2010–2019
Mímọ̀, Níní Ìfẹ́, àti Dídàgbà
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Mímọ̀, Níní Ìfẹ́, àti Dídàgbà

Njẹ́ kí gbogbo wa lóye ipá wa nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nlá yí kí a lè dàbíi Tirẹ̀.

Ní 2016 àwọn Akọrin Àgọ́ ní Gbàgede Tẹ́mpìlì wá bẹ Netherlands àti Belgium. Látìgbà tí mo ti kópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá náà, mo ní ànfàní láti gbádùn orin wọn ní ẹ̀ẹ̀mejì.

Ìṣeré Gọ́ngì

Bí wọ́n ti nkọrin wọn mo nronú nípa bí ó ti jẹ́ ojúṣe nlá tó láti gbé ẹgbẹ́ akọrin tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yíká. Iyè mi lọ sí ibi gọ́ngì títóbi, tí ó ṣòro àti bóyá kí ó gba ìnáwó gidi láti gbé kiri, ní àfiwé pẹ̀lú faolínì, fèrè, tàbí àwọn ohun èlò míràn tí ẹ lè gbé pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní abẹ́ apá yín. Ṣùgbọ́n ní wíwo ìkópa gọ́ngì yí gan, a lù ú fún àwọn ìgbà díẹ̀ péré, ṣùgbọ́n àwọn ohùn èlò kékèké míràn kópa fún ìgbà púpọ̀ nínú orin kíkọ náà. Mo ronú pé láìsí ìró gọ́ngì, orin kíkọ náà kò le rí bákannáà, àti pé nítorínáà aápọn náà níláti jẹ́ síṣe láti gbé gọ́ngì nlá náà la gbogbo ọ̀nà kọjá sí òdìkejì òkun.

Ìṣeré gọ́ngì pẹ̀lú ọ̀ṣẹ́strà

Nígbàmíràn a le rò pé a jẹ́, bíi gọ́ngì nnì, tó kàn wúlò tó láti ṣe ojúṣe ara kékeré nìkan nínú ohun síṣe kan. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́kí nsọ fún yín pé ìró yín nmú ìyàtọ̀ gbogbo wá.

A nílò gbogbo àwọn ohun èlò. Díẹ̀ nínú wa máa nkọ́ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn wọ́n sì nṣe dáadáa ní ilé ìwé, nígbàtí àwọn míràn ní ẹ̀bùn iṣẹ́ ọwọ́. Àwọn kan nya àwòrán àti ṣe àwọn nkan, tàbí tọ́jú, dáàbò bò, tàbí kọ́ àwọn ẹ̀lòmíràn. Gbogbo wa ni a nílò láti mú àwọ̀ àti ìtumọ̀ wá sí ayé yìí.

Sí àwọn wọnnì tí wọ́n ní èrò pé àwọn kò ní ohunkóhun láti fifúnni tàbí tí wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn kò jẹ́ pàtàkí tàbí já mọ́ nkankan sí ẹnikẹ́ni, sí àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n le rò pé àwọn wà ní òkèlókè ayé, àti ẹnikẹ́ni ní ààrin méjì, mo fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ yí.

Níbikíbi tí ẹ bá wà ní ipa ọ̀nà ìgbé ayé, nínú yín le ní ẹrù wíwúwo jù tí ẹ kò tilẹ̀ rò nípa ara yín pé ẹ wà ní ipa ọ̀nà náà. Mo fẹ́ pè yín láti jáde kúrò nínú òkùnkùn sí inú ìmọ́lẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere tí yío pèsè ìmóoru àti ìwòsàn, àti tí yío ràn yín lọ́wọ́ láti ní òye ẹ̀nití ẹ jẹ́ gan, àti ohun tí èrèdí yín nínú ayé í ṣe.

Díẹ̀ nínú wa ti nrìn kiri ní àwọn ipa ọ̀nà èèwọ̀ láti gbìyànjú wá ìdùnnú níbẹ̀.

A pè wá láti ọwọ́ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run láti rìn ní ipa ọ̀nà jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn àti láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó fẹ́ràn wa pẹ̀lú ìfẹ́ pípé.1

Kíni ọ̀nà náà? Ọ̀nà náà ni láti ran ara wa lọ́wọ́ ní òye ẹnití a jẹ́ nípa síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wa.

