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì, àti láti wá àti láti fèsì sí ìfihàn araẹni.
Ní ìgbà èwu wọ̀nyí nípa èyí tí Àpóstélì Páùlù sọtẹ́lẹ̀,20 Sátánì kò tilẹ̀ gbìyànjú mọ́ láti fi àwọn àtakò rẹ̀ pamọ́ lórí ẹ̀tò Ọlọ́run. Ibi híhàn-gboro wà káàkiri. Nítorínáà, ọ̀nà kanṣoṣo láti wà láìléwu níti ẹ̀mí ni láti pinnu láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa, láti kọ́ láti gbọ́ ohun Rẹ̀, àti láti lo agbára wa láti ṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ.
Nísisìyí, báwo ni Olúwa ṣe ní ìmọ̀lára nípa àwọn ènìyàn tí yíò jẹ́kí Ọlọ́run borí? Néfì ròópọ̀ pé ó dára: “[Olúwa] fẹ́ràn àwọn tí wọ́n yíò jẹ́kí ó jẹ́ Ọlọ́run wọn. Kíyèsi, Ó fẹ́ràn àwọn baba wa, àti pé ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ni, àní Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù; àti pé ó ránti [i] àwọn májẹ̀mú èyí tí ó [ti] ṣe .”21
Àti pé kíni Olúwa nfẹ́ láti ṣe fún Ísráẹ́lì? Olúwa ti jẹjẹ pé Òun yíò “ja àwọn ogun [wa], àti àwọn ogun àwọn ọmọ [wa], àti [ogun] àwọn ọmọ-ọmọ wa … dé ìran ikẹta àti ìkẹ́rin”!22
Bí a ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ fún oṣù mẹ́fà tó mbọ̀, mo gbà yín níyànjú láti ṣe ìtò lẹsẹẹsẹ gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ìlérí pé Òun yíò ṣe fún ìrọ̀rùn Isráẹ́lì. Mo ronú pé yíò yà yín lẹ́nu! Ẹ jíròrò àwọn ìlérí wọ̀nyí. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa wọn pẹ̀lú ẹbí yín àti àwọn ọ̀rẹ́. Nígbànáà ẹ gbé kí ẹ sì wo àwọn ìlérí wọ̀nyí láti jẹ́ ìmúṣẹ nínu ayé ara yín.
Ẹ̀yin arábìnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ti nyàn láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín, ẹ ó ní ìrírí fún ara yín pé Ọlọ́run ni “Ọlọ́run àwọn iṣẹ́ ìyanu.”23 Gẹ́gẹ́bí ènìyàn kan, a jẹ́ àwọn ọmọ májẹ̀mú Rẹ̀, a ó sì pè wá nípa orúkọ Rẹ̀. Nípa Èyí ni mo jẹrí ni orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.