Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Mo Gbàgbọ́ nínú Àwọn Angẹ́lì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Mo Gbàgbọ́ nínú Àwọn Angẹ́lì

Olúwa mọ̀ nípa àwọn ìpèníjà tí o ndojúkọ. O mọ̀ yín, Ó ní ìfẹ́ yín, mo sì ṣe ìlérí pé, Òun yío rán àwọn ángẹ́lì láti ràn yín lọ́wọ́.

Ẹ̀yin Arákùnrin àti arábìnrin, mo gbàgbọ́ nínú àwọn angẹ́lì, yío sì wùmí láti ṣe àbápín pẹ̀lú yín àwọn ìrírí mi pẹ̀lú wọn. Ní síṣe bẹ́ẹ̀, Mo ní ìrètí mo sì gbàdúrà pé a ó mọ pàtàkì àwọn angẹ́lì nínú ìgbé ayé wa.

Nihin ni àwọn ọ̀rọ̀ Alàgbà Jeffrey R. Holland látinú ìpàdé àpàpọ̀ gbogbogbò: “Nígbàtí a bá sọ̀rọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, a nrán wa létí pé kìí ṣe gbogbo àwọn angẹ́lì ni ó wá láti apá kejì ìbòjú náà. Díẹ̀ nínú wọn ni a mbá rìn tí a sì mbá sọ̀rọ̀—níhin, nísisìyí, lójoojúmọ́. Díẹ̀ nínú wọn ngbé nínú àwọn àdúgbò tiwa. … Nítòótọ́, ọ̀run kò tíì dàbí pé ó súnmọ́ni ju ìgbàtí a bá rí ìfẹ́ Ọlọ́run tó farahàn nínú inúrere àti ìfọkànsìn àwọn ènìyàn tí wọ́n dára tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ àìléèrí tó bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé bíì ti ángẹ́lì ni ọ̀rọ̀ kanṣoṣo tí ó wá sí ọkàn” (“Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ ti Àwọn Angẹ́lì,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2008, 30).

Nípa àwọn ángẹ́lì ti apá ìhín ti ìbòjú ni mo fẹ́ sọ. Àwọn ángẹ́lì tí wọ́n nrìn láàrin wa nínú ìgbé ayé wa ojoojúmọ́ jẹ́ àwọn ìránnilétí tí ó lágbára nípa ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa.

Àwọn ángẹ́lì àkọ́kọ́ tí èmi ó mẹ́nubà ni àwọn arábìnrin méjì oníṣẹ́ ìránṣẹ́ tí wọ́n kọ́ mi ní ìhìnrere nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin: Arábìnrin Vilma Molina àti Arábìnrin Ivonete Rivitti. A pe abùrò mi obìnrin àti èmi sí ibi iṣẹ́ ìdárayá kan tí Ijọ níbítí a ti pàdé àwọn ángẹ́lì méjì wọ̀nyí. Èmi kò fi ojú inú wòó láe bí iṣẹ́ ìdárayá rírọrùn náà yío ṣe yí ìgbé ayé mi padà tó.

Àwọn òbí mi àti àwọn arákùnrin mi kò nífẹ láti ní ìmọ̀ síwájú si nípa Ìjọ ní àkókò náà. Àní wọn kò tilẹ̀ fẹ́ àwọn oníṣẹ́ ìránṣẹ́ náà nínú ilé wa, nítorínáà mo gba àwọn ẹ̀kọ́ oníṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú Ilé Ìjọ́sìn kan. Yàrá kékeré náà nínú ilé ìjọ́sìn di “igbó ṣúúrú mímọ́” tèmi.

Ọ̀dọ́ Alàgbà Godoy pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀

Oṣù kan lẹ́hìn tí àwọn ángẹ́lì wọ̀nyí fi ìhìnrere hàn mí, a rì mí bọmi. Mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógun nígbànáà. Pẹ̀lú àbámọ̀, èmi kò ní àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ mímọ́ náà, ṣùgbọ́n mo ní àwòrán arábìnrin mi àti èmi ní àkókò tí a kópa nínú iṣẹ́ ìdárayá náà. Mo le nílò láti ṣe àlàyé tani ó jẹ́ tani nínú àwòrán yi. Èmi ni ẹni gígá kan ní apá ọ̀tún.

Bí ẹ ti le fi ojú inú wò, dídúró pẹ̀lú ìkópa nínú Ìjọ jẹ́ ìpèníjà fún ọ̀dọ́ langba kan ẹnití ìgbésí ayé rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ yípadà àti tí ẹbí rẹ̀ kò tọ ipa ọ̀nà kannáà.

