2010–2019
Ṣíṣọ́ra sí Gbígba Àdúrà Léraléra
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


2:3

Ṣíṣọ́ra sí Gbígba Àdúrà Léraléra(Álmà 34:39; Mórónì 6:4; Lúkù 21:36)

A nílò ìṣọ́ra lemọ̀lemọ̀ láti tako ìtẹ́lọ́rùnjù àti àìlàròjinlẹ̀.

Mo gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ fún yín àti fún èmi bí a ṣe nyọ̀ tí a sì njọ́sìn papọ̀.

Ní Oṣù Kẹ́rin ti 1976, Alágbà Boyd K. Packer sọ̀rọ̀ pàtó sí àwọn ọ̀dọ́ ti Ìjọ nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ tótayọ tí àkọlé rẹ̀ njẹ́ “Àwọn Ọ̀ọ̀ni ti-Ẹ̀mí,” ó ṣàpèjúwe ìgbà ìfúnni-niṣẹ́ṣe kan ní Áfríkà bí òun ṣe ṣàkíyèsí àwọn ọ̀ọ̀nì ìparadà-dídára tó ndọdẹ lórí àwọn olùjìyà àìròtẹ́lẹ̀. Lẹ́hìnnáà ó fi àwọn ọ̀ọ̀ni wé Sàtánì, ẹnití ó ndọdẹ lórí àwọn ọ̀dọ́ aláìbìkítà nípa ṣíṣe ìparadà ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tó npani.

Mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹtàlélógún nígbàtí Alàgbà Packer fúnni ní ọ̀rọ̀ náà, àti tí emi àti Susan nretí ìbí ọmọ wa àkọ́kọ́ ní ọjọ́ díẹ̀ si. A ní ìtẹ̀mọ́ra pẹ̀lú àwọn ohun tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa yíyẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀nà tógajùlọ tí ó fi lo ìwà àwọn ẹranko lásán láti kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì ti-ẹ̀mí kan.

Susan àti èmi bákannáà rin ìrìn-àjò lọ sí Áfríkà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfúnni-níṣẹṣe. A sì ní àwọn ànfàní láti rí àwọn ẹrankò ọlọ́lá tí ó ngbé ní orílẹ̀-èdè náà. Rírántí ipa tí ọ̀rọ̀ Alàgbà Packer ní inú ayé wa, a gbìyànjú láti ṣàkíyèsí kí a sì kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ látinú ìwà ìgbé-ayé ẹrànko ti Áfríkà.

Mo fẹ́ ṣe àpèjúwe àwọn ìhùwàsí àti ètè àwọn Ológbò-nlá méjì tí Susan àti èmi wò tí wọ́n ndọdẹ ohun-ọdẹ wọn a sì fi wé díẹ̀ lára àwọn ohun tí a ṣàkíyèsí sí ìgbé ayé ojoojúmọ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì.

Àwọn Ológbò-nlá àti Ẹtu

Àwọn Ológbò-nlá ni ẹranko ilẹ̀ tó nsáré jùlọ lórí ilẹ̀ wọ́n sì nsáré gan ní gígùn dé bíi kilómítà ọgọ́fà ní wákàtí kan. Awọn ẹranko tó rẹwà wọ̀nyí lè saré láti ipò ìdúró sí yíyára sísáré bíi kilómítà mẹsanlélọ́gọ́ọ̀rún ní wákàtí kan ní ìṣẹ́ju-àáyá mẹ́ta ódín. Àwọn ológbò-nlá jẹ́ apani tí ó nṣọ́ ohun-ọdẹ wọn tí wọ́n sì nsáré gidi ní ibi kúkurú láti léni àti láti kọlù.

Ológbò-nlá tí Alàgbà àti Arábìnrin Bednar wò

Susan àti èmí fẹ́rẹ̀ lo wákàtí méjì tí à nwo àwọn ológbò-nlá ti wọ́n nyọdẹ àkópọ̀ ẹtu títóbi kan, àwọn ẹtu tó tẹ́rẹrẹ ó sì wọ́pọ̀ ní Áfríkà. Pápá gbígbẹ, tó ga ní savanna Áfríkà jẹ́ àwọn idẹ bráún àti pé ó díjú àwọn apani tán pátápátá bí wọ́n ṣe nsálé àwọn ẹtu kan. Àwọn ológbò-igbó náà yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ ara wọn bíi yáàdì ọgọ́ọ̀rún(ìwọ̀n àádọ́rún) ṣùgbọ́n wọ́n nrìn ní àpapọ̀.

