Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ̀bùn Dídára ti Ọmọ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ẹ̀bùn Ọlọ́rìnrìn ti Ọmọ

Nípasẹ̀ Jésù Krístì, a lè yọ nínú àwọn ìrora ìkùnà ìwà wa kí a sì borí àwọn ìrora tí kò tọ́ sí wa nípa àwọn aburú ayé ikú wa.

Nígbàtí mo nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì fún ẹ̀kọ́ Wá, Tẹ̀lé Mi ní ìgbà ìsinmi tó kọjá, ìròhin láti ẹnu Álmà là mí gàrà pé nígbàtí òun nífura kíkún nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òun, kò sí “ohun kan tó tayọ tóbẹ́ẹ̀ àti bí ìkorò ìrora [rẹ̀] ṣe tó.”1 Mo jẹ́wọ́ pé, ọ̀rọ̀ ìrora dídára náà jáde sí mi ní apákan torí ogun jíjà mi pẹ̀lú òkúta millímítà-méje kídìnrín ní ọ̀sẹ̀ náà. Ọkùnrin kan kò ní ìrírí irú “ohun nlá” bẹ́ẹ̀ rí nígbàtí ohun “nlá àti kékeré” nwá “sí ìmúṣẹ”2

Èdè Álmà bákannáà yọ sítanítorí ọ̀rọ̀ náà títayọ nínu ìtumọ̀ Gẹ̀ẹ́sì Ìwé ti Mọ́mọ́nì, fi ìjọra júwe àwọn ohun ẹlẹ́wà tó tayọ tàbí títóbi tí kò láfiwé. Fún àpẹrẹ, Joseph Smith fi ìrántí ṣe àkíyèsí pé ángẹ́lì Mórónì wọ aṣọ “funfun tó tayọ,” “funfun tí ó kọjá ohun ti ayé kankan tí [ó] kò tíì rí rí.”3 Síbẹ̀ yíyàtọ̀ bákannáà lè gbé títóbi gidi àwọn ohun ẹ̀rù jáde. Báyìí, Álmà àti àwọn ìwé-ìtumọ̀ so títayọ ìrora pọ̀ sí jíjẹ́ “ìdálóró,” “gbígbò,” àti “ìforó” sí “ipò títóbi jùlọ.”4

Ìronú Almà fi òtítọ́ gbígbọ̀n hàn pé ní àmì kan, ẹ̀bi kíkún olóró ti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ní a gbọ́dọ̀ ní lára. Ìdáláre bèèrè fun un, àti pé Ọlọ́run Fúnrarẹ̀ kò yipadà.5 Nígbàtí Álmà rántí “gbogbo” ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—nípàtàkì àwọn tí ó pa ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn run—ìrora rẹ̀ fẹ́rẹ̀ di àìlègbà mọ́ra, àti pé èrò dídúró níwájú Ọlọ́run kún inú rẹ̀ pẹ̀lú “ìbànújẹ́ àìlèsọ.” Ó yára làti “di mímúkúrò ní ẹ̀mí àti ara.”6

Bkannáà, Álmà wípé ohungbogbo bẹ̀rẹ̀ láti yípadà ní àkokò tí “ọkàn mi dúró lórí” àṣọtẹ́lẹ̀ “bíbọ̀ Krístì kan … láti ṣe ètutù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé” ó sì “kígbe ní ọkàn [rẹ̀]: Jésù, ìwọ Ọmọ Ọlọ́run, ṣàánú fún mi.” Pẹ̀lú èrò kan àti ẹ̀bẹ̀ kan yẹn, Álmà kùn fún ayọ̀ “títayọ” “títóbi bí ìrora [rẹ̀] ti pọ̀.”7

A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé èrèdí gan nípa ìr`núpìwàdà ni láti mú ọ̀ṣì pàtó kí a sì yi padà sí àláfíà mímọ́ Ọpẹ́ s “ìwà rere ẹsẹ̀kẹsẹ̀” Rẹ̀,8kété tí a bá wá sọ́dọ̀ Krístì—ní ìjúwe ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ àti ìyípadà òtítọ́ ti ọkàn—ẹrù àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa yíò bẹ̀rẹ̀ sí nyí kúrò ní ẹ̀hìn wa sí Tirẹ̀. Èyí ṣeéṣe nìkan nítorí Òun tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ ti jìyà “ìrora àìlópin àìlèsọ”9 nípa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ayé nípa àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀—ìjìyà kan tó le gidi, tí ẹ̀jẹ̀ njáde nínú ihò gbogbo ara Rẹ̀. Látinú ìrírí, araẹni tààrà, Olùgbàlà kìlọ̀ fún wa báyìí, nínú ìwé mímọ́ òde-òní, pé a kò ní èrò bí “títayọ” bí àwọn “ìjìyà” wa yíò jẹ́ tí a kò bá ronúpìwàdà. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìnúrere àìlèmọ̀ “Èmi, Ọlọ́run, ti jìyà àwọn ohun wọ̀nyí fùn gbogbo ènìyàn, kí wọ́n má bà jìyà tí wọ́n bá ronúpìwàdà”10—ìrònúpìwàdà èyí tí ó fàyè gbà wá láti “tọ́” ayọ “títóbi” tí Álmà ti tọ́wò rí wo.11 Fún ẹ̀kọ́ yí nìkan, “Mo dúró ní gbogbo ìyanu.”12 Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú ìyanilẹ́nu, àní Krístì fúnni ní púpọ̀ si.

