Agbára Ìfaradà
Ìgbàgbọ́ nìkan àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó kún inú ẹ̀mí wa tó láti mú wa dúró—àti láti fi àyè gbà wá sí agbára Rẹ̀.
Ní àtúnyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, mo rí ọ̀rọ̀ kan tí ó nlo léraléra nínú àwọn ọ̀rọ̀ púpọ̀. Ọ̀rọ̀ náà ni agbára.
Nínú ìpàdé àpapọ gbogbogbò àkọ́kọ́ lẹ́hìn tí a ṣe ìmúdúró rẹ̀ gẹ́gẹ́bí Àpóstélì, Ààrẹ Nelson sọ̀rọ̀ nípa agbára.1 Ó ti tẹ̀síwájú ní kíkọ́ni nípa agbára ní àwọn ọdún. Látìgbà tí a ti ṣe ìmúdúró Ààrẹ Nelson bí wòlíì wa, ó ti kọ́ wa nípa ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ agbára—nípàtàkì, agbára Ọlọ́run—àti bí a ṣe lè ní àyè si. Ó ti kọ́ wa bí a ó ṣe fa agbára Ọlọ́run sórí wa bí a ti nṣé iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn,2 bí ìrònúpìwàdà ti npe agbàra Jésù Krístì àti ètùtù Rẹ̀ nínú ayé wa,3 àti bí oyè-àlùfáà— àṣẹ Ọlọ́run—ti nbùkún gbogbo ẹni tí wọ́n ndá ti wọ́n sì npa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́.4 Ààrẹ Nelson ti jẹri pé agbára Ọlọ́run ti ṣàn sí gbogbo ẹní tí wọ́n gba agbára ẹ̀bùn nínú tẹ́mpìlì bí wọ́n ti npa àwọn májẹ̀mú mọ́.5
Nípàtàkì ìpènijà kan tí Ààrẹ Nelson fúnni ní ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020 mú mi lọ́kan. Ó pàṣẹ fún wa láti “ṣe àṣàrò kí a sì gbàdúrà láti kekọ si nípa agbára àti ìmọ̀ pẹ̀lú èyí tí ẹ ti gba agbára ẹ̀bùn—tàbí pẹ̀lú èyí tí ẹ ó gba agbára ẹ̀bùn síbẹ̀.”6
Ní ìfèsì sí ìpènijà mo ti ṣe àṣàrò mo sì gbàdúrà láti kọ́ àwọn ohun pàtàkì nípa agbára àti ìmọ̀ pẹ̀lú èyí tí ẹ ti gba agbára ẹ̀bùn—tàbí èyí tí ẹ ó gba agbára ẹ̀bùn síbẹ̀.
Lílóye ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti ní àyè sí agbára Ọlọ́run nínú ìgbé ayé wa kò rọrùn.7 Alàgbà Richard G. Scott fúnni ní ìtùmọ̀ kedere nípa ohun tí agbára Ọlọ́run jẹ́: ó jẹ́ “agbára láti ṣe púpọ̀ ju bí a ti lè ṣe nípasẹ̀ ara wa.”8
Àní kíkún ọkàn wa àti ẹ̀mí wa pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ṣe pàtàkì sí fífa lé agbára Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbà ìpènijà wọ̀nyí. Láìsí gbígba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì jinlẹ̀ sínú ọkàn wa, àwọn ẹ̀rí wa àti ìgbàgbọ́ lè kùnà, àti pé a lè sọ àyè sí agbára tí Ọlọ́run nfẹ́ láti fún wa nù. Ìgbàgbọ́ ògèèrè kò tó. Ìgbàgbọ́ nìkan àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó kún inú ẹ̀mí wa tó láti mú wa dúró—àti láti fi àyè gbà wá sí agbára Rẹ̀.
Bí Arábìnrin Johnson àti èmi ṣe ntọ́ àwọn ọmọ wa, a gba ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ìyànjú láti kọ́ láti tẹ ohun èlò òrin. Ṣùgbọ́n a ó fi àyè gba àwọn ọmọ wa láti gba àwọn ẹ̀kọ́ òrin tí wọ́n bá sa ipa wọn nìkan tí wọ́n sì ntẹ ohun èlò wọn lójojúmọ́. Ní Sátidé kan, inú ọmọbìnrin wa kẹta dùn láti lọ ṣeré pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, ṣùgbọ́n òun kò tíì tẹ dùrù síbẹ̀síbẹ̀. Ó mọ̀ pé òun ti fi kíkọ́ tìtẹdùrù fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sílẹ̀, ó lérò láti gbé àkokò kalẹ̀, nítorí òun kò fẹ́ kọ́ títẹ̀dùrù àní fún ìṣẹ́jú kan kọjá ju bí ó ti yẹ lọ.
