Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020 Abala Òwúrọ̀ Sátidé Abala Òwúrọ̀ Sátidé Russell M. NelsonTítẹ̀ SíwájúÀàrẹ Nelson kọ̀ni pé pẹ̀lú ìpọ́njú, iṣẹ́ Olúwa nls síwájú a sì lè lo àkokò yí láti dàgbà níti ẹ̀mí. David A. BednarÀwa Yóò Dán Wọn Wò BáyiAlàgbà Bednar kọ́ni pé bí a bá múrasílẹ̀ tí a sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, a ó lè ṣẹgun ìpọ́njú. Scott D. WhitingDídà Bí Rẹ̀Alàgbà Whiting kọ́ni bí a ti lè tẹ̀lé òfin láti dà bí Olùgbàlà wa, Jésù Krístì si. Michelle D. CraigÀwọn Ojú láti RíArábìnrin Craig kọ́ni pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ a lè kọ́ láti rí àwọn ẹlòmíràn àti arawa bí Olùgbàlà ti ṣe. Quentin L. CookÀwọn Ọ̀kan Iṣọ̀kan ní Òdodo àti Ìṣọ̀kanAlàgbà Cook gbà àwọn ọmọ ìjọ níyànjú láti jẹ́ ènìyàn Síónì àti láti gbé nínú òdodo, dída óásísì ìrẹ́pọ̀ nígbàtí a bá nṣayẹyẹ onírurú. Ronald A. RasbandÌkaniyẹ sí OlúwaAlàgbà Rasband gba wá níyànjú láti tiraka láti jẹ́ “ìkaniyẹ sí Olúwa nípa títẹ̀lé Olùgbàlà àti jíjẹ́ yíyẹ ti ìkaniyẹ tẹ́mpìlì. Dallin H. OaksFẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá RẹÀàrẹ Oaks kọ́ni pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà, ó ṣeéṣe láti gbọ́ràn àti láti wá láti tún àwọn àṣẹ orílẹ̀-èdè wa ṣe àti pé bákannáà láti nifẹ àwọn onúnibíni wa àti àwọn ọ̀tá wa. Abala Ọ̀sán Sátidé Abala Ọ̀sán Sátidé D. Todd ChristoffersonÀwọn Àwùjọ AlágberóAlàgbà Christofferson kọ́ni pé òtítọ́ Ọlọ́run nawọ́ sí ọ̀nà ìdùnnú araẹni kan àti wíwà-dáadáa ìletò nísisìyí àti àláfíà àti ayọ̀ lẹ́hìnwá. Steven J. LundRírí Ayọ̀ nínú KrístìArákùnrin Lund kọ́ni pé àwọn ọ̀dọ́ le r ayọ̀ nínú Krístì nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú nípasẹ̀ ètò Àwọn Ọmọdé àti Ọdọ́. Gerrit W. GongGbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè, Ìbátan, àti AhọnAlàgbà Gong júwe bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí láti bùkú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ndi mímúṣẹ, ní àwọn ọ̀nà kékeré àti ìrọ̀rọ̀. W. Christoper WaddellBúrẹ́dì WàBiṣọ́ọ̀pù Waddell kọ́ni pé ó yẹ kí a wá ìmísí kí a sì gbaralé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere láti di olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni. Matthew S. HollandẸ̀bùn Ọlọ́rìnrìn ti ỌmọAlàgbà Holland júwe bí ìjìyà àti Ètùtù Jésù Krístì lè yípada sí òṣì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìpọ́njú sí ayọ̀ William K. JacksonÀṣà KrístìAlàgbà Jackson kọ́ni pé gbogbo wa lè ṣe àjọyọ̀ àwọn àṣà ilẹ̀-ayé olúkúlúkú wa nígbàtí a njẹ́ ara ìhìnrere Jésù Krístì. Dieter F. UchtdorfỌlọ́run Yíò Ṣe Ohun Àìlerò Kan Alàgbà Uchtdorf kọ́ni pé bí a ṣe nfaradà àwọn àdánwò wa, Ifẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ìbùkún ìhìnrere yíò ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájù àti síwáju sí ibi gíga tí a kò lérò. General Women’s Session General Women’s Session Sharon EubankNípa Ìṣọ̀kan ti Ìmọ̀lára A Gba Agbára pẹ̀lú Ọlọ́runArábìnrin Eubank kọ́ni bí a ti lè ṣe àṣeyege ìrẹ́pọ̀ gíga jù pẹ̀lú arawa kí a sì gbà agbára gíga ju látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Becky CravenTẹramọ́ YíyípadàArábìnrin Craven kọ́ni pé nípasẹ̀ Jésù Krístì, a lè ṣe àwọn ìyípadà pípẹ́ kí a sì dà bíi Tirẹ̀ si. Cristina B. FrancoAgbára Ìwòsàn ti Jésù KrístìArábìnrin Franco kọ́ni pé nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì, gbogbo wa lè ṣe àtúnṣe kí a sì wòsàn. Ìmọ́lẹ̀ Tí Ntàn nínú ÒkùnkùnÌkójọ jẹ́jẹ́ fífíò kan nípa àwọn obìnrin káàkiri ayé nṣiṣẹ́ ní àwọn onírurú ipò iṣẹ́ ìsìn, ìpènijà, àti ìsopọ̀. Henry B. EyringAwọn Arábìnrin ní SíónìÀàrẹ Eyring kọ́ni pé ẹ̀yin obìnrinyíò jẹ́ kókó sí kíkójọ Ísráẹ́lì àti ní dídásílẹ̀ àwọn ènìyàn Síónì kan tí ó ngbé ní àláfíà ní Jerúsálẹ́mù Titun. Dallin H. OaksẸ tújúka.