Rírí Ayọ̀ nínú Pípín Ìhìnrere
A ní olufẹni Bàbá ni Ọ̀run, ẹni ti o ndúró dè wá láti kọjú sí I kí O lè bùkún ayé wa ati ayé àwọn tí ó yí wa ká.
Ìkan nínú àwọn orin Alakọbẹrẹ tí mo fẹ́ràn jù bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:
Mo jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn
Mo mọ ẹni tí mo jẹ́.
Mo mọ ètò Ọlọrun
Èmi o tẹ̀lé E nínú ìgbàgbọ́
Mo gbàgbọ́ nínú OlùgbàIà, Jésù Krístì.1
Irú ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn ti o si lẹ́wà fún àwọn òtítọ́ ti a gbàgbọ́!
Àwa bi ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a mọ ẹni tí a jẹ́. A mọ̀ pé “Ọlọrun ni Bàbá àwọn ẹ̀mí wa. Ọmọ Rẹ̀ ... ni wá, àti pé Ó nifẹ wa. A gbé [pẹ̀lú Rẹ̀ ní ọ̀run] ṣíwájú ki a [tó wá] si ilẹ̀ ayé.”
A mọ ètò Ọlọ́run. A wà pẹ̀lú Rẹ̀ bí Ó ti gbé e kalẹ̀. “Gbogbo èrò Bàbá wa Ọ̀run—Iṣẹ́ Rẹ̀ àti ògo Rẹ̀—ni láti mu ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbádùn àwọn ìbùkún Rẹ̀. Ó ... ti pèsè ètò pípé kan fún wa láti ṣe àṣepé èrò Rẹ̀. A ní ìmọ̀ a sì tẹ́wọ́gba ètò yí ... Ti ìdùnnnú, ... Ìràpadà, àti ... Ìgbàlà” ṣíwájú kí a tó wá sí ayé.
“Jésù Krístì jẹ́ ààrin gbùngbùn sí ètò Ọlọ́run. Nípasẹ̀ Ètùtu Rẹ̀, Jésù Krístì mu èrò Bàbá Rẹ̀ ṣẹ, ó sì jẹ́ ki o ṣeéṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti gbádùn àìkú àti ìgbéga. Sátánì, tàbí èṣù, jẹ́ ọ̀tá sí ètò Ọlọ́run” ó sì ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀.
“Agbára láti yàn, tàbí okun láti yàn, ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run títóbi jùlọ sí àwọn ọmọ Rẹ̀. ... A gbọ́dọ̀ yàn bóyá láti tẹ̀lẹ́ Jésù Krístì tàbí Èṣù.”2
Ìwọ̀nyí ni àwọn òtítọ́ tó rọrùn tí a le pín pẹ̀lú àwọ́n míràn.
Ẹ jẹ́ kí nsọ ìgbà kan tí ìyá mi ṣe àbápín irú àwọn òtítọ́ jẹ́jẹ́ nìpa ṣíṣetan láti ní ìbánisọ̀rọ̀ kan àti dídá ànfàní kan mọ̀.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìyá mi n padà sí Argentina fún ìbẹ̀wò pẹ̀lú arákùnrin mi. Ìyá mi ko fẹ́ràn lati fo rárá, nítorínáà o wípé ki ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin mi fún òun ní ìbùkún ìtùnú àti ààbò. O ni ìmọ̀lára lati bùkún ìyá rẹ̀ àgbà bákannáà pẹ̀lú ìtọ́ni àti ìdarí pàtàkì láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ láti fi okun fún àti láti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́-inú láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìhìnrere.