Bí mo ti ngbìyànjú láti túnraṣe sí ìgbé ayé mi tuntun, àṣà tuntun, àti àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, mo ní ìmọ̀lára àìbánidọ́gba. Mo ní ìmọ̀lára ànìkanwà àti ìrẹ̀wẹ̀sì ní ìgbà púpọ̀. Mo mọ̀ pé Ìjọ náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n mo ní ìṣòro mímọ̀lára pé mo jẹ́ apákan rẹ̀. Nígbàtí kò rọrùn àti tí kò dájú bí mo ti ngbiyànju láti wọlé sínú ẹ̀sìn mi tuntun, mo ni ìgboyà láti kópa nínú ìpadé àpapọ̀ ọlọ́jọ́-mẹ́ta ti àwọn ọ̀dọ́, èyítí mo rò pé yío rànmí lọ́wọ́ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Èyí ni ìgbà tí mo pàdé ángẹ́lì agbanilà míràn, tí orúkọ̀ rẹ̀ jẹ́ Mônica Brandão.

Arábìnrin Godoy

Ó tuntun ní agbègbè náà, nítorí ó kó wá láti apá ibòmiràn ti Brazil. Mo tètè ṣe àkíyèsí rẹ̀ àti pé, bíi oríire fún mi, ó gbà mí bí ọ̀rẹ́ kan. Mo rò pé ó wò mí láti inú dáradára jù láti ìta lọ.

Nítorípe ó ṣe ọ̀rẹ́ mi, a múmi mọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí wọ́n di àwọn ọ̀rẹ́ èmi náà bí a ṣe gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ ìdárayá tí àwọn ọ̀dọ́ ti mo lọ lẹ́hìnwá. Àwọn iṣẹ́ ìdárayá wọnnì ṣe pàtàkì púpọ̀ sí ifibọ̀ mi sínú ìgbé ayé mi tuntun yi.

Ọ̀rẹ́ alàgbà Godoy

Àwọn ọ̀rẹ́ rere wọ̀nyí mú ìyàtọ̀ títóbi kan wá, ṣùgbọ́n bí ìhìnrere kò ṣe jẹ́ kíkọ́ni nínú ilé mi pẹ̀lú ẹbí alátìlẹ́hìn kan ṣì fi ìlànà ìyípadà mi tí ó nlọ lọ́wọ́ sínú ewu. Àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ìhìnrere mi nínú Ìjọ di pàtàkì púpọ̀ sí ìyípadà mi tí ngbèrú síi. Nígbànáà àfikún àwọn ángẹ́lì méjì ni a rán sími láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ṣe ìrànwọ́.

Ọ̀kan lára wọn ni Leda Vettori, olùkọ́ sẹ́mínárì mi ní òwúrọ̀ kùtù. Nípasẹ̀ ìfẹ́ gbígbà àti àwọn ìkọ́ni onímisí rẹ̀, ó fúnmi ní ìwọn ojúmọ́ ti “ọ̀rọ̀ rere ti Ọlọ́run (Mórónì 6:4), èyítí ó jẹ́ nínílò tóbẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi. Èyí rànmí lọ́wọ́ láti gba okun ti ẹ̀mí láti máa tẹ̀síwájú.

Ángẹ́lì míràn tí a rán láti ràn mí lọ́wọ́ ni ààrẹ ti Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin, Marco Antônio Fusco. Bákannáà a yàn án láti jẹ́ ojúgbà mi àgbà fún ìkọ́ni ní ilé. Pẹ̀lú àìní ìrírí mi àti ìfarahàn tí ó yàtọ̀, ó fún mi ní àwọn iṣẹ́ yíyànsílẹ̀ láti kọ́ni nínú àwọn ìpàdé iyejú àwọn àlùfáà wa àti àwọn àbẹ̀wò ìkọ́ni ní ilẹ́. Ó fún mi ní ààyè láti ṣiṣẹ́ àti láti kẹ́kọ̀ọ́, kìí ṣe láti jẹ́ olùworan ìhìnrere lásán. Ó gbẹ́kẹ̀lé mi, ju bí mo ti gbẹ́kẹ̀lé ara mi lọ.

Ọpẹ́ sí gbogbo àwọn ángẹ́lì wọ̀nyí, àti àwọn púpọ̀ míràn tí mo bá pàdé láàrin àwọn ọdún pàtàkì ti ìbẹ̀rẹ̀ wọnnì, mo gba okun tí ó tó láti dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú bí mo ti jèrè ẹ̀rí ti ẹ̀mí nípa òtítọ́ náà.

Àti ní ẹ̀gbẹ́ kan, ọ̀dọ́ ọmọbìnrin ángẹ́lì náà, Mônica? Lẹ́hìn tí àwa méjèèjì ti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, ó di ìyàwó mi.

Èmi kò rò pé ó jẹ́ ṣèèsì pé àwọn ọ̀rẹ́ rere, àwọn ojúṣe Ìjọ, àti bíbọ́ni nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rere ti Ọlọ́run jẹ́ apákan ti ìlànà náà. Ààrẹ Gordon B. Hinckley fi ọgbọ́n kọ́ni: “Kìí ṣe ohun tó rọrùn láti ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ ìpapòdà sí dídarapọ̀ mọ́ Ìjọ yi. Ó túmọ̀ sí gígé àwọn àsopọ̀ àtijọ́. Ó túmọ̀ sí fífi àwọn ọ̀rẹ́ sílẹ̀. Ó le túmọ̀ sí gbígbé àwọn ìgbàgbọ́ tí a mọyì sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ó le nílò àyípadà àwọn ìwà kan àti títẹ àwọn ìpòngbẹ kan mọ́lẹ̀. Ní àwọn ipò tí ó pọ̀ púpọ̀ ó túmọ̀ sí ìdánìkanwà àti ẹ̀rù fún ohun àìmọ̀. Bíbọ́ àti fífún lókun gbọ́dọ̀ wà láàrin àkókò síṣòro yí ní ìgbé ayé ẹnití a ṣẹ̀ṣẹ̀ yípadà kan” (“Àwọn Ìránṣẹ́ Gbọ́dọ̀ Wà,” Ẹ́nsáìnì, Oṣù Kẹwa. 1987, 5).

Lẹ́hìnwá ó fi kún un, “Olúkúlùkù wọn nílò àwọn ohun mẹ́ta: ọ̀re kan, ojúṣe kan, àti títọ́jú pẹ̀lú ‘ọ̀rọ̀ dídára ti Ọlọ́run’” (“Àwọn Olùyípadà àti àwọn Ọdọ́mọkùnrin,” Ensign, May 1997, 47).

Kínidí tí mo fi nṣe àbápìn àwọn ìrírí wọ̀nyí pẹ̀lú yín?

Ìkínní, ó jẹ́ láti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn wọnnì tí wọn nla irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kọjá lọ́wọ́ nísisìyí. Bóyá ó jẹ́ àṣẹ̀ṣẹ̀ yípadà tuntun, tàbí o npàdàbọ̀ wá sí Ìjọ lẹ́hìn rírìnkiri àyíká fún ìgbà díẹ̀, tàbí ẹnìkan tí ó ntiraka láti wọlé. Jọ̀wọ́, jọ̀wọ́, máṣe jáwọ́ nínú akitiyan rẹ láti jẹ́ apákan ẹní nlá yi. Ó jẹ́ Ìjọ ti Jésù Krístì tòótọ́!

Nígbàtí ó bá jẹmọ́ ìdùnnú àti ìgbàlà rẹ, ó máa nfi ìgbàgbogbo yẹ fún akitiyan náà láti tẹ̀síwájú ní títiraka. Ó yẹ fún akitiyan náà láti ṣe àtúnṣe ìgbé ayé àti àwọn àṣà rẹ. Olúwa mọ̀ nípa àwọn ìpèníjà tí o ndojúkọ. O mọ̀ yín, Ó ní ìfẹ́ yín, mo sì ṣe ìlérí pé, Òun yío rán àwọn ángẹ́lì láti ràn yín lọ́wọ́.

Ní àwọn ọ̀rọ̀ Tirẹ̀ Olùgbàlà sọ pé: “Èmi ó lọ níwájú yín. Èmi yíó wà ní ọwọ́ ọ̀tún yín àti ti òsì, … Ẹ̀mí mi yíó wà nínú [ọkàn] yín, àti àwọn ángẹ́lì mi rọ̀gbà yí i yín ká, láti gbé e yín sókè” (Ẹkọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:88).

