Dánwò, Ridi, àti Dídán
Ìbùkún títóbi julọ tí yíò wá nígbàtí a bá dán ìgbàgbọ́ arawa sí àwọn májẹ̀mú wa wo ní ìgbà àwọn ìdánwò wa yíò jẹ́ àyípadà kan nínú ìwá-àdánidá wa.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín loni Ìrètí mi ní pàtàkì ni láti fúnni ní ìyànjú nígbàtí ayé bá dàbí ó ṣòrò àti àìní-dánilójú. Fún àwọn kan lára yín, àkokò náà ni ìsisìyí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, irú àkokó bẹ́ẹ̀ yíò dé.
Ìyẹn kìí ṣe ìwò kan tó ṣókùnkùn. Ó bojùmu—síbẹ̀ ó jẹ́ ire—nítorí èrèdí Ọlọ́run nínú Ìṣẹ̀dá ayé yí. Èrèdí yẹn ni láti fún àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ànfàní láti fi ara wọn hàn ní ìfẹ́ àti agbára láti yan òtítọ́ nígbàtí ó lè. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìwà-àdánidá wọn yíò yípadà àti pé wọ́n lè dàbíi Rẹ̀ si. Ó mọ pé ìyẹn yíò bèèrè fún ìgbàgbọ́ àìyẹsẹ̀ nínú Rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ lára ohun ti mo mọ̀ wá látọ̀dọ̀ ẹbí mi. Nígbàtí mo wà ní bíi ọmọ ọdún mẹ́jọ, ìyá mi ọlọ́gbọ́n ní kí arákùnrin mi àti èmi ge oko pẹ̀lú òun ní ọgbà ẹ̀hìnkùlé ẹbí wa. Nísisìyí, ó dàbí iṣẹ́ tó rọrùn, ṣùgbọ́n à ngbé ní New Jersey. Òjò máa nrọ̀ léraléra. Ilẹ́ sì máa nní amọ̀ wúwo. Àwọn ewéko ndàgbà kíakíá ju ewébẹ̀ lọ.
Mo rántí ìbànújẹ́ mi nígbàtí àwọn ewéko bá já mọ́ mi lọ́wọ́, tí àwọn ìtàkùn wọn bá dùróṣinṣin nínú ẹrẹ̀ wúwo. Ìyá mi àti arákùnrin mi máa nṣíwájú mi lọ nínú àwọn ìlà wọn. Bí mo ṣe ngbìyànjú líle sí, bẹ́ẹ̀ni mo nrẹ̀hìn sí.
“Èyí ti Le Jù!” Mo kígbe sókè.
Dípò fífúnni ní àánú, ìyá mi rẹrin ó sì wípé, “Áà, Hal, bẹ́ẹ̀ni, ó le. Ó yẹ kó lè. Ìgbé-ayé jẹ́ ìdánwó kan.”
Ní àkokò náà, mo mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti pé yíò tẹ̀síwájú láti jẹ́ òtítọ́ ní ọjọ́-ọ̀la mi.
Ìdí fún ẹ̀rín olólùfẹ́ ìyá mi hàn kedere ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà nígbàtí mo ka nípa Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n nsọrọ èrèdí Wọn ní ṣìṣẹ̀dá ayé yí àti fífún àwọn ọmọ ẹ̀mí ní ànfàní ayé ikú:
“A ó sì dán wọn wò ní báyí,” láti ríi bóyá wọn yíó ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wọn yíó paláṣẹ fún wọn;
“Àti pé àwọn tí ó bá pa ohun ìní wọn àkọ́kọ́ mọ́ yíò ní àfikún lórí wọn; àwọn tí kò bá sì pa ohun ìní wọn àkọ́kọ́ wọn mọ́ kì yíò ní ògo nínú ìjọba kannáà pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ó pa ohun ìní àkọ́kọ́ wọn mọ́; àti pé àwọn tí ó pa ohun ìní wọn ìkejì mọ́ yíò ní àfikún ògo lórí wọn títíláé àti láéláé.”1
Ẹ̀yin àti èmí tẹ́wọ́gba ìpè láti gba àdánwò àti láti fihàn pé a ó yàn láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ nígbàtí a kò ní sí ní iwájú Baba wa Ọ̀run.
Àní pẹ̀lú irú ìpè ìfẹ́ni látọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run, Lúcíférì rọ ìdásímẹ́ta àwọn ọmọ ẹ̀mí láti tẹ̀lé òhun kí wọ́n sì kọ ètò ti Baba fún ìdàgbàsókè àti ìdùnnú ayérayé wa. Fún ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì, a le jáde pẹ̀lú àwọn àtẹ̀lé rẹ̀. Nísisìyí ó ngbìyànjú láti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó lè mú yípadà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrún nínú ayé ikú yí.
