Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìkaniyẹ sí Olúwa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ìkaniyẹ sí Olúwa

Bẹ̀rẹ̀ ètò láti di “ìkaniyẹ sí Olúwa” kí Ẹ̀mí Rẹ̀ lè wà pẹ̀lú yín lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ẹ kú òwúrọ̀, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin. Gẹ́gẹ́bí ọmọẹ̀hìn Olùgbàlà, Jésù Krístì kan, mo ti nfojúsọ́nà sí ìkórajọ orí afẹ́fẹ́ láti gbogbo igun mẹ́rin ayé fún ìpàdé àpapọ̀ yí.

Tẹ́mpìlì Durban South Africa

Èyí ti jẹ́ ọdún tó yàtọ̀ jùlọ. Fún mi ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ yíyàn fúnmi látọ̀dọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní láti ya tẹ́mpìlì mímọ́ sí Olúwa ní Durban, South Africa. Èmi kò ní gbàgbé títóbi ilé náà láéláé. Ṣùgbọ́n ju àgbékalẹ̀ náà lọ, èmi ó máa fi ọlá fún iyì àwọn ẹni tì wọ̀n múrasílẹ̀ gan an làti wọnú ilé-nlá mímọ́ náà nígbàgbogbo. Wọ́n wá ní ṣiṣetán láti ṣe àbápín ọ̀kan lára àwọn ìbùkún aládé ti Ìmúpadàbọ̀sípò: ìyàsọtọ̀ ilé Olúwa kan. Wọ́n wá pẹ̀lú ọkàn kíkún pẹ̀lú ifẹ́ fún Un àti Ètùtù Rẹ̀. Wọ́n wá pẹ̀lú ọpẹ́ kíkún fún Baba wa ní Ọ̀run fún pípèsè àwọn ìlànà mímọ́ tí yíò darí sí ìgbéga. Wọ́n wá ní yíyẹ.

Àwọn Ọmọ Ìjọ Tẹ́mpìlì Durban Gúsù Áfríkà

Àwọn tẹ́mpìlì, ibikíbi èyíowù kí wọ́n wà, ga ju àwọn ọ̀nà ayé lọ. Gbogbo tẹ́mpìlì àwọn Ènìyàn Mírmọ́ ní ayé—gbogbo ọgọ́jọlémẹ́jọ wọn—dúró bíi májẹ̀mú sí ìgbàgbọ́ wa nínú ìyè ayérayé àti ayọ̀ lílò pẹ̀lú àwọn ẹbí wa àti Baba Ọ̀run. Lílọ sí tẹ́mpìlì nmú òye wa nípa Olórí-ọ̀run àti ìhìnrere àìlópin pọ̀ si, ìfarasìn wa làti gbé ìgbé ayé òtítọ́ àti ìfarasìn, àti ìfẹ́ wa láti tẹ̀lé àpẹrẹ Olúwa wa àti Olùgbàlà, Jésù Krístì.

Ìkaniyẹ sí Olúwa

Ní ìtà gbogbo tẹ́mpìlì nínú Ijọ ní àwọn ọ̀rọ̀ ìbámu, “Ìwà-mímọ́ sí Olúwa.” Tẹ́mpìlì ni ilé Olúwa àti ibi-ààbò kúrò nínú ayé. Ẹ̀mí Rẹ̀ rọ̀mọ́ àwọn ẹnití wọ́n njọ́sìn nínú àwọn ilé mímọ́ náà. Ó gbé òṣùwọ̀n Rẹ̀ kalẹ̀ nípa èyí tí a lè wọlé bí àlejò Rẹ̀.

Blaine Twitchell

Baba ìyàwó mi, Blaine Twichell, ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin rere tí mo ti mọ̀ rí, kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ nlá kan. Arábìnrin Rasbánd àti èmi lọ kíi nígbàtí ó nsúnmọ́ òpin ìrìnàjò ayé ikú rẹ̀. Bí a ṣe wọnù yàrá rẹ̀, bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀ ṣẹ̀ nkúrò. Bí a ṣe kí bíṣọ́ọ̀pù, mo ronú pé, “Irú bíṣọ́ọ̀pù rere tó jẹ́. Ó wà nihin láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ọmọ ìjọ olódodo kan ti wọ́ọ̀dù rẹ̀.”

