Èso
Ẹ pa ojú yín àti ọkàn yí mọ́ lóókan Olùgbàlà Jésù Krístì àti ayọ̀ ayérayé tí ó nwá nípa Rẹ̀ nìkan.
Mo mọ̀ ohun tí ẹ̀ nrò! Ọ̀rọ̀ kan péré ni ókù tí a ó gbọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu Ààrẹ Nelson. Ní ìrètí láti pa yín mọ́ ní ìdiramú fún íṣẹ́jú díẹ̀ bí a ṣe ndúró dé àyànfẹ́ wòlíì wa, mo ti yan àkolé kan tó wuni: ẹ̀kọ́ mi ni èso.
Pẹ̀lú àwọ̀, ìwọ̀n, àti adùn ti bẹ́rì, ọ̀gẹ̀dẹ̀, ẹ̀gúsíolómi, àti mángòrò, tàbí ti èsò tó tayọ bíi kiwano tàbí pòmégránátì, èso ti jẹ́ oúnjẹ aládùn ọlọ́ṣọ́ pípẹ́.
Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ayé Rẹ̀, Olùgbàlà fi èso rere wé àwọn ohun yíyẹ ayérayé. Ó wípé, “A ó mọ̀ wọ´n nípa èso wọn.”1 Gbogbo igi rere nmú èso rere wá.”2 Ó gbà wá lámọ̀ràn láti kó “èso jọ sí ìyè ayérayé.”3
Ní àlá kedere tí a mọ̀ dáadáa nínú Ìwé Mọ́mọ́nì, wòlíì Léhì rí ara rẹ̀ nínú “òkùnkùn àti gùdẹ̀ aginjù.” Omi ìdọ̀tí wa, òkùnkùn biribiri, ọ̀nà àjèjì àti ipa-ọ̀nà èèwọ̀, bákannáà bí ọ̀pá irin4 lẹgbẹ ọ̀nà híhá àti tóóró tó darí lọ síbi igi ẹlẹ́wà tó kún fún “èso [tí ó nmú inú] ẹnì dùn.” Títún àlá náà sọ, Léhì wípé: “Mo ṣe ... Àbápín èso náà; ... ó dùn rékọjá, ju gbogbo ohun tí mo [ti] tọ́ wò ... Rí. ... [Ó sì] kún ọkàn mi pẹ̀lú ayọ̀ nlá.“ Èso yí jẹ́ aládùn “[síi] [ju] gbogbo èso míràn lọ.”4
Ìtumọ̀ Igi náà àti Èso
Kíni ohun tí igi yí pẹ̀lú èso oníyebíye jùlọ fihàn? Ó fi “ìfẹ́ Ọlọ́run” hàn6 ó sì polongo ètò ìràpadà oníyanu ti Bàbá Ọ̀run. “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ràn aráyé, tí Ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ nìkanṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”7
Èso oníyebíye yí fi àwọn ìbùkún oníyanu ti àìláfarawé Olùgbàlà hàn. Kìí ṣe pè a ó gbé lẹ́ẹ̀kansi lẹ́hìn ayé ikú wa nìkan, ṣùgbọ́n nípa ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì, ìrònúpìwàdà wa, àti pípa àwọn òfin mọ́, a lè gba ìdáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì dúró níjọ́ kan ní mímọ́ àti áìlẹ́gbin níwájú Bàbá wa àti Ọmọ Rẹ̀.
Ṣíṣe àbápín èso igi náà bákannáà fihàn pé a gba àwọn ìlànà àti májẹ̀mú mọ́ra—ní ṣíṣe ìrìbomi, gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti wíwọ ilé Olúwa láti gba agbára-ọ̀run pẹ̀lú okun láti òkè. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì àti nípa bubọlá fún àwọn májẹ̀mú wa, a gba ìlérí àìníwọ̀n ti gbígbé pẹ̀lú ẹbí òdodo wa ní gbogbo ayérayé.8
Ìdí nìyí tí ángẹ́lì fi júwe èso náà bíi “ayọ̀ tó rékọjá sí ọkàn.”9 Ó jẹ́ òtítọ́ ni!
Ìpènijà Dídúró ní Òtítọ́
Bí gbogbo wa ti kọ́, àní lẹ́hìn gbígbádùn èso aládùn ti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere, dídúró lotitọ àti òdodo kò tíì rọrùn láti ṣe. Bí a ti sọ lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà nínú ìpàdé àpapọ̀, a ntẹ̀síwájú láti dojúkọ idaniláàmú, ìtànjẹ́, ìdàrú, rúkèrúdò, ìfanimọ́ra àti ìdánwò tí ó ndánwa wò láti fa ọkàn wa kúrò lọ́dọ̀ Olùgbàlà àti ayọ̀ àti ẹ̀wà tí a ti ní ìrírí rẹ̀ ní títẹ̀lé E.
