Ìfarasìn Àìyẹsẹ̀ sí Jésù Krístì
Ọlọ́run pè wá láti fi àwọn ọ̀nà àtijọ́ wa sílẹ̀ pátápátá kí a sì bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé titun kan nínú Krístì.
Oṣù Kẹ́rin tó kọjá, mo ní ànfàní yíya Tẹ́mpìlì Kinshasa Democratic Republic ti Congo sí mímọ́.2 Àwọn ọ̀rọ̀ kò lè fi ayọ́ àwọn olóótọ́ Congolese hàn àti ìmọ̀lára tí mo ní láti rí ìyàsímímọ́ tẹ́mpìlì ní ilẹ̀ wọn.
Àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tó wọnú Tẹ́mpìlì Kinshasa rí ìkunlé àtilẹ̀bá tí a pè ní Àwọn Ìṣubú Congo.3 Ó rán àwọn tó-nlọ́-tẹ́mpìlì létí lọ́nà àrà nípa ìfarasìn àìyẹsẹ̀ tó ṣeéṣe láti dúró ti Jésù Krístì àti láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà májẹ̀mú ti ètò Bàbá wa Ọ̀run. Ìṣubúomi nínú ìkunlé pe àkíyèsí sí ìṣe tí ó wọ́pọ̀ jù ní sẹ́ntúrì kan sẹ́hìn ní àárín àwọn olùyípadà ìṣaájú sí Krìstẹ́nì ní Congo.
Ṣíwájú ìyípadà wọn, wọ́n nsin àwọn ohun tí kò lẹmi, ní ìgbàgbọ́ pé àwọn nkan náà ní agbára tó ju àbínibí lọ.4 Lẹ́hìn ìyípadà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ rìnrìnàjo lọ sí ọ̀kan lára àwọn àìlónkà ìṣubú-omi lẹgbẹ Odò Congo, bí irú àwọn ìṣubú Nzongo.5 Àwọn olùyípadà wọ̀nyí ju àwọn ohun ìbọ̀rìṣà wọn sínú àwọn ìṣubúomi bí àmì kan sí Ọlọ́run àti àwọn míràn pé wọ́n fi àwọn àṣà àtijọ́ wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì tẹ́wọ́gba Jésù Krístì. Wọn ko mọ̀ọ́mọ̀ ju àwọn nkan wọn sínú àgbàrá, omi jẹ́jẹ́; wọ́n ju wọn sínú omi rírú ti ìṣubúomi nlá, níbi tí àwọn ohun náà ti di àìlèrígbà. Àwọn ìṣe wọ̀nyí jé ẹ̀bùn ìbẹ̀rẹ̀ ìfarasìn àìyẹsẹ̀ sí Jésù Krístì.
Àwọn ènìyàn ní àwọn ibi àti ọjọ́ orí ti júwe ìfarasìn wọn sí Jésù Krístì ní irú àwọn ọ̀nà kannáà.6 Àwọn ènìyàn Ìwé Mọ́mọ́nì tí a mọ̀ sí àwọn Kòṣe-Nífáì-Léhì “fi àwọn ohun-ìjà oríkunkun wọn sílẹ̀,” wọ́n sin ín “sínú ilẹ̀ tó jìn” bí “ẹ̀rí kan sí Ọlọ́run ... Pé wọn kò ní lò àwọn ohun-ìjà [wọn] mọ́ láéláé.”7 Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣèlérí láti tẹ̀lé àwọn ìkọ́ní Ọlọ́run àti láti máṣe padà sẹ́hìn lórí ìfarasìn wọn láéláé. Ìṣe yí ni ìbẹ̀rẹ̀ jíjẹ́ “yíyípadà sí Olúwa” kí wọ́n má sì ṣubú kúrò láéláé.9
Jíjẹ́ “yíyípadà sí Olúwa” túmọ̀ sí fífi èrò ìṣe kan sílẹ̀, ní ìdarí nípa ìṣètò ìgbàgbọ́ àtijọ́ kan, àti gbígba ọ̀kan titun tó dá lórí ìgbàgbọ́ nínú ètò Bàbá Ọ̀run àti nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Ìyípadà yí ju ìtẹ́wọ́gbà òye kan ti àwọn ìkọ́ni ìhìnrere lọ̀. Ó ntú ìdánimọ̀ ṣe, ó nyí ìmọ̀ tì ìtumọ̀ ìgbé ayé wa po, ó sì ndarí sí àìyípadà ìwàmímọ́ sí Ọlọ́run. Ìfẹ́ araẹni tí ó tako àwọn wọnnì tí Olùgbàlà dìmú àti láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà májẹ̀mú pajúdé àti pé ìpinnu kan láti firasílẹ̀ fún ìfẹ́ Bàbá Ọ̀run rọ́pò rẹ̀.
