Olùfẹ́ àwọn Ọmọbìnrin
Ní ọkán gbogbo ohun tí à nṣe nínú Ọ̀dọ́mọbìnrin ni ìfẹ́ wa láti ràn yín lọ́wọ́ láti jèrè ìgbàgbọ́ àìmìkan nínú Olúwa Jésù Krístì.
Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ó jẹ́ ayọ̀ kan láti wà pẹ̀lú yín! Àwa njẹri ìtújáde ti ìfihàn kan tí ó jẹ́ ọkàn nínà àti gbígbọ̀n.
Bí a ti bẹ̀rẹ̀, màá fẹ́ láti fi àwọn ọ̀rẹ́ kan hàn yín; wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀, àṣà, àti olúkúlùkù àti ibi ẹbí rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, bíi gbogbo yín, ti gba ọkàn mi.
Ní àkọ́kọ́, ẹ pàdé Bella. Ó dúró ṣinṣin bí ọ̀dọ́mọbìnrin kan ṣoṣo ní ẹ̀ka rẹ ní Iceland.
Ẹ pàdé Josephine olùfọkànsìn láti Áfríkà, ẹnití ó tún padà sí ṣíṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójojúmọ́. Ó nṣe àwárí agbára àti àwọn ìbùkún tí ó wá láti ìṣe jẹ́jẹ́, àti olódodo yi.
Àti ní ìparí, ẹ pàdé Ashtyn, ọ̀dọ́mọbìnrin àràọ̀tọ̀ kan ẹni tí o kọjá lọ lẹyin ìjàkadì ọdún mẹ́fà kan pẹ̀lú àrùn jẹjẹrẹ. Ẹ̀rí alágbára Ẹ̀tùtù ti Jésù Krístì rẹ̀ ṣì ndún ní ọkàn mi.
Gbogbo yín jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ní àpẹrẹ. Ẹ jẹ́ àràọ̀tọ̀, ìkọ̀kan pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ àti àwọn ìrírí síbẹ̀ bákanáà ni àwọn ọ̀nà pàtàkì àti ayérayé.
Ẹ jẹ àwọn ọmọbìnrin ẹ̀mí ti àwọn Òbí Ọ̀run, kò sí ohun tí ó lè yà yín nínú ìfẹ́ Wọn àti ìfẹ́ ti Olùgbàlà yín.1 Bí ẹ ti nsún mọ́ Ọ, àní bí ìgbésẹ̀ kékeré bí ọmọ ọwọ síwájú, ẹ ó ri àláfíà pípẹ́ tí yíò sọ̀kalẹ̀ sí ọkàn yín gẹ́gẹ́bí olóòótọ́ ọmọ ẹ̀hìn ti Olùgbàlà, Jésù Krístì.
Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ wípé kí nṣe àbápín ìmísí àtúnṣe tí yíò ràn yín lọ́wọ́ “mu agbara mímọ́ ti araẹni [rẹ] dàgbàsókè”2 kí o sì mú ipa òdodo rẹ pọ̀si. Mo ma sọ̀rọ̀ nípa ọ̀na àtúnṣe mẹrin ní alẹ́ yi.
Àkòrí Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin
Ní àkọ́kọ́, kókó ohun tí a nṣe ní ọ̀dọ́mọbìnrin ni ìfẹ́ wa láti ràn yín lọ́wọ́ láti jèrè ìgbàgbọ́ aláìyẹsẹ̀ nínú Olúwa Jésù Krístì3 àti ìmọ̀ kan tó dájú nípa ìdánimọ́ yín ti tọ̀run gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin Ọlọ́run.