Ni pápákọ̀ òfúrufú Salt Lake, ìyá ati arákùnrin mi pàdé ọmọdébìnrin ọdún méje ti o n padà bọ̀ sí ilé láti ìrìn àjò yìnyín kan pẹ̀lú ẹbí rẹ̀. Àwọn òbí rẹ ṣe àkíyèsí bí o ti pẹ́ tó tí ó ti nbá ìyá àti arákùnrin mi sọ̀rọ̀ wọ́n pinnu láti darapọ̀ mọ́ ọmọbìnrin wọn. Wọ́n júwe ara wọn àti ọmọbìnrin wọn náà bi Eduardo, Maria Susana, àti Giada Pol. Ìsopọ̀ àdánidá àti àtọkànwá wà fun àwọn ẹbí aládùn yi.
Inú àwọn ẹbí méjéèjì dùn láti rin ìrìnàjò papọ̀ lórí ọkọ̀ òfúrufú kannáà lọ si Buenos Aires, Argentina . Bí ìbárasọ̀rọ̀ wọn ti tẹ̀síwájú, ìyá mi ṣe àkíyèsí pé títí di àkókò náà. wọ́n ko ì tíì gbọ́ nípa Ìjọ ti Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò.
Ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí Susana bèèrè ni, “Njẹ́ ẹ o sọ fún mi nípa mùsíọ̀mù rírẹwà pẹ̀lú ère góòlù ni oke?”
Ìyá mi ṣe àlàyé pé ilé rírẹwà náà kìí ṣe mùsíọ̀mù ṣùgbọ́n tẹ́mpìlì Olúwa, níbi tí a ti n dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ki a le padà láti lọ gbé pẹlu Rẹ̀ ni ọjọ́ kan. Susana jẹ́wọ́ fún ìyá mi pé ṣaájú ìrìn-àjò wọn si Salt Lake, òun ti gbàdúrà fun ohun kan tí yío fi okun fún ẹ̀mí rẹ̀.
Nínú ọkọ̀ òfúrufú, ìyá mi jẹ́ ẹ̀rí rẹ̀ tí ó rọrùn ṣùgbọ́n tí ó ní agbára nípa ìhìnrere, ó sì pe Susana láti wá àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ni ìlú rẹ. Susana bèrè lọ́wọ́ ìyá mi, “Báwo ni èmi ó ṣe ri wọn?”
Ìyá mi dáhùn pé, “ O ko lè dárò wọn; wọ́n jẹ́ bóyá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjì nínú ṣẹ́ẹ̀tì funfun ati táì, tàbi àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjì nínú yẹ̀rì, wọ́n si ma nlo táàgì ti o fi orúkọ wọn àti ‘Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn hàn.’”
Àwọn ẹbí náà ṣe pàṣípààrọ̀ nọ́mbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọ́n sì sọ ó dìgbà ní pápákọ̀ òfúrufú ní Buenos Aires. Susana, ẹnití o ti di ọ̀rẹ́ mi rere lati ìgbà náà, ti sọ fún mi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà pé inú rẹ̀ bàjẹ́ lati fi ìyá mi sílẹ̀ ni pápákọ̀ òfúrufú. Ó sọ pé, “Ìyá rẹ dán. Èmi kò lè ṣe àlàyé rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ní ohun dídán kan ti nkò fẹ́ fi sílẹ̀ lẹ́hìn.”
Lọ́gán ti ìyá Susana padà dé ìlú rẹ̀, òun ati ọmọ rẹ, Giada, lọ ṣe àbápín ìrírí yí pẹ̀lú ìyá Susana, ẹni tí ó ngbe ní ibití kò jìnnà púpọ̀ sí ilé wọn. Bí wọ́n ti nwakọ̀, Susana ri àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjì ti wọn nrin lọ ni àdúgbò nínú wíwọ aṣọ bí ìyá mi ti júwe. Ó dá ọkọ̀ rẹ̀ dúró ní àárín àdúgbò, ó jáde, ó sì bèrè lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjì náà, “Njẹ́ ó ṣeéṣe pé láti Ìjọ Jésù Krístì ni ẹ ti wá?”
Wọ́n sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ni.”
“Ẹ̀yin ìránṣẹ́ ìhìnrere?” ó bèrè
Àwọn méjèèjì dáhùn, “Bẹ́ẹ̀ni àwa ni!”
