2010–2019
Ayọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Ayọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́

Ayọ̀ nwá látinú pípa àwọn àwọn òfin mọ́, látinú bíborí ìkorò àti àìlera nípa Rẹ̀, àtì latinú sínsìn bí ó ti sìn.

Wòlíì Énọ́sì Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ọmọ-ọmọ Léhì, kọ ìrírí kanṣoṣo tí ó ṣẹlẹ̀ ṣíwájú nínú ayé rẹ̀. Nígbaìtí òun nìkan nṣọdẹ nínú ẹgàn, Énọ́sì bẹ̀rẹ̀ sí njìròrò lórí àwọn íkọ́ni bàbá rẹ̀, Jákọ́bù. Òun sọ, Àwọn ọ̀rọ̀ èyítí mo sábà máa ngbọ́ tí bàbá mi nsọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun, àti ayọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, sì wọ ọkàn mi lọ.”1 Nínú ẹbi ti ẹ̀mí rẹ̀, Énọ́sì kúnlẹ̀ nínú àdúrà, àdúrà ọlọ́lá kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ àti títí di alẹ́, àdúrà kan tí ó mú àwọn ìfihàn pàtàkí, ìdánilójú, àti ìlérí wá fun.

Ọ̀pọ̀ wà tí a lè kọ́ látinú ìrírí Énọ́sì, ṣùgbọ́n ní òní ohun tó hàn nínú mi ni ìrántí Énọ́sì nípa bàbá rẹ̀ tó nṣọ̀rọ̀ nípa “ayọ̀ a`wọn ènìyàn mímọ́.”

Nínú ìpàdé àpàpọ̀ yí ní ọdún mẹta sẹ́hìn, Ààrẹ Russell M. Nelson sọ̀rọ̀ nìpa ayọ̀.3 Ní àárín àwọn ohun míràn, ó wípé:

“Ayọ̀ tí à nní ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbé ayé wa àti ohungbogbo ní iṣé pẹ̀lú ìdojúkọ àwọn ìgbé ayé wa.

“Nígbàtí ìdojúkọ ti ìgbé ayé wa bá wà lórí ètò ìgbàlà Ọlọ́run, ... àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ayọ̀ lákà ohun tó nṣẹlẹ̀ sí—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbé ayé wa. Ayọ̀ nwá látọ̀dọ̀ àti nítorí Rẹ̀. ... Fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, Jésù Krístì ni ayọ̀!”4

Àwọn ènìyàn mímọ́ ni àwọn wọnnì tí wọ́n ti wọnú májẹ̀mú ìhìnrere nípa ìrìbọmi tí wọ́n sì ntiraka láti tẹ̀lé Krístì bí àwọ ọmọẹ̀hìn Rẹ̀.5 Báyìí, “ayọ̀ awọn ènìyàn náà” fi ayọ̀ ti didàbí ti Krístì hàn.

Èmi ó fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ tí ó nwá látinú pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, ayọ̀ tó ndìde látinú bíborí ìkorò àti àìlera nípa Rẹ̀, àti ayọ̀ tó wà nínú sísìnnbí Òun ti sìn.

Ayọ̀ ti pípa àwọn òfin Krístì mọ́.

À ngbé ní ìgbà ìgbàgbọ́ nínú ìgbádun-ayé nìkan, nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nbèèrè bí àwọn òfin Olúwa ṣe jẹ́ pàtàkì sí tàbí kí wọ́n rọra pá wọ́n tì. Láìkìí ṣe lemọ́lemọ́, àwọn ènìyàn tí wọ́n nju àwọn ìdarí tọ̀run bíiti àṣẹ ìwààìléèrí kiri, odiwọn òtitọ́, àti ìwàmímọ́ Ọjọ́-ìsinmi dabí wọ́n nyege wọ́n sì ngbádùn àwọn ohun ayé, àní nígbàmíràn ju àwọn wọnnì tí wọ́n ntiraka láti jẹ́ olùgbọ́ran. Ó nya àwọn kan lẹ́nu tí àwọn ìlàkàkà àti ẹbọ-ọrẹ bá tilẹ̀ yẹ. Àwọn ènìyàn àtijọ́ ti Ísráẹ́lì ráun nígbàkan:

“Asán ni láti sin Ọlọ́run, ànfàní kíni ó sì jẹ́, tí àwa ti pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́, tí àwa ti rìn nínú ìrora-ọkàn níwájú Olúwa àwọn Ọmọ-ogun?

