Ìgbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú Ìtẹramọ́ àti Ìfaradà
Gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbígbẹ́kẹ̀lé àkókò Rẹ̀, ó sì gba sùúrù àti ìpamọ́ra tí ó tayọ àwọn ìjì ìgbé ayé.
Ọmọkùnrin wa Daniel ṣe àìsàn gidigidi ní ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní Afríkà wọ́n sì mú un lọ sí ilé ìwòsàn kan tí àwọn ohun èlò rẹ̀ kò tó. Bí a ṣe ka lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́hìn àìsàn rẹ̀, a retí pé òun yío ní ìrẹ̀wẹ̀sì, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ó kọ pé, “Àní bí mo ti dùbúlẹ̀ nínú yàrá ẹ̀májẹ́nsì, mo ní ìmọ̀lára àlàáfíà. Èmi kò tíì ní irú ìnú dídùn pẹ̀lú ìtẹramọ́ àti pẹ̀lú ìfaradà bẹ́ẹ̀ rí ní ayé mi.”
Bí ìyàwó mi àti èmi ṣe ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, a kún fún ẹ̀dùn ọkàn. A ní inúdídùn léraléra àti láìmikàn. A kò gbọ́ kí wọ́n júwe ìdùnnú ní ọ̀nà bẹ́ẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ laago òtítọ́. A mọ̀ pé ìdùnnú tí ó júwe kìí ṣe ìgbàdú lásán tàbí ipò ìgbéga ṣùgbọ́n àláfíà kan àti ayọ̀ tí ó nwá nígbàtí a bá yọ̀ọ̀da arawa sí Ọlọ́run àti kí a gbé ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Rẹ̀ nínú ohun gbogbo.1 Àwa náà ti ní irú àwọn àkókò wọnnì nínú ìgbé ayé wa, nígbàtí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí ọkàn wa, tí ó sì mú kí a ní ìrètí nínú Kristì àní nígbàtí ìgbé ayé le tí kò sì dáni lójú.2
Léhì kọ́ni pé bí Adámù àti Éfà kò bá ṣubú “wọn ìbá wà ní ipò àìmọ̀kan, láìní àyọ̀, nítorí wọn kò mọ òṣì; ...
“Ṣùgbọ́n kíyèsĩi, ohun gbogbo ni a ti ṣe ní ọgbọ́n rẹ̀ ẹni tí ó mọ ohun gbogbo.
“Ádámù ṣubù kí àwọn ènìyàn lè wà; àwọn ènìyàn sì wà, kí wọ́n ó lè ní ayọ̀.”2
Ní ọ̀nà kan tí ó rújú, àwọn ìpọ́njú àti ìbànújẹ́ npèsè wa láti ní ìrírí ayọ̀ bí a bá ní ìgbẹkẹ̀lé nínú Olúwa àti èrò Rẹ̀ fún wa. Òtítọ́ yí ni a fihàn dárdára nípasẹ̀ akéwì sẹntúrì-mẹ́tàlá kan: “Ìkorò nmúra wa sílẹ̀ fún ayọ̀. Ó máa nfi pẹ̀lú agídí gbá ohun gbogbo jáde ní ilé rẹ, kí ayọ̀ tuntun ó le rí ààyè láti wọlé. Ó ngbọn àwọn ewé pupa kúro ní ẹ̀ka igi ọkàn rẹ, kí ewé tuntun, tútù ó le hù ní ààyè wọn. Ó nfa àwọn gbòngbò jíjẹrà tu, kí àwọn gbòngbò tuntun ní ìfarapamọ́ ó le ráàyè dàgbà. Ohunkóhun tí ìbànújẹ́ bá gbọ̀n dànù nínú ọkàn rẹ, àwọn ohun tí ó dára jù yío dípò wọn.”3
Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni, “Ayọ̀ tí Olùgbàlà fún [wa] … wà lemọ́lemọ́, nmu dáwalójú pé ‘àwọn ìpọ́njú wa yíò di ṣùgbọ́n àkokò kékeré kan’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:7] àti láti yàsọ́tọ̀ fún èrè wa.”5 Àwọn àdánwò wa àti ìpọ́njú lè fi ààyè fún ayọ̀ nlájùlọ.6
Ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere kìí ṣe ìlérí ìgbé ayé tí ó ní òmìnira kúrò nínú ìbànújẹ́ àti ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ìgbé ayé tí ó kún fún èrèdí àti ìtumọ̀—ìgbé ayé kan níbití àwọn ìbànújẹ́ àti ìpọ́njú wa ti le di gbígbémì nínú ayọ̀ ti Krístì.”6 Olùgbàlà kéde, “Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”7 Ìhinrere Rẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ ìrètí kan. Ìbànújẹ́ ní àfikún pẹ̀lú ìrètí nínú Jésù Krístì ndi ìlérí ayọ̀ pẹ́títí mú.