Nígbàtí ológbó-igbó kan joko sókè nínú pápá tí kó mira, ológbò-nlá míràn lẹ ara mọ́lẹ̀ ó sì yọ́ díẹ̀díẹ̀ lọ súnmọ́ àwọn ẹtu láìròtẹ́lẹ̀. Lẹ́hìnnáà ni ológbò-igbó tó ti joko sókè parẹ́ mọ́ inú pápá ní àkokò kannáà tí ológbò-nlá míràn joko sókè. Yíyí àwòṣe padà ti ológbò-nlá kan tí ó nyọ́ sísálẹ̀ yí àti nà síwájú nígbàtí ológbò-nlá míràn joko sókè nínú pápá tẹ̀síwájú fún ìgbà pípẹ́. Àrékérekè abẹ́lẹ̀ tì ẹ̀tàn náà ni èrò láti dàláàmú àti láti tan àwọn ẹtu náà kí wọ́n sì darí ìdojúkọ wọn lọ kúrò níbi ewu tó nbọ̀. Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti ìdúro-déédé, ni àwọn ológbò-nlá méjì náà fi ṣiṣẹ́ bí ẹgbẹ́ kan láti gba oúnjẹ wọn to nbọ̀.

Dídúró ní àárín ẹgbẹ́ àwọn ẹtu tó tóbí àti bíbọ̀ àwọn ológbò-igbó ti jẹ́ onírurú ẹtu tó dàgbà àti alágbára tó ndúró bí adènà lórí òkìtì ikán. Títóbi ìwò ti ilẹ̀-pápá náà látinú àwọn òkè kékèké fi ààye gba olùtọ́ àwọn ẹtu láti ṣọ́lẹ̀ fún àwọn àmì ewu.

Lẹ́hìnnáà lọ́gán, bí àwọn ológbò-igbó ṣe dé láti wà ní ìbi ìkọlù, gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ẹtu náà yípadà wọ́n sì sálọ. Èmi kò mọ̀ bí tàbí báwo ni adènà àwọn ẹtu ṣe bá ẹgbẹ́ títóbi náà sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ní ọ̀nà kan a fún wọn ní ìkìlọ.

Àti pé kíni àwọn ológbò-igbó náà ṣe? Láìsí ìdádúró kankan, àwọn ológbò-nlá náà bẹ̀rẹ̀ ìyípadà àwòṣe tí ológbò-nlá kan nyọ́ lábẹ́ tí ó sì nrìn lọ síwájú nígbàtí ológbò-nlá míràn joko sókè nínú pápá. Àwòṣe ìlépa náà tẹ̀síwájú. Wọn kò dúró. Wọn kò sinmi tàbí gba ìdádúró díẹ̀ kan. Wọn kò dúró ní títẹ̀lé ẹ̀tàn ìdàmú àti yíyàkúrò wọn. Susan àti èmi wo àwọn ológbò-igbó náà tí wọ́n túká lókèèrè, tí wọ́n nsúnmọ́ àti súnmọ́ àwọn ẹgbẹ́ ẹtu náá nígbàgbogbo.

Ní alẹ́ náà Susan àti èmi ní ìbárasọ̀rọ̀ onírántí nípa ohun tí a ṣe àkíyèsí tí a sì kọ́. Bákannáà a sọ ìrìrì yi pẹ̀lú àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ wa a sì fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ oníyebíye hàn. Báyíì èmi ó ṣàpèjúwé mẹ́ta lára àwọn ẹ̀kọ́ náà.

Ẹ̀kọ́ #1—Ṣọ́ra nípa Ibi ti Ìrẹ́jẹ Ìparadà

Fún mi, àwọn ológbò-igbó jẹ́ àwọn ẹdá dídán, ẹlẹ́tàn, àti onígbẹ̀kùn. Àwọ̀ rẹ́súrẹ́sú ológbò-igbó kan sí kóòtù funfun pẹ̀lú àwọn àmìn dúdú ni ìparadà ẹlẹ́wà tí ó nmú àwọn ẹranko wọ̀nyí ṣe àláìrí bí wọ́n ṣe nyọ́dẹ ohun-ọdẹ wọn ní pápá-ilẹ̀ Áfrícàn.

Ológbò-nlá yírapadà lórí ilẹ̀

Ní irú ọ̀nà kannáà, àwọn èrò ewu ti-ẹ̀mí àti àwọn ìṣe lè fi lẹmọ́lemọ́ hàn láti wuni, dùnmọ́ni, tàbí ládùn. Báyìí, ní ayé wa kanáà, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa níláti ṣọ́ra ẹ̀tàn buburú tó ndíbọ́n láti jẹ́ ire. Bí Ísáíàh ṣe kìlọ̀, “Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n npe ibi ní rere, àti rere ní ibi; tí nfi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀, àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn; ti nfi ìkorò pe adùn, àti adùn pe ìkorò!”1

Ní àkokò ìtakora ọ̀rọ̀ nígbàtí wọ́n nṣẹ̀ sí ìwàmímọ́ ìgbé ayé ènìyàn ni ó kéde bí ẹ̀tọ́ àti rúdurùdu tí a júwe bí òmìnira, bí a ti jẹ́ alábùnkún to láti gbé ní àsìkò ọjọ́-ìkẹhìn yí nígbàtí ìmọ́lẹ̀ ìmùpadàbọ̀sìpò ìhìnrere lè tàn yereyere nínú ayé wa kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀tàn òkùnkùn ọ̀tá àti ìdàmú.

“Nítorí àwọn tó gbọ́n tí wọ́n gba òtítọ́, tí wọ́n mú Ẹ̀mí Mímọ́ fún atọ́nà wọn, tí wọ́n kò gba ẹ̀tànlootọ ni mo wí fún yín, a kò ní ké wọn kúrò kí a sì jù wọ́n sínú iná, Ṣùgbọ́n wọn yíò gbé ní ọjọ́ náà.”2

Ẹ̀kọ́ #2—Ẹ Jí Dide Kí Ẹ Sì Níṣọ́ra

Fún ẹtu kan, ìgbà ránpẹ́ àìjáfáfá tàbí àìfetísílẹ̀ lè mú ìkolù látọ̀dọ̀ ológbò-nlá wá. Bákannáà, ìtẹ́lọ́rùnjù ti-ẹ̀mí àti àìláròjinlẹ̀ lè mú wá gba ìpalára sí àwọn ìgbàmọ́ra ọ̀tá. Àìnírònú ti-ẹ̀mí npe ewu nlá sínú ayé wa.

Fu àwọn tọ́pì lára

iStock.com/Angelika

Néfì ṣe àpèjúwe bí Sàtánì yíò ṣe dán niwò ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn láti rọ̀ ni àti láti tan àwọn ọmọ Ọlọ́run sínú ọgbọ́n àìṣòdodo ti ààbò ti-ara, “tí wọ́n yíò wípé: Ohun gbogbo dará ní Síónì; bẹ́ẹ̀ni, Síónì ṣe rere, ohun gbogbo dára—àti báyìí eṣù tan ọkàn wọn jẹ, ó sì nfi pẹ̀lẹ́pẹ́lẹ́ darí wọn lọ sí ọ̀run-àpáàdì.”3

A nílò ìṣọ́ra lemọ̀lemọ̀ láti tako ìtẹ́lọ́rùnjù àti àìlàròjinlẹ̀. Níní ìṣọ́ra ni ipò tàbí iṣe ti fífi ìtẹramọ́ ṣọ́nà fún èwu tó ṣeéṣe tàbí àwọn ìṣòro. Àti pé títẹramọ́ ṣíṣọ́nà fi ìṣe ti dídúróṣinṣin láti tọ́nisọ́nà àti láti dáàbòbò. Sísọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí, a nílò láti dúróṣinṣin kí a sì ṣọ́ra sí àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́ àti àwọn àmì tí ó nwá látọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ Olúwa lórí àwọn ilé ìṣọ́ gíga.4

“Bẹ́ẹ̀ni, bákannáà mo kìlọ̀ fún yín … pé kí ẹ jẹ́ olùṣọ́ sí ṣíṣe àdúrà léraléra, kí àwọn àdánwò èṣù máṣe darí yín lọ, … nítorí kíyèsíi, kìí yíò fún yín léré ohun rere kankan.”5

Dídojú ìgbé ayé wa sí àti lórí Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀ yíò fún wa lágbára láti borí ìtẹ̀sí ẹlẹ́ran-ara láti jẹ́ ọ̀lẹ àti aláìjáfáfá ti-ẹ̀mí. Bí a ṣe ndi alábùkún pẹ̀lú ojú láti ríran àti etí láti gbọ́ran,6 Ẹ̀mí Mímọ́ lè mú okun wa pọ̀si láti wò àti láti fetísílẹ̀ nígbàtí a lè má tilẹ̀ ronú pé a nílò láti wò tàbí fetísílẹ̀ tàbí a lè ma ronú wípé a lè gbọ́ tàbí rí.

“Nítorínáà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ lè múrasílẹ̀.”7

Ẹ̀kọ́ #3—Ní Ìmọ̀ Èrò Ọ̀tá

Ológbò-nlá kan jẹ́ apani tí ó máa nṣọdẹ lórí àwọn ẹranko míràn. Gbogbo ọjọ́, ojoojúmọ́, ológbò-nlá jẹ́ apani.

Ológbò-nlá ndọdẹ

Sátánì “ni ọ̀tá òdodo àti níti àwọn wọnnì tí wọ́n nwá láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.”8 Gbogbo ọjọ́, lojoojúmọ́, èrò-inú rẹ̀ nìkanṣoṣo àti kókó èrò rẹ̀ ni láti mú kí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run níbànújẹ́ bíiti ararẹ̀.9

Ètò ìdùnnú ti Bàbá ni a ṣe láti pèsè ìdarí fún àwọn ọmọ Rẹ̀, láti rànwọ́nlọ́wọ́ láti ní ìrírí ayọ̀ pípẹ́, àti láti mú wọ́n wá sílé láìléwu sọ́dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú àjíìnde, ìgbéga àwọn ara. Èṣù nṣiṣẹ́ láti mú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run nídàmú àti ìbànújẹ́ àti láti dí wọn lọ́nà ìlọsíwájú ayérayé. Ọ̀tá nṣiṣẹ́ láìsimi láti kọlu àwọn ohun-èlò ètò Bàbá tí ó kóríra jùlọ.

Sátánì kò ní ara, àti pé ìlọsíwájú ayérayé rẹ̀ ti dópin. Gẹ́gẹ́bí adágún ṣe ndá ìṣàn omi odò dúró, bẹ́ẹ̀ni ilọsíwájú ayérayé ọ̀tá ṣe dàrú nítori kò ní ẹran ara kankan. Nítorí oríkunkun rẹ̀, Lúsíférì ti sẹ́ ararẹ̀ nínú gbogbo ìbùkún ayé-ikú àti àwọn ìrírí tó ṣeéṣe látinú àgọ́ ẹran-ara àti egungun. Ọ̀kan lára ìtumọ̀ ìwé-mímọ́ tó múná sí ọ̀rọ̀ náà parun ni a júwe nínú àìlágbára rẹ̀ láti tẹ̀síwájú nínú ìlọsíwájú àti dídàbíi Bàbá wa Ọ̀run.

Nítorí ẹran-ara wà ní oókan ètò ìdùnnú Bàbá wa Ọ̀run àti ìgbèrú ti ẹ̀mí wa, Lúsíférì nwá láti da ìlọsíwájú wa rú nípa dídánwa wò láti lo ara wa láìdáa. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé ààbò ti ẹ̀mí nígbẹ̀hìn wà ní “máṣe gbe ìgbésẹ̀ ìfanimọ́ra àkọ́kọ́ sí lílọ síbi tí ẹ kò gbọ́dọ̀ lọ àti ṣíṣe ohun tí ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe.’ ... Bí ẹlẹ́ran ara gbogbo wa ní ìpebi [ti ara] tó ṣeéṣe fún ìgbàlà wa. ‘Àwọn ìpebi wọ̀nyí ṣe pàtàkì gidigidi fún wíwà láyé. Nítorínáà, kíni ohun tí ọ̀tá nṣe? Ó nkọlù wa nípa àwọn ìpebi wa. Ó ndánwa wò láti jẹ àwọn ohun tí kò yẹ kí á jẹ, láti mu àwọn ohun tí kò yẹ kí á mu, àti láti fẹ́ràn ohun tí kò yẹ kí á fẹràn!’”10

Ọ̀kan lára àwọn ìgbẹ̀hìn ti àìlópin ni pé ọ̀tá, ẹnití ó nbanújẹ́ gẹ́gẹ́ nítorí kò ní ẹran-ara, npe ó sì nfa wá mọ́ra láti pín nínú oṣì rẹ̀ nípa àìmọ ìlò ara wa. Ohun èlò gan an tí kò ní tí kò sì lè lò báyìí ni kókó ìfojúsùn ti ìgbìyànjú rẹ̀ láti tàn wá sí ìparun ti ara àti ti ẹ̀mí.

