Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 1


Ìwé Kejì ti Nífáì

Ìwé ìtàn ti ikú Léhì. Àwọn arákùnrin Nífáì ṣọ̀tẹ̀ sí i. Olúwa kìlọ̀ fún Nífáì kí ó kúrò lọ sínú ijù. Àwọn ìrìn àjò rẹ̀ ní ijù, àti bẹ̃ lọ.

Ori 1

Léhì sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ òmìnira—Irú-ọmọ rẹ̀ ni a ó túká ti a ó sì pa bí wọ́n bá kọ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì sílẹ̀—Ó gba àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ níyànjú láti gbé ìhámọ́ra òdodo wọ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, ti fi òpin sí kíkọ́ àwọn arákùnrin mi, bàbá wa, Léhì, sọ àwọn ohun púpọ̀ sí wọn pẹ̀lú, ó sì tún sọ fún wọn, àwọn ohun nlá èyí tí Olúwa ti ṣe fún wọn nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù.

2 Ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn òtẹ̀ wọn lórí àwọn omi, àti àwọn ãnú Ọlọ́run ní dídá ẹ̀mí wọn sí, tí a kò gbé wọn mì nínú òkun.

3 Ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú nípa ilẹ̀ ìlérí, èyí tí wọ́n ti gbà—bí Olúwa ti ní ãnú ní kíkìlọ̀ fún wa kí á lè sá jáde ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù.

4 Nítorí, kíyèsĩ i, ni ó wí, èmi ti rí ìran kan, nínú èyí tí mo mọ̀ wípé a pa Jerúsálẹ́mù run; ìbá sì ṣepé àwa dúró ní Jerúsálẹ́mù àwa ìbá ti parun pẹ̀lú.

5 Ṣùgbọ́n, ni ó wí, l’áìṣírò awọn ìpọ́njú wa, àwa ti gba ilẹ̀ ìlérí, ilẹ̀ èyí tí ó jẹ́ àṣàyàn lórí gbogbo àwọn ilẹ̀ míràn; ilẹ̀ èyí tí Olúwa Ọlọ́run ti fi dá májẹ̀mú pẹ̀lú mi kí ó lè jẹ́ ilẹ̀ fún ìní irú-ọmọ mi. Bẹ̃ni, Olúwa ti fi ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú sí mi, àti sí àwọn ọmọ mi títí láé, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn wọnnì tí a ó tọ́ jáde ní àwọn ilẹ̀ ìbí míràn nípa ọwọ́ Olúwa.

6 Nítorí-èyi, èmi, Léhì, sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ Ẹ̀mí èyítí ó wà nínú mi, pé kò sí ẹnìkan tí yíò wá sínú ilẹ̀ yí àfi tí a ó bá mú wọn wá nípa ọwọ́ Olúwa.

7 Nítorí-èyi, ilẹ̀ yí ni a yà sí mímọ́ sí ẹni tí oun yíò mú wá. Bí ó bá sì jẹ́ pé wọn yíò sìn ín gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyí tí ó ti fi fún wọn, yíò jẹ́ ilẹ̀ òmìnira sí wọn; nítorí-èyi, a kì yíò mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá láé sínú ìgbèkun; bí ó bá rí bẹ̃, yíò jẹ́ nítorí ti àìṣedẽdé; nítorí bí àìṣedẽdé bá di púpọ̀ a ó fi ilẹ̀ nã bú nítorí wọn, ṣùgbọ́n sí olódodo alábùkún fùn ni yíò jẹ́ títí láé.

8 Sì kíyèsĩ i, ó jẹ́ ọgbọ́n pé kí á pa ilẹ̀ yí mọ́ síbẹ̀ kúrò ní ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè míràn; nítorí kíyèsĩ í, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ni yíò kún ilẹ̀ nã, tí kì yíò sí ibi fún ìní.

9 Nítorí-èyi, èmi, Léhì, ti rí ìlérí kan gbà, pé níwọ̀n bí àwọn wọnnì tí Olúwa Ọlọ́run yíò mú jáde wá láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, wọn yíò ṣe rere lórí ojú ilẹ̀ yí; a ó sì pa wọ́n mọ́ kúrò ní ìmọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè míràn, kí wọ́n lè gba ilẹ̀ yí fún àwọn tìkalãwọn. Bí ó bá sì ṣe pé wọn yíò pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ a ó bùkún wọn lórí ojú ilẹ̀ yí, kì yíò sì sí ẹnìkan láti yọ wọ́n lẹ́nu, tàbí láti mú ilẹ̀ ìní wọn kúrò; wọn yíò sì gbé láìléwu títí láé.

10 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, nígbàtí àkókò nã bá dé tí wọn bá rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, lẹ́hìn tí wọ́n bá ti gba àwọn ìbùkún nlá báyĩ láti ọwọ́ Olúwa—tí wọ́n ní ìmọ̀ nípa ẹ̀dá ayé, àti gbogbo ènìyàn, tí wọ́n mọ́ àwọn iṣẹ́ nlá Olúwa tí ó sì ya ni lẹ́nu láti ìgbà ẹ̀dá ayé; tí a fún wọn ní agbára láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; tí wọ́n ní gbogbo òfin láti àtètèkọ́ṣe, tí a sì ti mú wọn wá nípasẹ̀ õre rẹ̀ tí kò lópin sínú ojúlówó ilẹ̀ ìlérí yí—kíyèsĩ i, ni mo wí, bí ọjọ́ nã bá dé tí wọn yíò kọ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì sílẹ̀, Messia òtítọ́ nã, Olùràpadà wọn àti Ọlọ́run wọn, kíyèsĩ i, ìdájọ́ ẹni nã tí ó tọ́ yíò simi lórí wọn.

11 Bẹ̃ni, òun yíò mú àwọn orílẹ̀-èdè míràn wá sọ́dọ̀ wọn, òun yíò sì fi agbára fún wọn, òun yíò sì gbà kúrò lọ́wọ́ wọn àwọn ilẹ̀ ìní wọn, òun yíò sì mú kí á tú wọn ká kí á sì pa wọ́n.

12 Bẹ̃ni, bí ìran kan ti nkọjá sí òmíràn ìta-ẹ̀jẹ̀-sílẹ̀ yíò wà, àti ìbẹ̀wò nlá lãrín wọn; nítorí-èyi, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí; bẹ̃ni, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.

13 A! ẹ̀yin ìbá jí; ẹ jí kúrò ní õrun àsùnwọra, bẹ̃ni, àní kúrò ní õrun ọ̀run àpãdì, kí ẹ sì gbọn àwọn ẹ̀wọ̀n búburú èyí tí a fi dì yín kúrò, èyí tí ó jẹ́ àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó di àwọn ọmọ ènìyàn, tí a fi gbé wọn ní ìgbèkun sọ̀kalẹ̀ sí ọ̀gbun ayérayé òṣì àti ìbànújẹ́.

14 Ẹ jí! ẹ sì dìde kúrò nínú erùpẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òbí tí nwárìrì, ara ẹni tí ẹ kò lè sài gbe sin laipẹ sinu ìsà-òkú tútù tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́, láti ibi tí àrìnrìn-àjò kan kò lè padà; ọjọ́ díẹ̀ sii èmi yíò sì lọ ọ̀nà gbogbo ayé.

15 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, Olúwa ti ra ọkàn mi padà kúrò ní ọ̀run àpãdì; èmi ti kíyèsĩ ògo rẹ̀, a sì yí mi ká nínú apá ìfẹ́ rẹ̀ títí ayérayé.

16 Mo sì fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí láti kíyèsĩ àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ Olúwa; kíyèsĩ i, èyí ti jẹ́ àníyàn ọkàn mi láti ìpilẹ̀sẹ̀.

17 Ọkàn mi ni a ti rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ìrora-ọkàn láti ìgbà dé ìgbà, nítorí mo ti bẹ̀rù, kí ó má bã jẹ́ pé nítorí ti líle ọkàn yín Olúwa Ọlọ́run yín yíò jáde wá ní ẹ̀kún ìbínú rẹ̀ sórí yín, kí á lè gé yín kúrò kí á sì pa yín run títí láé;

18 Tàbí, kí ègún kí ó wá sórí yín fún ìwọ̀n àkókò ìran púpọ̀; àti tí a bẹ̀ yín wò nípasẹ̀ idà, àti nípasẹ̀ ìyàn, àti tí a kórìra yín, àti tí a tọ́ yín nípa ìfẹ́ àti ìgbèkun ti èṣù.

19 A! ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, kí àwọn ohun wọ̀nyí má lè wá sórí yín, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè jẹ́ àṣàyàn àti àyànfẹ́ ènìyàn Olúwa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ìfẹ́ rẹ̀ ni kí ó ṣẹ; nítorí àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ òdodo títí láé.

20 Ó sì ti wí pé: Níwọ̀n bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã; ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin mi mọ́ a ó gé yín kúrò níwájú mi.

21 Àti nísisìyí kí ọkàn mi lè ní ayọ̀ nínú yín, àti kí ọkàn mi lè fi ayé yí sílẹ̀ pẹ̀lú inúdídùn nítorí yín, kí a má lè mú mi sọ̀kalẹ̀ wa pẹ̀lú ìbànújẹ́ àti írora-ọkàn lọ sí ìsà-òkú, ẹ dìde kúrò nínú erùpẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, kí ẹ sì jẹ́ ọkùnrin, kí ẹ sì pinnu ní inú kan àti ní ọkàn kan, ní ìdàpọ̀ nínú ohun gbogbo, kí ẹ̀yin má bà sọ̀kalẹ̀ wá sínú ìgbèkun;

22 Kí a má bà fi yín bú pẹ̀lú ègún kíkan; àti pẹ̀lú, kí ẹ̀yin má bà jigbèsè ìbínú Ọlọ́run ẹnití ó tọ́, sórí yín, sí ìparun, bẹ̃ni, ìparun ayérayé ti ọkàn àti ara.

