Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Wá Kristì Nínú Gbogbo Èrò Ọkàn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ẹ Wá Kristì Nínú Gbogbo Èrò Ọkàn

Jíjà ní títako àdánwò gba ọjọ́ ayé ti síṣe aápọn àti síṣòtítọ́. Ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé Olúwa ṣetán láti tì wá lẹ́hìn.

Nínú ewì orin ìyìn rẹ̀, Onísáàmù náà sọ pé:

“Olúwa, ìwọ ti wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.

“Ìwọ mọ ìjóko mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.

“Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mímọ̀ fún ọ.”1

Nínú ìbárajọ àròsọ ti ewì yí, Onísáàmù náà yin àbùdá àtọ̀runwá ti Jésù Krístì bíi olùmọ̀ ohun gbogbo nítorípé nítòótọ́ Ó mọ gbogbo abala ọkàn wa.2 Ní mímọ ohun gbogbo tí ó ṣe dandan fún wa ní ayé yi, Olùgbàlà pè wá láti wá Òun nínú gbogbo èrò àti láti tẹ̀lé E pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa.3 Èyí nfún wa ní ìlérí n náà pé a le rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ àti pé ìtọ́ni Rẹ̀ ndènà agbára òkùnkùn nínú ayé wa.4

Wíwá Krístì nínú gbogbo èrò àti títẹ̀lé E pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa nílò pé kí a mú ọkàn àti àwọn ìfẹ́ inú wa bárajọ pẹ̀lú Tirẹ̀.5 Àwọn ìwé mímọ́ tọ́kasí mímúbárajọ yi bíi “[dí]dúró ṣinṣin nínú Olúwa.”6 Èyí tọ́ka sí pé láìdúró kí a máa darí ìgbé ayé wa ní ìbámu pèlú ìhìnrere ti Krístì kí a sì fi ojú sùn lójoojúmọ́ sí orí ohun gbogbo tí ó jẹ́ rere.7 Nígbànáà nìkan ni a le gba “àlàáfíà Ọlọ́run, èyítí ó kọjá gbogbo òye” àti èyítí yío “pa ọkàn àti inú [wa] mọ́ nípasẹ̀ Jésù Krístì.”8 Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ pàṣẹ fún àwọn alàgbà Ìjọ ní Oṣù Keji 1831pé, “Pa àwọn ohun wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ, kí o sì jẹ́kí àwọn ọ̀wọ̀ ti ayérayé sìnmi lé inú rẹ.”9

Àní pẹ̀lú àwọn akitiyan wa lemọ́lemọ́ láti wá Olúwa, àwọn èrò ọkàn tí kò dára sì le wọ inú wa. Nígbàtí a bá gba irú àwọn èrò ọkàn bẹ́ẹ̀ láàyè àti tí a pèé láti dúró, wọ́n le ṣe apẹrẹ àwọn ìfẹ́ inú ọkàn wa kí wọn ó sì darí wa sí ohun tí a ó dà ní ayé yi àti ohun ti a ó jogún fún ayérayé.10 Alàgbà Neal A. Maxwell fi ìgbà kan rí tẹnumọ́ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ yi nípa sísọ pé, “Àwọn ìfẹ́ tún npinnu àwọn àyọrísí, pẹ̀lú ìdi tí a fi pe ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ní a yàn.’”13

Ǎwọn wòlíì wa àtijọ́ àti ti òde òní ti ránwaléti léraléra láti dojú ìjà kọ ìdánwò kí a le yẹra fún pípàdánù agbára wa ní ti ẹ̀mí kí a sì di pípòrũrũ, dídààmú, àti jíjakulẹ̀ ní ìgbé ayé.

