Àwọn Obìnrin Májẹ̀mú nínú Iṣẹ́ Ṣíṣe pẹ̀lú Ọlọ́run
Dída obìnrin majẹ̀mú nínú ìṣẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú Ọlọ́run ni bí títóbi àti ire àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run ti nfìgbàgbogbo ṣe-ìyá, darí, àti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.
Mo fi ìmoore hàn fún ìbùkún ti bíbá yín sọ̀rọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin Ọlọ́run. Lalẹyi, èrò mi ni láti gbà yí níyànjú nínú iṣẹ́ ìsìn nlá ti a pè yín sí. Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo ọmọbìnrin Ọlọ́run tó nfetísílẹ̀ sí ohùn mi ti gba ìpè kan látọ̀dọ̀ Olúwa Jésù Krístì.
Ìpè yìn bẹ̀rẹ̀ nígbàtí a gbé yín sínú ayé ikú, ní ibì kan àti àkokò tí a yàn fún yín nípasẹ̀ Ọlọ́run tí ó mọ̀ yín dáadáa tí ó sì fẹ́ràn yín bí ọmọbìnrin Rẹ̀. Nínú ayé ẹ̀mí, Ó mọ̀ yín Ó sì kọ́ọ yín Ó sì fi yín sí ibi tí ẹ ó ti ní ànfàní, tó ṣọ̀wọ́n nínú ìwé ìtàn ti ayé, láti gba ìpè sínú omi ìrìbomi. Níbẹ̀, ẹ ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a sọ nípasẹ̀ olùpè ìránṣẹ́ Jésù Krístì: “Níní àṣẹ nípasẹ̀ Jésù Krístì, mo ṣe ìrìbomi rẹ ní orúkọ ti Bàbá, àti Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́. Àmín.”1
Nígbàtí ẹ jáde nínú omi, ẹ ti tẹ́wọ́gba ìpè míràn láti sìn. Ọmọbìnrin májẹ̀mú titun Ọlọ́run, ẹ ṣe ìlérí ẹ sì gba ìfúnni-níṣẹ́ṣe nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ti èyí tí ẹ gba ìfẹsẹ̀múlẹ̀ lẹ́hìnnáà. Ẹ dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run láti gbé orúkọ Jésù Krístì sórí ara yín, láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti láti sìn Ín.
Fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n dá májẹ̀mú wọ̀nyí, iṣẹ́ ìsìn tí Olúwa npe ọkùnrin tàbí obìnrin náà láti ṣe yíò bá ẹni náà mu rẹ́gí. Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin májẹ̀mú Ọlọ́run gbogbo, bákannáà, ṣe àbápín ípé ayọ̀ pàtàkì kan. Ó jẹ́ láti sin àwọn ẹlòmíràn fún Un.
Sísọ̀rọ̀ sí àwọn arábìnrin, Ààrẹ Russell M. Nelson fúnni ní àkékúrú ìyanu kan nípa ìpè Olúwa síi yín láti darapọ̀ Mọ nínú iṣẹ́ Rẹ̀. Ààrẹ Nelson ṣàpèjúwe ìpè yín ní ọ̀nà yí: Olúwa wípé, ‘Iṣẹ́ mi àti ògo [ni] láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ.’‘ (Mósè1:39.) Nítorínâ olùfọkànsìn ọmọlẹ́hìn-obìrin Rẹ̀ lè sọ nítòótọ́, ‘Iṣẹ́ mi àti ògo mi ni láti ran àwọn olólùfẹ́ mi lọ́wọ́ láti dé ìfojúsùn tọ̀run.’
“Láti ran ẹlẹ́ran ara míràn lọ́wọ́ láti dé ipò cẹ́lẹ́stíà tẹni ni apákan iṣẹ́ ìránṣẹ́ tọ̀run obìnrin. Bí ìyá, olùkọ́ni, tàbí títọ́ ènìyàn mímọ́, óun nmọ amọ̀ alààyè sí ẹ̀yà ti àwọn ìrètí rẹ̀. Ní ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, iṣẹ́ ìránṣẹ́ tọ̀run rẹ̀ ni láti ran àwọn ẹ̀mí lọ́wọ́ láti gbáyé àti kí ọkàn wọn gba ìgbèga. Èyí ni òṣùwọ̀n ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó lọ́lá, ndàgbàsókè, ó sì ngbéniga.”2
Ẹ kò lè mọ ìgbàtí, tàbí fún àkokò ìgbà, tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ araẹni yín yíò dojúkọ iṣẹ́-ìsìn nínú àwọn ìpè yín bí ìyá, olórí, tàbí arábìnrin òjíṣẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́. Olúwa, nínú ìfẹ́, kìí fi yíyàn ìgbà, àkokò, tàbí ìtòlẹhìn ti ìfúnni-níṣẹ́ṣe wa sílẹ̀ fún wa. Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ mọ̀ látinú àwọn ìwé-mímọ́ àti àwọn wòlíì alààyè pé gbogbo àwọn ìfúnni-níṣẹ́ṣe wọ̀nyí yíò wá, bóyá ní ayé yí tàbí ní ayè tó nbọ̀, sí gbogbo ọmọbìnrin Ọlọ́run. Àti pé gbogbo wọn jẹ́ ìmúrasílẹ̀ fún ìyè ayérayé nínú àwọn ẹ̀bí olùfẹ́ni—àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run tó tóbí jùlọ.”3
Ẹ ó ní ọgbọ́n láti lo gbogbo ìlàkàkà yín láti múrasílẹ̀ báyìí pẹ̀lú òpin nínú yín. Iṣẹ́ náà ni a ṣe ní ìrọ̀rùn nítorí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìfúnni-níṣẹ́ṣe wọ̀nyí nfẹ́ ọ̀pọ̀ irú ímúrasílẹ̀ náà.
Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfùnni-níṣẹ́ṣe láti jẹ́ arábìnrin òjíṣẹ́ ìṣẹ́ ìranṣẹ́ kan. Bóyá ẹ ní ìfúnni-níṣẹ́ṣe gẹ́gẹ́bí ọmọbìnrin ọdún mẹwa kan nínú ẹbí níbití bàbá ti kú, tàbí bí ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ẹnití ìlú rẹ̀ jọ́ná láìpẹ́, tàbí nígbàtí ẹ wà ní ilé ìwòsàn kan tí ẹ̀ nní ìwòsàn làtinù iṣẹ́ abẹ—ẹ lè ní ààyè láti mú ìpé yín ṣẹ látọ̀dọ̀ Olúwa láti jẹ́ ọmọbìnrin òjíṣẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀.
Àwọn wọnnì dàbíi ẹnipé wọ́n yàtọ́ gan an ní ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀ gbogbo rẹ̀ nfẹ́ ìmúrasílẹ̀ alágbára kan, ọkàn ìfẹ́ni, ìgbàgbọ́ tí kò léru pé Olúwa kìí fúnni láṣẹ láìṣe pé Òun pèsè ọ̀nà kan, àti ìfẹ́ kan láti lọ àti láti ṣeé fun Un.3
Nítorí óun ti múrasílẹ̀, ọmọbìnrin ọdún mẹwa gbé apá rẹ yíká ìyá rẹ̀ opó wọ́n sì gbàdúrà láti mọ bí òun ó ṣe ran ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́. Wọ́n si ntẹra mọ́ ọ.
Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ti múrasílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ṣíwájú àìròtẹ́lẹ̀ iná ní agbègbè rẹ̀. Ó ti wá mọ̀ ò sì ti nifẹ́ àwọn ènìyàn náà. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù Krístì ti dàgbà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti gba àwọn ìdáhùn sí àwọn àdúrà rẹ̀ fún Olúwa láti ràn an lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ kékèké fún Un. Nítorí imúrasílẹ̀ rẹ̀ pípẹ́, òun ti ṣetán ó sì nítara láti ṣèto àwọn arábìnrin rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn àti àwọn ẹbí nínú ìpọ́njú.
Arábìnri kan tó nní ìwòsàn ní ilé-ìwòsàn kan látinú iṣẹ́ abẹ ti múrasílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn aláìsàn bíi tirẹ̀. Ó tilo gbogbo ayé láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ fún Olúwa sí gbogbo àlejò bíi pé ọkùnrin tàbí obìnrin náà jẹ́ alabagbé àti ọ̀rẹ́ kan. Nígbàtí ó bá ní ìmọ̀lára nínú ọkàn rẹ̀ nípa ipè láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé-ìwòsàn, ó sin àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú àkínkanjú gidi àti pẹ̀lú irú ìfẹ́ tí àwọn aláìsàn míràn fi bẹ̀rẹ̀ sí nírètí pé ara rẹ̀ yíò yá láìpẹ́ jọjọ.
Ní irú ọ̀nà kannáà tí ẹ múrasílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, ẹ lè ẹ sì gbọ́dọ̀ múrasílẹ̀ fún ìpè láti jẹ́ olórí kan fún Ọlọ́run nígbàtí ó bá yá. Yíò gba ìbèèrè fún ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì to jinlẹ̀ nínú ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ yín fún ìwé mímọ́ láti darí àwọn ènìyàn àti láti kọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ láìsí ìbẹ̀rù. Lẹ́hìnnáà ẹ ó múrasílẹ̀ láti ní Ẹ̀mí Mímọ́ bí ojúgba yín nígbàgbogbo. Ẹ ó nítara láti sọ pé, “Èmi yíò” nígbàtí olùdámọ̀ràn yín nínú Àjọ Ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin sọ, pẹ̀lú ẹ̀rù nínú ohùn rẹ̀ pé, “Ara Arábìnrin Alvarez kò yá loni. Tani yíò kọ́ kilasi rẹ̀?
