Àwọn Ẹlẹri, Iyejù Oyèàlùfáà Árọ́nì, àti Kíláàsì àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin
Àwọn àtúnṣe tí a npolongo nísisìyí ni ìgbìrò láti ran àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin lọ́wọ́ láti mú agbára mímọ́ araẹni wọn gbèrú.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ó jẹ́ ìyàlẹ́nú láti wà pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kansi nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Ṣíwájú ní ọ̀sẹ̀ yí, a ṣe ìpolongo sí àwọn ọmọ Ìjọ nípa àwọn ìyípadà àkóso ní ìkàsí ẹnití ó lè sìn bí ẹlẹri láti ṣèrìbọmi àti àwọn ìlànà èdidì. Èmi ó fẹ́ lati sàmì sí àwọn kókó mẹ́ta wọ̀nni.
-
Arọ́pò ìrìbọmi fún ẹni tó kú lè jẹ́ ẹlẹri nípasẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ó di ìkaniyẹ tẹ́mpìlì mú lọ́wọ́lọ́wọ́, pẹ̀lú ìkaniyẹ ìlò-tó-lópin.
-
Ọmọ ìjọ kankan pẹ̀lú ìkaniyẹ tẹ́mpìlì lọ́wọ́lọ́wọ́ lẹ̀ sìn bí ẹlẹri làti ṣe àwọ ìlànà èdidì, ààyè àtì arọ́pò
-
Ọmọ Ìjọ tó ti ṣèrìbọmi kankan lè sìn bí ẹlẹri kan ti ìrìbọmi ẹnìkan tó wà láàyé. Ìyípada yí jẹ mọ́ gbogbo ìrìbọmi níta tẹ́mpìlì.
Àwọn àtúnṣe àkóso wọ̀nyí jẹ́ ìṣísẹ̀. Àwọn ẹ̀kọ́ àti májẹ̀mú abẹ́lẹ̀ náà kò yípadà. Wọ́n sì nípá bákannáà nínú gbogbo ìlànà. Àwọn ìyípadà gbọ́dọ̀ mú ìkópa ẹbí gbòòrò gidigidi nínú àwọn ìlànà wọ̀nyí.
Bákannáà mo fẹ́ láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín ní àkokò yí láti fi àwọn àtúnṣe hàn tí ó jẹmọ́ àwọn ọ̀dọ́ wa àti olórí wa.
Ẹ ó rántí pé mo ti pe àwọn ọ̀dọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti forúkọ ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ àwọn ọmọ ogun Olúwa sílẹ̀ láti kópa nínú èrò tìtóbijùlọ lórí ilẹ̀ ayé loni—ìkójọpọ̀ Ísráẹ́lì.1 Mo fi ìfipè yí fún àwọn ọ̀dọ́ wa nítorí wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn àìwọ́pọ̀ ní nínawọ́ jáde sí àwọn ẹlòmíràn àti ṣíṣe àbápín ohun tí wọ́n gbàgbọ́ ní ọ̀nà ìyìnilọ́kan padà. Èrò ti ìkójọpọ̀ jẹ́ apákan pàtàkì ti ṣíṣèrànwọ́ láti múra ayé sílẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa.
Ní wọ́ọ̀dù kọ̀ọ̀kan, ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀dọ́ Olúwa ni bíṣọ́ọ̀pù, olùfọkànsìn ìránṣẹ́ Olúwa kan ndarí. Ojúṣe rẹ àkọ́kọ́ àti ìṣaájú ni láti tọ́jú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin ní wọ́ọ̀dù rẹ̀. Bíṣọ́ọ̀pù àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ndarí iṣẹ́ àwọn iyejú Oyèàlùfáà Árọ́nì àti àwọn kìláàsì Ọdọ́mọbìnrin nínú wọ́ọ̀dù.
Àwọn àtúnṣe tí a npolongo nísisìyí ni ìgbìrò láti ran àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin lọ́wọ́ láti mú agbára mímọ́ araẹni wọn gbèrú. Bákannáà a fẹ́ láti fún kíláàsì àwọn iyejú Oyèàlùfáà Árọ́nì àti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin lókun àti pípèsè àtìlẹhìn sí àwọn bíṣọ́ọ̀pù àti àwọn olórí àgbà míràn bí wọ́n ṣe nsin àwọn ìran tó ndìde.
Alàgbà Quentin L. Cook nísisìyí yíò bá wa sọ̀rọ̀ àtúnṣe tí ó bá àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mu. Lálẹ́yìí, ní abala gbogbogbò àwọn obìnrin, Arábìnrin Bonnie H. Cordon, Ààrẹ̀ Gbogbogbò àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, yíò bá wa sọ̀rọ̀ àtúnṣe tí ó bá àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mu.
Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti àwọn Méjìlá wà fi ìrẹ́pọ̀ fọwọ́ sí àwọn ìtiraka wọ̀nyí láti fún àwọn ọ̀dọ́ wa lókun. Óò, bí a ṣe nifẹ wọn tí a sì ngbàdúrà fún wọn! Àwọn ni “Ìrètí Ísráẹ́lì, ọmọ-ogun Síónì, àwọn ọmọ ọjọ́ ìlérí.”1 A fi ìgbẹ́kẹ̀lé pípé wa hàn nínú àwọn ọ̀dọ́ wa àti ìmoore wa fún wọn. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín