2010–2019
Àwọn Àtúnṣe láti Fún Àwọn Ọ̀dọ́ ní Okun
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


2:3

Àwọn Àtúnṣe láti Fún Àwọn Ọ̀dọ́ ní Okun

Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin púpọ̀ síi yío dìde sí ìpèníjà náà wọn yío sì dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú nítorí amúnáwá ìdojúkọ yi lórí àwọn ọ̀dọ́ wa.

Ẹ ṣeun, Ààrẹ Nelson ọ̀wọ́n, fún ìtọ́nisọ́nà aláyọ̀ náà tí ó nṣe ìfihàn nípa àwọn ẹlẹ́rìí ní ibi àwọn ìrìbọmi àti ìdarí tí ẹ ti ní kí a ṣe àbápín láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ ní okun kí wọn ó sì mú agbára ìṣe wọn mímọ́ dàgbà.

Kí ntó ṣe àbápín àwọn àtúnṣe wọnnì, a fi ìmoore wa nítòótọ́ hàn fún ọ̀nà àrà tí àwọn ọmọ ijọ́ ti kọ ibi ara sí àwọn ìdàgbàsókè nínú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere tí ó nlọ lọ́wọ́. Bí Ààrẹ Nelson ti dá àbá rẹ̀ ní ọdún tí ó kọjá, ẹ ti gba àwọn aṣaralóore yín!1

Ẹ nṣe àṣàrò Wá, Tẹ̀lé Mi pẹ̀lú ayọ̀ ní ilé.1 Ẹ ti fèsì sí àwọn àtúnṣe ní ilé ìjọsìn bákannáà. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ iyejú ti àwọn alàgbà àti àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ fi ìrẹ́pọ̀ ṣe iṣẹ́ ìgbàlà.2

Ìmoore wa jẹ́ àkúnwọ́sílẹ̀.3 Ní pàtàkì a ní ìmoore pé àwọn ọ̀dọ́ wa tẹ̀síwájú láti dúró bí alágbára àti onígbàgbọ́.

Àwọn ọ̀dọ́ ngbé ní àkókò tí ó dùnmọ́ni ṣùgbọ́n bákannáà tí ó kún fún ìdojúkọ. Àwọn yíyàn tí wọ́n wà ní àrọ́wọ́tó kò tíì jẹ́ bíi eré ìtàgé tó bẹ́ẹ̀ rí Àpẹrẹ kan: ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé npèsè ọ̀nà sí àwọn ìwífúnni pàtàkì àti gbígbéniga tí kò ṣeé gbàgbọ́, nínú èyítí ìtàn ẹbí àti àwọn ìwé mímọ́ wà. Ní ọ̀nà míràn, ó ní àìgbọ́n, àìdára, àti ibi tí kò sí ní arọ́wọ́tó ní ìgbà kan rí nínú.

Ohun-èlò gbùngbun-ilé
Ìdárayá Ọ̀dọ́

Láti ran àwọn ọ̀dọ́ wa lọ́wọ́ tukọ àwọn yíyàn tí ó rújú yìí, Ijọ ti pèsè àwọn ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ mẹ́ta kan. Ìkínní, ohun èlò ni a ti fún ní okun tí a sì ti mú gbòòrò dé inú ilé. Ìkejì, ètò kan fún àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ tí ó ní àwọn ìdárayá àti ìdàgbàsókè ara ẹni dídùnmọ́ni nínú ni a gbékalẹ̀ ní Ọjọ́ Ìsinmi tí ó kọjá láti ọwọ́ Ààrẹ Nelson, Ààrẹ Ballard, àti Àwọn Olóyè Gbogbogbò. Ẹ̀kọ́ kẹta ni àwọn àyípadà ìse-àmójútó láti fi àwọn ọ̀dọ́ ṣe pàtàkì ìfojúsùn àwọn bíṣọpù àti àwọn bíṣọ́pù àti àwọn olórí miràn. Ìfojúsùn yi gbọdọ̀ jé lílágbára ní ti ẹ̀mí kí ó sì ran àwọn ọ̀dọ́ wa lọ́wọ́ láti di ọ̀dọ́ ọmọ ogun tí Ààrẹ Nelson ti pè wọ́n láti dà.

Àwọn Àwòrán Àfibọnú-ara-wọn

Àwọn ìtiraka wọ̀nyí, papọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a kéde láàrin bí ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, kìí ṣe àwọn ìyípadà tí a yà sọ́tọ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àtúnṣe náà jẹ́ kókó abala kan nínú àwòrán àfibọnú-ara-wọn, láti bùkún àwọn Ènìyàn Mímọ́ kí ó sì pèsè wọn láti pàdé Ọlọ́run.