Mo sọ́ lójú Blaine, “Njẹ́ èyí kò dára nípa bíṣọ́ọ̀pù láti wá ṣe ìbẹ̀wò bí.”

Blaine wò mí ó sí wípé, “O ju iyẹn lọ gidi. Mo ní kí bíṣọ́ọ̀pù wá nítorí mo fẹ́ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìkàyẹ tẹ́mpìlì mi. Mo fẹ́ lọ pẹ̀lú ìkaniyẹ sí Olúwa.” Ó sì ṣe!

Gbólóhùn náà, “ìkaniyẹ sí Olúwa,” ti wà pẹ̀lú mi. Ó ti mú ìrísí titun wá lórí ṣíṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò déédé látọ́dọ́ àwọn olórí Ìjọ wa. Ìkaniyẹ tẹ́mpìlì ṣe pàtàkì dé bi pé nì ìbẹ̀rẹ̀ Ijọ̀, títí di 1891, ìkaniyẹ tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan ní a fọwọ́sí nípasẹ̀ Ààrẹ Ìjọ.1

Bóyá fún ọ̀dọ́ tàbí àgbà, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìkaniyẹ yín kìí ṣe nípa ṣe àti máṣe. Ìkaniyẹ kìí ṣe ìfàmisí kankan, ìwé ìkọja , tàbí tíkẹ́tì fún ijoko pàtàkì. Ó ní ìdí mímọ́ àti gígá púpọ̀ si. Láti yege fún ọla ìkaniyẹ tẹ́mpìlì, ẹ gbọ́dọ̀ gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìkọ́ni Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yín ẹ ní ànfàní láti yẹ ọkàn yín wò nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì araẹni yín àti Ètùtù Rẹ̀. Ẹ ní ìbùkún láti fi ẹ̀rí yín nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere hàn, ìfẹ́ yín láti ṣe ìmúdúró àwọn ẹni tí Olúwa ti pè láti darí Ìjọ Rẹ̀, ìgbàgbọ́ yín nínú ẹ̀kọ́ ìhìnrere, ìmúṣẹ yín nípa àwọn ojúṣe ẹbí, ìwà òtítọ́ yín, ìpamọ́ra, ìwà-mímọ́, ìgbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n, òfin idamẹwa, àti ìyàsímímọ́ ọjọ́ Ìsinmi. Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ ìgbé ayé olùfarasìn sí Jésù Krístì àti iṣẹ́ Rẹ̀.

Ìkaniyẹ tẹ́mpìlì yín nfi ìjìnlẹ̀, èrò ti ẹ̀mí pé ẹ̀ ntiraka láti gbé àwọn òfin Olúwa àti láti fẹ́ ohun tí Ó fẹ́: ìrẹ̀lẹ̀ inututu, ìdúróṣinṣin, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìgboyà, àánú, ìdáríjì, àti ìgbọràn. Kí ẹ sì fi arasìn fúnra yín sí àwọn òsùwọn nígbàtí ẹ bá fi àmín sí orúkọ yín sí ìwé mímọ́ náà.

Ìkaniyẹ tẹ́mpìlì yín nṣí ilẹ̀kùn ọ̀run fún yín àti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìlànà-ìsìn àti àwọn ìlànà pàtàkì ayérayé, pẹ̀lú ìrìbọmi, agbára ẹ̀bùn, ìgbeyàwó, àti èdidì.

Láti jẹ́ ”ìkaniyẹ sí Olúwa” ni láti rán wa létí nípa ohun tí à nretí látọ̀dọ̀ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn olùpamọ́-májẹ̀mú. Baba ìyàwó mi, Baline, ri bí ìmúrasílẹ̀ tó níyì fún ọjọ́ nígbàtí òun yíò dúrò pẹ̀lù ìrẹ̀lẹ̀ níwájú Olúwa.