Ààrẹ Oaks kọ́ni pé nítorí ìhìnrere a lè tújúká, àní ní àárín àwọn ìpènijà àti ìpọ́njú. Russell M. NelsonGba Ọjọ́ Ọ̀la Mú Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́Ààrẹ Nelson kọ́ni pé ó yẹ́ kí a múrasílẹ̀ níti ara, níti ẹ̀mí, àti ẹ̀dùn ọkàn ọjọ́ ọ̀la. Abala Àárọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi Abala Àárọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi M. Russell BallardẸ Máa Ṣọ́ra Nítorínáà, Kí Ẹ sì Máa Gbàdúrà Nígbà GbogboÀàrẹ Ballard kọ́ wa láti gbàdúrà fún ààbò àti àláfíà fún orílẹ̀-èdè wa. Lisa L. HarknessÀláfíà, Dákẹ́ Jẹ́Arábìnrin Harkness kọ́ni pé gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ti mú òkun Gálílì dákẹ́ jẹ́, Òun lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí okun àti àláfíà ní àárín àwọn àdánwò. Ulisses SoaresẸ Wá Kristì Nínú Gbogbo Èrò ỌkànAàgbà Soares kọ́ni pé pípa àwọn èrò ọkàn àti ìfẹ́ inú wa mọ́ ní rere maa nràn wá lọ́wọ́ lati kojú ìdánwò. Carlos A. GodoyMo Gbàgbọ́ nínú Àwọn Angẹ́lìAlàgbà Godoy kọ́ni pé Olúwa mọ àwọn àìní wa àti pé Òun yíò rán àwọn ángẹ́lì láti ràn wá lọ́wọ́. Neil L. AndersenÀ Sọ̀rọ̀ Nípa KrístìAlàgbà Andersen gbà wá níyànjú láti kẹkọ si nípa Olùgbàlà àti pé kí a sọ̀rọ̀ nípa Rẹ̀ nílé, ní ìjọ, lórí ìròhìn àwùjọ, àti nínú ìbárasọ̀rọ̀ ojojúmọ́ wa. Russell M. NelsonJẹ́kí Ọlọ́run BoríÀàrẹ Nelson júwe májẹ̀mú Ísráẹlì ọjọ́-ìkẹhìn bí àwọn ẹnití ó jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wọn. Ó pè wá láti mú Ọlọ́run jẹ́ alágbára pàtàkì jùlọ nínú ayé wa. Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Ìsimi Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Ìsimi Henry B. EyringDánwò, Ridi, àti DídánÀàrẹ Eyring kọ́ni pé fífarada àwọn àdánwò ti ayé ikú lódodo nrànwálọ́wọ́ láti dàbii ti Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Jeremy R. JaggiẸ Jẹ́ kí Sùúrù Ṣe Àṣepé Iṣẹ́ Rẹ̀, ẹ sì Ka Gbogbo Rẹ̀ Sí Ayọ̀!Alàgbà Jaggi ṣàlàyé bí a ṣe lè rí ayọ̀, àní ní àwọn ìgbà ìpọ́njú, nípa lílo sùúrù àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Gary E. StevensonOjúrere Olúwa Lọ́pọ̀lọpọ̀Alàgbà Stevenson kọ́ni pé bí o´ tilẹ̀ jẹ́ pé a dojúkọ ìjákulẹ̀ àti ìpọ́njú, a lè wá láti mọ̀ pé a ní ojúrere Olúwa Lọ́pọ̀lọpọ̀. Milton CamargoBèèrè, Wá Kiri, sì KànkùAràkùnrin Camargo kọ́ni bí a ṣe lè bèèrè, wákiri, kí a si kànkù nínù àdúrà. Dale G. RenlundṢe Ní Òdodo, Nífẹ Àánú, kí o sì Rì ní Ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́runAlàgbà Relun ṣàlàyé bí títẹ̀lé àmọ̀ràn ní Máíkà 6:8 fi lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú àti kí a dàbíiti Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì si. Kelly R. JohnsonAgbára ÌfaradàAlàgbà Johnson kọ́ni pe\ a lè ní ààyè sí agbára Ọlọ́run nípa gbígbé ìgbàgbọ́ wa ga àti pípa àwọn májẹ̀mú wa mọ́. Jeffrey R. HollandDídúró de OlúwaAlàgbà Holland kọ́ni pé a lè ní ìgbàgbọ́ pé Olúwa yíò dáhùn àwọn àdúrà wa ní àkokò Rẹ̀ àti ní ọ̀nà Rẹ̀. Russell M. NelsonTítọ́ Titun KanÀàrẹ Nelson kọ́ wa láti yí ọkàn wa padà sí Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà láti ṣaṣeyege agbára àtọ̀runwá wa àti làti nì ìmọ̀lára àláfíà. Ó kéde àwọn tẹ́mpìlì titun mẹ́fà.