Níní òye èrò-inú ọ̀tá kan ṣe pàtàkì sí ìmúrasílẹ̀ gidi fún ìkọlù tó ṣeéṣe.11 Kòngẹ́ nítorí Ọ̀gágun Mórónì mọ èrò-inú àwọn ará Lámánì, ó ṣetán láti pàdé wọn ní àkokò bíbọ̀ wọn ó sì ṣẹ́gun.12 Irú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti ìlérí kanáà ló wà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.

“Tí ẹ bá múrasílẹ̀, ẹ kò ní fòyà.

“Àti pé kí ẹ lè yọ nínú agbára ọ̀tá .”13

Ìfipè, Ìlérí, àti ẹ̀rí

Gẹ́gẹ́bí àwọn ẹkọ́ pàtàkì tí a lè kọ́ nípa ṣíṣe àkíyèsí ìwà àwọn Ológbò-nlá àti ẹtu, bẹ́ẹ̀ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ wá àwọn ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ tí a rí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ojojoojúmọ́ ìgbé ayé. Bí a ṣe nṣe ìwákiri fún inú àti ọkàn tó ṣí sílẹ̀ láti gba ìdarí ọ̀run nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, nígbànáà ọ̀pọ̀ nínú àwọn àṣẹ títóbijulọ tí a lè gbà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ìkìlọ alágbára jùlọ tí ó lè tọ́wasọ́nà yíò jáde nínú àwọn ìrírí lásán ti arawa. Àwọn òwe alágbára wà nínú méjèèjì àwọn ìwé mímọ́ àti nínú àwọn ìgbé ayé wa.

Mo ti fi mẹ́ta nìkan hàn lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí a lè yẹ̀wò nínú ìlọkiri tí Susan àti èmi ti ní ní Áfríkà. Mo pè mo sì gbà yín níyànjú láti ronú lórí ìran yí pẹ̀lú àwọn ológbò-nlá àti àwọn ẹtu kí ẹ sì yẹ àfikún àwọn ẹ̀kọ́ wò fún yín àti ẹbí yín. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí nígbàgbogbo pé ilé yín ni gbùngbun òtítọ́ ti ìhìnrere ìkọ́ni àti ìgbé ayé.

Bí ẹ ṣe ndáhùn nínú ìgbàgbọ́ sí ìfipè yí, àwọn èrò ìmísí yíò wá sínú yín, àwọn ìmọ̀lára ti ẹ̀mí yíò dàgbà nínú ọkàn yín, ẹ ó sì dá àwọn ìṣe tí a ó ṣe tàbí tẹ̀síwájú láti ṣe mọ̀ kí ẹ lè “gbé gbogbo àhámọ́ [ti Ọlọ́run] [náà] lé orí yín kí ẹ lè kojú ọjọ́ ibi náà, ní ṣíṣe ohun gbogbo, kí ẹ lè dúróṣinṣin.”14

Mo ṣèlérí pé àwọn ìbùkún ìmúrasílẹ̀ tó péye àti ìdáàbò ti-ẹ̀mí yíò ṣàn wá sínú ayé yín bí ẹ ti nfìṣọ́ra sí gbígba àdúrà ìwòye àti léraléra.

Mo jẹ́ẹ̀rí pé títẹ̀síwájú ní ipá-ọ̀nà májẹ̀mú npèsè ààbò ti-ẹ̀mí ó sì npè ayọ pípẹ́ sí ayé wa. Mo sì jẹ́ ẹ̀rí pé olùjíìnde àti alààyè Olùgbàlà yíò ṣe ìmúduró yíò sì fún wa lókun ní àwọn ìgbà rere àti ibi bàkannáà. Nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni mo jẹ́ẹ̀rí ni orúkọ mímọ́ Olúwa Jésù Krístì, Àmín.