Ní alẹ́ yi, mo má nifẹ láti kéde àtúnṣe sí Àkòrí Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin. Mo gbàdúrà ẹ ó ni ìmọ̀lára ìjẹ́ri Ẹ̀mí Mímọ́ sí òtítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bí mo ti nsọ àkòrí tuntun náà:
Mo jẹ́ olùfẹ́ ọmọbìnrin ti àwọn obí ọrun,4 pẹ̀lú ìwà ẹ̀dá àtọ̀runwá àti àyànmọ ayérayé .5
Gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì,6 Mo ngbìyànjú láti dàbí Rẹ̀.7 Mo wá láti ṣe ìṣe lórí ìfihàn araẹni8 àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn míràn ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀.9
Èmi yíò dúró bí ẹlẹri kan ti Ọlọ́run ni gbogbo ìgbà àti ohun gbogbo àti níbi gbogbo.10
Bí mo ṣe ngbìyànjú làti ṣe déédé fún ìgbéga,11 Mo ṣìkẹ́ ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà12 àti láti wá láti ṣàtúnṣe ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.13 Pẹ̀lú ìgbàgbọ́,14 Èmi yíò fún ilé àti ẹbí mi ní okun,15 ṣe àti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́,16 àti láti gba àwọn ètò17 àti àwọn ìbùkún ti tẹ́mpìlì mímọ́.18
Kíyèsí ìyípadà láti “àwa” sí “Èmi”. Àwọn òtítọ́ yi wáyé fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín. O jẹ́ Olùfẹ́ Ọmọbìnrin kan ti àwọn Òbí Ọrun. O jẹ́ ọmọ ẹ̀hìn májẹ̀mú kan ti Olùgbàlà, Jésù Krístì. Mo pè yín láti kà àti láti ṣe àṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Mo mọ̀ wípé bí ẹ ti ṣe, ẹ ó jèrè ẹ̀rí àwọn òtítọ́ wọn. Níní òye àwọn òtítọ́ yi yíò yi bí ẹ ti ndojúkọ àwọn ìpèníjà padà. Mímọ ìdánimọ̀ yin àti ìdí máa ràn yín lọ́wọ́ láti pa ìfẹ́ yín pọ̀ mọ́ ti Olùgbàlà.
Àláfíà àti ìtọ́sọ́nà yìó jẹ́ tiyín bí ẹ ti ntẹ̀lé Jésù Krístì.
Àwọn kílásì Àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin
Ibi àtúnṣe kejì kan kíláàsì Àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin. Alàgbà Neal A. Maxwell sọ, “Ní ìgbàgbogbo ohun tí àwọn ènìyàn nílò púpọ̀ ni láti wà ni ìfipamọ́ kúrò ní àwọn ìjì ti ìgbésí ayé ni ibi mímọ́ ti jíjẹ́.”19 Àwọn kílásì wa gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn ibi mímọ́ kúrò ní ìjì, àwọn àyè tó ni àbò ìfẹ́ àti jíjẹ́. Ní ipá wa láti ṣe ìsopọ̀ gíga, fún àwọn ọ̀rẹ́ ní okun, àti fífikún ìmọ̀lára jíjẹ́ laarin àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, à nṣe àwọn àtúnṣe si ètò kílásì.
Fún ọgọrun ọdún o le, a ti pín àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin sí àwọn kílásì mẹta. Bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a pe àwọn adarí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin àti àwọn bíṣọ́pù láti fi àdúrà wòye ìnílò ọ̀dọ́mọbìnrin kọ̀ọ̀kan kí wọ́n sì ṣètò wọn pẹ̀lú ọjọ́ orí gẹ́gẹ́bí àwọn àyídàyídà wọ́ọ̀dù pàtó. Níbí ni àwọn àpẹrẹ bí yìó ṣe rí.
-
Tí ẹ bá ní àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin díẹ̀, ẹ lè ni kílásì àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin pẹ̀lú gbogbo wọn pípàdé papọ̀.
-
Bóyá ẹ ní ẹgbẹ́ nla kan ti àwọn ọdọ́mọbìnrin ọdún mejila àti lẹ́hìnna ẹgbẹ́ kékeré àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí o dàgbà. Ẹ lè pinnu láti ní kílásì méjì: Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin ọdún mejila àti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin ọdún mẹtala de ọdún méjìdínlógún.
-
Tàbí tí ẹ bá ni wọ́dù nlá pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọgọta ti nwa, ẹ lè ní kílásì mẹ́fà, ọ̀kan fún ọjọ́ orí kan, ṣíṣètò gẹ́gẹ́bí ọdún.
Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn kílásì yín ni ètò, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin jẹ́ pàtàkì ni kíkọ́ ìṣọ̀kan. Ẹ jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní àyíká yín. Ẹ jẹ́ orísun ìfẹ́ àti ìtọ́jú tí ẹ nretí láti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Pẹ̀lú àdúrà ní ọkàn yin, ẹ túnbọ̀ ma tẹ̀síwájú láti ma jẹ́ ipa fún rere. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, ayé yín yíò kún fún inúrere. Ẹ o ni ìmọ̀lára dáradára sí àwọn míràn ẹ ó sì bẹ̀rẹ̀ síí rí ojúrere wọn ní àbọ̀ rẹ̀.
Àwọn Orúkọ Kílásì Àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin
Ìkẹ́ta, pẹ̀lú àkójọ kílásì tuntun yí, gbogbo kílásì yíò di pípè ni orúkọ ìsọdọ̀kan “Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin.”20 A kò ní fi àwọn orúkọ Beehive, Mia Maid, and Laurel pe wọ́n mọ́.
Fífún àwọn Ààrẹ Kílásì ní okun
Abala ìparí tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ni pàtàkì àwọn ààrẹ kílásì. Bí ó ti wù kí á ṣètò àwọn kílásì Àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin, kílásì kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ ni ààrẹ!21 Ìmọ̀ ti ọ̀run ni wípé kí á pe àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin láti darí ọ̀dọ́ wọn.
Ojúṣe àti èrò kíláàsì àwọn àjọ ààrẹ ni a ti fún lókun tí a sì fihàn yékéyéké. Iṣẹ́ ìgbàlà ni ọ̀kan lára àwọn ojúṣe pàtàkì wọ̀nyí, nípàtàkì ní àwọn ibi ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, iṣẹ́ ìhìnrere, aápọn, àti tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ ìwé-ìtàn ẹbí.22 Bẹ́ẹ̀ni, èyí ni bí a ó ti kó Ísráẹ́lì jọ23—iṣẹ́ ológo kan fún gbogbo ọ̀dọ́mọbìnrin bí ọmọ ẹgbẹ́ ogun ọ̀dọ́ Olúwa.
Bí ẹ ti mọ̀, ní gbogbo ipele ti Ìjọ, Olúwa pe àwọn àjọ ààrẹ láti darí àwọn ènìyàn Rẹ̀. Ẹ̀yin Ọ̀dọ́mọbìnrin, jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ààrẹ kílásì le jẹ́ ànfàní àkọ́kọ́ láti kópa ni ìlànà ìmísí ìdarí. Ẹ̀yin àgbà olúdarí, ẹ fi pípe àwọn ààrẹ kílásì ṣe pàtàkì kí ẹ sì máa darí ní ẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú wọn, ni ìdámọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà wọn kí wọ́n lè ṣe àṣeyọrí.24 Ohunkóhun yó wu kí ipele ìrírí ìdarí ààrẹ kílásì kán ní, ẹ bẹ̀rẹ̀ níbi tí wọ́n wa kí ẹ si ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìdàgbàsókè àwọn iṣẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí yio bùkún wọn gẹ́gẹ́bí olùdarí. Ẹ sún mọ́ wọn, ṣùgbọ́n ẹ máṣe gbagbára. Ẹ̀mí yìó tọ yin sọ́nà bí ẹ ṣe ntọ wọn sọ́nà.
Láti ṣe àpèjúwe ipa pàtàkì àwọn òbí àti olùdarí bí àwọn onímọ̀ràn, ẹ jẹ́ ki nsọ ìtàn kan fún yin. A pe Chloe láti sìn bi ààrẹ kílásì. Ọlọ́gbọ́n olùdarí oyèàlúfà gba nímọ̀ràn láti wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa ní fífi orúkọ silẹ fún àjọ ààrẹ. Chloe gbàdúra ó sì gba ìmísí nípa ẹni tí yio fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn olùdámọ̀ràn ní kíákíá. Bí ó ti ntẹ̀síwájú láti ronú àti láti gbàdúrà nípa akọ̀wé kan, Ẹ̀mí fi léraléra pe àkíyèsí rẹ̀ sí ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí ó yàá lẹ́nu—ẹni ti kìí fi bẹ wa si ìjọ tàbi àwọn ìdárayá ìjọ.