Àwọn tí ó tẹ́wọ́gba ètò náà lára wa ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì, ẹnití ó gbà láti di Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. A gbọ́dọ̀ ti ní ìgbàgbọ́ nígbànáà pé eyikeyi àwọn àìlera ayé-ikú tí a lè ní àti eyikeyi agbára ibi tí ó lè takò wá, àwọn agbara rere yíò lágbára títóbi jùlọ.
Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì mọ̀ wọ́n sì fẹ́ràn yín. Wọ́n fẹ́ kí ẹ padà sí ọ̀dọ̀ Wọn kí ẹ sì dàbíi Tiwọn. Àṣeyege yín ni àṣeyege Wọn. Ẹ ti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ nàà tí a fi múlẹ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ nígbàtí ẹ ti kà tàbí gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Nítorí kíyèsi, èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ.”2
Ọlọ́run ní agbára láti mú ọ̀ná wa rọrùn si. Ó fi mánnà bọ́ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nínú ìrìnkiri wọn sí ilẹ̀ ìlérí. Olúwa nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé-ikú Rẹ̀ wo àwọn alaarẹ̀ sàn, jí okú dìde, ó sì mú okùn dákẹ́rọ́rọ́. Lẹ́hìn Ajinde Rẹ̀, Ó ṣí ilẹ̀kùn “inú túbú fún àwọn tí a dè.”4
Síbẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ọ̀kan lára àwọn Wòlíì Rẹ̀ tó tóbi jùlọ, jìyà nínú túbú a sì kọ lẹkọ tí gbogbo wa njèrè látinú rẹ̀ tí a sì nílò nínú àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ lóòrèkóòrè: “Àti pé tí wọ́n bá jù ọ́ sí kòtò, tàbí sí ọwọ́ àwọn apànìyàn, tí a sì ṣe ìdájọ́ ikú fún ọ; tí a sì jù ọ́ sínú ibú; bí jíjì ìgbáradì bá dìtẹ̀ sí ọ; tí afẹ́fẹ́ líle bá di ọ̀tá rẹ; tí ọ̀run bá pe àwọ̀ dúdú, àti tí gbogbo iná àti omi kórajọpọ̀ làti se ọ̀nà; àti pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, tí ìjágbọ̀n ọ̀run àpáàdì gan bá la ẹnu rẹ̀ sí ọ, mọ̀ ìwọ, ọmọ mi, pé àwọn nkan wọ̀nyí yíò fún ọ ní ìrírí, àti pé yíò wá fún dídára rẹ.”4
Ẹ lè fi oyè ní ìyàlẹ́nú ìdí tí olólùfẹ́ kan àti Ọlọ́run tó ni gbogbo-ágbára fi àyè gba ìdánwò ayé-ikú wa láti le gidi. O jẹ́ nítorí pé Òun mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ dàgbà nínú ìwẹ̀nùmọ́ ti-ẹ̀mí àti ìgbèrú láti lè gbé ní ìwájú Rẹ̀ nínú àwọn ẹbí títíláé. Láti mú èyí ṣeéṣe, Baba Ọ̀run fún wa ní Olùgbàlà kan àti agbára láti yàn fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ àti làti ronúpìwàdà kí a sì wá sọ́dọ̀ Rẹ̀.
Gbùngbun ètò ìdùnnú Baba ní dídà bí Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì si. Nínú ohun gbogbo, àpẹrẹ Olùgbàlà ni atọ́nà wa dídárajùlọ. A kò yọ́ọ̀ kúrò ní inilo láti fi ara Rẹ̀ hàn. Ó ní ìfarada fún gbogbo àwọn ọmọ Baba Ọ̀run, ní sísan ìdíyelé fún gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó ní ìmọ̀lára ìjìyà gbogbo àwọn ẹnití ó ti àti tí yíò wá sínú ayé-ikú.
Nígbàtí ó bá yà yín lẹ́nu irú ìrora tí ẹ lè farada dáadáa, ẹ rántí Rẹ̀. Ó jìyà ohun tí ẹ̀ njìyà nítorí kí Òun lè mọ̀ bí yíò ti gbé yín sókè. Òun lè má mú àjàgà kúrò, ṣùgbọ́n òun yíò fún yín ní okun, ìtùnú, àti ìrètí. Ó mọ ọ̀nà náà. Ó mu ago ìkorò. Ó farada ìjìyà gbogbo ènìyàn.