Jíjẹ́ Olùyípadà sí Olúwa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfarasìn àìyẹsẹ̀ sí Ọlọ́run, tí ṣíṣe ìfarasìn ìpín ti ẹni tí a jẹ́ tẹ̀lé. Fífi irú ìfarasìn bẹ́ẹ̀ sínú ni ètò ìgbé ayé-pípẹ́ tí ó gba sùúrù àti ìrònúpìwàdà tó nlọ-lọ́wọ́. Nígbẹ̀hìn, ìfarasìn yí di ìpìn ẹni tí a jẹ́, tí ó wà nínú ọgbọ́n arawa, àti tí ó wà títí nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí a kò ṣe lè gbàgbé orúkọ ara wa ohunkóhun yówù kí a máa ronú nípa rẹ̀, a kò lè gbàgbé ìfarasìn kan tí a tẹ̀ sínú ọkàn wa láéláé.10
Ọlọ́run pè wá láti fi àwọn ọ̀nà àtijọ́ wa sílẹ̀ pátápátá kí a sì bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé titun kan nínú Krístì. Èyí nṣẹlẹ̀ bí a ṣe ngbèrú ìgbàgbọ́ wa nínú Olùgbàlà, èyí tí ó nbẹ̀rẹ̀ nípa gbígbọ́ ẹ̀rí àwọn wọnnì tí wọ́n ti ní ìgbàgbọ́.10 Lẹ́hìnnáà, ìgbàgbọ́ njìnlẹ̀ bí a ṣe nṣiṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà tí ó dìwá mọ́ Ọ gbọingbọin.11
Nísisìyí, ó lè dára tí àlékún ìgbàgbọ́ bá lè yíkanni bí ibà tàbí òtútú tó wọ́pọ̀. Nígbànáà “sínsín ti ẹ̀mí” jẹ́jẹ́ kan yíò gbé ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíran sókè. Ṣugbọ̀n kò rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà kanṣoṣo tí ìgbàgbọ́ fi ndàgbà ni fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ṣe ìṣe nínú ìgbàgbọ́. Àwọn ìṣe wọ̀nyí ngba ìṣílétí nígbàkugbà nípasẹ̀ àwọn ìfipè tí àwọn míràn fi ṣọ́wọ́ síwa, ṣùgbọ́n a kò lè “dàgbà” ìgbàgbọ́ ẹlòmíràn tàbu gbáralé àwọn míràn nìkan láti mú tiwa gbèrú. Fún ìgbàgbọ́ wa láti dàgbà, a gbọ́dọ̀ yan àwọn ìṣe gbígbé ìgbàgbọ́ sókè, bíi gígbàdúrà, àṣàrò ìwé-mímọ́, ṣíṣe àbápín oùnjẹ Olúwa, pípa àwọn òfin mọ́, àti sísin àwọn ẹlòmíràn.
Bí ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ṣe ndàgbà, Ọlọ́run npè wá láti ṣe ìlérí pẹ̀lú Rẹ̀. Àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí, bí a ṣe mọ̀ irú àwọn ìlérí náà, ni fífi ìyípadà wa hàn. Bákannáà àwọn májẹ̀mú ndá ìpìnlẹ̀ tó dájú fún ìlọsíwájú ti ẹ̀mí sílẹ̀. Bí a ṣe nyàn láti ṣe ìrìbọmi, à nbẹ̀rẹ̀ láti gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí ara wa12 àti yíyan láti dá arawa mọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. A jẹjẹ láti dà bíi Tirẹ̀ àti láti gbèrú àwọn íhùwàsí Rẹ̀.
Àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí tó ndì wa mọ́ Olùgbàlà tí ó sì nmú lọ lẹgbẹ ipa-ọ̀nà tí ó darí lọ sílé wa ọ̀run. Agbára àwọn májẹ̀mú nrànwálọ́wọ́ láti mú ìyípadà ọkàn nlá dúró, mú ìyípadà wa sí Olúwa jinlẹ̀ si, àti láti gba àwòrán Krístì ní kíkún sí ìwò wa.13 Ṣùgbọ́n ìdajì-ọkàn ìfarasìn sí àwọn májẹ̀mú wa kò ní fún wa ní nkankan.14 A lè gba àdánwò láti bádọ́gba, ju àwọn ìwà àtijọ́ wa sínú omi jẹ́jẹ́, tàbí ri àwọn ohun-ìjà oríkunkun wa mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ yíyọ síta. Ṣùgbọ́n ìwà-ìtakò ìfarasìn sí àwọn májẹ̀mú wa kò ní ṣí lẹ̀kùn sí agbára ìyàsímímọ́ Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì.
Ìfarasìn wa láti pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ti ipò tàbí onírurú pẹ̀lú àwọn ìyípadà ipò ní ìgbé ayé wa. Ìwùwàsí wa sí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ bíi ìgbáralé Odò Congo tí ó nṣàn nítòrí Tẹ́mpìlì Kinshasa. Odò yí, yàtọ̀ sí àwọn odò míràn ní ayé, ní ìṣàn ní gbogbo ọdun15 ó sì ndà bíi gállọ́nù míllíọ̀nù mọ́kànlá (41.5 míllíọ̀nù Lítà) omi ní ìṣẹ́jú-akàn sínú òkun Atlantic Ocean.
Olùgbàlà pe àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ láti jẹ́ olùgbáralé àti olùdúróṣinṣin. Ó wípé, “Nítorínáà, ṣe àtúnṣe èyí nínú ọkàn rẹ, pé iwọ ó ṣe ohun èyí tí èmí ó kọ́, àti paláṣẹ fún ọ.”18 Ìpinnu “àtúnṣe” kan láti pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ nfàyè gba dídámọ̀ àwọn ìlérí Ọlọ́run ní kíkún ti ayọ̀ pípẹ́.19
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olóòtítọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ-ìkẹhìn ti júwe pé wọ́n “ntún” pípa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́ ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run tí wọ́n sì nyípadà títíláé. Ẹ jẹ́ kí nsọ fún yín nípa irú àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan mẹ́ta bẹ́ẹ̀—Arákùnrin Banza Mucioko, Arábìnrin Banza Régine, àti Arákùnrin Mbuyi Nkitabungi.
Ní 1977 àwọn Banza ngbé ní Kinshasa ní orílẹ̀ èdè ti Zaire, tí wọ́n mọ̀ sí Democratic Republic ti Congo báyìí. Wọ́n nbọ̀wọ̀ fún wọn gidi nínú ìjọ Alátakò ní ìletò wọn. Nítorí ẹ̀bùn wọn, ìjọ wọn ṣètò fún ẹbí kékeré wọn láti lọ sí Switzerland láti kàwé àti láti pèsè unifásitì ọ̀fẹ́.
Nígbàtí wọ́n wà ní Geneva, lórí ọkọ̀ akérò sí ilé-ìwé, Arákùnrin Banza rí ilé-ìjọsìn kékeré léraléra pẹ̀lú orúkọ “Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.” Ó ròó pé, “Ṣé Jésù Krístì ní àwọn Ènìyàn Mímọ́ báyìí, ní àwọn Ọjọ́-ìkẹhìn?” Ó pinnu nígbẹ̀hìn láti lọ wòó.
