Fífún Ẹ̀mí Wa Lágbára lórí Ara Wa
Ó hàn kedere sí mi pé àwọn ohunkan pàtàkì tí a lè kọ́ nínú ayé yí ni bí a ṣe lè tẹnumọ́ ìwàẹ̀dá ayérayé ti ẹ̀mí àti láti kojú àwọn ìfẹ́ ìbi wa.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, bí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ṣe mbọ̀ lọ́dún tó kọjá, mo múra ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ mi sílẹ̀ láti fi ayẹyẹ-ọlọ́dọọdún ọgọ́ọ̀rún ọdún ti ìran ẹ̀mí tí Ààrẹ Joseph F. Smith ní Ọjọ́ Kẹta Oṣù Kẹwa, 1918.
Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìn tí mo fi ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀ fún àyípada, ojúgbà ayérayé mi, Barbara, pari ìdánwò ayé ikù rẹ̀ ó sì kọjá lọ sí ayé ẹ̀mí.
Bí àwọn ọjọ́ ṣe yípadà sí ọ̀sẹ̀, lẹ́hìnnáà oṣù, àti báyìí ọdún kan látigbà tí Barbara ti kú, mo rí arami ní ìmoore ìwé mímọ́ yí ní kíkún jùlọ: “Ẹ̀yin ó gbé papọ̀ nínú ìfẹ́, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó sọkún fún àdánù àwọn tó kú.”1 Bárbara àti èmi ní ìbùkún láti “gbé papọ ní ìfẹ́” fún ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rín Ṣùgbọ́n mo ti kọ́ ní ọ̀nà araẹni gidi pé ó túmọ̀ sí pé “kí a sọkún fún àdánù” àwọn wọnnì tí a fẹ́ran. Óò, bí mo ṣe nifẹ tí mo sì dáró!
Mo rò pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa kùnà láti fí moore hàn sí ohun tí àwọn míràn ṣe fún wa títí tí wọ́n fi kú. Mo mọ̀ pé Barbara máa nṣiṣẹ́ nígbàgbogbo, ṣùgbọ́n èmi kò ní ìmọ̀ ohun tí ẹbí, Ìjọ, àti ìletò ngbà ní àkokò rẹ̀. Àwọn àtúnṣe ìlàkàkà ìyàsímímọ́ ojoojúmọ́ ní ọgọ́rún àkokò nínú ọdún tí ó npa ẹbí wa mọ́ nínú ìṣe. Àti pé nínú gbogbo rẹ̀, kò sí ẹnìkankan nínú ẹbí wa tí ó gbọ́ kí òun gbé ohùn rẹ̀ sókè tàbí sọ ọ̀rọ̀ kan tí kò dára.
Àwọn ìṣàn ìrántí ti wẹ mí ní ọdún tó kọjá yí. Mo ronú nípa gbígba àṣàyàn araẹni líle tí ó ṣe láti jẹ́ ìyá sí àwọn ọmọ méje. Jíjẹ́ olùtọ́jú-ilé kan ni iṣẹ́ kanṣoṣo tí ó fẹ́ láti ṣe, àti pé ní gbogbo èrò ó jẹ́ aláṣepé amòye.
Nígbàkugbà, ó máa nyàmí lẹnu bí ó ṣe ntọ́jú àwọn ọmọ wa àti èmi. Óunjẹ́ ṣíṣe nìkan jẹ́ iṣẹ́ líle, kí a tó sọ àwọn irú ìṣe bí fífọ aṣọ gègèrè tí ẹbí lo ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, pípa àwọn bàtà mọ́ àti fífi aṣọ wọn àwọn ọmọ. Gbogbo wa nyípadà si i ní àìmoye àwọn ohun míràn tó ṣe pàtàkì sí wa. Àti pé nítorí wọ́n ṣe pàtàkì sí wa, wọ́n ṣe pàtàkì si. Ní ọ̀rọ̀ kan, ó jẹ́, ọlọ́lá—bí ìyàwó kan, bí ìyá kan, bí ọ̀rẹ́ kan, bí alábágbé kan, àti bí ọmọbìnrin Ọlọ́run kan.
Báyìí tí ó ti tẹ̀síwájú, inú mi dùn pé mo yàn láti joko tì í nígbàtí mo wálé ní àwọn oṣù tó kọjá nínú ayé rẹ̀, lati di ọwọ́ rẹ̀ mú bí a ṣe nwo àwọn ìparí orin alárinrin—lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansi nítorí Alzheimer kò ní fàyè gbàá láti rántí pé óun ti rí wọn kété ní ọ̀sán tó ṣíwájú. Àwọn ìrántí ti abala ìdì-lọ́wọ́mú wọnnì báyìí jẹ́, iyebìye sími gan an.
Ẹ̀yin arábìnrin àti arábìnrin, ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe pàdánù ànfàní kan láti wo ojú ọmọ ẹbí yín pẹ̀lú ifẹ́. Àwọn ọmọ àti òbí, nawọ́ jáde sí ara wọn àti fífi ìfẹ́ hàn àti ìmoore. Bíiti èmi, díẹ̀ lára yín lè jí dìde níjọ kan láti wákiri pé àkokò fún irú ibánisọ̀rọ̀ pàtàkì bẹ́ẹ̀ ti kọjá. Ẹ gbé ìgbé ayé ojoojúmọ́ papọ̀ pẹ̀lú ọkàn tó kún fún ìmoore, àwọn ìrántí rere, iṣẹ́ ìsìn, àti ìfẹ́ púpọ̀.
Nínú ọdún tó kọjá, mo jíròrò tinútinú si ju bí mo ti ṣe rí nípa ètò Bàbá wa Ọ̀run. Ní kíkọ́ ọmọ rẹ̀ Kọ́ríátúmù, Álmà tọ́ka si bí “ètò ìdùnnú nlá.”2
Ọ̀rọ̀ náà nwá sími lọ́kán báyìí nígbàtí mò ngbèrò ètò náà ni “ìtúnrarí.” Ó jẹ́ ètò kan, tí a ṣe nípasẹ̀ olùfẹ́ni Bàbá ní Ọ̀run, tí ó ní ìṣeéṣe ìtúnrarí ẹbí títóbi àti ológo ní oókan rẹ̀—ìtúnrarí ayérayé àwọn ọkọ àti aya, àwọn òbí àti àwọn ọmọ, ìran lórí ìran nínú agbo ilé Ọlọ́run.
Èrò náà nmú mi nítùnú àti ìdánilójú pé èmi ó wà pẹ̀lú Barbara lẹ́ẹ̀kansi. Bíótilẹ̀jẹ́pé ara rẹ̀ àti inú ti jìyà ní ìparí ayé rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀ le, akọni, àti mímọ́. Ó ti múra ararẹ̀ sílẹ̀ nínú ohun gbogbo nítorí ìgbatí ọjọ́ náà yíò dé tí yíò lè dúró níwájú “ìtẹ́ Ọlọ́run dídárá,”3 nínú ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìdánilójú àláfíà. Ṣùgbọ́n nihin ni mo wà, ní ọjọ́ méjì, mo pé ọdún mọ́kànléláàdọ́rún, mo ṣì níyanu, “Ṣé mo ṣetán? Mò nṣe ohun gbogbo tí mo nílò láti ṣe láti lè di ọwọ́ rẹ̀ mú lẹ́ẹ̀kansi.
Ohun jẹ́jẹ́ jùlọ, kókó ìdánilójú ayé ni èyí: gbogbo wa la máa kú. Bóyá a kú lágbà tàbí lọ́mọdé, ìrọ̀rùn tàbí hard, olówó tàbí aláìní, àyànfẹ́ tàbí àdáwà, kò sí ẹni tí yíò fo ikú.
Ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, Ààrẹ Gordon B. Hinckley sọ ohunkan tí ó jẹ́ pàtàkì àti onítumọ̀ nípa èyí: “Bí ìdánilójú náà ti dùn tó, bí ìtuninínú ni àláfíà tí ó nwá látinú ìmọ̀ pé tí a bá gbéyàwó ní títọ́ tí a sì gbé ní títọ́, ìbáṣepọ̀ wa yíò tẹ̀síwájú, bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ ìdánilójú ikú àti ìkọjá àkokò.”4
Dájúdájú mo gbéyàwó ní títọ́ Nípa ìyẹn kò lè sí ìyèméjì. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò tó, gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Hinckley ti sọ. Mo sì ní láti gbé ní títọ́.5
Loni, “gbígbé ní títọ́” lè jẹ́ ìgbìrò ìdanilámú dáadáá, nípàtàkì tí ẹ bá lo ọ̀pọ̀ àkokò lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn, níbití ohùn kankan lè kéde àwọn òtítọ́ òdodo tàbí ìgbìrò irọ́ nípa Ọlọ́run àti ètò Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Tọ́pẹ́tọpẹ́, àwa ọmọ Ìjọ ní àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ìhìnrere ayérayé láti mọ̀ bí aó ti gbé kí a lè di dídára si láti múrasílẹ̀ dìgbà tí a gbọ́dọ̀ kú.
Ní oṣù díẹ̀ ṣíwájú ìbí mi, Bàbá mi Àpọ́stélì, Alàgbà Melvin J. Ballard, sọ ọ̀rọ̀ kan pé, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn, láti gba àkojá ohun tí ó túmọ̀sí láti gbé ní títọ́. Àkọlé “Ìtiraka fún Ẹ̀mí,” ọ̀rọ̀ rẹ̀ dojúkọ ìjàkadì tó nlọ lọ́wọ́ ní àárín ẹran ara wa àti ẹmí ayérayé wa.
Ó wípé, “Ìja títóbi jùlọ tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin yíò ní láyé rí ... Yíò jẹ́ ogun tí a ní pẹ̀lú ara wa,” ṣíṣe àlàyé pé Sátáni (ọ̀tá ti ẹmí wa) ntakò wá nípa “ìfẹkufẹ, ìpebi, ọ̀kánjúwà ti ara.”6 Nítorínáà kókó ogun ní àárín ọ̀run wa àti ìwàẹ̀dá ti ẹ̀mí àti ọkùnrin ẹlẹ́ran ara.” Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ rántí pé, a lè gba ìrànlọ́wọ́ ti ẹ̀mí nípa agbára ti Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó lè “kọ́ wa ní ohun gbogbo.”7 Bákannáà ìrànlọ́wọ́ lè wá nípa agbára àti àwọn ìbùkún oyèàlùfáà.
Báyìí, mo bèèrè, báwo ni ogun yí ṣe nlọ pẹ̀lú yín?
Ààrẹ David O. McKay wípé: “Wíwà láyé ènìyàn kàn jẹ́ ìdánwò kan sí bóyá òun ó tẹramọ́ ìlàkàkà rẹ̀, inú rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, lórí àwọn ohun èyí tí ó dá sí ìtùnú àti ìsannilóore ti ìwàẹ̀dá ara rẹ̀, tàbí bóyá òun yíò ṣe bí èrò ayé rẹ̀ ti gba àwọn ìwà ti ẹ̀mí”7
Ogun yí ní àárín ẹran ara wa àti ìwàẹ̀dá ti ẹ̀mí ko jẹ́ ohun titun. Nínú ìwàásù ìparí rẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀, Ọba Benjamin kọ́ni pé, “Ènìyàn ẹlẹ́ran ara jẹ́ sí ọ̀tá sí Ọlọ́run, ó sì ti wà bẹ́ẹ̀ láti ìgbà ìṣubú Ádámù, yíò si wà bẹ́ẹ̀, títí láéláé, bíkòṣepé ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ònfà ẹ̀mí mímọ́, tí ó sì gbé ìwà ti ara sílẹ̀ kí ó sì da ẹni mímọ́ kan nípasẹ̀ ètùtù Krístì Olúwa .”8
Àpọ́stélì Paul kọ́ni pé “Àwọn tó bá wà nípa ara nlépa ohun ara; ṣùgbọ́n àwọn tó wà nípa ẹ̀mí nlépa ẹ̀mí.
“Nítorí láti jẹ́ ti ara ni ikú; ṣùgbọ́n láti jẹ́ ti ẹ̀mí ni ìyè àti àláfíà.”10
Ó hàn kedere sí mi pé àwọn ohunkan pàtàkì tí a lè kọ́ nínú ayé yí ni bí a ṣe lè tẹnumọ́ ìwàẹ̀dá ayérayé ti ẹ̀mí àti láti kojú àwọn ìfẹ́ ìbi wa. Èyí kò níláti ṣòro. Lẹ́hìnnáà, ẹ̀mí wa, èyí ti ó ti wa layika ni pípẹ́ ju ara wa lọ, ti yege ní yíyan òdodo lórí ibi nínú ìṣíwájú ayé. Ṣíwájú kí a tó dá ayé, a gbé ní ayé ẹ̀mí bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Òbí Ọ̀run, tí wọ́n fẹ́ràn wa tí wọ́n sì nfẹ́ wa lọ báyíì.
Bẹ́ẹ̀ni, a ti sí láti ṣe àwọn ìpinnu ìyípada-ayé àti àwọn àṣàyàn nínú ipò ìṣíwájú ayé. Gbogbo ènìyàn tí wọ́n ti gbé láyé rí tàbí tí wọn yóò gbé láyé yí ti ṣe ìpinnu pàtàkì láti yàn láti tẹ́wọ́gba ètò Bàbá Ọ̀run fún ìgbàlà wa. Nítorínáà gbogbo wa wá sáyé pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ìlàná tó tó hàn nípa àṣeyege ìwàẹ̀dá ti ẹ̀mí kan àti ìpín ayérayé.
Ronú nípa ìyẹn fún àkokò kan. Èyí ni ẹni tí ẹ jẹ́ lódodo, àti ẹni tí ẹ ti jẹ́ nígbàgbogbo: ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Ọlọ́run, pẹ̀lú gbòngbò ti ẹ̀mí nínú ayé àìlópin àti ọjọ́ ọ̀la tó nṣàn rekọjá pẹ̀lú àwọn ìṣeéṣe ayérayé. Lakọkọ—ẹ jẹ́, ẹni ẹ̀mí, ṣíwájú—àti nígbàgbogbo. Nítorínáà ìgbàtí a bá yàn láti fi ìwaẹ̀dá ara wa síwájú ti ìwaẹ̀dá ẹ̀mí wa, à nyan ohun kan tí ó lòdì sí òdodo, òtítọ́, àtilẹ̀wá, ti ẹ̀mí ara wa.
Síbẹ̀, kò sí ìbèèrè kankan pé ara àti ìfọwọ́tọ́ ayé nmú ìpinnu ṣíṣe le si. Pẹ̀lú ìbòjú ìgbàgbé tó fàlà laarin ìṣíwájú ayé ẹ̀mí àti ayé ikú yí, a le sọ òye ìbáṣepọ̀ wa sí Ọlọ́run nú àti ìwàẹ̀dá ti ẹ̀mí wa, àti pé ìwàẹ̀dá ara wa lè fi ìṣíwájú-ipò sí ohun tí a fẹ́ báyìíbáyìí. Kíkọ́ láti yan àwọn ohun ti Ẹ̀mí lórí àwọn ohun ti ara ni ọ̀kan lára kókó ìdí tí ìrírí ti ayé fi jẹ́ apákan ètò Bàbá Ọ̀run. Bákannáà ó jẹ́ ìdí tí ètò náà fi dálé ìpìnlẹ̀ dídájú, gidi nípa Ètutù Olúwa wa àti Olùgbàlà, Jésù Krístì, kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti pẹ̀lú àwọn àṣìṣe tí a ti ṣe nígbàtí a bá yọ̀da sí ara, lè mú wa borí nípa ìrònúpìwàdà lemọ́lemọ́ à sì lè gbé ni dídojúkọ ẹ̀mí. Báyìí ni àkokò láti darí àwọn ìpebi ara wa láti wà nibamu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ti ẹ̀mí Krístì. Ìyẹn ni ìdí tí a kò gbọ́dọ̀ fi sún ọjọ́ ìrònúpìwàdà wa síwájú.10
Ìrònúpìwàdà, nítorínáà, di ohun ìjà àìlèjùdànù nínú ogun wa lórí arawa. Ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá, Ààrẹ Russell M. Nelson tọ́ka sí ogun yí ó sì rán wa létí pé “nígbàtí a bá yàn láti ronúpìwàdà, a yàn láti yípadà! A nfàyè gba Olùgbàlà láti yí wa padà sínú ẹ̀yà arawa tó dárajùlọ. A yàn láti dàgbà níti ẹ̀mí àti láti gba ayọ̀—ayọ̀ ìràpadà Rẹ̀! Nígbàtí a yàn láti ronúpìwàdà, a yàn láti dàbí Jésù Krístì síi !9
Alaalẹ́ bí mo ṣe ntún ọjọ́ mi wò nínú àdúrà pẹ̀lú Bàbá mi Ọ̀run, mo nbèèrè fún ìdáríjì tí mo bá ṣe àṣìṣekáṣìṣe tí mo sì ṣèlérí làti gbìyànjú láti dára si lọla. Mo gbàgbọ́ pé ìrònúpìwàdà déédé ojoojúmọ́ yí nran ẹ̀mí mi lọ́wọ́ láti rán ara mi létí nípa ẹni tí ó wà ní àkóso mi.
Ohun èlò míràn ni ànfàní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí gbogbo wa ní láti túnra wa ṣe níti ẹ̀mí nípa ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní ìrántí Ètùtù àti ìfẹ́ Olúwa wa ati Olùgbàlà, Jésù Krístì, ní fún wa.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo gbà yín níyànjú láti tẹ̀ẹ́ jẹ́jẹ́ díẹ̀ kí ẹ sì ronú nípa ibi tí ẹ wà nísisìyí ní rírẹ ìwaẹ̀dá ẹran-ara yín sílẹ̀ àti fífun ìwàẹ̀dá ti ẹ̀mí àti ti ọ̀run yín lágbára nítorí nígbà tí àkokò bá tó, ẹ lè kọjá sínú ayé ẹ̀mí si níní ìrẹ́pọ̀ aláyọ̀ kan si pẹ̀lú àwọn olùfẹ́ yín—fún èyí ni mo jẹ́ẹ̀rí tí mo sì fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.