Àti nísisìyí àwa pe agbéraga ní onínúdídùn; bẹ̃ni, àwọn tí ó nṣe búburú npọ̀ síi; bẹ̃ní, àwọn tí ó dán Ọlọ́run wò sã ni a dá sí.”6

Ṣá ti dùrò, ni Olúwa wì, títí di “ọjọ́ náà nígbàtí èmi ó ṣe àlùmọ́nì mi. ... Nígbànã ni ẹ̀yin ... Ó mọ́ ìyàtọ̀ lãrín olódodo àti ẹni-búburú, lãrín ẹnití nsin Ọlọ́run àti ẹnití kò sìn ín.”8 Àwọn ẹni-bùburú lè “ní ayọ̀ nínú iṣẹ́ wọn fún àkokò kan,” ṣùgbọ́n fún ìgbà ránpẹ́ ni.9 Ayọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ npẹ́ títí.

Ọlọ́run rí ohun gbogbo nínú ìgbìrò òtítọ́, Ó sì nṣe àbápín ìgbìrò náà pẹ̀lú wa nípa àwọn òfin Rẹ̀, Ó ntọ́wasọ́nà dáadáa yíka àwọn ìṣubú àti kòtò ayé ikú síwájú ayọ̀ ayérayé. Ààrẹ Joseph Smith ṣàlàyé: “Nígbàtí òfin Rẹ̀ kọ́ wá pé, ó jẹ́ ní ìwò ayérayé; nitori Ọlọ́run nwò wá bí ẹnipé a wà ni ayé aìlópin; Ọlọ́run ngbé ní ayé aìlópin, kìí wo nkan bíi tiwa.”8

Èmi kò tíì pàdé ẹnìkankan tí ó gba ìhìnrere nígbẹ̀hìn tí kò ti rò pé ìbá ti ṣe ní ìṣíwájú. “Óò, àwọn àṣàyàn búburú àti àṣìṣe tí èmi ìbá ti yẹra fún,” ni wọ́n nsọ. Àwọn òfin Olúwa jẹ́ atọ́nà wa sí àwọn àṣàyàn tó dára àti àbájáde ìdùnnú si. Bí a ṣe níláti yọ̀ kí a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ fún fífi ọ̀nà pípé jùlọ hàn wá.

Àwòrán
Arábìnrin Kamwanya

Gẹ́gẹ́bí èwe, Arábìnrin Kalombo Rosette Kamwanya láti D. R. Congo, tó nsìn báyìí ní Cote d’Ivoire Abidjan Míṣọ̀n Ìwọ̀-oòrùn, gbàwẹ̀ ó sì gbàdúrà fún ọjọ́ mẹta láti rí ìdarí tí Ọlọ́run fẹ́ kí ó ṣe. Nínú ìran òru ọlọ́la kan, a fì ilé-ìjọ́sìn kan hàn án àti ohun tí òun dámọ̀ báyìí bí i tẹ́mpìlì kan. Ó bẹ̀rẹ̀ lá wákiri ó sì rí ilé-ìjọsìn tí ó ti rí nínú àlà rẹ̀ láìpẹ́. Àmì náà wípé, “Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Arábìnrin Kamwanya ṣe ìrìbọmi ńgbànáà àti ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ mẹ́fà. Arábìnrin Kamwanya wípé, “Nígbàtí mo gba ìhìnrere, mo ní ìmọ̀lára bí ẹyẹ tí a mú tí ó wá gba òmìnira. Ọkàn mi kún fún ayọ̀. ... Mo ní ìdánilójú pé Ọlọ́run fẹ́ràn mi.”11

Pípa àwọn òfin Olúwa mọ́ nfún wa lágbara si ìrọ̀rùn àti láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀ si. Ipá ọ̀nà tààrà àti híhá ti àwọn òfin ndarí tààrà sí ibi igi ìyè, àti pé igi náà àti èsò rẹ̀, tó dùn rékọjá tí ó sì dùnmọ́ni ju gbogbo ohun lọ,”10 ni ìrọ́pọ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run ó sì kún ẹ̀mí náà “pẹ̀lú ayọ̀ nlá tó tayọ.”11 Ni Olùgbàlà sọ:

Tí ẹ bá pa òfin mi mọ̀, ẹ ó gbé nínú ìfẹ́ mi; àní bí mo ti ṣe pà òfin Bàbá mi mọ́, tí mò ngbé nínú ìfẹ́ rẹ̀.