Arákùnrin àti Arábìnrin Banza gba ìkìni ìyárí ní ẹ̀ka náà. Àwọn Banza kò gba ìdáhùn tó tẹ́nilọ́rùn kan rí sí àwọn ìbèèrè lemọ́lemọ́ tí wọ́n ní nípa ìwaẹ̀dá Ọlọ́run, bí irú, “Tí Ọlọ́run bá jẹ́ ẹ̀mí, bíiti ìjì, báwo ni wọ́n ṣe lè dá wa nínú àwòrán Rẹ̀”? Báwo ni Ó ṣe lè joko lórí ìtẹ́?” Wọ́n kò gbà èsì tó tẹ́nilọ́rùn rí títí tí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere fi ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ìmúpadàbọ̀sípò nínú ẹ̀kọ́ ṣókí, Nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kúrò, àwọn Banza wo ara wọn wọ́n sì wípé, “Njẹ́ kìí ṣe òtítọ́ ni a ti gbọ́ yẹn?” Wọ́n tẹ̀síwájú ní wíwá sí ilé-ìjọsìn àti ìpàdé pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere. Wọ́n mọ̀ pé ìrìbọmi sí Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Jésù Krístì yíò ní àyọrísí. Wọ́n yíò pàdánù ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ wọn, wọn ó sọ ìwé ìgbéèlú wọn nu, àti pé àwọn àti àwọn ọmọ wọn kékeré méjì yíò nílati kúrò ní Switzerland. Wọ́n yàn láti ṣe ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ní Oṣù Kẹwa 1979.
Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́hìn ìrìbọmi wọn, Arákùnrin àti Arábìnrin Banza padà sí Kinshasa bí ọmọ Ìjọ ìkínní àti ìkejì ní orílẹ̀-èdè wọn. Àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ká Geneva dúró ní ìṣọ́wọ́síni pẹ̀lú wọn, wọn sì ṣèrànwọ́ láti so wọ̀n pọ̀ mọ́ àwọn olórí Ìjọ. Àwọn Banza ní ìgbìyànjú láti fi tòtìtọ́tòtítọ́ dúró de ìgbà ìlérí nígbàtí Ọlọ́run yíò gbé Ìjọ Rẹ̀ kalẹ̀ ní Zaire.
Bíótilẹ̀jẹ́pé, ìrọ́pò akàwé míràn láti Zaire, Arákùnrin Mbuyi, nkàwé ní Belgium. Ó ṣe ìrìbọmi ní 1980 ní Brussels Ward. Àìpẹ́ lẹ́hìnnáà, ó sìn ní míṣọ̀n ìgbà-kíkún kan lọ sí England. Ọlọ́run sì ṣe àwọn iṣẹ́-ìyanu Rẹ̀. Arákùnrin Mbuyi padà sí Zaire bí ọmọ Ijọ kẹta ní oílẹ-èdè rẹ̀. Pẹ̀lú àṣẹ ti-òbí, wọ́n nṣe àwọn ìpádé Ìjọ ní ilé ẹbí rẹ̀. Ní Oṣù Kejì 1986 wọ́n ṣe ìfìwéránṣẹ́ kan fún dídámọ́ gbogbogbò ìjọba ti Ìjọ. Ìfọwọ́síwé àwọn ọmọ-ìlú mẹta ti Zaire ní wọ́n nílò. Olùbọwọ́-lùwé olùdùnnú ìtọrọ̀ mẹ́ta ni Arákùnrin Banza, Arábìnrin Banza, àti Arákùnrin Mbuyi.