Ìdí kejì mi fún síṣe àbápín àwọn ìrírí wọ̀nyí ni láti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ—sí gbogbo wa. A níláti rántí pé kò rọrùn fún àṣẹ̀ṣẹ̀ yípadà tuntun, àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n npàdàbọ̀, àti àwọn wọnnì pẹ̀lú ìgbé ayé tí ó yàtọ̀ láti wọlé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Olúwa mọ̀ nípa àwọn ìpèníjà tí wọ́n ndojúkọ, Ó sì nwá àwọn ángẹ́lì tí wọ́n ṣetán láti ṣe ìrànlọ́wọ́. Olúwa máa nfi ìgbàgbogbo wá àwọn oníṣẹ́-ọ̀fẹ́ tí wọ́n ṣetán lati jẹ́ ángẹ́lì nínú ayé àwọn ẹlòmíràn.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, njẹ́ ẹ̀yin ó ṣetán lati jẹ́ ohun èlò ni ọwọ́ Oluwa bí? Njẹ́ ẹ̀yin ó ṣetán lati jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ángẹ́lì wọ̀nyí bí? Láti jẹ́ amí kan, tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, láti apá ìhín ti ìbòjú, fún ẹ̀nìkan tí Òun nṣe ànìyàn nípa rẹ̀? Ó nílò yín. Wọ́n nílò yín.

Bẹ́ẹ̀ni, a le fi ìgbàgbogbo gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Wọ́n máa nfi ìgbàgbogbo wà níbẹ̀, àwọn àkọ́kọ́ láti tò fún bíi ti àwọn ángẹ́lì yí. Ṣùgbọ́n wọn kò tó.

Bí ẹ bá wò káàkiri pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ẹ ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ ángẹ́lì. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí le má wọ ẹ̀wù funfun, àwọn kaba, tàbí èyíkéyi àṣọ wíwọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi. Wọ́n le máa dá nìkan jóko, ní ọ̀nà ẹ̀hìn ilé ìpàdé tàbí yàrá ìkẹ́kọ, nígbàmíràn pẹ̀lú ìmọ̀lára bíi pé a kò le rí wọn. Bóyá irun orí wọn léwu díẹ̀ tàbí èdè ìsọ̀rọ̀ wọn yàtọ̀, ṣùgbọ́n wọ́n wà níbẹ̀, wọ́n sì ngbìyànjú.

Àwọn míràn le máa ròó, “Ṣé kí nsì máa padà wá bí? Ṣé kí nsì máa gbìyànjú?” Àwọn miràn le máa ròó bóyá ní ọjọ́ kan àwọn ó ní ìmọ̀lára títẹ́wọ́gbà àti fífẹ́. A nílò àwọn ángẹ́lì, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí; àwọn ángẹ́lì tí ó nifẹ láti fi ibi ìtura wọn sílẹ̀ láti gbà wọ́n mọ́ra; “[àwọn ènìyàn tí ó] dára gan tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́ gan tí ó fi jẹ́ bíiti ángẹ́lì ni ọ̀rọ̀ kanṣoṣo tí ó wá sọ́kàn [láti júwe wọn]” (Jeffrey R. Holland, “The Ministry of Angels,” 30).

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, mo gbàgbọ́ nínú àwọn angẹ́lì! Gbogbo wa wà níhin lóni, ọ̀wọ́ ogun nlá àwọn angẹ́lì kan tí a ti yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn bíi ìnàjáde ọwọ́ olùfẹ́ni Ẹlẹ́da kan. Mo ṣe ìlérí pé bí a bá ṣetán láti sìn, Olúwa yío fún wa ní àwọn ànfàní láti jẹ́ ángẹ́lì oníṣẹ́ ìránṣẹ́. Ó mọ ẹnití ó nílò ìrànlọ́wọ́ bíi ti ángẹ́lì, Òun ó sì fi wọ́n sí ipa ọ̀nà wa. Olúwa nfi àwọn wọnnì tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ bíi ti ángẹ́lì sí ipa ọ̀nà wa ní ojojúmọ́.

Mo fi ìmoore hàn gidigidi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn angẹ́lì tí Olúwa ti fi sí ipa ọ̀nà mi ní gbogbo ìgbé ayé mi. Wọ́n jẹ́ nínílò. Mo fi ìmoore hàn bákannáà fún ìhìnrere Rẹ̀ tí ó ràn wá lọ́wọ́ láti yípadà tí ó sì fúnwa ní ààyè láti dára síi.

Èyí ni ìhìnrere ìfẹ́, ìhìnrere iṣẹ́ ìránṣẹ́. Nípa Èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.