Nítorí ìpọ́njú yí, àlá Léhì bákannáà pẹ̀lú ìkìlọ̀ kan! Ní ẹ̀gbẹ́ odò míràn ni ilé nlá kan pẹ̀lú àwọn ènìyàn ọjọ́ orí gbogbo tí wọ́n nnawọ́, ìṣẹ̀sín, àti ẹlẹ́yà wọn sí àwọn olódodo àtẹ̀lé Jésù Krístì.
Àwọn ènìyàn nínú ilé náà ntàbùkù wọ́n nrẹrin sí àwọn wọnnì, ní ìrètí láti tàbùkú àti yọṣùtì ìgbàgbọ́ wọn nínú Jésù Krístì àti ìhìhrere Rẹ̀. Nítorí ọ̀rọ̀ olóró ti ìyèméjì àti ìríra tí a gbé lé àwọn onígbàgbọ́, díẹ̀ lára àwọn wọnnì tí wọ́n ti tọ́ èso náà wò bẹ̀rẹ̀ sí ntijú ìhìnrere tí wọ́n ti gbà. Àwọn irọ́ ìfani ayé tó nfàwọ́n mọ́ra; wọ́n yí kúrò níbi igi àti èso; àti, nínú ọ̀rọ̀ Olúwa wọ́n, “[ṣubú] lọ sínú ipa-ọ̀nà èèwọ̀ [wọn] sọnù.”9
Ní ọjọ́ wa loni, ọ̀tá ti gba àwọn amòye òṣìṣẹ́ olùkọ́lé tí wọ́n nṣiṣẹ́ kọjá àlà, tí wọ́n nfi tipátipá kún ilé nlá àti títóbi. Ìgbòòrò náà ti nà kiri odò, ní ìrètí láti gba ilé wa kan, nígbàtí àwọn olùnawọ́ àti ẹlẹ́ẹ̀sín ndún ní gbogbo ọjọ́ àti òru lórí gbohùngbohùn ayélujára wọn.10
Ààrẹ Nelson ṣàlàyé, “Ọ̀tá nṣe ìlọ́po-mẹ́rin àwọn ìtiraka rẹ̀ láti da àwọn ẹ̀rí wa rú kí ó sì dènà iṣẹ́ Olúwa.”12 Ẹ jẹ́ kí a rántí àwọn ọ̀rọ̀ Léhì: “A kò kíyèsí wọn.”12
Bí ó tilẹ̀jẹ́pé a kò níláti bẹ̀rù, a gbọ́dọ̀ fojú sílẹ̀. Ìgbàmíràn àwọn ohun kékeré lè dojú ìbámu ti ẹ̀mí wa délẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́ a máṣe fàyè gba àwọn ìbèèrè yín, àbùkù àwọn ẹlòmíràn, àwọn ọ̀rẹ́ aláìnígbàgbọ́, tàbí àwọn àṣìṣe àìlóríre àti ìjákulẹ̀ láti yí yín kúrò nínú adùn, àìléèrí, àti àwọn ìbùkún ìtẹ́nilọ́rùn-ẹ̀mí. Ẹ pa ojú yín àti ọkàn yí mọ́ lóókan Olùgbàlà Jésù Krístì àti ayọ̀ ayérayé tí ó nwá nípa Rẹ̀ nìkan.
Ìgbàgbọ́ Jason Hall,
Ní Oṣù Kẹfà ìyàwó mi, Kathy, àti èmi lọ sí ìsìnkú Jason Hall. Ní ìgbà ikú rẹ̀, ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlọ́ta ó sì nsìn bí ààrẹ̀ iyejú àwọn alàgbà.
Nihin ni àwọn ọ̀rọ̀ Jason nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó yí ìgbé ayé rẹ̀:
“[Ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún] mo [wà] nínú ìjàmbá fífò kan. … Mo [kán] ọrùn mi mo sì di arọ láti àyà sílẹ̀. Mo pàdánù lílo ẹsẹ̀ mi pàtàpàtà àti lílo apá mi. Èmi kò lè rìn mọ́, dúró, ... Tàbí bọ́ ara mi. Mo fẹ́rẹ̀ má lè mí tàbí sọ̀rọ̀.”13
“‘Bàbá ọ̀wọ́n [ní Ọ̀run],’ mo bẹ̀bẹ̀, ‘tí mo bá kàn lè ní ọwọ́ mi, mo mọ̀ pé mo máa yege. Ẹ jọ̀wọ́, Bàbá, ẹ jọ̀wọ́. ...