Igbo jíjó

Ronú ìgbàtí Mósè gun Òkè Hórébù tí Olúwa Jèhòfà si farahàn an nínú igbo jíjó. Ọlọ́run wí fun pé, Bọ́ bàtà ẹ̀sẹ̀ rẹ̀, nítorí ilẹ̀ tí ìwọ wà ni ilẹ̀ mímọ́ ni.”2

Bíbọ́ bàtà wa ní ẹnu ọ̀nà tẹ́mpìlì ni fif àwọn ìfẹ́ ayé sílẹ̀ tàbí ìgbádùn tí yíò dà wá láàmú kúrò ní ìdàgbà ti ẹ̀mí, gbigbé sẹ́gbẹ àwọn ohun èyí tí yíò tì ayé ikú iyebíye wá sẹ́gbẹ́, dídìde kọjá ìwà ìjà, àti wíwá àkokò láti jẹ́ mímọ́.

Nípa àwoṣe tọ̀run, ara wa ni ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, tẹ́mpìlì kan fún ẹ̀mí yín, tí ẹ sì gbọ́dọ̀ tọ́jú pẹ̀lú ọ̀wọ̀. Òtítọ́ gidi ni àwọn ọ̀rọ̀ orin Alakọbẹrẹ, “Ara mi ni tẹ́mpìlì èyí tí ó nílò ìtọ́jú títóbí jùlọ.”3 Nígbàtí Olúwa farahàn sí àwọn ará Néfì, Ó pàṣẹ pé, “Ẹ di mímọ́ nípa gbígba Ẹ̀mí Mímọ́ kí ẹ̀yin lè dúró ní àìlábàwọ́n níwájú mi.” “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ̀yin ó jẹ́?” Olúwa bèèrè wọ́n sì fèsì, “Àní gẹ́gẹ́bí mo ti rí.”5 Láti jẹ́ “ìkaniyẹ sí Olúwa,” a níláti tiraka láti dàbí Rẹ̀.

Mo rántí gbígbọ́ Ààrẹ Howard W. Hunter nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀ bí Ààrẹ kẹrinla Ìjọ. Ó wípé: “Ó jẹ́ ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ ọkàn mi kí gbogbo ọmọ Ìjọ yẹ láti wọnú tẹ́mpìlì. Inú Olúwa yíò dùn bí gbogbo àwọn àgbà ọmọ ìjọ bá yẹ tí—wọ́n sì—ngbé ìkaniyẹ dání lọ́wọ́lọ́wọ.” Èmi ó fikun pé ìkaniyẹ Ìlò-tó-Lópin yíò gbé ipa-ọ̀nà kedere kalẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ iyebíye wa.

Ààrẹ Nelson tun ọ̀rọ̀ Ààrẹ Hunter sọ, “Ní ọjọ́ náà, Oṣù Kẹfa 1994, pé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì tí a ngbé dání di ohun ìyàtọ̀ nínú àpò mi. Ṣíwájú ìyẹn, ó jẹ́ ìtumọ̀ sí òpin kan. Ó jẹ́ ìtumọ̀ sí fífi àyè gbà mí láti wọnú ilé mímọ́ Olúwa; Ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí ó ṣe ìkéde náà, tí ó di ìparí fúnrarẹ̀. Ó di àmì ìgbọràn mi sí wòlíì Ọlọ́run kan.”7

