2010–2019
Kí A Gbé Àgbélèbú Wa
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Kí A Gbé Àgbélèbú Wa

Gbígbé àwọn àgbélèbú wa lé orí arawa àti títẹ̀lé Olùgbàlà túmọ̀sí títẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ní ipa-ọ̀nà Olúwa àti gbígba ìwà ayé mọ́ra.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a ti gba àwọn ìkọ́ni alárà látẹnu àwọn olórí wa ní àwọn ọjọ́ méjì tó kọjá wọ̀nyí. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé tí a bá tiraka láti ṣe àmúlò àwọn ìmísí wọ̀nyí àti àwọn ìkọ́ni ti àsìkò nínú ìgbé ayé wa, Olúwa, nípa ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀, yíò ran ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti gbé àgbelèbú wa àti láti mú àwọn àjàgà wa fúyẹ́.1

Nígbàtí a wà ní agbègbè Caesarea Philippi, Olùgbàlà fihan àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ ohun tí Òun yóò jìyà lọ́wọ́ àwọn alàgbà, àwọn olóyè àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ní Jérúsálẹ́mù. Ó kọ́ wọn nípa ikú Rẹ̀ nípàtàkì àti Àjíìnde ológo.2 Ní akokò náà, àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ kò nímọ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ tọ̀run lórí ilẹ̀ ayé pátápátá. Peter fúnrarẹ̀, nígbàtí ó gbọ́ ohun tí Olùgbàlà ti sọ, o mú U sí ẹ̀gbẹ́ ó sì ba A wí, pé, Kámá ríi, Olùwa: kì yíò rí bẹ́ẹ̀ fún ọ.”3

Láti ran àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pé ìfọkànsìn sí iṣẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìjọ̀wọ́araẹnisílẹ̀ àti ìjìya, ni Olùgbàlà fi ìtẹnumọ́ kéde:

“Bí ẹnìkẹ́ni bá nfẹ́ láti tọ̀ mí lẹ́hìn, kí ó sé ararẹ̀, kí o sì gbé agbélèbú rẹ, kí o sì máa tọ̀ mí lẹ́hìn.

Nítorí ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yíò sọọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nitorì mi yíò ri.

“Nítorípé èrè kíni fún énìyàn, bí ó bá jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? tàbí kíni ènìyàn ìbá fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀”4

Nípa ìkéde yí, Olùgbàlà tẹnumọ pé gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n nfẹ́ láti tẹ̀lé E níláti sẹ́ arawọn àti ìkoraẹni-níjánu fún ìfẹ́ wọn, òhùngbẹ wọn, àti ìdùnmọ́ni wọn, ìrúbọ ohungbogbo, àní ìjọ̀wọ́araẹni-sílẹ̀ gbogbo sí ìfẹ́ Bàbá—gẹ́gẹ́bí Òun ti ṣe.5 Lotitọ, ẹ̀yí ni, oye láti san fún ìgbàlà ẹ̀mí kan. Jésù fi tèròterò àti ìjúwe lo àmì àgbélèbú láti ran àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí ìrúbọ jẹ́ dáadáa àti ìfọkànsìn sí èrò Olúwa yíò túmọ̀ sí lotitọ. Àwòrán àgbélèbú kan ni a mọ̀ dáadáa ní àárín àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ àti àwọn olùgbé Ìjọba Rómù nítorí Romu mú àwọn olùpalára ti ìkànmọ́-àgbélèbú nípá láti gbé àgbélèbú ara wọn tàbí igi àgbélèbú lọ sí ibi tí a ó ti pa wọ́n.6

Lẹ́hìn Àjíìnde Olùgbàlà nìkan ni iyè wọn ṣí láti ní ìmọ̀ gbogbo ohun tí wọ́n ti kọ nípa Rẹ̀7 àti ohun tí a ó nílò látọ̀dọ̀ wọn láti ìgbà náà lọ.8

Ní irú kannáà, gbogbo wa, àwa arákùnrin àti arábìnrin, nílò láti ṣí inú àti ọkàn wa ní èrò láti ní ìmọ̀ kíkún síi nípá pàtàkì ti gbígbé àgbélèbú wa lórí ara wa àti láti tẹ̀le E. A kọ́ nípasẹ̀ ìwé-mímọ́ pé àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti gbé àgbélèbú wọn lórí ara wọn nifẹ Jésù Krístì ní irú ọ̀nà kan tí wọ́n fi sẹ́ ara wọn nínú gbogbo ìfẹkúfẹ́ àti gbogbo àdánù ayé tí wọ́n sì npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.9

Ìpinnu wa láti ju gbogbo ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run dànù àti láti fi gbogbo ohun tí wọ́n ni kí a fúnni ṣèrúbọ láti tẹ̀lé àwọn ikẹkọ́ Rẹ̀ yíò rànwálọ́wọ́ láti nífaradà ní ipa-ọ̀nà ti ìhìnrere Jésù Krístì—àní ní ojú ìpọ́njú, àìlera ẹ̀mí wa, tàbí ìtẹ̀mọ́ra ìbákẹ́gbẹ́ àti ẹ̀kọ́ ayé tí ó tako àwọn ìkọ́ni Rẹ̀.