Àwọn akọni ọmọ ìjọ wọ̀nyí mọ òtítọ́ nígbàtí wọ́n gbọ́ ọ; wọ́n dá májẹ̀mú kan ní ìrìbọmi tí ó mú wọn dìmọ́ Olùgbàlà. Wọ́n ti fi ìfijúwe ju ìwà àtijọ́ wọn sínú ìrumi ìṣubúomi pẹ̀lú àìlérò gbígbà wọ́n padà. Ipa-ọ̀nà májẹ̀mú náà kò rọrùn rárá. Ìrúkèrúdò òṣèlú, àìtọ́sí ìkànsí pẹ̀lú àwọn olórí Ìjọ, àti àwọn ìpènijà tó wà nínú gbígbé iletò àwọn Ènìyàn Mímọ́ kan ga lè ti dá àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ní dínkù sí ìfarasìn wọn. Ṣùgbọ́n Arákùnrin àti Arábìnrin Banza àti Arákùnrin Mbuyi níforítì nínú ìgbàgbọ́ wọn. Wọ́n wà ní ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Kinshasa, ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lẹ́hìn tí wọ́n fọwọ́ sí ìfiwéránṣẹ tí ó darí sí ìdámọ̀ gbogbogbò ti Ìjọ ní Zaire.
Àwọn Banzas wà ní Gbàgede Ìpàdé Àpapọ̀ loni. Àwọn ọmọkùnrin wọn méjì ló tẹ̀lé wọn, Junior àti Phil, àti àwọn ìyàwó-ọmọ-wọn, Annie àti Youyou. Ní 1986, Junior àti Phil ni àwọn méjì ẹni àkọ́kọ́ láti ṣe ìrìbọmi sínú Ìjọ ní Zaire. Arákùnrin Mbuyi nwo àwọn ìtẹ̀síwájú wọ̀nyí láti Kinshasa pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, Maguy, àti àwọn ọmọ wọn marun.
Àwọn olùlànà wọ̀nyí ní ìmọ̀ ìtumọ̀ àti àyọrísí àwọn májẹ̀mú nínú èyí tí a ti mú wọ́n wá “sí ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn “sí ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, àti láti yọ̀ nínú Jésù Krístì Olùràpadà wọn.”20
Báwo ni a ó ṣe dìmọ́ Olùgbàlà kí a sì dúró lotitọ bíiti àwọn wọ̀nyí àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ará-congo tí ó tẹ̀lé wọn àti ọ̀pọ̀ míllíọ́nù àwọn míràn káàkiri ayè? Olùgbàlà kọ́ni wa bẹ́ẹ̀. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ a nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa a sì ndá májẹ̀mú pẹ̀lú Bàbá wa Ọ̀run. A ṣèlérí láti somọ́ ìdánimọ̀ wa pẹ̀lú Olùgbàlà nípa jíjẹ́ ẹ̀jẹ́ ìfẹ́ wa láti gbé orúkọ Rẹ̀ lé orí arawa, láti rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo, àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.19 Fífi taratara múrasilẹ̀ fún àti dídá àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí ní yíyẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nmú wa dìmọ́ Olùgbàlà, ó sì nrànwálọ́wọ́ láti ni ìfarasìn wa dénúdénú,20 àti láti fi tagbára-tagbára tì wá lọ lẹgbẹ ipa-ọ̀nà májẹ̀mú.
Mo pe yín láti farasìn sí ètò ìgbé ayé pípẹ́ ti ọmọlẹ́hìn. Ẹ dá kí ẹ sì pa májẹ̀mú mọ́. Ẹ ju àwọn ìwà àtijọ́ sọnù jìnàjìnà, omi-ìṣubú ríru. Kí ẹ ri àwọn ohun-ìjà oríkunkun yí mọ́lẹ̀ pẹ̀lú àìjẹ́kí ọwọ́ rẹ̀ yọsítà. Nítorí ti Ètùtù Jésù Krístì, dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú èrò òtítọ́ láti bú-ọlá fún wọn lódodo yíò yí ìgbé ayé yín padà títíláé. Ẹ ó dà bíiti Olùgbàlà síi bí ẹ ṣe nfi ìgbàgbogbo rántí Rẹ̀, tẹ̀lé E, àti ní ìfẹ́ Rẹ. Mo jẹ́rí pé Òun ni ìpìnlẹ̀ dídúróṣinṣin. Òun ni olùgbọ́kọ̀nlé, àti pé àwọn ìlérí Rẹ̀ dájú. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.