Tẹ́mpìlì Nauvoo

Bí ẹ kò bá tíì gba ìkaniyẹ kan tàbí bí ìkaniyẹ yín bá ti tán, ẹ tò sí ẹnu-ọ̀nà bíṣọ́ọ̀pù gẹ́gẹ́bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìṣaájú ṣe tò sẹ́nu ọ̀nà Tẹ́mpìlì Nauvoo ní 1846.8 Àwọn bàbánlá mi wà ní àárín àwọn olódodo náà. Wọ́n npa ilú ẹlẹ́wa wọn tì wọ́n sì nlọ sí ìwọ̀-oòrùn, ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé ìrírí mímọ́ ndúró dè wọ́n nínú tẹ́mpìlì. Sarah Rich kọ látinú ìrìn líle ní Iowa, “Bí kò bá jẹ́ fún ìgbàgbọ́ àti òye tí a fún wa nínú tẹ́mpìlì náà … , ìrìnàjò wa ìbá ti dàbí … ìyọsẹ̀ kan nínú òkùnkùn.”10 Iyẹn ni ohun tí a nkùnà bí a bá ndá lọ nínú ayé láì ní ìmísí àti àláfíà tí agba ìlérí rẹ̀ nínú tẹ́mpìlì.

Bẹ̀rẹ̀ ètò láti di “ìkaniyẹ sí Olúwa” kí Ẹ̀mí Rẹ̀ lè wà pẹ̀lú yín lọ́pọ̀lọpọ̀ àti pe àwọn òṣùwọn Rẹ̀ yíò mú “àláfíà ẹ̀rí ọkàn wá fún yín.”10

Àwọn olórí ọ̀dọ́ yín, ààrẹ iyejú àwọn alàgbà, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, àti ojíṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin àti arábìnrin yíò ràn yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀, bíṣọ́ọ̀pù àti ààrẹ ẹ̀ka yín yíò sì tọ́ọ yín sọ́nà pẹ̀lú ìfẹ́.

A ti nní ìrírí ìgbà kan nígbàtí a ti tẹ́mpìlì tàbí ìlò òpin. Fún Ààrẹ Nelson àti àwọn kan lára wa tí à nsìn lẹgbẹ rẹ̀, ìpinnu ìmísí láti ti àwọn tẹ́mpìlì jẹ́ “ìrora” tí ó “kún fún ìdàmú.” Ààrẹ Nelson bèèrè, “Kíni èmì ó wí fún Wòlíì Joseph Smith? Kíni èmi ó wí fún Brigham Young, Wilford Woodruff, àti àwọn ààrẹ míràn títí dé Ààrẹ Thomas S. Monson?”11

Nísisìyí, à nrọra a sì ndúpẹ́ pe à nṣí àwọn tẹ́mpìlì fún èdidì àti agbára ẹ̀bùn lórí ìwọ̀n tó lópin.

Ṣùgbọ́n, a kò dá yíyẹ láti lọ sí tẹ́mpìlì, dúró. Ẹ jẹ́ kí ntẹnumọ, bóyá ẹ ní ààyè sí tẹ́mpìlì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ nílò ìkaniyẹ tẹ́mpìlì lọ́wọ́lọ́wọ́ láti dúró gbọingbọin ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú.

Ẹgbẹ́ ní New Zealand

Ní òpin ọdún tó kọjá Arábìnrin Rasband àti èmi wà lóri iṣẹ́ ṣíṣe yíyàn ní New Zealand tí à nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ títóbi àwọn ọ̀dọ́ àgbà. Wọn kò ní ààyè ìrọ̀rùn sí tẹ́mpìlì; ọ̀kan tó wà ní Hamilton ni wọ́n ntúnṣe lọ́wọ́, wọ́n ṣì ndúró de ilẹ̀-fífọ́ fún tẹ́mpìlì ní Auckland. Bákannáà, mo ní ìmọ̀lára ìṣíletí láti gbà wọ́n níyànjú láti túnṣe tàbí kí wọ́n gba ìkaniyẹ tẹ́mpìlì.

Àní bíótilẹ̀jẹ́pé wọn kò lè gbé wọn kálẹ̀ ní tẹ́mpìlì, wọn yíò máa gbé arawọn kalẹ̀ níwájú Olúwa ní mímọ́ àti ní ìmúrasílẹ̀ àti láti sìn Ín. Yíyẹ láti di ìkaniyẹ tẹ́mpìlì mú lọ́wọ́lọ́wọ́ ni ààbò kúrò lọ́dọ́ ọ̀tá, nítorí ẹ ti ṣe ìfarasìn gbọingbọin sí Olúwa nípa ìgbé ayé yín, àti ìlérí kan pé Ẹ̀mí yíò wà pẹ̀lú yín.

À nṣe iṣẹ́ tẹ́mpìlì nígbàtí a bá ṣe ìwákiri fún àwọn babanla wa kí a sì fi orúkọ wọn sílẹ̀ fún àwọn i`lànà. Nígbàtí a ti ti àwọn tẹ́mpìlì, a ṣì lè ṣe àwárí àwọn ẹbí wa. Pẹ̀lú Ẹ̀mí Ọlọ́run nínú ọkàn wa, a jẹ́, olùrọ́pò nípasẹ̀, dídúró fún wọn láti jẹ́ “ìkàniyẹ sí Olúwa.”

Nígbà tí mò nṣìn gẹ́gẹ́bí Alakoso Ẹ̀ka Tẹ́mpìlì, mò ngbọ́ léraléra tí Ààrẹ Gordon B. Hinckley tọ́kasí ìwé mímọ́ yí nípa ohun tí Olúwa sọ nípa Tẹ́mpìlì Nauvoo: “Ẹ jẹ́ kí iṣẹ́ ti tẹ́mpìlì mi, àti gbogbo àwọn iṣẹ́ tí èmi ti yàn fún yín, kí ó tẹ̀síwájú kí ó má sì ṣe dúró;ẹ sì jẹ́ kí aápọn yín, àti ìpamọ́ra yín, àti sùúrù, àti àwọn ìṣẹ́ yín kí ó sì di ìlọ́po lẹ́ẹ̀méjì, àti pé ẹ̀yin, bí ó ti wù kí ó rí yíò pàdánu èrè yín, ni Olúwa àwọn Ọmọ Ogun wí.”13

Iṣẹ́ wa nínú tẹ́mpìlì ni ó rọ̀mọ́ èrè ayérayé wa. Láìpẹ́ a ti fi wá sínú ìdánwò. Olúwa ti pè wá sí tẹ́mpìlì pẹ̀lú “aápọn, … ìpamọ́ra, àti sùúrù.”14 Jíjẹ́ “ìkaniyẹ sí Olúwa.” nbèèrè fún àwọn ìwà. A gbọ́dọ̀ ní aápọn ní gbígbé àwọn òfin , kí a ní ìforítì ní àkíyèsí wa sí Àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì, kí a sì dúpẹ́ fún ohun tí Olúwa ntẹ̀síwájú láti kọ́ni nípa wọn, kí a ní sùúrù bí a ṣe ndúró fún pípadàṣí àwọn tẹ́mpìlì ní kíkún wọn.

Nígbàtí Olúwa bá pè wá kí a ṣe “ìlọ́po” ìtiraka wa, Ó ní kí a pọ̀si nínú òdodo. Fún àpẹrẹ, a lè mú àṣàrò ìwé mímọ́ wa gbòòrò si, ìwákiri ìtàn ẹbí wa, àti pé àdúrà ìgbàgbọ́ ni kí a lè pín ìfẹ́ wa fún ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn tí wọ́n nmúra láti gba ìkaniyẹ tẹ́mpìlì, àwọn ọmọ ẹbí wa ní pàtàkì.

Mo ṣèlérí fún yín bí Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì pé bí ẹ ṣe nlàkàkà láti ṣe ìlọ́po ìtiraka òdodo yín, ẹ ó tún ìfọkànsìn ṣe sí Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì, ẹ o´ ní ìmọ̀lára ọ̀pọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ntọ́ yín sọ́nà, ẹ̀yin ó dúpẹ́ fún àwọn májẹ̀mú mímọ́ yín, ẹ ó ní ìmọ̀lára àláfíà ní mímọ̀ pé ẹ jẹ́ “ìkaniyẹ sí Olúwa.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.