Bí ó ṣe nrìn lẹgbẹ iná míkírówéfù ní ọ̀nà rẹ̀ síbi dùrù, ó dúró ó sì tẹ àwọn bọ́tìnì kan. Ṣùgbọ́n dípò kí ó gbé àkokò náà kalẹ̀, ó gbé míkírówéfù kalẹ̀ láti se oúnjẹ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ó sì tẹ̀ẹ́ láti bẹ̀rẹ̀. Lẹ́hìn ogún ìṣẹ́jú kíkọ́ títẹ̀, ó rìn padà sí ilé-ìdáná láti wo àkoko tí ó kù ó sì ri pé míkírówéfù ti gbiná.
Nígbànáà ó sáré wá sí ẹ̀hìnkùlé níbi tí mo ti nṣiṣẹ́ ọgbà, ó kígbe pé ilé ti njó. Mo sáré lọ sínú ilé kíákíá, àti pé, nítòótọ́, mo ri pé míkírówéfù ti njóná.
Nínú ìtiraka láti dá ààbò bo ilé kúrò ní jíjó, mo nawọ́ sẹ́hìn míkírówéfù, mo yọọ́ kúrò, mo sì lo okùn agbára rẹ̀ láti gbé míkírówéfù tí ó njó sókè kúrò lórí pátákó. Ní ìrètí láti jẹ́ akọni àti láti dá ààbò bo ọjọ́ bákannáà pẹ̀lú ilé wa, mo nyí míkírówéfù tí ó njoná yíka pẹ̀lú okùn agbára láti páa mọ́ kúrò ní ara mi, mo dé ẹ̀hìnkùlé, mo fi yíyí míràn ju míkírówéfù náà síta síwájú ilé. Níbẹ̀ ni a ti pa iná ìléru náà pẹ̀lú okùn-rọ́bà.
Kíní ó ṣẹlẹ̀? Iná míkírówéfù nílò ohunkan láti fa agbára rẹ̀, nígbà tí kò sí ohunkankan ní inú rẹ̀ láti fa agbára, iná fúnrarẹ̀ fa agbára, ó sì gbóná, ó sì lè gbiná, kí ó pa ararẹ̀ run ní àkópọ̀ iná àti eérú.9 Gbogbo míkírówéfù wa gbiná ó sì jóná nítorí kò sí ohunkankan ní inú rẹ̀.
Bákannáà, àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jinlẹ̀ nínú ọkàn wọn yíò lè fàá àti borí idà amúbí-iná èyí tí ọ̀tá yíò rán dájúdájú láti pa wá run.10 Bíkòṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wa, ìrètí, àti pé ìdánilójú lè má tilẹ̀ pẹ́ títí, àti bíiti iná míkírówéfù, a lè di olùfaragbá.
Mo ti kọ́ pé níní ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, fi àyè gbà mí láti fa agbára Ọlọ́run láti borí ọ̀tá àti ohunkóhun tí ó lè jù sí mi. Bí a ṣe ndojúkọ àwọn ìpènijà, a lè gbáralé ìlérí Olúwa tí a kọ́ nípasẹ̀ Páùlù: “Nítorípé Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bíkòṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ọkàn tí ó yè kooro.”
A mọ̀ pé gẹ́gẹ́bí ọmọ kan Olùgbàlà “dàgbà, ó sì nlágbára nínú ẹ̀mí , ó sì kún fún ọgbọ́n: ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì mbẹ ní ara rẹ̀.”12 A mọ̀ pé bí Ó ṣe ndàgbà si, “Jésù sì npọ̀ si ní ọgbọ́n àti ìdàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.”13 A sì mọ̀ pé ní ìgbà tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹnití ó gbọ́ Ọ ní “ẹnu sì yàá sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorípé tàṣẹ-tàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.”14
Nínú ìmúrasílẹ̀, Olùgbàlà dàgbà nínú agbára ó sì lè kọ gbogbo àwọn àdánwò Sátánì.15 Bí a ṣe ntẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà tí a sì nmúrasílẹ̀ nínú ṣíṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a sì nmú ìgbàgbọ́ wa jinlẹ̀ si, bákannáà a lè fa agbára láti kọ àwọn àdánwò.