Fún àpẹrẹ, fún àwọn wọnnì tí ọn kò tíi rí ojúgbà ayérayé kan tí wọ́n sì lè ní ìmọ̀lára àdánìkanwà àti àìnírètí, tàbí fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti kọ̀ tí wọ́n sì nímọ̀lára ìpatì àti ìgbàgbé, mo mu dáa yín lójú pé títẹ́wọ́gba ìfipè Olùgbàlà ní gbígbé àgbélèbú wa lé orí ara wa àti títẹ̀lé E túmọ̀ sí títẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ní ipa-ọ̀nà Olúwa, ní mímú àwòṣe ìṣòdodo wa dúró, àti láì fàyè gba ìhùwa ayé tí yíò mú ìrètí wa kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run àti àánú nígbẹ̀hìn.

Irú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ kannáà ló wà fún àwọn wọnnì lára yín tí wọ́n nní ìrírí ìfàmọ́ra ẹ̀yà-kannáà àti níní ìmọ̀lára àìníyànjú àti àìnírànwọ́. Bóyá fún ìdí yí díẹ̀ lára yín lè ní ìmọ̀lára pé ìhìnrere Jésù Krístì kìí ṣe fún yín mọ́. Tí ìyẹn bá rí bẹ́ẹ̀, Mo fẹ́ láti mu dáa yín lójú pé ìrètí nwà nígbàgbogbo nínú Ọlọ́run Bàbá àti nínú ètò ìdùnnú Rẹ̀, nínú Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, àti ní gbígbé ìgbé ayé àwọn òfin ìfẹ́ni Wọn. Nínú ọgbọ́n pípé Rẹ̀, agbára, ìdáláre, àti àánú, Olúwa lè sọ wa di Tirẹ̀, kí a lè wá sí iwájú Rẹ̀ àti láti ní ìgbàlà títíláé, tí a bá dúróṣinṣin àti àìyẹsẹ̀ ní pípa àwọn òfin mọ́11 tí a sì nfi ìgbàgbógbo wà nínú iṣẹ́ rere.12

Sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle, títẹ́wọ́gba ìfipè kannáà túmọ̀ sí pé, nínú ohun gbogbo, láti rẹ̀ ara yín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, láti dámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn olórí Ìjọ, àti láti ronúpìwàdà kí a sì pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tì. Bákannáà ètò yí nbùkún gbogbo àwọn tí ó njà ní ìlòdì sí àìlèmójú kúrò líle, pẹ̀lú ohun olóró, àwọn egbògi, ọtí líle, àti ìwà èérí. Gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí nmú yín wá sọ̀dọ̀ Olùgbàlà, tani yíò sọ yín di òmìnira kúrò nínú ẹ̀bì, ìbànújẹ́, àti ìgbẹ̀kùn ti ẹ̀mí àti ti ara nígbẹ̀hìn. Ní àfikún, bákannáà ẹ lè fẹ́ láti wá àtìlẹhìn ẹbí yín, àwọn ọ̀rẹ̀, àti elégbògi tó jáfáfá àti amoye onímọ̀ràn.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe juwọ́lẹ̀ lẹ́hìn onírurú ìjákulẹ̀ kí ẹ ro ara yín bí aláìlókun láti pa ẹ̀ṣẹ̀ tì àti bíborí ìwà-àìlèfisílẹ̀. Ẹ kò lè gbà láti fi ìgbìyànjú sílẹ̀ kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú àìlera àti ẹ̀ṣẹ̀! Ẹ tiraka láti sa ipá yín nígbàgbogbo, ní ìfìhàn ìfẹ́ nínú iṣẹ́ yín láti wẹ inú yín mọ́, bí Olùgbàlà ti kọ́ni.13 Nígbà míràn àwọn ìdáhùn sí àwọn ìpènija nwá lẹ́hìn àwọn oṣù àti ọdún ìtiraka lemọ́lemọ́. Ìlérí tí a rí nínú Ìwé Mọ́mọ́nì pé “nípa ore-ọ̀fẹ́ ní a ní ìgbàlà, lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe,”14 wà fún gbogbo ènìyàn nínú ọ̀ràn wọ̀nyí. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí pé ẹ̀bùn ti ore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà “kò fibẹ́ẹ̀ lópin ní àkokò sí “lẹ́hìn” gbogbo ohun tí a lè ṣe. A lè gba ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ṣíwájú, ní àárín, àti lẹ́hìn àkokò nígbàtí a ti lo àwọn ìtiraka ti arawa tán.15

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ṣe ntẹ̀síwájú ní ìlàkàkà láti borí àwọn ìpènijà wa, Ọlọ́run yíò bùkún wa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ láti ní ìwòsàn àti ní ìṣiṣẹ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu.16 Òun yíò ṣe ohun tí a kò lágbára láti ṣe fúnrawa fún wa.

Láfikún, fún àwọn wọnnì tí wọ́n nímọ̀lára ìkorò, ìbínú, ìṣẹni, tàbí dèmọ́ àwọn ìkorò fún ohunkan tí ẹ rò pé kòtọ́, láti gbé àgbélèbú araẹni àti láti tẹ̀lé Olùgbàlà túmọ̀ sí ìlàkàkà láti gbé àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí sẹgbẹ kí a sì yípadà sí Olúwa kí Òun lè fún wa ní òmìnira látinú ipò iye-inu yí àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti rí àláfíà. Láìlóríre, tí a bá di ìmọ̀lára ibi mú àti ẹ̀dùn ọkàn, a lè rí arawa ní gbígbé láìsí agbára Ẹ̀mí Olúwa nínú ayé wa. A kò lè ronúpìwàdà fún àwọn ènìyàn míràn, ṣùgbọ́n a lè dáríjì wọ́n—nípa kíkọ̀ láti wà nígbèkùn nípasẹ̀ àwọn tó ti pa wá lára wọnnì.17

Àwọn ìwé-mímọ́ kọni pé ọ̀nà kan wà nínú àwọn ipò wọ̀nyí—nípa pípe Olùgbàlà wa láti rànwálọ́wọ́ láti rọ́pò ọkàn líle wa pẹ̀lú ọkàn titun.18 Fún èyí láti ṣẹlẹ̀, a nílò láti wá sọ́dọ̀ Olúwa pẹ̀lú àwọn àìlera wa19 kí a sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ àti ìdáríjì,20 nípàtàkì ní àkokò mímọ́ nígbàtí à nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní Ọjọọjọ́-ìsinmi. Ẹ jẹ́ kí a yàn láti wá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ àti láti gbé ìṣìsẹ̀ pàtàkì àti ṣíṣòro nípa dídáríji àwọn wọnnì tí wọ́n pawálára kí àwọn ọgbẹ́ wa lè bẹ̀rẹ̀ sí nníwòsàn. Mo ṣèlèrí fún yín pé ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn alẹ́ yín kún fún ìrọ̀rùn tí ó nwá látinú iyenu àláfíà kan pẹ̀lú Olúwa.

Nígbàtí ó wà ní àtìmọ́lé Liberty ní 1839, Wòlíì Joseph Smith kọ lẹ́ta gígùn kan sí àwọn ọmọ Ìjọ tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wa nínú rẹ̀ tí ó wà fún àwọn ipò àti ìtẹ̀dó wọ̀nyí gidi. Ó kọ pé, “Gbogbo ìtẹ́ àti ilẹ̀-ọba, agbára-ọba àti agbára, yíò di ìfihàn àti ìgbékalẹ̀ lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fitàra farada fún ìhìnrere Jésù Krístì.”21 Nítorínáà, àwọn wọnnì tí wọ́n gbé orúkọ Olùgbàlà lé orí ara wọn, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Rẹ̀ àti ìforítì dé òpin, yíò nígbàlà22 wọ́n sì lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run ní ipò ìdùnnú tí kò lópin.23

Gbogbo wa ndojúkọ àwọn ipò líle nínú ìgbé ayé wa tí ó nmú wa banújẹ́, àìnírànlọ́wọ́, àìnírètí, àní nígbàmíràn àìnílera Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí lè darí wa sí ìbèèrè Olúwa: “Kínìdí tí èmi fi nní ìrírí ipò wọ̀nyí?” tàbí “Kínìdí tí àwọn ìgbìrò mí kò fi bọ́si? Ní gbogbo rẹ̀, ṣé mò nṣe ohun gbogbo ní ìkáwọ́ mi láti gbé àgbélèbú mi àti láti tẹ̀lé Olùgbàlà!”