Olùfẹ́ni Olùgbàlà nṣìkẹ́ Ó sì ntù yín nínú, ẹnití ó mọ̀ bí yíò ti ràn yín lọ́wọ́ nínú eyikeyi àwọn ìdánwò tí ẹ dojúkọ. Álmà kọ́ni:
“Òun yíò sì jáde lọ, ní ìfaradà ìrora àti ìpọ́njú àti àdánwò onírurú; èyítí ó rí bẹ̃ kí ọ̀rọ̀ nã lè ṣẹ èyítí ó wípé òun yíò gbé ìrora àti àìsàn àwọn ènìyàn rẹ̀ lé ara rẹ̀.
“Òun yíò sì gbé ikú lé ara rẹ̀, kí òun kí ó lè já ìdè ikú èyítí ó de àwọn ènìyàn rẹ̀; òun yíò sì gbé gbogbo àìlera wọn lé ara rẹ̀, kí inú rẹ̀ lè kún fún ãnú, nípa ti ara, kí òun kí ó lè mọ̀ nípa ti ara bí òun yíò ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nínú gbogbo àìlera wọn.”5
Ọ̀nà kan tí Òun yíò fi ràn yín lọ́wọ́ yíò jẹ́ láti pè yín nígbàgbogbo láti rántí Rẹ̀ àti láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó ti gbà wá níyànjú:
“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.
“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.”6
Ọ̀nà láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni láti ṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, láti lo ìgbàgbọ́ sí ìronúpìwàdà, láti yan láti ṣe ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Rẹ tí a fún láṣẹ, lẹ́hìnnáà kí ẹ pa àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́. Ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ wá láti jẹ́ ojúgbà, olùtùnú àti olùtọ̀nà yín.
Bí ẹ ṣe ngbé yíyẹ nípa ẹ̀bún Ẹ̀mí Mímọ́, Olúwa lè darí yín sí ààbò àní nígbàtí ẹ kò lè rí ọ̀nà. Fún èmi, Òun ti fi ìṣísẹ̀ tókàn tàbí ìkejì tàti ṣe hàn fún mi léraléra jùlọ. Ó ṣọ̀wọ́n kí Ó tó fún mi ní fìrí jíjìn ọjọ́-ọ̀là, ṣùgbọ́n àní àwọn fìrí àìwáléraléra tọ́ àwọn ohun tí mo yàn láti ṣe ní ìgbé ayé ojojúmọ́ sọ́nà.
Olùwa ṣàlàyé:
“Ẹ̀yin kò lè ri pẹ̀lú ojú ti ara yín, ní àkokò yí àwọn ètò Ọlọ́run yín nípa àwọn ohun wọnnì tí yíò wá lẹ́hìnwá, àti ògo tí yíò tẹ̀le … ìpọ́njú púpọ̀.
“Nítorí lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ni àwọn ìbùkún yíò wá.”7
Ìbùkún títóbi julọ tí yíò wá nígbàtí a bá fi arawa hàn ní ìgbàgbọ́ sí àwọn májẹ̀mú wa nínú àwọn àdánwò wa yíò jẹ́ àyípadà nínú ìwá-àdánidá wa. Nípa yíyàn láti pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, agbára Jésù Krístì àti àwọn ìbùkún Ètùtù Rẹ̀ lè ṣiṣẹ́ nínú wa. Ọkàn wa lè rọ̀ láti fẹ́ràn, láti dáríjì, àti láti pe àwọn ẹlòmíràn láti wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà. Ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Olúwa a pọ̀si. Àwọn ẹ̀rù wa a dínkù.
Nísisìyí, àní pẹ̀lú irú àwọn ìlérí ìbùkún nínú ìpọ́njú, pẹ̀lú ọgbọ́n a kò lè wá ìpọ́njú. Nínú ìrírí ayé ikú, a ní àwọn ànfàní láti dán arawa wo, láti yege ìdánwó lile tó láti dà bíi ti Olùgbàlà àti Baba Ọ̀run si láélàé.
Ní àfikún, a gbọ́dọ̀ kíyèsí ìpọ́njú àwọn ẹlòmíràn kí a sì gbìyànjú láti ṣèrànwọ́. Ìyẹn yíò le nípàtàkì ìgbàtí a bá gba ìdánwo ọlọgbẹ́ fúnrawa. Ṣùgbọ́n a ó ri pé nígbàtí a bá gbé àjàgà ẹlòmíràn sókè, àní ní díẹ̀, ẹhìn wa a lókun a ó sì ní iyè-ara ìmọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn.
