2010–2019
Àwọn Ọmọlẹ́hìn Tòótọ́ ti Olùgbàlà
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


2:3

Àwọn Ọmọlẹ́hìn Tòótọ́ ti Olùgbàlà

A lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ pípẹ́ nígbàtí Olùgbàlà wa àti ìhìnrere Rẹ̀ bá di àwòrán èyíti a fi ìgbé ayé wa sí àyíká rẹ̀.

Bí ó ti pamọ́ nínú ìwé Májẹ̀mú Láéláé ti Haggai ni ìjúwe ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn kan ẹnití ìbá ti ló àmọ̀ràn Alàgbà Holland. Wọ́n ṣe àṣìṣe ní àìfi Krístì ṣe gbùngbun ìgbé ayé wọn, àti iṣẹ́ ìsìn wọn. Haggai fi àmì àwọn ọ̀rọ̀ tó wọnilọ́kàn hàn bí ó ti bá àwọn ènìyàn wí fún dídúró nínú ilé wọn tó tura dípò gbígbé tẹ́mpìlì Olúwa ga:

“Àkókò ha ni fún yín, ẹ̀yin, láti máa gbé ilé ọ̀ṣọ́ yín, ṣùgbọ́n ilé yí wà ní ahoro?

“Njẹ́ nísisìyí báyi ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, Ẹ kíyèsí àwọn ọ̀nà yín.

“Ẹ̀yin ti fún irúgbìn púpọ̀, ẹ sì mú díẹ̀ wá ilé; ẹ̀yin njẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó; ẹ̀yin nmu, ṣùgbọ́n kò tẹ yín lọ́rùn; ẹ̀yin nbora, ṣùgbọ́n kò sí ẹnití ó gbóná; ẹnití ó sì ngba owó ọ̀yà ó ngba owó ọ̀yà sínú ajádi àpò.

“Báyi ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ẹ kíyèsí àwọn ọ̀nà yín.”1

Njẹ́ ẹ̀yin kò ha fẹ́ràn àwọn àpèjúwe wọnnì pé ó jẹ́ àsán bí a bá to àwọn ohun tí kò ní àyọrísí ayérayé lé orí àwọn ohun ti Ọlọ́run?

Nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa kan ti mo wà níbẹ̀, ìránṣẹ́ ìhìnrere kan tí ó ti padà sílé ṣe àtúnwí ọ̀rọ̀ bàbá kan ẹnití ó ṣe ìkékúrú èrò yí ní pípé, nígbàtí ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ohun tí a nílò níhĩn ni àdínkù Wi-Fi àti àlékún Néfì!”

Nítorítí mo ti gbé ní Ìwọ̀-oòrùn Áfríkà fún ọdún márũn, mo rí àwọn àpẹrẹ púpọ̀ ti àwọn ènìyàn tí wọ́n nfi ìhìnrere sí àkọ́kọ́ ní àdánidá àti ní àìtijú. Ọ̀kan irú àpẹrẹ bẹ́ẹ̀ ni orúkọ ilé iṣẹ́ kan tí wọn ti ntún táyà àti ọwọ́ ọkọ̀ ṣe ní Ghana. Ẹnití ó ni ibẹ̀ ti pe orúkọ rẹ̀ ní “Ìfẹ́ Tirẹ Ní-ìbámu.”

A lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ pípẹ́2 nígbàtí Olùgbàlà wa àti ìhìnrere Rẹ̀ bá di àwòrán èyíti a fi ìgbé ayé wa sí àyíká rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó rọrùn gidi fún àwòrán náà láti jẹ́, àwọn ohun ti ayé, nibití ìhìnrere yío jókòó bíi àlékún tí a fẹ́, tábí bíi kí a kàn wà nínú ilé ìjọ́sìn fún wákàtí méjì ní àwọn Ọjọ́- ìsinmi. Nígbàtí ó bá rí báyi, ó fi ara jọ fífi owó ọ̀yà wa sí inú “ajádi àpò.”

Hággáì nsọ fún wa láti jẹ́—olùfọkànsìn, bí a ti í sọ ni Australia, láti jẹ́ “ẹni rere” nípa gbígbé ìgbé ayé ìhìnrere. Àwọn ènìyàn jẹ́ ẹni rere nígbàtí wọ́n bá jẹ́ ohun tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́.

Mo kọ́ ẹ̀kọ́ díẹ̀ nípa jíjẹ́ ẹni rere àti sísa gbogbo ipá mi nípasẹ̀ síṣe eré rọ́gbì. Mo kọ́ ẹ̀kọ́ pé nígbàtí mo bá ṣe eré lílejùlọ mi, nígbàtí mo bá sa gbogbo ipá mi, ìgbádùn mi nípa eré náà máa npọ̀ jùlọ.