“Àwọn ohun wọ̀nyí ni mo wí fún yín, kí ayọ̀ mi lè dúró nínú yín, àti kí ayọ̀ yín lè kún.”14

Ayọ̀ Bíborí nípasẹ̀ Krístì

Àní nígbàtí a bá nfi òtítọ́ pa àwọn òfin náà mọ́, àwọn àdánwò àti àjálù wà tí ó lè dá ayọ̀ wa dúró. Ṣùgbọ́n bí a ṣe ntiraka láti borí àwọn ìpènijà wọ̀nyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà, ó ndá ààbò bo ayọ̀ tí à nní nisisìyí àti àyọ̀ tí à nretí. Krístì tún dá àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ lójú, “Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”15 Nínú yíyípadà sí I, gbígbọ́ran sí I, dídi arawa mọ́ Ọ kí àdánwò àti ìkorò lè yípadà sí ayọ̀. Mo sọ àpẹrẹ kan.

Ní 1989, Jack Rushton nsìn bí ààrẹ Èèkan Irvine California (USA). Ní ìgbà ìsinmi ẹbí kan ní etí òkun California, Jack nfò lórí omi nígbàtí ìjì gbe lọ sínú òkúta tí omi bòmọ́lẹ̀, ó kán ọ̀rùn rẹ̀ ó sì pa ọ̀pá ẹ̀hìn rẹ̀ lára. Jack sọ lẹ́hìnnáà pé, “Ní kété ti mo sọ lùú, mo mọ̀ pé mo ti di arọ.”16 Kò lè sọ̀rọ̀ mọ́ tàbí kí ó tilẹ̀ mí fúnra rẹ̀.17

Àwòrán
Ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ nran àwọn Rushton lọ́wọ́

Ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àti ọmọ èèkàn wá níbẹ̀ fún Arákùnrin Rushton àti ìyàwó rẹ̀, Jo Anne, àti, ní ọ̀nà míràn, tun apákan ilé wọn ṣe láti fàyè gba ijoko-yíyí ti Jack. Jo Anne di ọ̀gá-iṣẹ́ ibi ìfúnni-nítọ́jú Jack fún ọdún mẹtàlélógún. Títọ́kasí àkọsílẹ̀ Ìwé Mọ́mọ́nì bí Olúwa ṣe bẹ àwọn ènìyàn wò nínú ìpọ́njú wọn tí ó sì mú ẹrù wọn fúyẹ́,18 Jo Anne sọ pé, “Ó máa nyà mí lẹ́nu nígbàkugbà fún ìfuyẹ́ ọkàn tí mo ní ní títọ́jú ọkọ mi.”19

Àwòrán
Jack àti Jo Anne Rushton

Àtúnṣe kan sí mímí rẹ̀ mú okun láti sọ̀rọ̀ padà fún Jack, àti nínú ọdún náà, Wọ́n pe Jack bí olùkọ́ni Ẹ̀kọ́ Ìhìnrere àti bàbánlá èèkàn. Nígbàtí òun bá nfúnni ní ìbùkún bàbánlá, olùdìmú oyèàlùfáà míràn yíò gbé ọwọ́ Arákùnrin Ruston le orí ẹni tí ó ngba ìbùkún yíò si ti ọwọ́ àti apá rẹ̀ lẹ́hìn nígbà ìbùkún náà. Jack kú ní ọjọ́ Kérésìmesì 2012, lẹ́hìn ọdún méjìlélógún iṣẹ́ ìsìn ìfọkànsìn.