Ní sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú àfiwé, títẹ̀ sí àwọn àdáwò dà bíi títọ mágínẹ́tì lọ pẹ̀lú ohun kan ti a fi irin ṣe. Ipá àìfojúrí ti mágínẹ́tì náà ndi ohun náà mú sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ a sì dì í mú ṣinṣin. Mágínẹ́tì máa npàdánù agbára rẹ̀ lórí rẹ̀ nígbàtí a bá fi ohun àfirinṣe náà sí ibi tí ó jìnnà sí i nìkan. Nítorínáà, gẹ́gẹ́bí mágínẹ́tì yi kò ṣe le lo agbára lórí ohun ti a fi irin ṣe kan tí ó jìnnà rere, bí a ṣe ndojú ìjà kọ àwọn àdánwò, wọ́n máa nparẹ́ wọ́n sì máa npàdánù agbára wọn lori inú àti ọkàn wa àti pé, ní ìyọrísí, lórí àwọn ìgbésẹ̀ wa.

Àfiwé yi ránmilétí ìrírí kan tí olóotọ́ gidi ọmọ Ìjọ kan ṣe àbápín pẹ̀lú mi ní ìgbà kan sẹ́hìn. Ó sọ fúnmi pé nígbàtí òun jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, èrò rírínilára kan tí òun kò tíì ní ìrírí rẹ̀ rí tẹ́lẹ̀ wọ inú rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó báa lójijì pátápátá, ó fèsì tako ipò náà ní ìpín ìṣẹ́jú àáyá kan, ní sísọ sí ara rẹ̀ àti sí èrò náà pé, “Rárá!” tí ó sì rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú ohun rere kan láti ya ọkàn rẹ̀ kúrò ní ti èrò àìnífẹsí náà Ó sọ fúnmi pé bí òun ti lo ìwà òmìnira rẹ̀ láti yàn nínú òdodo, èrò àìronúsí burúkú, náà parẹ́ lójúkannáà.

Nígbàtí Moronì ké sí àwọn wọnnì tí wọn kò gbàgbọ́ nínú Krístì láti ronúpìwàdà, ó kìlọ̀ fún wọn láti wa sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn, ní bíbọ́ ara wọn kúrò nínú gbogbo àìmọ́. Síwájú síi, Moronì gbà wọ́n nímọ̀ràn láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìpinnu tí kò ṣeé ṣẹ́, pé àwọn kò ní ṣubú sínú ìdánwò.14 Mímú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí lò nínú ìgbé ayé wa bèèrè ju ìgbàgbọ́ lásán lọ; ó bèèrè fún títún inú àti ọkàn wa ṣe sí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àtọ̀runwá wọ̀nyí. Irú àtúnṣe bẹ́ẹ̀ bèèrè fún aápọn ti ara ẹni lójoojúmọ́ àti léraléra, ní àfikún sí gbígbára wa lé Olùgbàlà, nítorí pé àwọn ohun fífẹ́ wa ti ayé kíkú kò ní parẹ́ fúnra wọn. Jíjà tako ìdánwò gba ọjọ́ ayé ti síṣe aápọn àti síṣòtítọ́. Ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́, ẹ mọ̀ pé Olúwa ṣetán láti rànwá lọ́wọ́ nínú àwọn aápọn ara ẹni wa ó sì ṣe ìlérí àwọn ìbùkún tó lápẹrẹ bí a bá forítì dé òpin.

Láàrin àkókò ìṣoro kan pàtó nígbàtí Joseph Smith àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ rẹ̀ ní Ọgbà Ẹwọn Liberty kò ní òmìnira nínú ohunkóhun bíkòṣe fún àwọn èrò ọkàn wọn, Olúwa pèsè ìmọ̀ràn rírannilọ́wọ́ àti ìlérí kan fún wọn èyítí ó le ràn dé ọ̀dọ̀ gbogbo wa:

“Kí inú rẹ pẹ̀lú kún fún ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ sí gbogbo ènìyàn, àti sí ará ilé ìgbàgbọ́, kí ìwa ọ̀run ó sì ṣe èrò ọkàn rẹ lọ́ṣọ̀ọ́ láì dáwọ́ dúró; nígbànáà ni ìfi ọkàn tán rẹ yíò ní agbára síi ní ọdọ̀ Ọlọ́run; …

“Ẹ̀mí Mímọ́ yíò jẹ́ alábàárìn rẹ ní gbogbo ìgbà, àti pé ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pa àṣẹ tí kìí yípadà ti ìṣòdodo àti òtítọ́.”13

Ní síṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èrò mímọ́ yío máa ṣe inú wa lọ́ṣọ̀ọ́ láìdúró àti pé àwọn ìfẹ́ inú àìlábàwọ́n yío darí wa sí àwọn ìgbésẹ̀ òdodo.

Mórónì pẹ̀lú rán àwọn ènìyàn rẹ̀ létí láti máṣe jẹ́ gbígbémì nípa àwọn ìfẹ́kúfẹ wọn.14 Ọrọ̀ náà ìfẹ́kúfẹ ntọ́ka sí fífi agbára fẹ́ àti ìfé inú ti kò dára fún ohun kan.15 Ó ṣe àkópọ̀ èyíkéyi àwọn èrò tó ṣókùnkùn tàbí àwọn ìfẹ́ inú ibi tí ó nfa ẹnìkọ̀ọ̀kan láti fi ojú sùn sí àwọn ìwa ìmọ-taraẹni-nìkan tàbí kíkó àwọn ohun ìní ti ayé jọ dípò ṣíṣe rere, jẹ́ onínúrere, àti ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ó nfarahàn ní ọ̀pọ̀ ìgbà nípasẹ̀ àwọn ìmọ̀lára ti ara jùlọ nínú ọkàn. Paulù Apóstélì ṣe ìdámọ̀ díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí, bí iirú “àìmọ́, wọ̀bìà, … ìkórìíra, … ìbínú, ìjà, … ìlara, … àti iru wọn.”17 Yàtọ̀ sí gbogbo àwọn abala búburú ti ìfẹ́kúfẹ, a kò le gbàgbé pé ọ̀tá nlò ó bíi ohun ìjà rẹ̀ ìkọ̀kọ̀ dojú kọ wá nígbàtí ó bá dán wa wò láti ṣe ohun àìtọ́ kan.

Ẹyin olólùfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti ngbé ara le orí àpáta ìgbàlà, Oùgbàlà ọkàn wa, tí a sì ntẹ̀lé ìmọ̀ràn Moronì, agbára wa láti darí àwọn èrò ọkàn wa yío pọ̀ síi ní pàtàkì. Mo le fi dá yín lójú pé dídàgbà wa ní ti ẹ̀mí yío pọ̀ síi ní ìgbésẹ̀ àlékún, ní yíyí ọkàn wa padà, ní mímú wa dà bíi Jésù Krístì síi. Ní àfikún, ipá ti Ẹmí Mímọ́ yío di lílágbára síi àti àìdúró nínú ayé wa. Àwọn ìdánwò ọ̀tá, díẹ̀ díẹ̀, yío pàdánù agbára wọn lórí wa, tí yío yọrí sí inú dídùn àti ìgbé ayé ìwà rere síi.

