2010–2019
Ìfọwọ́kàni Olùgbàlà Náà.
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


2:3

Ìfọwọ́kàni Olùgbàlà Náà.

Bí a ṣe nwá sọ́dọ̀ Rẹ̀, Ọlọ́run yíò wá sí ìgbàlà wa, bóyá láti wò wá sàn tàbí láti fún wa ní okun láti dojúkọ ipòkípò.

Ní bíi ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́hìn, Olùgbàlà wá sílẹ̀ látòkè lẹ́hìn kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìdùnnú àti àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ ìhìnrere míràn. Bí Ó ṣe nrìn, ọkùnrin aláìsàn kan pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin náà fun ní ọ̀wọ̀ àti ọlá bí ó ṣe kúnlẹ̀ níwájú Krístì, tó nwá ìrànlọ́wọ́ látinú ìpọ́njú rẹ̀. Jẹ́jẹ́ ni ìbèèrè rẹ̀: “Olúwa, tí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi lára dá.”

Olùgbàlà nígbànáà nawọ́ Rẹ̀, Ó sì fọwọ́ kàn án, Ó wípé, “Èmi ó ṣeé, gba ìmúláradá.”1

A kọ́ níbí pé Olùgbàlà wa nfẹ́ láti bùkún wa nígbogbo ìgbà. Àwọn ìbùkún kan lè wá kíákíá, àwọn míràn le pẹ́ si, àní àwọn kan lè wá lẹ́hìn ayé yí, ṣùgbọ́n àwọn ìbùkún yíò wá ní ìgbà tó bá yá.

Gẹ́gẹ́ bí ti adẹ́tẹ́, a lè rí agbára àti ìtùnú nínú ayé yí nípa títẹ́wọ́gba ìfẹ́ Rẹ̀ àti mímọ̀ pé Òun nfẹ́ láti bùkún wa. A lè rí agbára láti dojúkọ ìpènijà-kípènijà, láti borí àwọn ádánwò, àti láti ní ìmọ̀ àti láti farada àwọn ipò ìṣòro wà. Dájúdájú, nínú àkokò ìtúká gidi nínú ayé Rẹ̀, agbára Olùgbàlà láti farada jìnlẹ̀ si bí Ó ṣe wí fún Bàbá Rẹ̀ pé, “Ìfẹ́ Tìrẹ ni ká ṣe.”2

Adẹ́tẹ̀ náà ko ṣe ìbèèrè rẹ̀ nínú ìdíbọ́n tàbi ìwà ipa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn, pẹ̀lú ìgbìrò gíga ṣùgbọ́n bákannáà pẹ̀lú ìfẹ́ àtinúwá pé ìfẹ́ Olùgbàlà yíó ṣẹ. Èyí ni àpẹrẹ ìwà kan pẹ̀lú èyítí a gbọ́dọ̀ wá sọ́dọ̀ Krístì. A gbọ́dọ̀ wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìfẹ́ Olùgbàlà lọ́wọ́lọ́wọ́ ni àti pé yíò jẹ́ èyí tó darajùlọ fùn ayé ikú wa àti ìyè ayérayé nígbàgbogbo. Ó ní ìgbìrò ayérayé tí a kò ní. A gbọ́dọ̀ wá sọ́dọ̀ Krístì pẹ̀lú ìfẹ́ àtinúwá pé ifẹ́ Bàbá yíò borí ìfẹ́ wa, bí Tirẹ̀ ti ṣe.3 Èyí yíò múra wa sílẹ̀ fún ìyè ayérayé.

Ó le gan an láti ro ẹ̀dùn ọkàn àti ìjìyà ti ara tó bo adẹ́tẹ̀ náà ẹnití ó wá sọ́dọ̀ Olùgbàlà mọ́lẹ̀. Ẹ̀tẹ̀ mbá iṣan àti àwọ̀ ara jà, ó sì nfa àbùkù àti àìpé-ara. Láfikún, ó darí sí ìbákẹ́gbẹ́ àbùkù nlá. Ẹnìkan tí ẹ̀tẹ̀ bá bá jà ní láti fi àwọn àyànfẹ́ wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì lọ gbé ní ibi ìpatì kúrò láwùjọ. Àwọn adẹ́tẹ̀ ní a mọ̀ sí aláìmọ́, níti ara àti níti ẹ̀mí. Fún ìdí èyí, òfin Mósè fẹ́ kí àwọn adẹ́tẹ̀ wọ ẹ̀wù yíya kí wọ́n sì kígbe síta pe “Àìmọ́!” bí wọ́n ti nrìn lọ.4 Aláìsàn àti olùkẹgàn, àwọn adẹ́tẹ̀ nparí sí gbígbé ní àwọn ilé pípatì tàbí àwọn itẹ́ òkús.5 Kò ṣòro láti rò pé adẹ́tẹ̀ náà tí ó dé ọ̀dọ̀ Olùgbàlà tí banújẹ́.

Nígbàmíràn—ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn—àwa bákannáà lè nímọ̀ ìròbìnújẹ́, bóyá nítorí àwọn ìṣe ara tiwa tàbí àwọn ẹlòmíràn, nítorí àwọn ipò tí a lè tàbí tí a kò lè darí. Ní irú àwọn àkokò náà, a lè gbé ìfẹ́ wa sọ́wọ́ Rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, Zulma—ìyàwó mi, ẹnibí-ọkàn mi, ara mi dídarajùlọ—gba àwọn ìròhìn lílè ní ọ̀sẹ̀ méjì ṣíwájú àjọyọ̀ ìgbeyàwó ọ̀kan lára àwọn ọmọ wa. Ó ní àrùn ní abonú rẹ̀, ó sì ndàgbà si gidigidi. Ojú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀sí íwú, ó sì níláti lọ ṣe iṣẹ́ abẹ ẹlẹgẹ́ kan kíákíá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò ní ó nlọ nínú rẹ̀ ó sì tẹ ọkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ṣé ìdàgbà náà lóró? Báwo ni ara rẹ̀ ó ṣe jiná? Ṣé ojú rẹ̀ ó darọ? Báwo ni ìrora rẹ̀ yíò ti le sí? Ṣé ojú rẹ̀ yíò ní àpá títíláé? Ṣé ìdàgbà náà yíò padà lẹ́hìn ìyọkùrò? Ṣé òun yíò lè lọ síbi ìgbeyàwó ọmọkùnrin wa? Bí ó ṣe sùn sí yàrá ìṣẹ́ abẹ, ó ní ìmọ̀lára ìbànújẹ́.

Ní àkokò pàtàkì náà gan an, Ẹ̀mí kùn síi létí pé ó níláti tẹ́wọ́gba ìfẹ́ Bàbá. Nígbànáà ó pinnu láti fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú Ọlọ́run. Ó ní ìmọ̀lára gidi pé ohunkóhun tí àbájádé bá jẹ́, ìfẹ́ Rẹ yíò jẹ́ dídára jùlọ fún òun. Láìpẹ́ o wọnú oorun abẹ lọ.

Lẹ́hìnnáà, ó fi ewì kọ sínú ìwé ìrántí rẹ̀: “Lórí tábìlì alábẹ mo bẹ̀rẹ̀ níwájú Yín, mo sì yọ̀ọ̀da sí ìfẹ́ Yín, mo sùn lọ. Mo mọ̀ pé mo lè gbẹ́kẹ̀lé e Yín, ní mímọ̀ pé kò sí ohun búburú tí ó lè wá látọ̀dọ̀ Yín.”

Ó rí agbára àti ìtùnú látinú ìyọ̀ọ̀da ìfẹ́ rẹ̀ sí ìyẹn ti Bàbá. Níjọ́ náà, Ọlọ́run bùkún rẹ̀ dáadáa.

Eyikeyi tí ipò wa lè jẹ́, a lè lo ìgbàgbọ́ wa láti wá sọ́dọ̀ Krístì kí a sì rí Ọlọ́run tí a lè gbẹ́kẹ̀lé. Bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ mi, Gabriel, ti kọ nígbàkan:

Gẹ́gẹ́bíi ti wòlíì, ojú Ọlọ́run tàn ju òòrùn lọ

àti pé irun Rẹ̀ sì funfun ju yìnyín lọ

ohùn Rẹ̀ nràn bí ìṣàn odò kan,

Ènìyàn kò sì ja mọ́ nkankan lẹgbẹ Rẹ. ...