Níní ìmọ̀lára àìnífọ̀kànbalẹ̀ ìmísí naa, Chloe bá ìyá rẹ̀ sọ̀rọ̀, ẹnití ó ṣe àlàyé wípé ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí a le fi gba ìfihàn ni nípa àwọn èrò tí ó nwá léraléra. Pẹ̀lú àtúnṣe ìgbẹ́kẹ̀lé, Chloe ní ìmọ̀lára wípé kí ó fi ọ̀dọ́mọbìnrin yi sílẹ̀. Bíṣọ́pù nawọ́ ìpè náà, ọ̀dọ́mọbìnrin náà si gbà. Lẹ́hìn tí a yàá sọ́tọ̀, akọ̀wé dídùn yí sọ pé, “Ẹ mọ, èmi kò ní ìmọ̀lára rí bí ẹnipé mo ní àyè tàbí a nílò mi níbikíbi. Mi ò ní ìmọ̀lára wípé mo bámu. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìpè yí, Mo ní ìmọ̀lára bí ẹni pé Bàbá Ọ̀run ní ìdí àti ibìkan fún mi.” Bí Chloe àti ìyá rẹ ti fi ìpàdé sílẹ̀, Chloe kọjú sí ìyá rẹ̀ pẹ̀lú omijé lójú rẹ wípé, “Ìfihàn dájú! Ìfihàn nṣiṣẹ́ gidi!”
Ẹ̀yin Àjọ Ààrẹ Kílásì, Ọlọ́run ti pè yín ó sì jẹri yín láti darí àjọ àwọn ọmọbìnrin Rẹ̀. “Olúwa mọ̀ yín. … Ó yàn yín.”25 A ti yà yín sọ́tọ̀ láti ọwọ́ ẹni tí ó ni àṣẹ oyèàlúfà; èyí túmọ̀ sí pé bí ẹ ti nṣe àwọn ojúṣe ipè yín, ẹ̀ nlo ipá àṣẹ oyèàlúfà. Ẹ ní iṣẹ́ pàtàkì kan láti ṣe. Ẹ ní ìfura láti àti ní ìṣe lórí àwọn ìṣílétí ti Ẹ̀mí Mímọ́. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lè sìn pẹ̀lú ìgboyà, nítorí ẹ ko dánìkan sìn!
Ẹ̀yin ààrẹ kílásì, a nílò ọgbọ́n yín, ohùn, àti agbára lórí ìgbìmọ̀ ọ̀dọ́ wọ́ọ̀dù tuntun tí Alàgbà Quentin L. Cook polongo loni. Ẹ jẹ́ ipa pàtàkì lára àtúnṣe sí bíbá àwọn àìní àwọn arákùnrin àti arábìnrin pàdé.26
Àwọn ìyípadà nínú ìṣètò kílásì àti ìdarí lè bẹ̀rẹ̀ ni kété tí àwọn wọ́ọ̀du àti ẹ̀ka bá ti ṣe tán ṣùgbọ́n kí ó ti wà ní ètò ní Ọjọ́ Kinni Oṣù Kinni, 2020.
Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, Mo jẹri wípé àwọn àtúntò tí mo sọ̀ nípa rẹ̀ loni jẹ ìtọ́sọ́nà tí ó ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí a ti nfi aápọn mú àwọn àtúntò wọ̀nyí lo, kí a máṣe gbàgbé èrò wa; láti mú ìpinnu láti tẹ̀lé Jésù Krístì àti láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti wa sọ́dọ̀ Rẹ̀ ṣẹ. Mo jẹ́ri pé èyí ni Ìjọ Rẹ̀. Bí mo ṣe ní ìmoore to wípé O gbàmí láyè láti jẹ́ kó ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀.
Mo gbàdúrà wípé Ẹ̀mi kan naa ti o darí àtúntò wọ̀nyí yio darí yín bi ẹ ti ntẹ̀síwájú nínú ipa májẹ̀mú. Mo jẹ̀ri bẹ́ẹ̀ ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.