Àwòrán
Jack Rushton

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan, Jack ṣàkíyèsí: “Àwọn ìṣòrò yíò wá sínú gbogbo àwọn ìgbé ayé wa; ó jẹ́ ara jíjẹ́ wíwà lórí ilẹ̀ ayé. Àti pé àwọn ènìyàn rò pé ẹ̀sìn tàbí níní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run yíò dáàbò bò yín kúrò nínú àwọn ohun burúkú. Èmi kò rò pé ìyẹn ni. Mo rò pé ọ̀ràn náà ni pé ìgbàgbọ́ lágbára, pé nígbàtí àwọn ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀, èyí tí yíò ṣẹlẹ̀, a ó le dojúkọ wọ́n. ... Ìgbàgbọ́ mi kò yẹsẹ̀ rí, ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé èmi ko ní ìbonimọ́lẹ̀. Mo ronú fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ayé mi pé a tì mí dé òpin, àti pé ní ọ̀ràn kan kò sí ibi tí a lè yípadà sí, àti pe nítorí bẹ́ẹ̀ mo yípadà sí Olúwa, títí di oní yí, mo ni ìmọ̀lára ayọ̀ lọ́gán.”19

Èyí ni ọjọ́ ìkọlù líle nínú ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn nígbàmíràn àti nínútí wọ́n ẹni ní ìlòdì sí àwọn wọnnì tí wọ́n ndi òṣùwọ̀n Olúwa ní wíwẹ̀wu, ìgbàlejò, àti ìbálò mímọ́. Ó wà lemọ́lemọ́ ní àárín àwọn ọ̀dọ́ àti àgbà kékeré Ènìyàn Mímọ́, bákannáà bí àwọn obìnrin àti ìyá, tí wọ́n ngbé àgbélèbú ti ìṣẹ̀sín àti ìlépa. Kò rọrùn láti dìde kọjá irú ìlòkulò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n rántí àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù: “Tí ẹ bá gba íbáwí fùn orúkọ Krístì, onínídídùn ni ẹ̀yin; fún ẹ̀mí ògo àti ti Ọlọ́run ti bà lórí yín: ní ara tiwọn a sọ̀rọ̀ ibi nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ara tiyín ó di ológo.”20

Nínú ọgbà Édénì, Ádámù àti Éfà wà ní ipò àìmọ̀, “ láìní ayọ, nítorí wọn kò mọ ìbànújẹ́.”21 Nísisìyí, bí olùṣírò ènìyàn, a rí ayọ̀ ní bíborí ìbànújẹ́ ní ọ̀nàkọnà, bóyá ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àdánwò, àìlera, tàbí àtakòkátakò míràn sí ìdùnnú. Èyi ni ayọ̀ lílóye ìlọsíwájú ní ipa-ọ̀nà ọmọlẹ́hìn; ayọ̀ ti gbígba idáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti níní àláfíà ẹ̀rí ọkàn”22 ayọ̀ níní ìmọ̀lára ẹ̀mí láti gbòòrò àti láti dàgbà nípa oore-ọ̀fẹ́ Krístì.23

Ayọ̀ Sísìn bíiti Krístì

Olùgbàlà rí ayọ̀ ní mímú àìkú àti ìyè ayérayé wa wá sí ìmúṣẹ.24 Ní sísọ̀rọ̀ Ètùtù Olùgbàlà, Ààrẹ Russell M, Nelson wí pé:

“Bí ohun gbogbo, Jésù Krístì alápẹrẹ ìgbẹ̀hìn wa, ‘nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀, tí ó farada àgbélèbú’ [Hébérù 12:2]. Ronú nípa èyíinì! Ní èrò fún Un láti farada ìrírí olóró jùlọ tí a faradà rí nílẹ̀ ayé, Olùgbàlà wa dojúkọ ayọ̀!

“Kíni ayọ̀ tí a gbé ka iwájú Rẹ̀? Dájúdájú ó pẹ̀lú ayọ̀ ìwẹ̀nùmọ́, ìwòsàn, àti fífúnwalokun; ayọ̀ sísan gbèsè fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí yíò ronúpìwàdà; ayọ̀ mímu ṣeéṣe fún yín àti èmi láti padà sílé—ní mímọ́ àti yíyẹ—láti gbé pẹ̀lú àwọn Òbí Ọ̀run àti ẹbí wa.”25

Bákannáà, ayọ̀ tí a “gbé ka iwájú wu” ni ayọ̀ ríran Olùgbàlà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìràpadà Rẹ̀. Bí irú-ọmọ àti ọmọ Ábráhámù,26 a kópa ní bíbùkún gbogbo àwọn ẹbí ti ilẹ̀ ayé “pẹ̀lú àwọn ìbùkún Ìhìnrere, èyí tí ó jẹ́ àwọn ìbùkún ìgbàlà, àní ìyè ayérayé.”27

Àwọn ọ̀rọ̀ ti Álmà wá sọ́kàn:

“Èyí sì ni ògo mi, pé bóyá èmi lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run láti mú ọkàn àwọn ẹ̀mí díẹ̀ wá sí ìrònúpìwàdà; èyí sì ni ayọ̀ mi.

Sì kíyèsĩ, nígbàtí mo bá rí púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin mi pé nwọ́n ti ronúpìwàdà nítoótọ́, tí nwọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, ìgbàyĩ ni ọkàn mi kún fún ayọ̀. ...

“Ṣùgbọ́n èmi kò yọ̀ nínú àṣeyọrí mi nìkan, ṣùgbọ́n ayọ̀ mi kún síi nítorí àṣeyọrí àwọn arákùnrin mi, tí nwọ́n ti lọ sí ilẹ̀ Néfì. ...

“Nísisìyí, nígbàtí mo bá ro ti àṣeyọrí àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí ó nmu ọkan mi fo lọ ani bi i pe a pin niya kuro ní ara mi, bi o ti ri, bẹ́ẹ̀ ni ayọ mí tobi to.”28

Èrè iṣẹ́ ìsin wa sí arawa nínú Ìjọ jẹ́ ara ayọ̀ tí a “gbé ka iwájú wa.” Àní ní ìgbà àìnírètí tábí àárẹ̀, a lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ tírẹ́lẹ́tírẹ́lẹ́ tí a bá dojúkọ ayọ̀ dídùnmọ́ni Ọlọ́run àti mímú ìmọ́lẹ̀, ìrànlọ́wọ́, àti ìdùnnú sí àwọn ọmọ Rẹ̀, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa.

Nígbàtí mo wà ní Haiti lóṣù tó kọjá fún ìyàsímímọ́ ti Tẹ́mpìlì Port-au-Prince, Alàgbà David àti Arábìnrin Susan Bednar arábìnrin kékeré kan pàdé ẹnití wọ́n pa ọkọ rẹ̀ nínú ìjàmbá líle ní ọjọ́ díẹ̀ ṣíwájú. Wọ́n sọkún papọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Síbẹ̀ lọ́jọ́ Ìsinmi obìnrin ọ̀wọ́n yí wà ní ipò rẹ̀ bí ọ́ṣà àti ní ibi ìsìn ìyàsímímọ́ pẹ̀lú, pẹ̀lú ẹ̀rín, jẹ́jẹ́ ìkínni káàbọ̀ fún gbogbo ẹni tó wọnú tẹ́mpìlì.

Mo gbàgbọ́ pé “ayọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́” nwá ní mímọ̀ pé Olùgbàlà nbẹ̀bẹ̀ fún ìlepa wọn,30 àti pé kò sí ẹnikan tí ó lè gba ayọ̀ náà èyí tí [yíò kún] ẹ̀mí wa [bi] a ṣe [ngbọ́ tí Jésù] ngbàdúrà fún wa lọ́dọ̀ Bàbá.”31 Pẹ̀lú Ààrẹ Russell M. Nelson, mo jẹ́ ẹ̀rí pé ayọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn kan fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ olotitọ́ “tí wọ́n ti fi aradà àwọn àgbélèbú ayé”29 tí wọ́n sì “nmọ̀ọ́mọ̀ gbìyànjú láti gbé ìgbé ayé òdodo, bí a ti kọ́ni nípasẹ̀ Jésù Krístì.”30 Njẹ́ kí ayọ̀ yín kún, ni mo gbàdúrà ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Enos 1:3.

  2. Wo Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Yíyè Ti Ẹ̀mí;” Liahona, Nov. 2016, 81-84.

  3. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Yíyè Ti Ẹ̀mí.” 82.

  4. Wo Bible Dictionary, “Ènìyan Mímọ́.

  5. Málákì 3:14–15.

  6. Málákì 3:17–18.

  7. Olùgbàlà kéde pé tí a kò bá gbé ìjọ kan (tàbí aye) lé orí ìhìn-rere mi, tí a sì gbe lé orí iṣẹ́ ènìyàn, tàbí lé orí iṣẹ́ èṣù, lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọn ó ní ayọ̀ nínú iṣẹ́ wọn fún ìgbà díẹ̀, àti pé bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ òpin yíò dé, tí a ó ké wọn lulẹ̀ tí a ó sì sọ wọ́n sínú iná, láti inú èyítí kò sí ìpadàbọ̀”(3 Nephi 27:11).

  8. Teachings of Presidents of the Church: Joseph Smith (2007), 186.

  9. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  10. 1 Néfì 11:22; bákannáà wo 1 Néfì 8:11.

  11. 3 Néfì 8:12.

  12. Jòhánù 15:10–11; àfikún àtẹnumọ́.

  13. John 16:33.

  14. Jack Rushton, in “Faith in Adversity: Jack Rushton and the Power of Faith,” SmallandSimpleTV, Sept. 2, 2009, YouTube.com.

  15. Wo Allison M. Hawes, “Ó Dára láti Wà Láàyè,” Ensign, Apr. 1994, 42.

  16. Wo Mòsíàh 24:14.

  17. Jo Anne Rushton, in Hawes, “It’s Good to Be Alive,” 43.

  18. Jack Rushton, in “Ìgbàgbọ́ nínú Ìpọ́njú: Jack Rushton àti Agbára Ìgbàgbọ́.”

  19. 1 Pétérù 4:14. Bákannáà ránti àwọn ìlérí tí a ṣe ní 2 Néfì 9:18 and 3 Néfì 12:12.

  20. 2 Néfì 2:23; bákannáà wo Mósè 5:10-11.

  21. Mòsíàh 4:3.

  22. A rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù tí ó fún Joseph Smith ní ìmísí láti “bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run” (Jákọ́bù 1:5). Àwọn ẹsẹ tí kò bániláramu tóbẹ́ẹ̀ ni ó tẹ̀le:

    “Ẹ̀yin ará mi, nígbàtí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀;

    “Kí ẹ sì mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín nṣiṣẹ́ sùúrù.

    “Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù ṣe iṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti àìlábùkú, kí ó má ku ohun kan fú ẹnikẹ́ni” (Àyípadà èdè Joseph Smith, James 1:2 [in James 1:2, footnote a]; James 1:3–4).

  23. Wo Moses 1:39.

  24. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ ati Yíyè Ti Ẹ̀mí82–83; emphasis in original.

  25. “Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Krístì, nígbànáà ẹ̀yin ni irú ọmọ Ábráhámù, àti àrólé gẹ́gẹ́bí ìlérí” (Galatians 3:29; see also Genesis 22:18; 26:4; 28:14; Acts 3:25; 1 Nephi 15:18; 22:9; Doctrine and Covenants 124:58).

  26. Ábráhámù 2:11.

  27. Álmà 29:9–10, 14, 16. Àní bẹ́ẹ̀náà, Olúwa wí fún wa pé, “Bí ayọ̀ yín yíò bá pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ mú wá sí ọ̀dọ̀ mi sínú ìjọba mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó bí ẹ̀yin bá lè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi!Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:16. Àwọn Ará Néfì mẹta ni a ṣèlérí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ nítorí wọ́n fẹ́ láti mú àwọn ẹ̀mí wá sọ́dọ̀ Krístì “Nígbàtí ayé bá ṣì wà” (3 Néfì 28:9; bakannáà wo 3 Nephi 28:10).

  28. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 45:3–5.

  29. 3 Nífáì 17:17.

  30. 2 Nephi 9:18.

  31. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Yíyè Ti Ẹ̀mí,” 84.

Tẹ̀