Ó sì wí pé, “Ẹ wọ inu ọkọ mi; ẹ̀ nbọ̀ nílé láti kọ́ mi.”
Oṣù méjì lẹ́hìnnáà, a rì Maria Susana bọmi. Ọmọ rẹ̀, Giada, náà ṣe ìrìbọmi nígbàtí ó pé ọdún mẹsan A ṣì nṣiṣẹ́ lórí Eduardo, ẹni ti a nifẹ bíótiwùkórí.
Látì ìgbà náà, Susana ti di ìránṣẹ́ ìhìnrere nlá jùlọ tí mo ti pàdé rí. Ó dàbí àwọn ọmọ Mòsíà, ní mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí wa sí ọ̀dọ̀ Krístì.
Ninu àwọn ìbánisọ̀rọ̀ wa, mo bi í léèrè pé, “Kinni àṣírí rẹ? Báwo ni o ti nṣe àbápín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?”
Ó sọ fún mi pé, “Ó rọrùn gidi. Ní ojoojúmọ́ ki n tó kúrò ní ilé mi, mo má ngbàdúrà si Bàbá ní Ọ̀run kí Ó darí mi sí ẹnìkan tí ó nílò ìhìnrere ninú ayé wọn. Ìgbàmíràn mo ma nmú Ìwé ti Mọ́mọ́nì dání láti pín pẹ̀lú wọn, tàbí káàdì ìléwọ́ láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere—nígbàti mo ba sì bẹ̀rẹ̀ síí bá ẹnìkan sọ̀rọ̀, mo má nbèrè bóyá wọ́n ti gbọ́ nípa Ìjọ náà.”
Susana tún sọ pé, “Ní àwọn ìgbà míràn mo kàn máa rẹ́rin tí mo ba ti nduro fun ọkọ̀ ojú-irin. Ní ọjọ́ kan ọkùnrin kan wò mí ó sì wí pé, ‘Kínni ò nrẹrin fún?’ O kámi láìrò tẹ́lẹ̀.
Mo dáhùn pé, ‘Mo nrẹrin nitoripe inu mi dùn!’
Ó sì wí pé, ‘Kínni ohun tí ó nmú inú rẹ dùn tó bẹ́ẹ̀?’
“Mo dáhùn pe ‘Ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni èmi, èyí sì nmu inú mi dùn. Njẹ́ o ti gbọ́ nípa rẹ̀?’”
Nígbàtí tí ó sọ pé rárá, ó fún un ni ìwé ìléwọ́ kan, ó sì pè é láti wà ni àwọn ìsìn ti Ọjọ́-Ìsinmi tí ó nbọ̀. Ní Ọjọ́-Ìsinmi tí ó tẹ̀lé, ó kíi ni ẹnu ọ̀nà.
Ààrẹ Dallin H. Oaks ti kọ́ni pé:
“Ohun mẹ́tà wà tí gbogbo àwọn ọmọ ìjọ ní láti ṣe láti ran àbápín ìhìnrere. ...
Àkọ́kọ́, gbogbo wa le gbadura fun ifẹ-inú lati ṣe ìrànlọ́wọ́ ní apákan pataki ti iṣẹ igbala yí.
Ìkejì, a lè pa àwọn òfin mọ́ fúnra ara wa. … Àwọn olõtọ́ ọmọ ìjọ yío fi ìgbà gbogbo ní Ẹ̀mí Olùgbàlà ... pẹ̀lú wọn, láti tọ́ wọn bi wọ́n ṣe nwá láti kópa nínú iṣẹ́ nla ti ṣíṣe àbápín ìhìnrere ti Jésù Krístì tí a múpadà bọ̀sípò.