Ìtàn ti ìrìn-àjò àwọn ará Járẹ́dì sí ilẹ̀ ìlérí ni a le lò bíi àfijọ fún ìrìn-àjò wa la ayé kíkú já. Olúwa ṣe ìlérí fún arákùnrin Járẹ́dì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé Òun yío “lọ ṣaájú [wọn] sí inú ilẹ̀ kan èyítí ó jẹ́ àṣàyàn tayọ gbogbo àwọn ilẹ̀ ayé.”8 Ó pàṣẹ fún wọn láti kan àwọn ọ̀kọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ìgbọràn, ní kíkàn wọ́n ní ìbámu sí àwọn àṣẹ Olúwa. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, bí iṣẹ́ ti ntẹ̀síwájú, arákùnrin Járẹdì ṣe àníyàn nípa bí Olúwa ti ya àwòrán àwọn ọkọ̀ náà kò tó. Ó kígbe sókè:
“Áà Olúwa, èmi ti ṣe iṣe náà èyítí o ti pàṣẹ fún mi, mo sì ti ṣe àwọn ọkọ̀ náà ní ìbámu sí bí o ti darí mi.
“Sì kíyèsíi, Óò Olúwa, kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú wọn;9
Áà Olúwa, njẹ ìwọ ó ha fi ààyè gbà pé kí àwa ó là omi nla yĩ kọjá nínú okùnkùn bí?”10
Njẹ́ ẹ̀yin ti tú ọkàn yín jáde sí Ọlọ́run ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ rí láé? Nígbàtí ẹ ntiraka láti gbé ìgbé ayé bí Olúwa ti pàṣẹ tí ẹ kò sì bá àwọn ìrètí òdodo pàde, ṣé ẹ ti ròó bóyá ẹ̀yin níláti la ayé yí kọjá nínú òkùnkùn?11
Àní arákùnrin Járẹ́dì nígbànáà fi àníyàn títóbijùlọ Lẹ́hìn kan hàn nípa okun wọn láti wà láàyè nínú àwọn ọkọ̀-omi náà. Ó kígbe, “Àti pẹ̀lú àwa yíò parun, nítorípé àwa kò lè mí nínú wọn, bíkòṣe afẹ́fẹ́ tí ó wà nínú wọn.”12 Njẹ́ àwọn ìṣòro ìgbé ayé ti mú kí ó le fún yín láti mí, tí ó sì mú kí ẹ ro báwo ní ẹ ó ti la là á já ní ọjọ́ náà, kí a má sọ nípa àtipadà sí ibùgbé yín ti ọ̀run?
Lẹ́hìn tí Olúwa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú arákùnrin Járẹ́dì láti yanjú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àníyàn rẹ̀, lẹ́hìnnáà Ó ṣe àlàyé pé, “Ẹ̀yin kò le dá ọ̀gbún nlá yi kọjá bíkòṣepé èmi múra [ọ̀nà kan fún] yín ní ìdojúkọ àwọn ìgbì òkun náà, àti àwọn àfẹ́fẹ́ èyítí ó ti lọ ṣaájú, àti àwọn omi èyítí yío wá.”13
Olúwa mú un hàn kedere pé ní ìparí àwọn ará Járẹ́dì kò le dé ilẹ̀ ìlérí ní àìsí Òun. Wọn kò ní ìdarí ní ìkáwọ́, àti pé ọ̀nà kanṣoṣo tí wọ́n fi le la ọ̀gbun nlá náà kọjá ni láti fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí inú Rẹ̀ Àwọn ìrírí wọ̀nyí àti ìkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa dàbí láti mú ìgbàgbọ́ arákùnrin Járẹ́dì jìnlẹ̀ síi àti láti fi okun fún ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Olúwa.
Ẹ kíyèsí bí àwọn àdúrà rẹ̀ ṣe yípadà láti ìbéèrè àti àníyàn sí fífi ìgbàgbọ́ áti ìgbẹ́kẹ̀lé hàn.
“Èmí mọ̀, Óò Olúwa, pé ìwọ ní gbogbo agbara, ìwọ sì lè ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ fún èrè ènìyàn; ...
“Kíyèsíi, Áà Olúwa, ìwọ lè ṣe èyí. Àwa mọ̀ pé ìwọ lè fi agbára nlá hàn, èyítí ó dàbíi pé o kere sí òye àwọn ọmọ ènìyàn.”14
A kọ ọ́ sílẹ̀ pé lẹ́hìnnáà àwọn ará Járẹ́dì “wọ inú ... àwọn ọkọ̀ wọn, wọ́n sì gbéra lọ sí inú òkun, ní fífi ara wọn lé Olúwa Ọlọ́run wọn lọ́wọ́.”15 Láti fi lé lọ́wọ́ túmọ̀ sí láti fi fún tàbí láti fi sílẹ̀. Àwọn ará Járẹ́dì kò wọlé sí inú ọkọ̀ nítorípé wọ́n mọ̀ ní pàtó bí àwọn nkan yío ti rí ní ìrìn-àjò wọn. Wọ́n wọlé sínú rẹ̀ nítorípé wọ́n ti kọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé agbára, inúrere, àti àánú Olúwa, wọ́n sì ṣetán nítorínáà, láti fi ara wọn, àti èyíkéyi iyèméjì àti ẹ̀rù tí wọn lè ti ní, sílẹ̀ fún Olúwa.
Láìpẹ́ ọmọ-ọmọ wa Abe níbẹ̀rù láti wa ọ̀kan lára ẹranko kàrósẹ̀lì tó nrìn sókè àti ìsàlẹ̀. Ó yàn ọ̀kan tí kò rìn. Ìyáàgbà rẹ̀ ní òpin rọ̀ ọ́ pé kò ní léwu, nítorínáà, nígbígbẹ́kẹ̀lé e, ó gùn ún. Lẹ́hìnnáà ó sọ pẹ̀lú ẹ̀rín nlá, “Èmi nímọ̀lára pé ewu wà, ṣùgbọ́n mo wàláaìléwu.” Bóyá bẹ́ẹ̀ni àwọn Ará Járẹ́dì ṣe ní ìmọ̀lára. Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run lè má fìgbàgbogbo wà láìléwu ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n ayọ̀ tẹ̀le.
Ìrìàjò náàa kò rọrùn fún àwọn Ará Járẹ́dì. “Wọ́n fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà jẹ́ bíbòmọ́lẹ̀ nínú àwọn ibú òkun, “nítorí òkè àwọn ìgbì èyítí ó ya bò wọ́n.”16 Síbẹ̀ a kọ sílẹ̀ pé “afẹ́fẹ́ náà kò dáwọ́ dúró láti máa fẹ́ [wọn] sí ìhà ilẹ̀ ìlérí náà.”17 Bí ó ti ṣòró tó láti ní òye, pàápàá ní àwọn àkókò nínú ìgbé ayé wa nígbàti àwọn oríafẹ́fẹ́ bá lé tí òkun náà sì njà, a le gba ìtùnú nínú mímọ̀ pé, Ọlọ́run nínú àìlópin ìnú rere Rẹ̀ nfi ìgbà gbogbo fẹ́ wa sí ihà ilé.