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, a gbọ́dọ̀ rántí pé gbígbé àgbélèbú wa lórí arawa pẹ̀lú jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti nínú ọgbọ́n àìlópin Rẹ̀. A gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé Òun ní ìfura ẹnìkọ̀ọ̀kan wa àti àwọn ìnílò wa. Bákannáà ó ṣeéṣe láti tẹ́wọ́gba òtítọ́ pé àkokò Olúwa yàtọ̀ sí tiwa. Nígbàmíràn a nwá ìbùkún a sì ngbé òpin àkokò kalẹ̀ fún Olúwa láti mu ṣẹ. A kò lè fì ipò ìṣòtítọ́ wa sí I nípa fífi ipá mu U fún àwọn ìdáhùn sí ìfẹ́ wa. Nígbàtí a bá ṣe èyí, à ndàbí àwọn Ará Néfì oníyèméjì ìgbà àtijọ́, tí wọ́n fi àwọn arákùnrin wọn ṣẹ̀sín nípa sísọ pé àkokò náà ti kọjá fún ìmúṣẹ ti àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ nípasẹ̀ Sámúẹ́lì ti Lámánáítì, tó ndá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ní àárín àwọn wọnnì tí wọ́n gbàgbọ́.26 A nílò láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa tó láti ṣì jẹ́ àti láti mọ̀ pé Òun ni Ọlọ́run, pé Ó mọ ohun gbogbo, àti pé Ó nífura ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.27

Alàgbà Soares ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí Arábìnrin Calamassi

Láìpẹ́ mo ní ànfàní láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí arábìnrin opó tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Franca Calamassi, ẹnití ó njìyà nínú ààrùn—ìbàjẹ́ ara. Arábìnrin Calamassi ni ọmọ ìjọ àkọ̀kọ̀ nínú ẹbí rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ ti Jésù Krístì. Bíótilẹjẹ́pé ọkọ rẹ̀ kò ṣe ìrìbọmi rárá, ó gbà láti bá àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere pàdé àti láti lọ ilé ìjọsìn léraléra. Pẹ̀lú ipò wọ̀nyí, Aràbìnrin Calamassi dúró ní òtítọ́ ó si tọ́ àwọn ọmọ rẹ mẹ́rin ní ìhìnrere Jésù Krístì. Ọdún kan lẹ́hìn ikú ọkọ rẹ̀, Arábìnrin Calamass àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹrin rìnrìnàjo papọ̀ lọ sí tẹ́mpìlì wọ́n sì kópa nínú àwọn ìlànà fún arawọn àti fún ọkọ rẹ̀, pẹ̀lú ṣíṣe èdidì papọ̀ bi ẹbí. Àwọn ìlérí tó rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà wọ̀nyí mú ìrètí púpọ̀, ayọ̀, àti ìdùnnú wá fun tí ó ràn an lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìgbé ayé rẹ̀.

Ẹbí Calamassi ní tẹ́mpìlì

Nígbàtí ìfarahàn àìsàn náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí hàn, bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀ fun ní ìbùkún kan. Ní ìgbà náà ó sọ fún bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀ pé òun ṣetán láti tẹ́wọ́gba ìfẹ́ Olúwa, fífi ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn láti gba ìwòsàn bákannáà bí ìgbàgbọ́ láti farada àìsàn rẹ̀ dé òpin.

Ní ìgbà ìbẹ̀wò mi, nígbàtí mo di ọwọ́ Arábìnrin Calamas mú tí mo sì nwo ojú rẹ̀, mo rí ìwò ti àngẹ́lì tó nwá látojú rẹ̀—ní ríronú nípa ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínù ètò Ọlọ́run àti ìtànná ìrètí pípé rẹ̀ nínú ìfẹ́ Bàbá àti ètò fún un.29 Mo ní ìmọ̀lára ìpinnu dídúróṣinṣin láti nífaradà nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀ títí dé òpin nípa gbígbé agbélèbú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìpènijà tí ó ndojúkọ. Ìgbé ayé arábìnrin yí ni ẹ̀rí Krístì, ẹ̀là-ọ̀rọ̀ ìgbágbọ́ rẹ̀ àti ìfọkànsìn sí I.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo jẹ́ ẹ̀rí síi yín pé gbígbé àgbélèbú wa lé orí wa àti títẹ̀lé Olùgbàlà bèèrè fún wa láti tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ àti láti làkàkà láti dàbíi Rẹ̀,30 fífi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dojúkọ àwọn ipò ayé, sísẹ́ àti fífi àwọn ìpebi ti ẹlẹ́ran-ara ènìyàn sílẹ̀, àti dídúró de Olúwa. Akéwì kan kọ pé:

“Dúró de Olúwa: tújúka, òun ó sì fún ọkàn rẹ lókun: dúró, mo wí, de Olúwa.”28

“Òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti ààbò.”29

Mo jẹ́ ẹ̀rí síi yín pé nípa títẹ̀lé ìṣísẹ̀ Ọ̀gá wa àti dídúró dè É ẹnití Ó jẹ́ olùwòsàn ìgbẹ̀hìn sí ayé wa yíò pèsè ìsinmi sí ẹ̀mí wa yíò sì mú àwọn àjàgà wa rọrùn àti fúyẹ́.29 Nípa Èyí ni mo jẹ́ẹ̀rí ni orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, Àmín.