Fún àwọn wọnnì tí, fún ìdí yìówù, wọ́n ṣubú sínú ìdánwò tí wọ́n sì ngbé nínú àwọn ìgbésẹ̀ àìṣòdodo, mo fi dáà yín lójú pé ọ̀nà kan wà lati padà, pé ìrètí wà nínú Krístì. Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, mo ní ànfààní láti ṣe àbẹ̀wò pẹ̀lú olùfẹ́ ọ̀wọ́n ọmọ Ìjọ Jésù Krístì kan ẹnití ó ti la àkókò ìṣòro gidigidi kan kọjá ní ìgbé ayé rẹ̀ lẹ́hìn tí ṣíṣẹ̀ sí kókó ìrékọjá kan. Nígbàtí mo kọ́kọ́ rí i, mo le rí ìbànújẹ́ kan nínú ojú rẹ̀, tí ó lọ pẹ̀lú mímọ́lẹ̀ ìrètí ní ìwò ojú rẹ̀. Bí ó ti rí gan ṣe àfihàn ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ àti yíyípadà. Ó ti jẹ́ olùfarajì Onígbàgbọ́ a sì ti bùkún un lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ti jẹ́ kí èrò tí kò dára kan gba inú rẹ̀ kan, èyítí ó dárí sí àwọn miràn. Bí ó ti di ẹnití ó nfi òrè-kóòrè gba àwọn èrò wọ̀nyí láàyè díẹ̀ àti díẹ̀ síi, láìpẹ́ wọ́n ta gbòngbò ní inú rẹ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà jinlẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀. Níkẹhìn ó gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ìfẹ́ inú tí kò yẹ wọ̀nyí, èyí tí ó dárí rẹ̀ láti ṣe àwọn ìpinnu tako ohun gbogbo tí ó jẹ́ iyebíye jùlọ nínú ìgbé ayé rẹ̀. Ó sọ fúnmi pé bí òun kò bá ti fún èrò aláìgbọ́n náà ní ààyè ní ìbẹ̀rẹ̀, òun ìbá má di aláìlágbára àti títẹ̀rì sínú àwọn ìdánwò ọ̀tá—àwọn ìdánwò tí ó mú ìbànújẹ́ púpọ̀ wá sí ìgbé ayé rẹ̀, fún ìgbà díẹ̀ ó kéré ju.

Pẹ̀lú oríire, bíi ti ọmọ onínakúna nínú gbajúmọ̀ òwe tí a rí nínú ìhìnrere ti Lúkù, “ó padà sí ara rẹ̀” ó sì taji nínú àlá náà.18 Ó ṣe àtúnṣe ìgbẹ́kẹ̀lé re nínú Olúwa lákọ̀tun ó sì ní ìmọ̀lára àbámọ̀ tòótọ́, ó sì ní ìfẹ́ inú láti padà nígbẹ̀hìn sí inú agbo Olúwa. Ní ọjọ́ náà àwa méjèèjì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ tó nranipadà tí Olùgbàlà fún wa. Ní ìparí àbẹ̀wò kúkúrú wa, àwa méjèèjì ní a borí pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, àti pé títí di òní yi, mo ràntí ayọ̀ ológo dídán tí ó wà ní ìwò ojú rẹ̀ nígbàtí ó kúrò ní ọfísì mi.

Ẹyin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, nígbàti a bá tako àwọn ìdánwò kékeré, tí ó máa nfi ọ̀pọ̀ ìgbà wá láìròtẹ́lẹ̀ nínú ayé wa, a ndára síi ní gbígbaradì láti yẹra fún àwọn ìrékọjá tó wúwo, Bí Ààrẹ Spencer W. Kimball ti sọ pé: “Kò wọ́pọ̀ kí ẹnìkan wọ inú ìrékọjá jíjinlẹ̀ láìṣepé ó kọ́kọ́ tẹra sí àwọn kékèké, èyítí ó nṣílẹ̀kùn fún títóbi jù. … ‘Pápá kan tí ó mọ́ [kò kìí] dédé [di] kíkún lójijì.’”18

Nígbàtí ó ngbaradì láti parí iṣẹ́ àtọ̀runwá Rẹ̀ lóri ilẹ̀ ayé, Olùgbàlà Jésù Krístì tẹnumọ́ síṣe pàtàkì àìdúró ní dídojú ìjà kọ ohun gbogbo tí ó ba le mú ìrẹ̀wẹ̀sí bá wa kúrò nínú gbígba èrò ayérayé wa. Lẹ́hìn àìyege àwọn àtakò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti ọwọ́ ọ̀tá náà, nínú ìdánwò kan láti darí Rẹ̀ kúrò níbi iṣẹ́ rẹ̀. Olùgbàlà lé e lọ láìlekọ̀ nípa sísọ pé: “Padà kúrò lẹ́hìn mi, Sátánì. … Nígbànáà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àti pé, kíyèsíi, àwọn ángẹ́lì tọ̀ọ́ wá, wọ́n sì nṣe ìránṣẹ́ fún un.”19