Nígbàmíràn ìrora dídára kò wá látinú ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n látinú àwọn àṣìṣe òtítọ́, àwọn ìṣe ẹlòmíràn, tàbí agbára tó kọjá àkóso wa. Nínú àwọn àkokò wọ̀nyí. Ẹ lè kígbe bíiti Olórín olódodo:

“Àyà dùn mí gidigidi nínú mi: Ìpayà ikú sì ṣubú lù mí.

“… Àti ìbẹ̀rù ikú bò mí mọ́lẹ̀.

“… A! ìbá ṣe pé èmi ní ìyẹ́ apá bí àdàbà! èmi ìbá fò lọ, èmi a sì simi.”11

Síyẹ́nsì egbòogi, àmọ̀ràn ọ̀jọ̀gbọ́n, tàbí àtúnṣe òfin lè ràn wá lọ́wọ́ láti dín ìjìyà wa kù. Ṣùgbọ́n kíyèsi, gbogbo ẹ̀bùn rere—pẹ̀lú ìwọ̀nyí—wá látọ̀dọ̀ Olùgbàlà.14 Láìka ìdí ìpalára àti ìrora-ọkàn wa tó burù jù sí, orísun ìgbẹ̀hìn ìrànlọ́wọ́ rí bákannáà: Jésù Krístì. Òun nìkan ló di agbára kíkún mú àti ìkúnra ìwòsàn láti tùn gbogbo àṣìṣe ṣe, títọ́ kúrò nínú àṣìṣe, títún gbogbo àìpé ṣe, wo gbogbo ọgbẹ́ sàn, àti fúnni ní gbogbo ìbùkún tó ní ìdádúró. Bí àwọn ẹlẹri àtijọ́, mo jẹri pé “a kò ní àlùfáà gíga èyí tí kò lè ní ìmọ̀lára àwọn àìlera wa,”13 ṣùgbọ́n Olùràpadà olùfẹ́ni ẹnití ó sọ̀kalẹ̀ láti ìjọba Rẹ lókè tí ó sì jáde lọ ní “jíjìyà ìrora àti ìpọ́njú àti onírurú àwọn àdánwò … , kí ó lè mọ … bí òun ó ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́.”14

Fún ẹnikẹ́ni ní òní pẹ̀lú àwọn ìrora líle tàbí àìlékejì gidi pé ẹ ní ìmọ̀lára pé ẹnìkankan kò lè mọyì wọn ní kíkún, ẹ lè ní àmì kan níbẹ̀. Ó mà tilẹ̀ sí ẹbí kankan, ọ̀rẹ́, tàbí olórí oyè-àlùfáà—èyíówù kí ìfura àti ìtumọ̀-dáadáa tí ọ̀kọ̀ọ̀kan lè jẹ́—ẹnití ó mọ déédé ìmọ̀lára ohun tí ẹ̀ nní tàbí tí ó ní ọ̀rọ̀ ìbámu láti ràn yín lọ́wọ́ láti rí ìwòsàn. Ṣùgbọ́n mọ èyí pé: ẹnìkan wà tí ó mọ̀ ohun tí ẹ̀ nní ìrírí rẹ̀ ní pípé, ẹni tí ó “tóbí ju gbogbo ayé lọ,”17 àti ẹnití ó “lè ṣe púpọ̀ kọjá ohun gbogbo tí [ẹ] bèèrè tàbí ronú lọ.”18 Ètò náà yíò hàn nínú ọ̀nà Rẹ̀ àti nínú iṣètò Rẹ̀, ṣùgbọ́n Krístì dúró ní ṣíṣetán nígbàgbogbo láti wò gbogbo ibi àti èròngbà ti ìrora yín sàn.