“ ... ‘Pa ẹsẹ̀ mi mọ́, Bàbá; mo kan [gbàdúrà fún] ìlò ọwọ́ mi ni.’”14
Jáson kò gba lílò àwọn ọwọ́ rẹ rárá. Njẹ́ ẹ̀ ngbọ́ àwọn ohùn látinú ilé nla? “Jason Hall, Ọlọ́run kò gbọ́ àwọn àdúrà rẹ. Tí Ọlọ́run bá jẹ́ Ọlọ́run olùfẹ́ni, báwo ni Ó ṣe lè fi ọ́ sílẹ̀ báyìí? Kínìdí tí a fi nní ìgbàgbọ́ nínú Krístì?” Jason Hall gbọ́ àwọn ohùn wọn, ṣùgbọ́n kò kíyèsi wọn. Dípò bẹ́ẹ̀ ó ṣàpèjẹ lórí èso igi náà. Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ nínú Jésù Krístì di àìyẹsẹ. Ó jáde ní unifásitì ó gbé Kolette Coleman níyàwó ní tẹ́mpìlì, ó júwe rẹ̀ bí ìfẹ́ ayé rẹ̀.”15 Lẹ́hìn ìgbeyàwó ọdún mẹrìndínlógún, ìyanu míràn, ọmọkùnrin oníyebíye, Coleman, ni a bí.
Báwo ni ìgbàgbọ́ wọn ṣe dàgbà? Kolette ṣàlàyé: “A ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú èto Ọlọ́run. Ó sì fún wa ní ìrètí. A mọ̀ pé Jason yíò gba ìwòsàn [àti pé ní ọjọ́ ọ̀la] ... di aláralíle. ... A mọ̀ pé Ọlọ́run pèsè Olùgbàlà kan fún wa, ẹnití ìrúbọ̀ ètùtù rẹ̀ fún wa lókun láti tẹramọ́ títẹ̀síwájú nígbàtí a bá fẹ́ ṣíwọ́.”16
Ní sísọ̀rọ̀ níbi ìsìnkú Jason, ọmọ ọdún mẹwa Coleman wípé bàbá òun kọ́ òun pé: “Bàbá Ọ̀run [ní] ètò kan fún wa, ìgbè ayé yíò lárinrin, à ti pé a lè gbé nínú ẹbí. ... Ṣugbọ̀n ... A ó níláti lọ nínú àwọn ohun líle àti pé a ó ṣe àṣiṣe.”
Coleman tẹ̀síwájú: “Bàbá Ọ̀run rán Ọmọ Rẹ̀, Jésù, wá sayé. Iṣẹ́ Rẹ̀ ni láti jẹ́ pípé. Láti wo àwọn ènìyàn sàn. Láti ní ìfẹ́ wọn. Lẹ́hìnnáà láti jìyà fún gbogbo ìrora wa, ìkorò, àti ẹ̀ṣẹ. Lẹ́hìnnáà Ó kú fún wa.” Nígbànáà Coleman fikun pé, “Nítorínáà Ó ṣe èyí, Jésù mọ bí mo ṣe ní ìmọ̀ara báyìí.”
“Ọjọ́ kẹta lẹ́hìn tí Jésù kú, O ... Wà láàyè lẹ́ẹ̀kansi pẹ̀lú ara pípé. Èyí ṣe pàtàkì sí mi nítorí mo mọ̀ pé ... ara [bàbá] yíò di pípé a ó sì wà papọ̀ bí ẹbí.
Coleman parì pé: “Alaalẹ́ látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ-ọwọ́, bàbá mi nwí fún mi pé, ‘Bàbá fẹ́ràn rẹ, Bàbá Ọ̀run fẹ́ràn rẹ̀, ìwọ sì jẹ́ ọmọdékùnrin rere.’”17
Ayọ̀ Nwá Nítorí Jésù Krístì
Ààrẹ Russell M. Nelson ṣàpèjúwe ìdí tí ẹbí Hall fi ní ayọ̀ àti ìrètí. Ó sọpé:
“Ayọ̀ tí à nní ìmọ̀ rẹ̀ ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbé ayé wa àti ohungbogbo íṣe pẹ̀lú ìdojúkọ àwọn ìgbé ayé wa.
“Nígbàtí ìdojúkọ ti ìgbé ayé wa bá wà lórí ètò ìgbàlà Ọlọ́run, ... àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ayọ̀ láìkà ohun tó nṣẹlẹ̀ sí—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbé ayé wa. Ayọ̀ nwá látọ̀dọ̀ àti nítorí Rẹ̀. Òun ni orísun gbogbo ayọ̀.”18
“Tí a bá nwo ayé ... , a kò ní ní ayọ̀ láéláé. ... [Ayọ̀] jẹ́ ẹ̀bùn tí ó nwá láti mímọ̀ọ́mọ̀ gbìyànjú láti gbé ìgbé ayé òdodo, bí a ṣe kọ́ nípasẹ̀ Jésù Krístì.”18
Ìlérí kan bí Ẹ Ṣe Padà
Tí ẹ bá ti wà láìsí èso igi náà fún ìgbà díẹ̀, ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé apá Olùgbàlà nà síi yín nígbàgbogbo. Ó nfi ìfẹ́ nawọ́, “Ẹ ronúpìwàdà kí ẹ wa sọ́dọ̀ mi.”19 Èso Rẹ̀ pọ lọ́pọ̀lọpọ̀ ó sì nwá sí àkokò nígbàgbogbo. A kò lè ràá pẹ̀lú owó, kò sì sí ẹnìkẹ́ni tó fìfẹ́ wa lódodo tí a sẹ́.20
Fún ẹnìkẹ́ni tí ó fẹ́ láti padà síbi igi náà àti láti tọ́ èso wò lẹ́ẹ̀kansi, ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa gbígbàdúrà sí Bàbá yín Ọ̀run. Ẹ gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti agbára irúbọ ètùtù Rẹ̀. Mo ṣèlérí fún yín pé bí ẹ ṣe nwo Olùgbàlà “ní gbogbo èrò,”21 èso igi náà yíò jẹ́ tiyín lẹ́ẹ̀kansi, rékọjá ohun tí mo ti ẹ ti tọ́wò, fi ayọ̀ nlá sí ọkàn yín, “ẹ̀bùn títóbi ju gbogbo ẹbùn Ọlọ́run lọ.”22
Ọ̀sẹ̀ mẹta sẹ́hìn loni, mo rí ayọ̀ èso Olùgbàlà ní ìgbékalẹ̀ kíkún bí Katty àti èmi ṣe lọ ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Lisbon Portugal. Àwọn òtítọ́ ìmúpadabọ̀sípò ìhìnrere ṣí Portugal nì 1975 bí òmìnira ẹ̀sìn ṣe dé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọni Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ tọ́wò lára èsò náà nígbàtí kò sí gbogbo ìjọ, tí kò sí ilé ìjọsìn, tí kò sì sí tẹ́mpìlì tó súnmọ́ tó ẹgbẹ̀rún máìlì yayọ̀ pẹ̀lú wa pé èso aládùn igi náà ni a ó rí báyìí lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilé Olúwa ní Lisbon, Portugal. Bí mo ṣe bu ọlá àti ọ̀wọ́ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn wọ̀nyí tí wọ́n ti pa ọkàn wọn mọ́ ní líle lórí Olùgbàlà.
Olùgbàlà wípé, “Ẹni tí ó bá bá mi gbé, àti èmi nínú rẹ, ọ̀kannáà mú ọ̀pọ̀ èso wá: nítorí láìsí èmi ẹ kò lè ṣe ohunkankan.”23
Ní sísọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Ìjọ káàkiri ayé ní àárọ̀ yí, Ààrẹ Nelson wípé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, ẹ̀ ngbé ìgbé ayé alápẹrẹ ti èso tí ó nwá ní titẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì.” Lẹ́hìnnáà ó fikun pe, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ! Mo nifẹ rẹ!”24
A ní ìfẹ́ rẹ̀, Ààrẹ Nelson.
Mo jẹ́ ẹlẹri sí agbára ìfihàn tí ó bà lé Ààrẹ wa ọ̀wọ́n. Òun ni wòlíì Ọlọ́run. Bíiti Léhì àtijọ́, Ààrẹ Russell M. Nelson npè wá àti gbogbo ẹbí Ọlọ́run láti wá ṣe àbápín èso igi náà. Njẹ́ kí a ní ìrẹ̀lẹ̀ àti okun láti tẹ̀lé àmọ̀ran rẹ̀.
Mo fìrẹ̀lẹ̀ jẹri pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run. Ìfẹ́ rẹ, agbára Rẹ̀, àti oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ nmú ohun gbogbo jẹ́ yíyẹ nígbẹ̀hìn. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.