Àní mo ní ìtúká bí mo ṣe roó pé èmi kò jẹ́ nkankan.

Àti pé nígbànáà nìkan ni mo kọsẹ̀ lọ́nà mi sí ọlọ́run kan tí mo lè gbẹ́kẹ̀lé.

Àti pé nígbànáà nìkan ni mo ṣàwárí Ọlọ́run náà tí mo lè gbẹ́kẹ̀lé.5

Ọlọ́run kan tí a lè gbẹ́kẹ̀lé nmú ìrètí wa gbòòrò ní gbogbo ipò. A lè gbẹ́kẹ̀lé E nítorí Òun fẹ́ràn wa Ó sì nfẹ́ ohun tí ó dárajùlọ fún wa ní gbogbo ipò.

Adẹ́tẹ̀ náà wá síwájú nítorí agbára ìrètí. Ayé kò fun ní àwọn àyọrírí kankan. Báyìí, ìfọwọ́kàn jẹ́jẹ́ Olùgbàlà gbọ́dọ̀ ti dàbí ìtura sí gbogbo ẹ̀mí rẹ̀. A kàn lè ro ìmoore àwọn ìmọ̀lára ìjìnlẹ̀ nìkan tí adẹ́tẹ̀ náà ìbá ti ní ní ìfọwọ́kan Olùgbàlà, nípàtàkì nígbàtí òun gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ “Èmi o´ ṣeé; gba ìwòsàn.”

Ìtàn náà sọ pé “kíákíá ni ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ mọ́.”6

Àwa bákannáà lè ní ìmọ̀lára ìfọwọ́tọ́ni, ọwọ́ ìwòsàn ti olùfẹ́ni Olùgbàlà, Irú ayọ̀, ìrètí, àti mímoore tí ó nwá sínú ẹ̀mí wa ní mímọ̀ pé Òun nfẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti di mímọ́! Bí a ṣe nwá sọ́dọ̀ Rẹ̀, Ọlọ́run yíò wá sí ìgbàlà wa, bóyá láti wò wá sàn tàbí láti fún wa ní okun láti dojúkọ ipòkípò.

Ní ọ̀nàkọnà, títẹ́wọ́gba ifẹ́ Rẹ̀—kìí ṣe tiwa—yíò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ àwọn ipò wa. Kò sí ohun búburú tí ó lè wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó mọ ohun tí ó darajùlọ fún wa. Bóyá Òun ó mú àwọn àjàgà wa kúrò lọ́gán. Nígbàmíràn Ó lè mú kí àwọn àjàgà wọnnì di fífúyẹ́, bí Ó ti ṣe pẹ̀lú Álmà àti àwọn ènìyàn rẹ̀.7 Nígbẹ̀hìn, nítorí àwọn májẹ̀mú wa, àwọn àjàgà náà yíò di gbígbé kúrò,8 bóyá ní ayé yí tàbí ní Àjíìnde mímọ́.

Ìfẹ́ àtinúwá kan pé kí ifẹ́ Rẹ̀ ṣẹ, lẹgbẹ pẹ̀lú ìmọ̀ nípa ìwàẹ̀dá tọ̀run Olùràpadà wa, nṣèrànwọ́ láti mú wa gbèrú irú ìgbàgbọ́ tí adẹ́tẹ̀ fihàn ní èrò láti gba wẹ̀nùmọ́. Jésù Krísti ni Ọlọ́run ifẹ́, Ọlọ́run ìrètí, Ọlọ́run ìwòsàn. Ọlọ́run ẹnití ó nfẹ́ láti bùkún wa àti láti ranwálọ́wọ́ láti di mímọ́. Ìyẹn ni ohun tí Òun nfẹ́ ṣíwájú wíwá sí ilẹ̀ ayé nígbàtí Ó yọ̀ọ̀dà láti gba wá là nígbàtí a bá ṣubú sínú ìrékọjá. Ìyẹn ni ohun tí Ó fẹ́ nínú Gẹ́tsémáni nígbàtí Ó dojúkọ ìrora àìlóye ti ènìyàn nínú ìnira ti sísan oye ẹ̀ṣẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí Ó fẹ́ báyi nígbàtí ó nbẹ̀bẹ̀ ní ìtìlẹhìn wa níwájú Bàbá.9 Ìyẹn ni ìdí tí ohùn Rẹ̀ fi ndúnrara síbẹ̀: “Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yóò sì fi ìsinmi fún yín”4