Ní àkókò ìdèná ìkórajọ yí tí kò mú lílọ sí tẹ́mpìlì ṣeéṣe, dájúdájú mo ti ṣètò láti tẹ̀síwájú láti ṣe àṣàrò àti láti kọ́ nípa agbára Ọlọ́run tí ó nwá sọ́dọ̀ wa bí a tì nṣe tí a sì npa májẹ̀mú mọ́ si. Bí a ti ṣe ìlérí nínú àdúrà ìyàsọ́tọ̀ ti Tẹ́mpìlì Kirtland, a fi tẹ́mpìlì sílẹ̀ nínú agbára Ọlọ́run.16 Kò sí òpin ọjọ́ tí ó wà pẹ̀lú agbára tí Ọlọ́run fún àwọn tí ó ndá tí wọ́n sì npa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́, tàbí kí ìdádúró wà ní níní àyè sí agbára náà nínú àjàkálẹ̀ àrùn kan. Agbára rẹ̀ ndínkù nínú ayé wa nìkan tí a bá kùnà láti pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ tí a kò sì gbé ní ọ̀nà kan tí ó fàyè gbà wá láti tẹ̀síwájú láti yege fún gbígba agbára Rẹ̀.
Nígbàtí mò nsìn bí olórí míṣọ̀n pẹ̀lú ìyáwó mi ọ̀wọ́n ní Thailand, Laos, àti Myanmar, a jẹri agbára Ọlọ́run lọ́wọ́kan tí ó wá sára àwọn ẹnití ó ṣe tí ó sì pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́ nínú tẹ́mpìlì. Igbá-kejì Alákóso-ọkùnrin ti ìnáwó mu ṣeéṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè mẹta wọ̀nyí láti lọ sí tẹ́mpìlì lẹ́hìn ṣíṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe nípasẹ̀ ìrúbọ ti araẹni wọn àti ìmúrasílẹ̀. Mo rántí ìpàdé ẹgbẹ́ kan ti ogún olóòtọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti Laos ní pàpá-ọkọ̀-òfúrufú kan ní Bangkok, Thailand, láti ran àwọn tí a gbé kúrò lọ́wọ́ láti lọ sí pápá ọkọ̀-òfúrufú ní Bangkoko láti fò lọ sí Hong Kong. Àwọn ọmọ ìjọ wọ̀nyí nní ìyárí pẹ̀lú ayọ̀ láti fẹ́ rìrìnàjò lọ sí ilé Olúwa ní ìgbẹ̀hìn.
Nígbàtí a pàdé àwọn Ènìyàn Mímọ́ rere náà nígbà tí wọ́n dé, ìdàgbà àfikún ìhìnrere pẹ̀lú agbára tí ó jádé látinú gbígba agbára ẹ̀bùn tẹ́mpìlì àti wíwọnú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ni ó hàn gbangban. Àwọn Ènìyàn Mímọ́ wọ̀nyí lọ jáde látinú tẹ́mpìlì “pẹ̀lú agbára [Rẹ̀].”17 Agbára yí láti ṣe púpọ̀ si ju bí wọ́n ti lè ṣe fúnrawọn fún wọn ní okun láti farada àwọn ìpènijà ti jíjẹ́ ọmọ Ìjọ nínú orílẹ-èdè ara wọn àti láti lọ jẹ́ ẹ̀rí “ayọ̀ títayọ nlá àti ológo, nínú òtítọ́,”18 bí wọ́n ṣe tẹ̀síwájú ní gbigbé ìjọba Olúwa ní Laos ga.
Ní àárín ìgbà náà a kò lè lọ sí tẹ́mpìlì, ṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn májẹ̀mú tí a dá nínú tẹ́mpìlì láti gbé, ọ̀nà àìyípadà ti dídarí ayé wa kedere kan kalẹ̀? Àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí, tí a bá paá mọ́, nfún wa ní ìran àti àwọn ìrètí nípasẹ̀ ọjọ́ ọ̀la àti ìpinnu kedere kan láti yege láti gba gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣèlérí nípa òtítọ́ wa.
Mo pè yín láti wá agbára tí Ọlọ́run fẹ́ láti fún wa. Mo jẹri pé bí a ṣe nwá agbára yí, a ó di alábùkúnfún pẹ̀lú lílóye títóbi ifẹ́ tí Baba Ọ̀run ní fún wa si.
Mo jẹri pé nítorí Baba Ọ̀run fẹ́ràn ẹ̀yin àti èmí, Ó rán Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Mo jẹri nípa Jésù Krístì, ẹnití O ní gbogbo agbára,19 mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.