Bí ẹ ti nfi ààyè gbà Á láti ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó ri pé àwọn ìrora yín kò já sí asán. Ní sísọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọni àti ìbànújẹ́ wọn, Àpóstélì wípé “Ọlọ́run … pèsè àwọn ohun dídárá fún wọn nípasẹ̀ ìjìyà wọn, nítorí láìsí ìjìyà wọn kò lè di pípé.”19 Ẹ ri pé, ìwà ẹ̀dá Ọlọ́run gan an àti èrò wíwà láye wa ni ìdùnnú,20 ṣùgbọ́n a kò lè di ènìyàn pipé alayọ̀ tọ̀run láìsí àwọn ìrírí tí yíò dán wa wò, nígbàmíràn dénúdénú wa. Gẹ́gẹ́bí Páùlù ṣe tún àwọn àkọsílẹ̀ sọ, Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ ni a ṣe “pé [tàbí ṣetán] ní-ayérayé nípa ìjìyà.”21 Nítorínáà ẹ yẹra ní ìlòdì sí ìkùnsí sátánì pé tí ẹ bá jẹ́ ẹni dídára, ẹ ó yẹra fún irú àwọn àdánwò náà.

Bákannáà ẹ gbọ́dọ̀ kọ irọ́ pé ìjìyà yín dá àbá pé ẹ dúró ní ìta agbo àwọn àṣàyàn Ọlọ́run, ẹnití ó dàbí ó ṣàṣeyọrí láti ipò ìbùkún kan sí òmíràn. Dìpò bẹ́ẹ̀, ẹ rí ara yín bí Jòhánnù Olùfihàn ṣe ríi yín dájúdájú nínú ìfihàn ọlánlá ti àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Nítorí Jòhánnù sì rí “ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn, tí ẹnìkẹ́ni kòlè kà, látinú orílẹ-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, [ẹnití] ó dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú ọ̀dọ́-àgùtàn náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ funfun, … [ẹnití] ó kígbe pẹ̀lú ohun rara, wípé, Ìgbàlà sí Ọlọ́run wa.”22

Nígbàtí wọ́n bèèrè, “Tani àwọn wọ̀nyí tí a wọ̀ ní aṣọ funfun ni? níbo ní wọ́n sì ti wá?” Jòhánnù gba èsì, “Àwọn wọ̀nyí ni ó jáde láti inú ìpọ́njú nlá, wọ́n sì fọ àṣọ wọn, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn náà.”23

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ rántí nígbàgbogbo pé ìjìyà nínú òdodo nṣèrànwọ́ láti mú yín yege, sànju yíyà yín sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀, àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run. Àti pé ó ṣe àwọn ìlérí wọn ní àwọn ìlérí yín. Gẹ́gẹ́bí Jòhánnù ti wí “ebi kì yíò pa yín mọ́, bẹ́ẹ̀ni òhùngbẹ kì yíò gbẹ yín mọ́; bẹ́ẹ̀ni òòrùn kì yíò pa [yín], mọ́, tàbí oorukóru. Nítorí Ọ̀dọ́-àgùtàn tí mbẹ ní ààrin ìtẹ́ náà ni yíò bọ́ [yín], yíò sì darí [yín] lọ sí orísun ìyè àwọn omi: Ọlọ́run yíò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú yín.”24

“Kò sì ní sí ikú mọ́, tàbí ìbànújẹ́, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ni kò ní sí ìrora mọ́.”

Mo jẹri sí yín pé nípasẹ̀ inúrere Jésù Krístì àti Ètùtù àìlópin Rẹ tó tànká, a le fo àwọn ìrora ìwà ìkùnà lílẹ́tọ́ wa dá kí a sì ṣẹ́gun àwọn ìrora àìlẹ́tọ́ ti àìníóríre ayé ikú wa. Lábẹ́ ìdarí Rẹ̀, àyànmọ́ àtọ̀runwá yín ni ọ̀kan lára ayọ̀ nlá tí kò láfiwé tí kò sì ṣe fẹnusọ—ayọ̀ kan tó le gidi tí kò sì lékejì sí yín, “àwọn eérú” yín ní pàtàkì yíò di ẹwà “kọjá ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ayé.”26 Kí ẹ lè tán ìdùnnú yín wò nísisìyí kí ó sì kún inú yín títí láé, mo pè yín láti ṣe ohun tí Álmà ṣe: Ẹ jẹ́ kí inú yín di ẹ̀bùn títayọ ti Ọmọ Ọlọ́run mú bí a ṣe fihàn nípasẹ̀ ìhìnrere Rẹ nínú èyí, Ìjọ alààyè àti òtítọ́ Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.