Alàgbà Vinson pẹ̀lú ẹgbẹ́ rúgbì

Ọdún tí mo fẹ́ràn jù fún rọ́gbì ni ọdún tí ó tẹ̀lé ilé iwé gíga mi. Àwọn ẹgbẹ́ tí mo wà nínú rẹ̀ ní ẹ̀bún àti ìfarasìn. Àwa ni ẹgbẹ́ olúborí ní ọdún náà. Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ kan a fẹ́ ṣeré pẹ̀lú ẹgbẹ́ kékeré kan, lẹhìn ìdárayá náà gbogbo wa ní ọ̀rẹ́ láti mú lọ sí ibi ijó nlá, ọlọ́dọdún ti kọ́lẹ́jì náà. Mo ròó pé nítorípé yío jẹ́ ìdárayá tí ó rọrùn, ó yẹ kí ngbìyànjú láti dáàbò bo ara mi lọ́wọ́ ìpalára kí nlè gbádùn ijó náà ní kíkún. Nínú eré náà, a ko ní ìfarasìn púpọ̀ nínú àwọn ìkọlù líle bí ó ti yẹ kí a ní, a sì pàdánù. Láti ba gbogbo rẹ jẹ́, mo parí ìdíje náà pẹ̀lú ètè wíwú, títóbi tí kò jẹ́ kí nlè fi ara hàn fún ètò nlá mi. Bóyá mo nílò láti kọ́ ohun kan.

Ìrírí tí ó yàtọ̀ gidigidi ṣẹlẹ̀ nínú ìdárayá kan lẹ́hìn náà nínú èyíti mo fi ara sìn pátápátá. Ní àkókò kan mo sáré gidi kọlu ẹnikan; lójúkannáà mo ní ìmọ̀lára ìrora ní ojú mi Nítorítí bàbá mi ti kọ́mi pé èmi kò gbọdọ̀ jẹ́kí ọ̀tá mọ̀ bí mo bá fi ara pa, mo tẹ̀síwájú láti ṣe eré náà dé òpin. Ní alẹ́ ọjọ́ náà, bí mo ti ngbìyànjú láti jẹun, mo ríi pé nkò le gé nkan jẹ. The àárọ̀ ọjọ́ kejì, mo lọ sí ilé ìwòsàn, níbití fọ́tò eegun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àgbọ̀n mi ti fọ́. Wọ́n fi wáyà ti ẹnu mi pa fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà tí ó tẹ̀lé.

A kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ láti inú òwe ti ètè sísanra àti àgbọ̀n fífọ́ yìí. Pẹ̀lú àwọn ìrántí mi nípa àwọn oúnjẹ líle tí ó wù mí tí nkò rí ní ààrin ọ̀sẹ̀ mẹ́fà náà nígbàtí mo le mu àwọn nkan olómi nìkan, èmi kò ní ìmọ̀lára àbámọ̀ nípa àgbọ̀n fífọ́ mi nítorípé ó wáyé láti ibi sísa gbogbo ipá mi. Ṣùgbọ́n mo ní àbámọ̀ nípa ètè sísanra nítorípé ó ṣe àpẹrẹ dídira mú.

Sísa gbogbo ipá wa kò túmọ̀ sí pé a ó máa wà nínú àwọn ìbùkún pẹ́ títí tàbí kí a ní àṣeyọrí nígbàgbogbo. Ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pé a ó ní ayọ̀. Ayọ̀ kìí ṣe ọ̀wọ́ ìtura tàbí ìdùnnú ìgba díẹ̀. Ayọ̀ nfi ara dà, a sì nríi nínú kí àwọn aápọn wa ó jẹ́ títẹ́wọ́gbà sí Olúwa.3

Àpẹrẹ kan irú ìtẹ́wọ́gbà bẹ́ẹ̀ ni ìtàn Oliver Granger. Bí Ààrẹ Boyd K Packer ti sọ: “Nígbàtí a lé àwọn ènìyàn mímọ́ kúró ní Kirtland, ... a fi Oliver sílẹ̀ lẹ́hìn láti ta àwọn ohun ìní wọn fún iye kékeré tí ó bá le tà á. Kò sí ààye púpọ̀ pé òun le ṣe àṣeyọrí. Àti pé, nítòótọ́, òun kò ṣe àṣeyọrí!”4 Ó ti gba àṣẹ láti ọwọ́ Àjọ Ààrẹ Ìkínní láti ṣe iṣẹ́ kan tí ó ṣòro, bí kò bá jẹ́ àìlèṣeéṣe. Ṣùgbọ́n Olúwa gbé oríyìn fún un fún àwọn aápọ̀n àìní àṣeyọrí rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:

“Èmi rantí ìránṣẹ́ mi Oliver Granger; kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún un pé orúkọ rẹ̀ yíò wà ní ìrantí mímọ́ láti ìran dé ìran, láé ati títí láéláé, ni Olúwa wí.

“Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí ó fi ìtara jà fún ìràpadà ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ mi, ... àti nígbàtí òun bá ṣubú òun yíò tún dìde lẹ́ẹ̀kansíi, nítorí ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ yíò jẹ́ mímọ́ jù sími ju ọrọ̀ rẹ̀ lọ, ni Olúwa wí.”5

Èyíinì le jẹ́ òtítọ́ nípa gbogbo wa—kìí ṣe àwọn àṣeyọrí wa, ṣùgbọ́n dípo rẹ̀, ọrẹ-ẹbọ àti àwọn aápọn wa, ní ó jẹ́ nkan sí Olúwa.

Àpẹrẹ míràn ti ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì tòótọ́ ni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n kan ní Côte d’Ivoire ní Ìwọ̀-oòrùn Áfríkà. Arábìnrin ìyanu àti olõtọ́ yìí jìyà ìmí ẹ̀dùn, àti ìlòkulò àfojúrí díẹ̀ papàá láti ọwọ́ ọkọ rẹ̀ fún àkókò tí ó gùn díẹ̀, àti pé ní ìgbẹ̀hìn wọ́n ṣe ìkọ̀sílẹ̀. Kò rẹ̀hìn láé nínú ìgbàgbọ́ àti ìṣerere rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí ìrorò rẹ̀ sí i, arábìnrin náà ní ìjìnlẹ̀ ìpalára fún ìgbà pípẹ́. Ní àwọn ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ó ṣe àpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀:

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sọ pé mo ti dárí jì í, nígbà gbogbo ni mo nsùn pẹ̀lú ọgbẹ́; mo lo àwọn ọjọ́ mi pẹ̀lú ọgbẹ́ náà. Ó dàbí ìjóná kan nínú ọkàn mi. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni mo gbàdúrà sí Olúwa láti mú un kúrò nínú mi, ṣùgbọ́n dídunni rẹ̀ burú tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbọ́ gidigidi pé èmi yíó lo ìyókù ìgbé ayé mi pẹ̀lú rẹ̀. Ó dunni ju ìgbà tí mo pàdánù ìyá mi ní ọjọ orí èwe; ó dunni ju ìgbà tí mo pàdánù bàbá mi àti ọmọkùnrin mi pàápàá. Ó dàbí ẹnipé ó gbòòrò ó sì bo ọkàn mi, ní fífún mi ní èrò pé mo le kú ní ìgbàkugbà.

“Ní àwọn ìgbà míràn mo nbi ara mi léèrè ohun tí Olùgbàla ìbá ṣe nínú ipò mi, èmi ó sì sọ pe, ‘Eléyìí ti pọ̀ jù, Olúwa.’

“Lẹ́hìnnáà ní àárọ̀ ọjọ́ kan mo wá ìrora tí ó máa nwá láti inú gbogbo èyí nínú ọkàn mi mo lọ jínjinlẹ̀ síi, ní wíwá a nínú ẹ̀mí mi. Kò sí ní ibi kankan láti rí. Iyè inú mi yára kọjá láti ṣe àyẹ̀wò gbogbo àwọn èrèdí tí mo ní láti ní ìmọ̀lára ìpalára, ṣùgbọ́n èmi kò ní ìmọ̀lára ìrora. Mo dúró ní gbogbo ọjọ́ láti ríi bóyá ìrora náà yío wá sí inú ọkàn mi; èmi ko ní ìmọ̀lára rẹ̀. Lẹ́hìnnáà mo kúnlẹ̀ mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tí ó jẹ́ kí ẹbọ ètùtù Olúwa ó ṣiṣẹ́ fún mi.”6

Nísisìyí arábìnrin yìí ti fi ìdùnnú ṣe èdidì pẹ̀lú ọkunrin ìyanu àti olõtọ́ kan tí ó fẹ́ràn rẹ̀ jinlẹ̀.

Nítorínáà kínni ó yẹ kí ìṣe wa ó jẹ́ bí a bá jẹ́ ọmọlẹ́hìn Krístì tòótọ́? Àti pé kínni yíyẹ ìhìnrere sí wa nígbàtí a bá “kíyèsí àwọn ọ̀nà [wa],” bí Haggáì ti daba.

Mo fẹ́ràn àpẹrẹ ìwà pípé tí a fihàn láti ọwọ́ bàbá Ọba Lámọnì. Ẹ ó rántí ìbínú rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ríri tí ọmọkùnrin rẹ̀ nbá Ámọ́nì rìn, ará Néfì kan—àwọn ènìyàn kan tí àwọn ara Lámánì kórìíra. Ó yọ idà rẹ̀ láti jà pẹ̀lú Ámọ́nì àti pé láìpẹ́ ó rí idà ti Ámọ́nì ní ọ̀fun ara rẹ̀. “Nísisìyí nítorítí ọba bẹ̀rù kí ó má sọ ẹ̀mí ara rẹ̀ nù, ó wípé: Bí ìwọ bá dá mi sí, èmi yíò fún ọ ní ohunkóhun tí ìwọ lè bẽrè, àní títí fi dé ìlàjì ìjọba yí.”7

Ẹ kíyèsí ohun tí ó fi sílẹ̀—ìlàjì ìjọba rẹ̀ fún ẹ̀mí rẹ̀

Ṣùgbọ́n ní ìkẹhìn, lẹ́hìn níní òye ìhìnrere, ó fi ohun míràn sílẹ̀. “Ọba náà wí pé: Kínni èmi yíò ṣe kí èmi ó le ní ìyè ayérayé èyítí ìwọ ti sọ nípa rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ni, kínni èmi yíò ṣe tí a ó fi bí mi nipa Ọlọ́run, tí ẹ̀mí búburú yí yíò jẹ́ fífàtu jáde kúrò ní àyà mi, tí èmi yíò sì gba Ẹ̀mí rẹ̀, kí èmi ó lè kún fún ayọ̀, kí èmi ó má baà di títa nù ní ọjọ́ ìkẹhìn? Kíyèsíi, ni ó wí, èmi yíò fi ohun gbogbo tí mo ní sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò kọ ìjọba mi sílẹ̀, kí èmi ó le gba ayọ̀ nlá yìí.”8

Ní àkókò yí, ó ṣetán láti fi gbogbo ìjọba rẹ̀ sílẹ̀, nítorípé ìhìnrere yẹ ju ohun gbogbo tí ó ní lọ! Òun jẹ́ ẹni rere nípa ìhìnrere.

Nítorínáà, ìbéèrè fún olukúlùkù wa ni pé: Njẹ́ àwa bákannáà jẹ́ ẹni rere nípa ìhìnrere bí? Nítorípé jíjẹ́ onílàjì ọkàn kìí ṣe jíjẹ́ ẹni rere! A kò sì mọ Ọlọ́run dída ìyìn sorí ẹni tó dúró lójukannáà.9

Kò sí ìṣúra, tàbí ìyówù iṣẹ́ tí ó wuni jù, tàbí ìyówù ipò, tàbí ìyówù ìròhìn ìgbàlódé, tàbí ìyówù eré aláwòrán, tàbí ìyówù eré ìdárayá, tàbí ìyówù ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ojúlùmọ̀ kan, tàbí ohunkóhun ní orí ilẹ̀ ayé tí ó ṣe iyebíye ju ìyè ayérayé. Nítorináà ìmọ̀ràn Olúwa sí olukúlùkù ènìyàn ni “kíyèsí àwọn ọ̀nà rẹ.”

Àwọn ìmọ̀lára mi ni a le sọ dáradára jùlọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Néfì pé: “Èmi ṣògo nínú ṣíṣe kedere; mo ṣògo nínú òtítọ́; mo ṣògo nínú Jésù mi, nítorítí ó ti ra ọkàn mi padà nínú ọ̀run apáàdì.”10

Ṣé a jẹ́ àtẹ̀lé Rẹ̀ tòótọ́ ẹnití ó fi gbogbo Rẹ̀ fún wa? Òun ẹnití ó jẹ́ Olùràpadà wa àti Alágbàwí wa pẹ̀lú Bàbá? Òun ẹnití ó fi Ararẹ̀ sìn pátápátá nínú ìrùbọ ètùtù Rẹ̀ àti pé bẹ́ẹ̀ ni nísisìyí, íyọ́nú rẹ̀, àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa láti ní ayọ ayérayé? Mo rọ gbogbo ẹnití ó gbọ́ àti tí ó ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Jọ̀wọ́, jọ̀wọ́ máṣe mú ìfarasìn pátápátá rẹ kúrò títí ìwọ ó fi mú un lò ní ojó iwájú tí kò tíì sí. Gba ẹni rere nísisìyí kí o ní ìmọ̀lára ayọ̀ náà! Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.