23 Ẹ jí, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi; ẹ gbé ìhámọ́ra òdodo wọ̀. Ẹ gbọn àwọn ẹ̀wọ̀n èyí tí a fi dì yín nù, kí ẹ sì jáde wá kúrò láti inú ìṣókùnkùn, kí ẹ sì dìde kúrò nínú erùpẹ̀.

24 Ẹ máṣe ṣe ọ̀tẹ̀ mọ́ sí arákùnrin yín, ẹni tí ìrí rẹ̀ ti ni ógo, ẹni tí ó sì ti pa àwọn òfin mọ́ láti ìgbà tí a ti kúrò ní Jerúsálẹ́mù; ẹni tí ó sì ti jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, ní mímú wa jáde wá sí ilẹ̀ ìlérí; nítorí bí kò bá jẹ́ fún òun, àwa ìbá ti parun pẹ̀lú ebi nínú ijù; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ̀yin nwá láti gba ẹ̀mí rẹ̀; bẹ̃ni, òun sì ti ní ìrora-ọkàn púpọ̀ nítorí yín.

25 Mo sì bẹ̀rù mo sì wárìrì lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí yín, kí ó má bà tún jìyà; nítorí kíyèsĩ, ẹ̀yin ti fi ẹ̀sùn kán an pé ó nwá agbára àti àṣẹ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé òun kò wá agbára tàbí àṣẹ lórí yín, ṣùgbọ́n òun ti wá ògo Ọlọ́run, àti àlãfíà ayérayé tiyín.

26 Ẹ̀yin sì ti kùn sínú nítorí òun ti ṣe kedere sí yín. Ẹ̀yin sọ wípé òun ti lo ìkannú; ẹ̀yin sọ wípé òun ti bínú sí yín; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ìkannú rẹ̀ jẹ́ ìkannú tí agbára ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó wà nínú rẹ̀; èyí tí ẹ sì pè ní ìbínú jẹ́ òtítọ́, gẹ́gẹ́bí èyí tí ó wà nínú Ọlọ́run, èyí tí kò lè dá lẹ́kun, tí ó nfihàn tìgboyà-tìgboyà nípa ti àwọn àìṣedẽdé yín.

27 Ó sì di dandan kí agbára Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, àní sí pípa àṣẹ fún yín pe ẹ̀yin gbọdọ̀ gbọ́ran. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, kì í ṣe òun, ṣùgbọ́n Ẹ̀mi Olúwa èyí tí ó wà nínú rẹ̀ ni, èyí tí ó la ẹnu rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ sísọ tí kò lè pa á dé.

28 Àti nísisìyí ìwọ ọmọkùnrin mi, Lámánì, àti pẹ̀lú Lẹ́múẹ́lì àti Sãmú, àti pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin mi tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì, kíyèsĩ i, bí ẹ̀yin bá fetísílẹ̀ sí ohùn Nífáì ẹ̀yin kò ní parun. Bí ẹ̀yin bá sì fetísílẹ̀ sí i èmi fi ìbùkún kan sílẹ̀ fún yín, bẹ̃ni, àní ìbùkún mi èkíní.

29 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá ní fetísílẹ̀ sí i èmi yíò mú ìbùkún mi èkíní kúrò, bẹ̃ni, àní ìbùkùn mi, yíò sì simi lórí rẹ̀.

30 Àti nísisìyí, Sórámù, mo wí fún ọ: Kíyèsĩ i, ìwọ jẹ́ ìránṣẹ́ Lábánì; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a ti mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, èmi sì mọ̀ wípé ìwọ jẹ́ ọ̀rẹ́ òtítọ́ sí ọmọkùnrin mi, Nífáì, títí láé.

31 Nítorí-èyi, nítorí tí ìwọ ti ṣe olóotọ́ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún pẹ̀lú irú-ọmọ rẹ̀, tí wọn ó gbé ní alãfíà pẹ́ lórí ilẹ̀ yí; kò sì sí nkan, àfi tí yíò bá jẹ́ àìṣedẽdé lãrín wọn, tí yíò pa àlãfíà wọn lára tàbí dí i lọ́wọ́ lórí ojú ilẹ̀ yí títí láé.

32 Nítorí-èyi, bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin Olúwa mọ́, Olúwa ti ya ilẹ̀ yí sí mímọ́ fún ãbò irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú irú-ọmọ ti ọmọkùnrin mi.