Ó ngbà ọ̀pọ̀ ìmúrasílẹ̀ bákannáà fún ọjọ́ ìyanu nígbàtí Olúwa npè yín sí ìfúnni-níṣẹ́ṣe kan bí ìyá. Ṣùgbọ́n bákannáà àní yíò gba ọkàn olùfẹ́ni si jù bí ẹ ṣe nílò ṣíwájú. Yíò gba ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì kọjá ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀ nínú ọkàn yín. Yíò sì gba okun láti gbàdúrà fún agbára, ìdarí, àti ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́ kọjá ohun tí ẹ lè ti ní ìmọ̀lára bó ti ṣeéṣe.
Ẹ lè ti fòye bèèrè bí ọkùnrin ọdúnkọ́dún ṣe lè mọ ohun tí àwọn ìyá nílò. Ó jẹ́ ìbèèrè tó tọ́. Àwọn ọkùnrin kò lè mọ ohun gbogbo, ṣùgbọ́n a le kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ nípa ìfihàn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bákannáà a kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nípa àkíyèsí, nígbàtí a bá gba ánfàní láti wá Ẹ̀mí láti rànwálọ́wọ́ ní ìmọ̀ ohun tí a ṣàkíyèsí.
Mo tí nṣàkíyèsí Kathleen Johnson Eyring fún ọdún mẹtadinlọta tí a ti ṣègbeyàwó. Òun ni ìyá àwọn ọmọkùnrin mẹ́rin àti ọmọbìnrin méjì. Di òní, òun ti tẹ́wọ́gba ìpè láti jẹ́ ìyá alágbára lórí ọgọ́ọ̀rú ẹbí tààrà àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ẹ rántí Ìjúwe pípé ti Aàrẹ Nelson nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tọ̀run ti obìnrin kan—pẹ̀lú iṣẹ́ ìránṣẹ ti ṣíṣe ìyá: “Bí ìyá, olùkọ́ni, tàbí ẹni mímọ́ alágbàtọ́, ó nmọ amọ̀ alààyè sí ìwò ti ìrètí rẹ̀. Ní ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, iṣẹ́ ìránṣẹ́ tọ̀run rẹ̀ ni láti ran àwọn ẹ̀mí lọ́wọ́ àti kí ọkàn wọn gba ìgbèga. Èyí ni òṣùwọ̀n ìṣẹ̀dá rẹ̀.”4
Bí ó ṣe pẹ́ tí mo lè rántí, ìyàwó mi, Kathleen, ti tẹ̀lé àṣẹ náà, tí a fún àwọn ọmọbìnrin Bàbá wa. Kókó náà tó farahàn sí mi láti jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ náà ni “ó mọ amọ̀ alààyè sí ìwò ti ìrètí rẹ̀ ... ní iṣẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú Ọlọ́run.” Òun ko mu nípá. Ó mọọ́. Ó sì ní àpẹrẹ kan fún ìrètí rẹ̀, àti sí èyí tí òun gbìyànjú láti mọ àwọn wọnnì tí ó nifẹ tí ó sì ṣe ìyá sí. Àpẹrẹ rẹ̀ ni ìhìnrere ti Jésù Krístì—bí mo ṣe lè ri nípa fífi tàdúràtàdúrà ṣàkíyèsí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Dída obìnrin majẹ̀mú nínú ìṣẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú Ọlọ́run ni bí títóbi àti ire àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run ti nfìgbàgbogbo ṣe-ìyá, darí, àti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, sísìn ní ọ̀nàkọnà àti ibikíbi tí Ó ti múrasílẹ̀ fún wọn. Mo ṣe ìlérí pé ẹ̀yin yíò rí ayọ̀ nínú ìrìnàjò yín sí ilé yín ọ̀run bí ẹ ṣe npadà sọ́dọ̀ Rẹ̀ bí ọmọbìnrin olùpamọ́-májẹ̀mú ti Ọlọ́run.
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run Bàbá wà láàyè Ó sì fẹ́ràn yín. Òun yíò dáhùn àwọn àdúrà yín. Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ ndarí, nínú ohungbogbo yékéyéké ní, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ààrẹ Russell M. Nelson ni Wòlíì alààyè Rẹ̀. Àti pé Joseph Smith rí ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Bàbá àti Jésù Krístì ní aginjù àwọn igi ní Palmyra, New York. Mo mọ̀ pé èyí jẹ́ òtítọ́. Bákannáà mo jẹri pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà yín. Àti pé nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, ẹ lè di yíyàsímímọ́ àti gbígbéga sí àwọn ipè gíga àti mímọ́ èyí tí yíò wá sọ́dọ̀ yín. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.