“Ìkẹ́ta, a lè gbàdúrà fún ìmísí lórí ohun tí a lè ṣe … láti ṣe abápín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn … [àti] láti gbàdúrà pẹ̀lú ìfarasìn láti ṣe ìṣé lórí ìmísí tí ẹ gbà.”3
Ẹ̀yin arákùnrin, ẹ̀yin arábìnrin, ẹ̀yin ọmọ, àti ọ̀dọ́, njẹ́ a le dàbi ọ̀rẹ́ mi Susana ki a sì pín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Njẹ́ a le pe ọ̀rẹ́ kan ti kii ṣe ti igbagbọ wa láti wá si ìjọ pẹ̀lú wa ni Ọjọ́-ìsinmi? Tàbí njẹ́ a le pín Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí kan tàbí ọ̀rẹ́ kan? Njẹ́ a lè ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti wá àwọn bàbá nla wọn lórí Wíwádìí-Ẹbí tàbí ṣe àbápín ohun ti a ti kọ́ ni àárín ọ̀sẹ̀ bí a ti nṣe àṣàrò Wá, Tẹ̀lé Mi? Ṣé a lè dà bíi Olùgbàlà, Jésù Krístì si, kí a sì ṣe àbápín ohun tí ó nmú ayọ̀ wá sínú ayé wa? Ìfèsì sí gbogbo àwọn ìbèèrè wọ̀nyí ni bẹ́ẹ̀ni! Ẹ lè ṣeé!
Nínú àwọn ìwé mímọ́ a kà pé àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ni a rán lọ “láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà fún ìgbàlà ẹ̀mí àwọn ènìyàn’ (Ẹ̀kọ́ and Covenants 138:56). “Iṣẹ́ ìgbàlà yí pẹ̀lú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere ọmọ ìjọ, ìmuduro ọmọ ijọ titun, mímú àwọn tí kò ṣe déédé padà, tẹmpili ati iṣẹ́ iwé ìtàn ẹbi, ati kíkọ́ni ní ìhìnrere.’”5
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, Olúwa nílò wa láti kó Ísráẹ́lì jọ. Nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú Ó ti wípé, “Kí ẹ̀yin máṣe rò ṣíwájú ohun tí ẹ̀yín ọ́ sọ; ṣùgbọ́n ẹ fi pamọ́ bíi ìṣúra sínú ọkàn yín ní gbogbo ìgbà àwọn ọ̀rọ̀ ìyè, a ó sì fi í fún yín ní wákàtí gan an apákan èyítí ẹ ó pín fún olukúlùkù ènìyàn.”6
Ní àfikún, Ó ti ṣelérí fún wa:
“Bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀ pé ẹ̀yin ṣe làálàá ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní kíkígbe ironúpìwàdà sí àwọn ènìyan yìí, tí ẹ̀yin sì mú, bí ó ṣe ọkàn kan péré wá sí ọ̀dọ̀ mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó pẹ̀lú rẹ̀ ní ìjọba Bàbá mi!
Àti nísisìyí, bí ayọ̀ yín yíò bá pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ̀yin mú wá sí ọ̀dọ̀ mi sínú ìjọba Bàbá mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó bí ẹ̀yin bá lè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi!”7
Orin Alákọbẹrẹ ti mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú parí pẹ̀lú kókó ọ̀rọ̀ yi:
Mo gbàgbọ́ nínú OlùgbàIà, Jésù Krístì.
Èmi ó bu ọlá fún orúkọ rẹ̀.
Èmi ó ṣe ohun tí ó tọ́;
Èmi o tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ rẹ.
Òtítọ́ Rẹ̀ ni èmi o polongo.8
Mo jẹri pé àwọn ọrọ wọnyi jẹ otitọ ati pé a ní olufẹni Bàbá ni Ọ̀run, ẹni ti o ndúró dè wá láti kọjú sí I kí O lè bùkún ayé wa ati ayé àwọn tí ó yí wa ká. Ki a le ni ifẹ-inú lati mu àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa wá si ọ̀dọ̀ Krístì ni àdúrà mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín