2010–2019
Nínú Ìkukù àti Òòrùn, Olúwa, Bá Mi gbé!
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Nínú Ìkukù àti Òòrùn, Olúwa, Bá Mi gbé!

Mo jẹri pé “nínú ìkukù àti òòrùn” Olúwa yíò bá wa gbé, kí ayọ̀ Krístì [lè] gbé àwọn ìpọ́njú wa mi.”

Ọ̀kan lára àwọn orin alárinrin fi ẹ̀bẹ̀ náà hàn “Nínú ìkukù àti òòrùn, Olúwa, bá mi gbé hàn!”1 Mo ti wà nínú ọkọ̀-òfúrufú nígbàkan bí ó ṣe ndébi ìjì nlá kan. Wíwo ìta látibi fèrèsé, mo lè rí ìkukù ìbora nlá kan ní ìsàlẹ wa. Ìtànná òòrùn tó sọ̀kalẹ̀ hàn níbi ẹ̀gbẹ́ ìkukù, ó mú kí wọ́n tàn pẹ̀lú ìtànṣán líle. Láìpẹ́, bákannáà, ọkọ̀ òfúrufú náà sọ̀kalẹ̀ nínú ìkukù líle, òkunkùn nlá bò wá mọ́lẹ̀ lọ́gán tí ó fọ́ wa lójú pátápátá sí ìmọ́lẹ̀ líle náà tí a ti jẹri ní àkokò tí kò pẹ́ ṣíwájú.2

Ìtànṣán ìgbèkalẹ̀ òòrùn
Òkuùkù Dúdú

Bákannáà àwọn ìkukù lè wá sínú ayé wa, Èyí tí ó lè fọ́ wa lójú sí ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run àní kí ó múwa bèèrè tí ìmọ́lẹ̀ náà bá wà láyé fún wa lẹ́ẹ̀kansi. Díẹ̀ lára àwọn ìkukù wọnnì jẹ́ ìrẹ̀wẹ̀sì, àníyàn, àti àwọn ohun ọpọlọ àti ìpọ́njú ẹ̀dùn ọkàn. Wọ́n lè da ọ̀nà tí a ti rírawa rú, àwọn ẹlòmíràn, àní Ọlọ́run. Wọ́n mú àwọn obìnrin àti ọkùnrin lọ́kàn ní ọjọ́ orí gbogbo ní gbogbo igun mẹ́rin àgbáyé.

Bákannáà ìparun ni títú ìkukù náà ká nípa ìdájọ́ tàbí iyèméjì tí ó lè kan àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n kò ní ìrírí àwọn ìpènijà wọ̀nyí. Bí ẹ̀yà ara kan, ọpọlọ jẹ́ ìsọ̀mgbè sí àwọn ààrùn, ìdágìrì, àti àìpé ti òògùn-olóró. Nígbàtí iyenu wa njìyà, ó wà ní ìbámu láti wá ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, látọ̀dọ̀ àwọn wọnnì ní àyíká wa, àti látọ̀dọ̀ àwọn olóye ìlera egbòògi àti ọpọlọ.

“Gbogbo ẹlẹ́ran-ara—ọkùnrin àti obìnrin—ni a dá ní àwòrán Ọlọ́run. Ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ àyànfẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin ẹ̀mí àwọn òbí Ọ̀run, àti pé ... ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìwà-àbínibí tọ̀run àti àyànmọ́.”3 Bíiti àwọn Obí Ọ̀run àti Olùgbàlà wa, a ní ẹran ara4 àti ìrírí àwọn ẹ̀dùn ọkàn.5

Ẹyin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ó jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láti ní ìmọ̀lára ìbànújẹ́ tàbí dàmú nígbà kọ̀ọ̀kan. Bíbanújẹ́ àti àníyàn jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn àbínibí ènìyàn.6 Bákannáà, tí a bá nbanújẹ́ léraléra tí ìrora wa sì ndí okun wa láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ti Bàbá wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀ àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́, nígbànáà a lè máa jìyà látinú ìrẹ̀wẹ̀sì, àníyàn, tàbí ipò ẹ̀dùn ọkàn míràn.

Ọmọbìnrin mi fìgbàkan kọ pé: “Ìgbà kan wà ... [Nígbàtí] Mo banùjẹ jùlọ ní gbogbo ìgbà. Mo fìgbà gbogbo lérò pé bíbanújẹ́ jẹ́ ohunkan lati tini lójú, àti pé ó jẹ́ àmì kan nìpa àìlera. Nítorínáà mo pa ìbánújẹ́ mi mọ́ fúnrami. ... Mo nímọ̀lára àìwúlò pátápátá.”7

Ọ̀rẹ́ kan ṣàpèjúwe rẹ̀ ní ọ̀nà yí: “Látìgbà èwe mi, mo dojúkọ ìjà kan léraléra pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára àìnírètí, òkùnkùn, àdánìkanwà, àti ẹ̀rù àti ọgbọ́n pé mo nírẹ̀wẹ̀sì tàbí aìpé. Mo ṣe ohungbogbo láti fi ìrora mi pamọ́ ṣùgbọ́n ntiraka àti nínú agbára.”8

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnìkẹ́ni lára wa—ní pàtàkì nígbàtí, bí onígbàgbọ́ nínú ètò ìdùnnnú, a gbé àwọn àjàgà àìṣeéṣe lé orí ara wa ní ríronú pé a nílò láti jẹ́ pípé báyìí. Irú àwọn èrò náà lè bonibọ́lẹ̀. Ṣíṣe àṣeyọrí pípé ni ètò kan tí yíò ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé ikú wa àti ìkọjá—àti pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì nìkan ni.9

Ní ìlòdì, ìgbàtí a bá lanu nípa ẹ̀dùn ọkàn àwọn ìpènijà wa, gbígbà pé a kò pé, a nfún àwọn ẹlòmíràn ní àyè láti ṣe àbápín ìlàkàkà wọn. Lápapọ̀ a damọ̀ pé ìrètí wà àti pé a kò ní láti dá jìyà.10

Ìrètí nínú Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì

Bí àwọn ọmọléhìn Jésù Krístì, a ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run pé a “nfẹ́ láti gbé àjàgà ara wa” àti “láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n nṣọ̀fọ̀.”11 Gbígbà àti ṣíṣọ̀fọ̀ lè pẹ̀lú dída olóye nípa ẹ̀dùn ọkàn àwọn aláìsàn, wíwá àwọn ohun èlò tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìlàkàkà wọ̀nyí, àti nígbẹ̀hìn mímú arawa àti àwọn ẹlòmíràn wá sọ́dọ̀ Krístì.12 Àní tí a kò bá mọ̀ bí a ṣe lè bá àwọn ẹlòmíràn tí ó wà nínú èyí lo, mímọ̀ lódodo pé ìrora wọn jẹ́ òtítọ́ lè jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ní wíwá ìmọ̀ àti ìwòsàn.13

Ní àwọn ọ̀ràn díẹ̀, èrèdí ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àníyàn ní a lè dámọ̀, ní àwọn ìgbà míràn ó lè ṣòro láti lóye.14 Àwọn ọpọlọ wa lè jìyà nítorí wàhálà15 tàbí ìtagàgà àárẹ̀,16 èyí lè fìgbàmíran mú àtúnṣe wá nínú oúnjẹ, oorun, àti ìdárayá. Nígbàkugbà, ìtora tàbí egbogi lábẹ́ ìdarí àwọn amòye tí a kọ́ bákannáà lèjẹ́ ìnílò.

Àwọn àbájáde àìwòsàn ọpọlọ tàbí ààrùn ẹ̀dùn ọkàn lè di píparun, ní ìdarí sí àlékún ìpatì, àwọn àṣìmọ̀, ìbáṣepọ̀ tó kùnà, ìpalára-araẹni, àní àti ìparaẹni. Mo mọ̀ ní ọwọ́kan, bí bàbá mi ṣe kú nípa ìparaẹni lọ́pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn. Ikú rẹ̀ jọ́ ìdágìrì àti ìroraọkàn fún ẹbí mi àti èmi. Ó ti gbà mí ní ọ̀pọ̀ ọdún láti ṣiṣẹ́ lórí ọ̀fọ̀ mi, àti pé ní àìpẹ́ nìkan ni mo kọ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ìparaẹni ní àwọn ọ̀nà tótọ́ dájúdájú nrànwálọ́wọ́ láti dẹ́kun rẹ̀ sànju láti gbàá níyànjú.17 Báyìí mo ti sọ̀rọ̀ ikú bàbá mi ní gbangba pẹ̀lú àwọn ọmọ mi àti pé mo ti nní ẹ̀rí ìwòsàn tí Olùgbàlà lè fúnni ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú.18

Tìbànújẹ́tìbànújẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tó njìyà látinú ìrẹ̀wẹ̀sì mú ara wọn jìnà síra látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ wọn nítorí wọ́n nímọ̀lára pé wọ́n ṣe ní àìbámu àwọn àwòrán nkan tí wọ́n mọ. A lè ràn wọ́nlọ́wọ́ láti mọ̀ àti láti nímọ̀lára pé wọ́n wà pẹ̀lú wa lódodo. Ó ṣe pàtàkì láti damọ̀ pé ìrẹ̀wẹ̀sì kìí ṣe àyọrísí àìlera, tàbí kò máa nfìgbàmíràn jẹ́ àyọrísí ẹ̀ṣẹ̀.19 Ó “ngbèrú ní ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ó ndínkù ní ìyọ́nú.”20 Lápapọ̀, a lè já nínú àwọn ìkukù ìpatì àti àlẹ̀mọ́ kí àjàgà ẹ̀sín lè kúrò kí àwọn ìwòsàn ìyanu lè ṣẹlẹ̀.

Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ ayé ikú rẹ̀, Jésù Krístì wo aláìsàn àti onírora sàn, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ kí wọ́n sì ṣe ìṣe ní èrò láti gba ìwòsàn Rẹ̀. Àwọn kan rìn fún ibi jínjìn, àwọn ẹlòmíràn nawọ́ wọn láti fi kan ẹ̀wù Rẹ̀, àti pé a níláti gbé àwọn míràn sọ́dọ̀ Rẹ̀ láti gba ìwòsàn.21 Nígbàtí ó di wíwòsàn, njẹ́ gbogbo wa kò ha nílò Rẹ̀ taratara bí? “Ṣe gbogbo wa kọ́ ni Alágbe bí?”22

Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé ipa ọ̀nà Olùgbàlà kí a ní àlékún àánú, dínkù nínú ipá láti dájọ́, àti dídúró ní àbẹ̀wò ti ẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn. Ní irú àkokò bẹ́ẹ̀, a lè lágbára láti ṣèrànwọ́ láti gbé tàbí ti àwọn ìkukù wúwo sókè tí ó nfún àwọn olùfẹ́ni wa àti àwọn ọ̀rẹ́ pa23 nítorí nípa, ìfẹ́ wa, kí wọ́n lè nímọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́ lẹ́ẹ̀kansì àtì láti nímọ̀ ìmọ́lẹ̀ tí ó nwá látọ̀dọ̀ Jésù Krístì.

Tí ẹ bá nwà ní àyíká “òkùnkùn biribiri,” léraléra23 ẹ yípadà sí Bàbá Ọ̀run. Kò sí ìrírí kankan tí ẹ ti ní rí tí ó lè yí òtítọ́ ayérayé padà pé ẹ jẹ́ ọmọ Rẹ̀ àti pé Ó fẹ́ràn yín.24 Ẹ rántí pé Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà yín, àti pé Ọlọ́run ni Bàbá yín. Wọ́n ní ìmọ̀. Ẹ wo àwòrán Wọn nítòsí yín, fífetísílẹ̀ àti fífi àtìlẹhìn fúnni.25 “[Wọn] yíò pàrọwà síi yín nínú àwọn ìpọ́njú yín.”26 Ṣe gbogbo yín lè ṣeé, kí ẹ sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú oore-ọ̀fẹ́ ètùtù Olúwa.

Ìlàkàkà yín kò fi yín hàn, ṣùgbọ́n wọ́n lè túu yìn ṣe.28 Nítorí ti “ẹ̀gún kan nínú ara,”29 ẹ lè ní okun láti ní ìmọ̀lára àánú si síwájú àwọn ẹlòmíràn. Bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ntọnisọ́nà, ẹ ṣe abápín ìtàn yín ní èrò láti “tu aláìlera lára, gbé ọwọ́ èyí tó relẹ̀ sókè, àti láti fún eékún àìlera lókun.”30

Fún àwọn wọnnì lára wa tí wọ́n nlàkàkà tàbí ṣàtìlẹhìn ẹnìkan tí ó nlàkàkà, ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ tẹ́lé àwọn òfin Ọlọ́run ki a lè fìgbàgbogbo ní Ẹ̀mí Rẹ̀ pẹ̀lú wa.31 Ẹ jẹ́ kí a ṣe “àwọn ohun jẹ́jẹ́ àti kékèké”32 tí yíò fún wa ní okun ti ẹ̀mí. Bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ: “Kò sí ohun tí ó nṣí ọ̀run bíti àpapọ̀ àlékún ìwàmímọ́, ìgbọràn déédé, ìtẹramọ́ ìwákiri, ṣíṣe àpèjẹ ojoojúmọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì nínú Ìwé Mọ́mọ́nì, àti fífi àkokò ìfarasìn sí tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ ìwé ìtàn ẹbí.”33

Wíwonisàn Olùgbàlà

Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa rántí pé Olùgbàlà, Jésù Krístì, “[ti gbé] àìlera [wa] lé orí rẹ̀, kí inú rẹ̀ lè kún fún àánú, bí ẹlẹ́ran ara, kí ó lè … tù [wá] nínú bí àìlera [wa] ṣe tó.”34 Ó wá “láti so ọkàn oníròbìnújẹ́ pọ̀, ... Láti tu àwọn tó nṣọ̀fọ̀ nínú; .. Láti fi ẹ̀wà fún eérú, òróró fún ọ̀fọ̀, èwù ìyìn fún ẹ̀mí wúwo.”34

Ìpadabọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì

Mo jẹ́ ẹ̀rí síi yín pé nínú ìkukù àti òòrùn Olúwa yíò bá wa gbé, kí “ayọ̀ wa nínú Krístì [lè] gbé ìpọ́njú wa mi,”35 àti pé “ó jẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ ní a nígbàlà, lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe.”36 Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì yíò padà sí orí ilẹ̀ ayé “pẹ̀lú ìwòsàn ní apá rẹ̀.”37 Nígbẹ̀hìn, Òun “yíò nu gbogbo omijé kúrò ní ojú [yín]; ìbànújẹ́ ... kì yíò sì sí mọ́.”38 Fún gbogbo ẹnití yíò “wá sọ́dọ̀ Krístì, kí wọ́n sì jẹ́ pípé nínú rẹ̀,”39 òòrùn kò ní wọ̀ mọ́; … nítorí Olúwa yíò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé [wa], àwọn ọjọ́ ọ̀fọ̀ [wa] yíò dópin.”40 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. “Bá Mi Gbé!” Àwọn orin, no. 166.

  2. Nígbàtí a wà lókè ìkuùkù, a kò lè rí òkùnkùn tí ó wà ní ìṣísẹ̀ díẹ̀ nísàlẹ̀ wa, àti nígbàtí ókùnkùn bá wé mọ́ wa lábẹ́, ó ṣòrò láti rí dídán òòrùn tí ó ntàn ní ìṣíṣẹ̀ díẹ̀ lórí wa.

  3. Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,Liahona, May 2017, 145.

  4. “The spirit and the body are the soul of man” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:15). “Ara yín jẹ́ tẹ́mpìlì fún ẹ̀mí yín. Àti pé bí ẹ ṣe nlo ara yín yíò nípá lórí ẹmí yín” (Russell M. Nelson, “Àwọn Ìpinnu fún Ayérayé,” Liahona, Nov. 2013, 107).

  5. Fún àpẹrẹ, wo, Isaiah 65:19; Lúkù 7:13; 3 Nífáì 17:6–7; Mose 7:28. Kíkọ́ láti dá iyì àti ẹ̀dùn ọkàn wa mọ̀ lè rànwálọ́wọ́ láti lò wọ́n dáadáa láti dàbíi ti Olùgbàlà, Jésù Krístì.

  6. Wo “Ìbànújẹ́ àti Ìrẹ̀wẹ̀sì,” kidshealth.org/en/kids/depression.html.

  7. Hermana Elena Aburto blog, hermanaelenaaburto.blogspot.com/2015/08. Bákannáà ó kọ pé:

    “Pé àdánwò fún mi ní ààyè láti lo ìgbàgbọ́ mi lotitọ nínú ètò ìgbàlà. Nítorí mo mọ̀ pé Bàbá mi Ọ̀run fẹ́ràn mi, àti pé Òun ti ní ètò kan fún mi, àti pé Krístì ní ìmọ̀ déédé ohun tí mò nrí lọ́wọ́lọ́wọ́.”

    “Ọlọ́run kò ní fiyín ṣẹ̀sín nítorí ẹ kò ní iṣẹ́ kan. Inú Rẹ̀ ndùn láti ràn yín lọ́wọ́ láti gbèrú àti láti ronúpìwàdà. Kò léró pé kí a ṣe ohun gbogbo lẹ́ẹ̀kan. Ẹ kò ní láti dá nìkan ṣe èyi” ” (iwillhealthee.blogspot.com/2018/09).

  8. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni Bákannáà ó kọ pé: “Òróró iwòsàn ti Ètùtù Olùgbàlà mi ti jẹ́ orísun lemọ́lemọ́ ti àláfíà àti ààbò káàkiri ìrìnàjò mi. Nígbàtí mo nímọ̀lára àdáwà nínú ìtiraka mi, a ránmilétí pé Òun ti ní ìrírí ohun tí mò nní ní ìtìlẹhìn mi bákannáà tẹ́lẹ̀ . … Ìrètí púpọ̀ wà ní mímọ̀ pé ọjọ́-ọ̀la mi pípé, ara àjíìnde kò ní ní ààrùn [ìpọ́njú] ayé ikú yí.”

  9. Wo Russell M. Nelson, “Perfection Pending,” Ensign, Nov. 1995, 86–88; Jeffrey R. Holland, “Be Ye Therefore Perfect—Eventually,” Liahona, Nov. 2017, 40–42; J. Devn Cornish, “Am I Good Enough? Ṣé Máà Ṣàṣeyọrí?Liahona, Nov. 2016, 32–34; Cecil O. Samuelson, “What Does It Mean to Be Perfect?New Era, Jan. 2006, 10–13.

  10. Ó ṣe pàtàkì láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ wa, àwọn ẹbí, àti àwọn ọ̀rẹ́ nínú àwọn ilé wa, wọ́ọ̀dù, àti àwọn ìletò.

  11. Mòsíàh 18:8–9.

  12. Wo Russell M. Nelson, “Jesus Christ—the Master Healer,” Liahona, Nov. 2005, 85–88; Carole M. Stephens, “The Master Healer,” Liahona, Nov. 2016, 9–12.

  13. Mímọ̀ bí a ó ṣe dá àwọn àmì mọ̀ àti àwọn àmúwá nínú ara wa àti àwọn ẹlòmíràn lé ṣèrànwọ́. Bákannáà a lè kọ́ láti rí ìbàmu tàbí àìlera àwoṣe ìrònú àti bí a ó ṣe rọ́pò wọn pẹ̀lú ìbámu àti àwọn onílera.

  14. Bákannáà ìrẹ̀wẹ̀sì lè jáde látinú ìyípada ayé rere—bí irú obí ọmọ kan tàbí iṣẹ́ titun—tí ó sì lè ṣẹlẹ̀ nígbàtí àwọn ohun kan bá dára nínú ayé ẹnìkan.

  15. Wo “Understanding Stress,” Adjusting to Missionary Life (2013), 5–10.

  16. Wo Jeffrey R. Holland, “Like a Broken Vessel,” Liahona, Nov. 2013, 40.

  17. Wo Dale G. Renlund, “Understanding Suicide” (video), ChurchofJesusChrist.org; “Talking about Suicide” (video), ChurchofJesusChrist.org; Kenishi Shimokawa, “Understanding Suicide: Warning Signs and Prevention,Liahona, Oct. 2016, 35–39.

  18. “Ìbẹ̀rẹ̀ ìwòsàn nfẹ́ ìgbàgbọ́ bí ọmọdé ní àìlèsọ òótọ́ pé Bàbá ní Ọ̀run nifẹ yín Ó sì ti pèsè ọ̀nà kan láti wòsàn. Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, fi ayé Rẹ̀ sílẹ̀ láti pèsè ìwòsàn náà. Ṣùgbọ́n kò sí àbájáde idán, kò sí ìtura jẹ́jẹ́ láti pèsè, tàbí ṣe ipa ọ̀nà ìrọ̀rùn kan wà sí àyọrísí pípé. Ìwòsàn náà nfẹ́ ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Jésù Krístì àti nínú okun àìlópin Rẹ̀ láti wòsàn”(Richard G. Scott, “To Heal the Shattering Consequences of Abuse,;” Liahona, May 2008, 42). Nígbàtí wàhálà bá wà, ìgbìrò wa ni láti tunṣe. Bákannáà, a kò ní láti di olùṣe kanṣoṣo ti arawa tàbí àwọn ẹlòmíràn. A kò níláti ṣe ohungbogbo fúnrawa. Ju bíi ẹ̀ẹ̀kan lọ nínú ayé mi, mo ti wá olùtora láti ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn ìgbà líle.

  19. Wo John 9:1–7.

  20. Jane Clayson Johnson, Silent Souls Weeping (2018), 197.

  21. Wo Matteu 9:2–7, 20–22; 14:35–36; Maku 1:40–42; 2:3–5; 3 Nífàí17:6–7.

  22. Mosiah 4:19; bákannáà wo Jeffrey R. Holland, “A Kìí Ṣe Oníbárà?Liahona Nov. 2014, 40–42.

  23. Wo Romans 2:19; 13:12; bákannáà wo Jeffrey R. Holland, “Come unto Me” (Brigham Young University devotional, Mar. 2, 1997), speeches.byu.edu.

  24. 1 Nephi 8:23; bákannáà wo 1 Nephi 12:4, 17; 3 Nephi 8:22.

  25. Wo Psalmu 82:6; Romu 8:16–18; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 24:1; 76:24; Mose 1:1–39.

  26. Wo Adjusting to Missionary Life, 20; bákannáà wo Micah 7:8; Matthew 4:16; Luke 1:78–79; John 8:12.

  27. Jakobu 3:1; bákannáà wo Efesu 5:8; Colose 1:10–14; Mosia 24:13–14; Alma 38:5. Ẹ ka ìbùkún bàbánlá nyín tàbí kí ẹ bèèrè fún ìbùkún oyèàlùfáà kí ẹ lè gbọ́ kí ẹ sì rántí bí Bàbá Ọ̀run ṣe fẹ́ràn tó àti bí Ó ṣe fẹ́ bùkún yín. .

  28. Wo 2 Corinthians 4:16–18; Doctrine and Covenants 121:7–8, 33; 122:5–9.

  29. 2 Korinti 12:7.

  30. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 81:5; bákannáà wo Isaiah 35:3.

  31. Wo Moroni 4:3; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:77.

  32. Álmà 37:6.

  33. Russell M. Nelson, “Revelation for the Church, Revelation for Our Lives,” Liahona, May 2018, 95.

  34. Alma 7:12; bákannáà wo Isaiah 53:4; 2 Nephi 9:21; Mosiah 14:4.

  35. Isaiah 61:1–3; bákannáà wo Luke 4:18.

  36. Alma 31: 38; bákannáà wo Alma 32:43; 33:23.

  37. 2 Nífáì 25:23.

  38. Malaki 4:2; 3 Nifai 25:2.

  39. Ìfihàn 21:4.

  40. Mórónì 10:32.

  41. Isaiah 60:20.