Àkọsílẹ̀ náà tẹ̀síwájú pé, “A sì gbé wọn lọ síwájú; ohun abàmì inú okun kankan kò sì lè dá wọn dúró, tàbí erinmi tí ó lè pa wọ́n lára; wọ́n sì ní ìmọ́lẹ̀ títí, bóyá ní orí omi tàbí ní ìsàlẹ̀ omi.”18 A ngbé inú ayé nibití àwọn ìgbì abàmì ti ikú, àìsàn àfojúrí àti ti ọpọlọ, àti àwọn àdánwò àti àwọn ìpọ́njú ní onírurú nfa ìdádúró fún wa. Síbẹ̀, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti yíyàn láti gbẹ́kẹ̀lé E, àwa náà le ní ìmọ́lẹ̀ ní gbogbo ìgbà bóyá ní orí omi tàbí ní ìsàlẹ̀ omi. A le ní ìdánilójú pé Ọlọ́run kìí dáwọ́dúró láé láti fẹ́ wa sí ìhà ilẹ̀ ìlérí.
Bí a ti ngbá wọn kiri nínú àwọn ọkọ̀ náà, àwọn ará Járẹ́dì “kọ orin ìyìn sí Olúwa; ... [wọ́n] sì dúpẹ́ wọ́n sì yin Olúwa ní gbogbo ọjọ́; àti nígbati alẹ́ lẹ́, wọn kò dáwọ́ dúró láti yìn Olúwa.”19 Wọ́n ní ìmọ̀lára ayọ̀ àti ìdúpẹ́ àní ní ààrin àwọn ìpọ́njú wọn. Wọn kò tíì dé ilẹ̀ ìlérí síbẹ̀, síbẹ̀ wọ́n nyayọ̀ nínú ìlérí ìbùkún nítorí ti ìgbẹ́kẹ̀lé wọn lemọ́lemọ́ àti àìmikàn nínú Rẹ̀.20
Àwọn ará Járẹ́dì jẹ́ títì síwájú ní orí omi fún ọgọ́rũn mẹ́ta àti ẹ̀rìnlélógójì ọjọ́ (344).21 Njẹ́ ẹ le fi ojú inú wo èyíinì? Nínú gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa ni gbígbẹ́kẹ̀lé àkókò Rẹ̀ wà, ó sì gba sùúrù àti ìpamọ́ra tí ó tayọ àwọn ìjì ìgbé ayé.23
Ní ìgbẹ̀hìn, awọn ará Járẹ́dì “gúnlẹ̀ ní èbúté ilẹ̀ ìlérí náà. Nígbàtí wọ́n sì ti fi ẹsẹ̀ wọn lé èbúté ilẹ̀ ìlérí náà, wọn tẹ̀ orí ara wọn ba ní orí ilẹ̀ náà, wọn sì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa, wọ́n sì sun ẹkún ayọ̀ níwájú Olúwa, nitori ọ̀pọ̀ ìrọ́nú àánú rẹ ní orí wọn.”22
Bí a bá jẹ́ olõtọ́ ní pípa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, àwa ná yío gúnlẹ̀ láìléwu ní ilé lọ́jọ́ kan, a ó sì fí orí balẹ̀ níwájú Olúwa, a ó sì sun ẹkún ayọ̀ fún ọ̀pọ̀ ìrọ́nú àánú Rẹ nínú ayé wa, nínú èyítí àwọn ìbànújẹ́ tí ó nfi àyè gba ayọ̀ púpọ̀ sí wà.23
Mo jẹ́ri pé bí a ti nyàn láti fi pẹ̀lú ìtẹramọ́ àti ìfaradà ní ìgbẹ̀kẹ̀lé nínú Jésù Krístì àti àwọn èrò àtọ̀runwá Rẹ̀ nínú ayé wa, Òun yío bẹ̀ wá wò pẹ̀lú àwọn ìdánilójú, yío sọ ọ̀rọ̀ àlàfíà sí ọkàn wa, yío sì mú kí a “ní ìrètí fún ìtúsílẹ̀ wa nínú rẹ̀.”24
Mo jẹ́ri pé Jésù ni Krístì náà. Òun ni orísun gbogbo ayọ̀.”18 Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tó, Ó sì lágbára láti gbàlà.28 Òun ni ìmọ́lẹ̀, ìyè, àti ìrẹ̀tí ti ayé.25 Òun kò ní jẹ́ kí a ṣègbé.26 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.