Ó lè wò wá sàn kí ó sì gbé wá sókè nítorí Òun ní agbára láti ṣe é. Ó gbé gbogbo ìrora ara àti ẹ̀mí lé orí Ara rẹ̀ kí inú Rẹ̀ lè kún fún ìyọ́nú ní èrò láti lè rànwálọ́wọ́ nínú ohun gbogbo àti láti wò wá sàn àti láti gbé wa ga.11 Àwọn ọ̀rọ̀ Ísáíàh, bí a ti kọ nípasẹ̀ Ábínádì, gbé kalẹ̀ dáadáa àti ní wíwúnilórí:

“Dájúdájú ó ti faradà ìbànújẹ́ wa, ó sì ti gbé ìrora-ọkàn wa. ...

“... A ṣá lọ́gbẹ́ nítorí ìrékọjá wa, a pã lára nítorí àìṣedẽdé wa; ìbáwí àlãfíà wa wà lára rẹ̀, àti nípa nínà rẹ̀ ni a fi mú wa lára dá.”12

Iru ìgbìrò kannáà ni a kọ́ nínú ewì yí:

“Óò Kápẹ́ntà ti Násárẹ́tì,

Ọkàn yí, tí ó níròbìnújẹ́ kọjá àtúnṣẹ.

Ayé yí, tí ó bàjẹ́ dé ojú ikú,

Óò, ṣe Ẹ lè tún wọ́n ṣe, Kápẹ́ntà?”

Àti pé nípasẹ̀ inúrere àti ọwọ́ nínà Rẹ,

Ayé dídùn Rẹ̀ ní ó wémọ́

Ìròbìnújẹ́ ayé wa, títí tí wọ́n fi dúró

Ìṣẹ̀dá Titun Kan—“gbogbo ohun titun.”

“[Ohun] ìfọ́nká ti ọkàn [náà],

Ìfẹ́, ìlépa, ìrètí, àti ìgbàgbọ́,

Tí a mọ sí ara pípé,

“Óò Kápẹ́ntà ti Násárẹ́tì!”13

Tí ẹ bá nímọ̀lára pé ní ọ̀nàkọnà ẹ kò mọ́, tí ẹ bá nímọ̀lára ìròbìnújẹ́, ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé ẹ lè di mímọ́, ẹ lè di àtúnṣe, nítorí Ó nifẹ yín. Ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé kò sí ohun búburú tí ó lè wá látọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Nítorí Ó “sọ́kalẹ̀ kọjá ohun gbogbo,”14 Ó mu ṣeéṣe fún ohun gbogbo tí ó ti bàjẹ́ nínú ayé wa láti di títúnṣe, àti pé báyi a lè làjà pẹ̀lú Ọlọ́run. Nípa Rẹ̀ ni ìlàjà ohun gbogbo, àwọn ohun tó wá nílẹ̀ ayé àtì àwọn ohun tó wà lọ́run méjèèjì, nmú àláfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ti àgbélèbú rẹ̀.”15

Ẹ jẹ́ kí a wá sọ́dọ́ Krístì, kí a gbé gbogbo ìṣísẹ̀ tó ṣeéṣe. Bí a ti nṣeé, njẹ́ kí ìwà wa jẹ́ ọ̀kan tó wípé, “Oluwa, tí ìwọ bá fẹ́, o lè wò mí sàn.” Tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè gba ìfọwọ́kàni ìwòsàn Ọ̀gá, lẹgbẹ ìró adùn ti ohùn Rẹ̀: “Èmi ó ṣeé; gba ìwòsàn.”

Olùgbàlà jẹ́ Ọlọ́run kan tí a lè gbẹ́kẹ̀lé. Òun ni Krístì, Ẹni Àmìn Òróró, Mèsíàh, ẹnití mo jẹ́ ẹ̀rí ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀, àní Jésù Krístì, àmín.