Sí mi, síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ lílo ìfẹ́ pátápátá.2 Ní ọ̀nà náà a nṣe ndá àyíká níbití afúnni àti ẹnití ó ngbà ti nní ifẹ́ inú láti ronúpìwàdà sílẹ̀. Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, a nyí ìdarí padà a sì nwá súnmọ́, a sì ndàbí, Olùgbàlà wa Jésù Krístì síi.

Fún àpẹrẹ, a kò nílò láti máa sọ lemọ́lemọ́ fún ẹnìkejì wa tàbí àwọn ọmọ ní gbogbo ìgbà ibití wọ́n ti le dára síi; wọ́n ti mọ èyí tẹ́lẹ̀. Nínú síṣẹ̀dá àyíka ìfẹ́ yìí, ni wọ́n ti le di ríró ní agbára láti ṣe àwọn àyípadà tí ó jẹ́ dandan ní ìgbé ayé wọn, kí wọn ó sì di ènìyàn dídára síi.

Ní ọ̀nà yí, ìrònúpìwàdà á di ìlànà àtúnṣe ojojúmọ́, nínú èyítí bíbẹ̀bẹ̀ fún ìwà àìdára tó le wà. Mo rántí mo ṣì nní ìrírí àwọn ipò níbití mo ti yára jù láti dájọ́, tàbí lọ́ra jù láti fi etí sílẹ̀. Àti pé ní òpin ọjọ́, ní ìgbà àdúrà ti ara ẹni mi, mo ní ìmọ̀lára ìmọ̀ràn ìfẹ́ni láti ọ̀run láti ronúpìwàdà kí nsì di dídára síi. Àyíká ìfẹ́ni tí a ti gbé kalẹ̀ nípasẹ̀ àwọn òbí, arákùnrin, àti àwọn arábìnrin mi àti lẹ́hìnwá nípasẹ̀ ìyàwó, àwọn ọmọ, àti bákannáà àwọn ọ̀rẹ́ mi ti ràn mí lọ́wọ́ láti di ẹni dídára síi.

Gbogbo wa ni a mọ ibití a ti lè dára síi. A kò nílò láti máa rán ara wa létí léraléra, ṣùgbọ́n a nílò láti ní ìfẹ́ kí a sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wa, àti ní síṣe bẹ́ẹ̀ kí a pèsè ojú ọjọ́ ti síṣetán láti yípadà.

Ní àyíká yìí kannáà a nkọ́ nípa ẹnití a jẹ́ gan àti ohun tí ojúṣe wa yío jẹ́ nínú àkòrí tí ó gbẹ̀hìn yìí nínú ìtàn ayé, ṣaájú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olùgbàlà.

Bí o bá nronú nípa ipa rẹ, èmi fẹ́ pè ọ́ láti wá ààyè kan níbití o ti le nìkan wà kí o sì béèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run láti sọ ipa tí iwọ yío kó di mímọ̀ fún ọ. Bóyá ìdáhùn yío wá díẹ̀díẹ̀ àti lẹ́hìnnáà ní kedere nígbàtí a bá ti fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ ṣinṣin síi ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú àti síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.

A nní ìrírí díẹ̀ nínú àwọn ìṣòro kannáà tí Joseph Smith dojúkọ nígbàtí ó wà “ní ààrin ogun àwọn ọ̀rọ̀ [kan] àti ìrúkèrúdò àwọn èró inú. Bí a ṣe kà nínú ìtàn ti ara rẹ̀, ó fi ìgbà púpọ̀ sọ fún ara rẹ̀ pé: Kíni a níláti ṣe? Taani nínú àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí ni ó tọ̀nà; tàbí, njẹ́ gbogbo wọn ni kò tọ̀nà lápapọ̀? Tí èyíkéyìí nínú wọn bá tọ́, èwo ni, àti pé báwo ni èmi yíò ṣe mọ̀ ọ́?”3

Pẹ̀lú ìmọ̀ tí ó rí nínú Èpístélì ti Jámésì, èyítí ó sọ pé “bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni nínú yín, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹnití nfi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kìí sì bá-ni-wí; a ó sì fi fún un,”4 Jósẹ́fù “wá sí ìpinnu láti ‘béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.’”5

A kà síwájú síi pé “ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ ní ayé [rẹ̀] tí [òun] gba irú ìyànjú bẹ́ẹ̀, nítorí ní ààrin gbogbo àwọn àníyàn [rẹ̀] síbẹ̀ [òun] kò tíì gbìdánwò rí láti gbàdúrà ní ohùn òkè.”6

Àti nítorínáà ó le jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ gan fún wa tí a nbá Ẹlẹ́dàá wa sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí a kò tíì ṣe rí ṣaájú.

Nítorí ìyànjú Jósẹ́fù, Baba Ọrun àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, fi ara hàn sí i, ní pípè é ní orúkọ, àti bíi àyọrísí a ní òye kedere síi nípa ẹnití a jẹ́ àti pé a já mọ́ nkan nítòótọ́.

A kà síwájú síi pé ní àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀, a ṣe inúnibíni sí Joseph láti ọwọ́ àwọn wọnnì tí ó yẹ kí wọn ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti tí ó yẹ kí wọn ó tọjú [rẹ̀] pẹ̀lú inúrere.”7 Àti nítorínáà a lè retí àtakò díẹ̀ bí a ṣe ngbé ìgbé ayé jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn.

Bí o bá nní ìmọ̀lára lọ́wọ́lọ́wọ́ pé o kò le jẹ́ ara ẹgbẹ́ ọ̀kẹ́sírà náà, àti tí ipa ọ̀nà ìrònúpìwàdà dàbí pé ó ṣòro fún ọ, jọ̀wọ́ mọ̀ pé bí a bá tẹ̀síwájú nínú rẹ̀, ẹrù náà yío di gbígbé kúrò ní èjìká wa, ìmọ́lẹ̀ yío sì wà lẹ́ẹ̀kansíi. Baba Ọrun kì yío fi wá sílẹ̀ láé nígbàtí a bá nawọ́ sí I. A lè ṣubú kí a tún dìde, Òun yío sì ràn wá lọ́wọ́ gbọn ìdọ̀tí nù kúrò ní àwọn orúnkún wa.

Nínú wa ti ní ọgbẹ́, ṣùgbọ́n àwọn èròjà ìtọ́jú àkọ́kọ́ ti Olúwa ní àwọn bándéjì nínú, tí ó tóbi tó láti bo gbogbo àwọn ọgbẹ́ wa.

Nítorínáà ìfẹ́ náà ni, ìfẹ́ pátápátá náà tí a tún npè ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ “tàbí ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Krístì,”6 èyítí a nílò nínú àwọn ibùgbé wa, níbití àwọn òbí ti nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ sí àwọn òbí wọn. A ó yí àwọn ọkàn padà, a ó sì ní ìfẹ́-inú láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.

Ìfẹ́ náà ni a nílò nínú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú ara wa, bíi ọmọ Bàbá wa Ọrun àti ọmọ Ìjọ Rẹ̀ tí yío ró wa ní agbára láti kó gbogbo àwọn ohun èlò orin sínú ọ̀kẹ́sírà wa, kí ó le ṣeéṣe fún wa láti kọrin nínú ògo pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ akọrin ángẹ́lì ti ọ̀run nígbàtí Olùgbàlà bá padà wá.

Ìfẹ́ náà ni, ìmọ́lẹ̀ náà tí yío tàn tí yío sì fi òye sí àyíka wa bí a ti nlọ nínú ìgbé ayé wa ojojúmọ́. Àwọn ènìyàn yío fura sí ìmọ́lẹ̀ náà wọn yío sì fà sí i. Ìyẹn ni irú iṣẹ́ i`hìnrere tí yíò mú àwọn ẹlòmíràn súnmọ́ “ati láti wá wo, wá láti ṣèrànwọ́, àti wá láti dúró.9 Jọ̀wọ́, nígbàtí ẹ bá gba ẹ̀rí yín nípa iṣẹ́ nlá yí àti i`pín wa nínú rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ papọ̀ pẹ̀lú àyànfẹ́ wa Wòlíì Joseph Smith, ẹnití ó kéde, “Nítorí mo ti rí i`ran; mo mọ̀ ọ́, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ọ́, èmi kò sì lè sẹ́ẹ.”10.

Mo jẹrìí sí yín pé mo mọ ẹnití èmi í ṣe, mo sì mọ ẹnití ẹ̀yin í ṣe. Gbogbo wa jẹ́ ọmọ Bàbá Ọrun kan ẹnití ó fẹ́ràn w. Òun kò sì rán wa sí ìhín yi láti kùnà ṣùgbọ́n láti padà pẹ̀lú ògo sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Pé kí a le wá ní ìmọ̀ ìpín wa nínú iṣẹ́ nlá ti síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí kí a le dàbí Rẹ̀ síi nígbàtí ó bá padà wá lẹ́ẹ̀kansi ni àdúrà mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.