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin njẹ́ ẹ lè ro kínni ohun tí yio ṣẹlẹ̀ bí ó bá ṣeéṣe fún wa láti fa okun àti ìgboyà láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà tí a sì sọ pé, “Rárá” àti pé “Padà kúrò lẹ́hìn mi” sí àwọn èrò àìyẹ ní àkọ́kọ́ gan tí wọn bá wá sí inú wa? Kínni yío jẹ́ ìtẹ̀mọ́ra lórí ìfẹ́ inú ọkàn wa? Báwo ni àyọrisí àwọn ìgbésẹ̀ wa yío ṣe mú wa súnmọ́ Olùgbàlà tí yío sì fi ààyè gba títẹ̀síwájú ipá Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ìgbé ayé wa? Mo mọ̀ pé ní síṣe bẹ́ẹ̀, a ó yẹra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ajálù àti àwọn ìhùwàsí tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó le fa àwọn wàhálà ẹbi àti àwọn èdè-àìyédè, àwọn ìmọ̀lára àti àwọn ohun fífẹ́ búburú, síṣe àwọn àìṣòótọ́ àti ìlòkulò, mímú lẹ́rú nípasẹ̀ àwọn ìwà bárakú ibi, àti ohunkóhun miràn tí yio tako àwọn òfin Olúwa.

Nínú ọ̀rọ̀ onítàn rẹ̀ àti wíwọra láti Oṣù Kẹrin ọdún yi, Ààrẹ Nelson ṣe ìlérí kan pé gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá ṣetán láti “gbọ́ Tirẹ̀”—gbọ́ ti Krístì—kí wọ́n sì gbọràn sí àwọn òfin Rẹ̀ “ni a ó bùkúnfún pẹ̀lú àfikún agbára láti ṣiṣẹ́ lórí ìdánwò, àwọn ìtiraka, àti aìlera” àti pé agbára wa láti ní ìmọ̀lára ayọ̀ yío pọ̀ síi, ání nínú ìrúkèrúdò tó npọ̀ síi lọ́wọ́lọ́wọ́ yí.20

Mo jẹrìí sí yín pé àwọn ìlérí tí a fi fúnni nípasẹ̀ wòlíì wa ọ̀wọ́n jẹ́ àwọn ìlérí tí a fi fúnni láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà Fúnra Rẹ̀. Mo pè yín láti “gbọ́ Tirẹ̀” nínú gbogbo èrò kí ẹ sì tẹ̀lé E pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín kí ẹ le gba okun àti ìgboyà láti sọ pé “Rárá” àti “Padà kúrò lẹ́hìn mi” sí gbogbo àwọn ohun tí ó le mú ìbànújẹ́ wá fúnwa nínú ìgbé ayé wa. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, mo ṣe ìlérí fún yín pé Olúwa yío rán Ẹmí Mímọ́ Rẹ̀ láti fún wa lókun àti láti tù wá nínú, àti pé a le di ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ọkàn ti Olúwa gan.21

Mó jẹ́ ẹ̀rí mi pé Jésù Krístì wà láàyè àti pé nípasẹ̀ Rẹ̀, a le ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ipá ibi ti ọ̀tá kí a sì yege lati gbé fún ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀ àti ní iwájú olùfẹ́ni Baba wa ní Ọrun. Mo jẹ́ ẹ̀rí àwọn òtítọ́ wọnyí pẹ̀lú ìfẹ́ mi fún yín àti fún arẹwà Olùgbàlà wa, sí orúkọ ẹnití mo fi ògo, ọlá, àti ìyìn fún títí láé. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.