Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 33


Ori 33

Àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì jẹ́ òtítọ́—Wọ́n jẹ́rĩ Krístì—Àwọn wọnnì tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Krístì yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì gbọ́, Tí yíò dúró bí ẹ̀rí níwájú irin ìdájọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò lè kọ gbogbo àwọn ohun tí a kọ́ni lãrín àwọn ènìyàn mi; bẹ̃ni èmi kò jẹ́ alágbára ní kíkọ̀wé, bí ti sísọ̀rọ̀; nítorí nígbàtí ènìyàn bá sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ngbé e sí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn.

2 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ọ̀pọ̀ ni ó wà tí wọ́n sé ọkàn wọn le sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí kò ní ãyè nínú wọn; nítorí-èyi, wọ́n sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun èyí tí a kọ nù wọ́n sì kà wọ́n sí gẹ́gẹ́bí ohun asán.

3 Ṣugbọn èmi, Nífáì, ti kọ ohun tí mo ti kọ, mo sì kà á sí gẹ́gẹ́bí iye nlá, àti pãpã fún àwọn ènìyàn mi. Nítorí mo gbàdúrà léraléra fún wọn nígbà ọ̀sán, ojú mi sì bù omi rin irọ̀rí mi nígbà òru, nítorí ti wọn; mo sì kígbe sí Ọlọ́run mi ní ìgbàgbọ́, mo sì mọ̀ pé òun yíò gbọ́ igbe mi.

4 Mo sì mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run yíò ya àwọn àdúrà mi sí mímọ́ fún ànfàní àwọn ènìyàn mi. Àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo sì ti kọ ní àìmókun ni a ó mú lágbára sí wọn; nítorí ó yí wọn lọ́kàn padà láti ṣe rere; ó mú kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn baba wọn; ó sì sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó sì yí wọn lọ́kàn padà láti gbàgbọ́ nínú rẹ̀, àti láti forítì í dé òpin, èyí tí ó jẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.

5 Ó sì sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà líle sí ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́bí ti kíkedere ti òtítọ́; nítorí-èyi, ẹnikẹ́ni kì yíò bínú sí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ti kọ àfi tí òun yíò bá jẹ́ ti ẹ̀mí èṣù.

6 Mo ṣògo nínú kíkedere; mo ṣògo nínú òtítọ́; mo ṣògo nínú Jésù mi, nítorí òun ti ra ọkàn mi padà kúrò nínú ọ̀run àpãdì.

7 Mo ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ fún àwọn ènìyàn mi, àti ìgbàgbọ́ nlá nínú Krístì pé èmi yíò bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn pàdé láìlábàwọ́n ní ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀.

8 Mo ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ fún àwọn Jũ—mo wípé Jũ, nítorí mo rò wọn láti ibi ti èmi ti wá.

9 Mo ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ fún àwọn Kèfèrí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, kò sí ẹnìkan nínú àwọn wọ̀nyí tí mo lè ní ìrètí fún àfi tí wọn yíò bá ṣe ìlàjà sí Krístì, kí wọ́n sì wọlé sínú ẹnu ọ̀nà tõró nã, kí wọ́n sì rìn ní ọ̀nà híhá èyí tí ó tọ́ sí ìyè, kí wọ́n sì dúró títí ní ọ̀nà nã dé òpin ọjọ́ ìdánwò.

10 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, àti Jũ pẹ̀lú, àti gbogbo ẹ̀yin ikangun ayé, ẹ fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kí ẹ sì gbàgbọ́ nínú Krístì; bí ẹ̀yin kò bá sì gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ẹ gbàgbọ́ nínú Krístì. Bí ẹ̀yin yíò bá sì gbàgbọ́ nínú Krístì ẹ̀yin yíò gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorí wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, ó sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì kọ́ gbogbo ènìyàn pé kí wọn ṣe rere.

11 Bí wọn kò bá sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, ẹ ṣe ìdájọ́—nítorí Krístì yíò fi hàn sí yín, pẹ̀lú agbára àti ògó nlá, pé wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ òun, ní ọjọ́ ìkẹhìn; ẹ̀yin àti èmi yíò sì dúró lójúkojú níwájú irin-ilé-ẹjọ́ rẹ̀; ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pé a ti pàṣẹ fún mi nípa rẹ̀ láti kọ àwọn ohun wọ̀nyí, l’áìṣírò àìlágbára mi.

12 Mo sì gbàdúrà sí Baba ní orúkọ Krístì pé ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa, bí kò bá jẹ́ gbogbo wa, le rí igbala ní ìjọba rẹ̀ ní ọjọ́ nlá àti ìkẹhìn nì.

13 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, gbogbo àwọn wọnnì tí ó jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì, àti gbogbo ẹ̀yin ikangun ayé, mo sọ̀rọ̀ sí yín bí ohùn ti ẹni tí ó nké láti inú eruku wá: Ó dìgbà míràn títí ọjọ́ nlá nì yíò dé.

14 Ẹ̀yin tí kì yíò bá sì pín nínú õre Ọlọ́run, kí ẹ sì bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ àwọn Jũ, àti àwọn ọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú, àti àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí yíò jáde wá láti ẹnu Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, kíyèsĩ i, mo ṣe ó dìgbà sí yín títí ayé, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yíò dá yín lẹ́bi ní ọjọ́ ìkẹhìn.

15 Nítorí ohun ti mo bá fi èdídì dì ní ayé, ni a ó mú wá dojúkọ yín ní ìjòkó ìdájọ́; nítorí báyĩ ni Olúwa pàṣẹ fún mi, èmi sì gbọdọ̀ gbọ́ran. Amin.