Títọ́ Titun Kan
Mo pè yín láti yí ọkàn, inú, àti ẹ̀mí yím padà púpọ̀ si gan sí Baba wa Ọrun àti Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, àwọn ọjọ́ méjì ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò wọ̀nyí ti jẹ́ ológo! Mo faramọ́ Alàgbà Jeffrey R. Holland. Bí ó ti sọ, àwọn ọ̀rọ̀, àdúrà, àti orin ní a ti gbà imísí nípasẹ̀ Olúwa. Mo fi ìmoore hàn sí gbogbo ẹni tí ó ti kópa ní ọ̀nàkọnà.
Nínú gbogbo àwọn ìtẹ̀síwájú, mo ti wo yín nínù ọkàn mi tí ẹ nfetísílẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀. Mo ti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa láti ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ ohun tí ẹ̀ nmọ̀lára, dídàmú nípa, tàbí ngbìyànjú láti yanjú. Mo ti ronú ohun tí mo lè sọ láti parí ìpàdé àpapọ̀ yí tí yíò rán yín jáde lọ pẹ̀lú ìyárí nípa ọjọ́-ọ̀là tí mo mọ̀ pé Olúwa nfẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀lára rẹ̀.
A ngbé ní ọjọ́ ológo kan, tí àwọn wòlíì ti rí fún àwọn sẹ́ntúrì. Èyí ni àkokò iṣẹ́ ìríjú nígbàtí kò sí ìbùkún ti ẹ̀mí kankan tí a ó dìmú kúrò lọ́dọ̀ olódodo.1 Pẹ̀lú ayé ìrúkèrúdò,2 Olúwa yíò fẹ́ kí a wo iwájú sí ọjọ́-ọ̀la pẹ̀lú “ìfojúsí aláyọ̀.”3 Ẹ ma jẹ́ kí a yí àwọn wíìlì wa ní ìrántí àná. Ìkójọ Ísráẹ́lì ntẹ̀síwájú. Olúwa Jésù Krístì ndarí àwọn ètò Ìjọ Rẹ̀, àti pé yíò ṣe àṣeyege àwọn ìfojúsùn àtọ̀runwá rẹ̀.
Ìpènijà fún yín àti èmi ni láti mu dájú pé ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa yíò ṣe àṣeyege àtọ̀runwá ọkùnrin tàbí obìnrin náà. Ní òní à ngbọ́ “títọ́ titun kan” léraléra. Bí ẹ bá fẹ́ gba títọ́ titun kan mọ́ra, mo pè yín láti yí ọkàn, inú, àti ẹ̀mí yín padà púpọ̀ si gan sí Baba wa Ọrun àti Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì. Ẹ jẹ́ kí ìyẹn jẹ́ títọ̀ titun yín.
Ẹ gba títọ́ titun yín mọ́ra nípa ríronúpìwàdà lójojúmọ́. Ẹ wá láti jẹ́ mímọ́ púpọ̀si ní èrò, ọ̀rọ̀, àti ìṣe. Ẹ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ teramọ́ ìrísí ayérayé. Ẹ gbé ìpè yín ga. Àti pé eyikeyi àwọn ìpènijà yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, gbé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan kí ẹ lè múrasílẹ̀ si láti pàdé Aṣẹ̀dá yín.4
Ìdí tí a fi ní àwọn tẹ́mpìlì nìyẹn. Àwọn ìlànà àti májẹ̀mú Olúwa nmúra wá sílẹ̀ fún ìyè ayérayé, èyí tí ó ga ju gbogbo àwọn ìbùkún Ọlọ́run.5 Bí ẹ ti mọ̀, àjàkálẹ̀ àrùn COVID nfẹ́ títí ránpẹ́ àwọn tẹ́mpìlì wa. Lẹ́hìnnáà a bẹ̀rẹ̀ fífi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí, ṣíṣí ní ipele. Pẹ̀lú Ipele kejì ní ọ̀nà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tẹ́mpìlì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn lọ́kọ-láyà ti ṣe èdidì, àti pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti gba agbára ẹ̀bùn ti arawọn ní àwọn oṣù díẹ̀ péré. A nfojúsọ́nà sí ọjọ́ náà nígbàtí àwọn ọmọ Ìjọ yíyẹ a lè sìn àwọn babanlá wọn lẹ́ẹ̀kansi kí wọn sì jọ́sìn nínú tẹ́mpìlì mìmọ́.
Nísisìyí inú mi dùn láti polongo àwọn ètò fún kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì mẹ́fà titun tí a ó kọ́ ní àwọn ibi wọ̀nyí: Tarawa, Kiribati; Port Vila, Vanuatu; Lindon, Utah; Greater Guatemala City, Guatemala; São Paulo East, Brazil; àti Santa Cruz, Bolivia.
Bí a ṣe nkọ́ tí a sì ntún àwọn tẹ́mpìlì wọ̀nyí ṣe, a gbàdúrà pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yíò kọ́ yíò gbéga kí a sì tún arawa ṣe kí a lè yẹ láti wọnú tẹ́mpìlì mímọ́.
Nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo bùkún yín láti kún fún àláfíà ti Olúwa Jésù Krístì. Àláfíà Rẹ̀ tó kọjá ìmọ̀ ayé-ikú.6 Mo bùkún yín pẹ̀lú ifẹ́ púpọsi àti agbára láti gbọ́ràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti nṣeé, a ó fọ́n àwọn ìbùkún lé yín lórí, pẹ̀lú ìgboyà gíga jùlọ, ìfihàn araẹni to ga jùlọ, ìbámu dídùn jùlọ ní ilé yín, àti ayọ̀ àní ní àárín àìnídánilójú.
Njẹ́ kí a tẹ̀síwájú papọ̀ láti mú àṣẹ àtọ̀runwá ṣẹ—tí mímúra arawa àti ayé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa. Mo gbàdúra bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìfihàn ìfẹ́ mi fún yín, ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.