Nínú èyí, Olúwa ni Alápẹrẹ wa. Ní orí àgbélèbú ní Gólgóthà, ní ìjìyà ìrora tẹ́lẹ̀ tó tóbí tí Òun ìbá ti kú tí kò bá ṣe pé Ó jẹ́ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Ọlọ́run, Ó wo àwọn apani Rẹ̀ Ó sì wí fún Baba Rẹ̀ pé, “Dáríjì wọ́n; nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n nṣe.”8 Nígbàtí Ó njìyà fún gbogbo ènìyàn tí ó tí gbé ní ayé rí, Ó wo Jòhánù, láti orí àgbélèbú àti oníbìnújẹ́ ìyá ara Rẹ̀ Ò sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí i nínú àdánwò rẹ̀:
“Nítorínáà nígbàtí Jésù rí ìyá rẹ̀, àti ọmọẹ̀hìn nà dúró, ẹnití Jésù fẹ́ràn, ó wí fún ìyá pé, Obìnrin, wo ọmọ rẹ̀!
“Lẹ́hìnnáà ni ó wí fún ọmọẹ̀hìn náà pé, Wo ìyá rẹ̀! Láti wákàtí náà lọ ni ọmọẹ̀hìn náà sì ti múu lọ sí ilé ararẹ̀.”
Nípasẹ̀ àwọn ìṣe Rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ mímọ́ jùlọ̀ náà, Òun fi arajìn láti fi ayé Rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, ẹbọ̀ tì kìí ṣe àánú ní ayé yí nìkan ṣùgbọ́n ní ìye ayérayé ní àkokò tó nbọ̀.
Mo ti rí àwọn ènìyàn tí wọ́n díde sí ibi gíga nípasẹ̀ ìfihàn ìgbàgbọ́ nínú àwọn àdánwò bíbanilẹ́rù. Káàkiri Ìjọ loni ni àwọn àpẹrẹ. Ìpọ́njú nmú àwọn ènìyàn lọ́ sórí eékún wọn. Nípasẹ̀ ìfaradà ìgbàgbọ́ wọn àti ìtiraka, wọ́n dàbí Olùgbàlà àti Baba Ọ̀run síi.
Mo kọ́ ẹ̀kọ́ míràn látọ̀dọ̀ ìyá mi. Bí ọ̀dọ́mọbìnrin kan ó ní àrùn-diptéríà ó sì fẹ́rẹ̀ kú. Lẹ́hìnnáà ó ní àrùn mẹnigítísì ọ̀pá-ẹ̀hìn. Baba rẹ̀ kú léwe, nítorínáà ìyá mi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣerànwọ́ láti ti ìyá wọn lẹ́hìn.
Ní gbogbo ayé rẹ̀, ó ní ìmọ̀lára àbájáde àwọn àdánwò àìlera. Ní ọdún mẹwa tó kẹ́hìn ìgbé-ayé rẹ̀, ó ṣe ìṣẹ́-abẹ oríṣiríṣi. Ṣùgbọ́n nínú gbogbo rẹ̀, ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn sí Olúwa, àní nígbàtí kò lè rìn mọ́. Mo rántí pé fótò kanṣoṣo ní ògiri yàrá rẹ̀ ni ti Olùgbàlà. Ọ̀rọ̀ ìgbẹ̀hìn rẹ̀ sí mi ni ibùsùn-ikú rẹ̀ ni ìwọ̀nyí: “Hal, ò ndún bíi pé òtútù nmú ọ. Ó yẹ́ kí ó tọ́jú ararẹ.”
Níbí ìsìnkú rẹ, olùsọ̀rọ̀ ìkẹhìn ni Alàgbà Spencer W. Kimball. Lẹ́hìn sísọ ohunkan nípa àwọn àdánwò rẹ̀ àti ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó sọ èyí nípàtàkì: “Ó lè ya àwọn kan lára yín lẹ́nu ìdí tí Mildred fi ní láti jìyà púpọ̀ àti pípẹ́ bẹ́ẹ̀. Èmi ó sọ ìdí rẹ̀ fún yín. Nítorí Olúwa fẹ́ láti tunṣe díẹ̀ si ni”
Mo fi ìdúpẹ́ mi hàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ọmọ Ìjọ ti Jésú Krístì ti wọ́n ngbé àjàga pẹ̀lú ìgbàgbọ́ dídúróṣinṣin àti àwọn ẹnití nran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gbé tiwọn bí Olúwa ṣe nwá láti tuń wọn ṣe díẹ̀ si. Bákannáà mo fi ìfẹ́ mi àti ìfẹràn hàn fún àwọn olùtọ́jú àti olórí káàkiri ayé tí wọ́n nsin àwọn ẹlòmíràn nígbàtí àwọn àti ẹbí wọn nfarada irú títúnṣe bẹ́ẹ̀.
Mo jẹri pé ọmọ Baba Ọ̀run, tí ó nifẹ wa ni a jẹ́. Mo ni ìmọ̀lara ìfẹ́ Ààrẹ Russell M. Nelson fún gbogbo ènìyàn. Òun ni wòlíì Olúwa ní ayé loni. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.