Abala kan ti àwòrán náà ní í ṣe pẹ̀lú ìran tí ó ndìde. Àwọn ọ̀dọ́ wa ni a nsọ fún láti gba ojúṣe síi bí ẹnikọ̀ọ̀kan ní àwọn ọjọ́ orí ọ̀dọ́mọdé—láì jẹ́ pé àwọn òbí tàbí àwọn olùdarí ngba ohun tí àwọn ọ̀dọ́ le ṣe fún ara wọn ṣe.4

Ìpolongo

Lónìí a polongo àwọn ìyípadà ìṣètò fún àwọn ọ̀dọ́ ní àwọn ìpele wọ́ọ̀dù àti èèkàn. Bí Ààrẹ Nelson ti ṣe àlàyé, Arábìnrin Bonnie H. Cordon yío sọ àwọn ìyípadà fún àwọn Ọdọ́mọbìnrin ní ìrọ̀lẹ́ yi. Èrò kan fún àwọn àyípadà náà tí èmi ó sọ̀rọ̀ le lórí nísisìyí ni láti fi okun fún àwọn tí wọ́n ní Oyè Àlùfáà Áárọ́nì, àwọn iyejú, àti àwọn àjọ ààrẹ iyejú. Àwọn àyípadà wọ̀nyí fi ìṣe wa sí ìbámu pẹ̀lú Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:15, èyítí ó kà pé, “Àjọ bíṣọ́pù ni àjọ ààrẹ ti òyè àlùfáà [ti Áárónì] yi, ó sì ní àwọn kọ́kọ́rọ́ tàbí àṣẹ ti èyí kan náà.”

Ọ̀kan nínú àwọn ojúṣe ti inú iwé mímọ́ fún bíṣọpù ni láti ṣe adarí lórí àwọn àlùfáà àti láti jókòó nínú ìgbìmọ̀ pẹ̀lú wọn, ní kíkọ́ wọn ní àwọn ojúṣe ti ipò ibi iṣẹ́ wọn.5 Ní àfikún, olùdámọ̀ràn ìkínní nínú àjọ bíṣọ́pù yío ní ojúṣe pàtó fún àwọn olùkọ́ni àti olùdámọ̀ràn kejì fún àwọn díákónì.

Nítorínáà, láti wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfihàn yi nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, àwọn àjọ ààrẹ ti Àwọn Ọdọ́mọkùnrin ní ìpele wọ́ọ̀dù ní a ó dá dúró. Àwọn arákùnrin olõtọ́ wọ̀nyí ti ṣe rere púpọ̀, a sì fi ìmoore hàn sí wọn.

A ní ìrètí pé àwọn àjọ bíṣọ́pù yío fi ìtẹramọ́ àti ìfojúsùn nlá sí àwọn ojúṣe oyè àlùfáà ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, tí wọn ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ojúṣe nínú àwọn ojúṣe iyejú wọn. Àwọn àgbàlagbà olùdámọ̀ràn tódangàjíá sí Àwọn Ọdọ́mọkùnrin ni a ó pè láti ṣe àtilẹhìn fún àwọn àjọ ààrẹ iyejú Oyè Àlùfáà ti Áárónì àti àjọ bíṣọpù nínú àwọn ojúṣe wọn.6 A ní ìgbẹ́kẹ́lé pé àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin púpọ̀ síi yío dìde sí ìpèníjà náà wọn yío sì dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú pẹ̀lú ìdojúkọ amúnáwá yi lórí àwọn ọ̀dọ́ wa.

Nínú àwóran ìmísí ti Olúwa, bíṣọ́pù ní ojúṣe fún olukúlùkù ènìyàn nínú wọ́ọ̀dù. Ó nbùkún fún àwọn òbí ọ̀dọ́ àti fún àwọn ọ̀dọ́ bákannáà. Bíṣọ́pù kan ríi pé bí òun ṣe ngbìmọ̀ràn pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó ntiraka pẹ̀lú ìwà ìṣekúṣe, òun le ran ọ̀dọ́mọkùnrin náà lọ́wọ́ nínú ìrònúpìwàdà rẹ̀ bí òun bá ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti hùwà síi pẹ̀lú ìfẹ́ àti lílo òye. Ìwòsàn ọ̀dọ́mọkùnrin náà jẹ́ ìwòsàn fún gbogbo ẹbí rẹ̀, ó sì ṣeéṣe nípasẹ̀ iṣẹ́ síṣe ti bíṣọpù náà ní ìgbẹnusọ ti gbogbo ẹbí náà. Ọdọ́mọkùnrin náà ti di kíkàyẹ nísisìyí fun Oyè Àlùfáà ti Mẹlkísẹ́dẹ́kì àti ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún.

Bí ìtàn yí ṣe dá àbá, àwọn àtúnṣe wọ̀nyí yío:

  • Ran àwọn bíṣọ́pù àti àwọn olùdámọ̀ràn wọn lọ́wọ́ nínú kókó àwọn ojúṣe wọn sí àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọmọdé Alákọ́bẹ̀rẹ̀.

  • Fi agbára àti àwọn ojúṣe Oyè Àlùfáà Áárónì sí ààrin gbùngbùn ìgbé ayé àti àfojúsùn araẹni ti olukúlùkù ọ̀dọ́mọkùnrin.

Bákannáà àwọn àtúnṣe wọ̀nyí tun:

  • Ṣe àtẹnumọ́ àwọn ojúṣe ti àwọn àjọ ààrẹ iyejú Òyè Àlùfáà Áárónì àti ìlà ìjíhìn wọn tààrà sí àjọ bíṣọ́pù.

  • Fún àwọn àgbà olùdarí ní ìwúrí láti ṣe àtilẹhìn àti ìtọ́ni fún àwọn àjọ ààrẹ ti iyejú Oyè Àlùfáà Áárónì, láti mú agbára àti àṣẹ ipò iṣẹ́ wọn tóbi.

Bí àkíyèsí, àwọn àtúnṣe wọ̀nyí kò mú ojúṣe àjọ bíṣọpù kéré fún àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin. Bí Ààrẹ Nelson ti ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ni, “Ojúṣe àkọ́kọ́ àti tí ó ṣíwájú jùlọ [ti bíṣọ́pù] ni láti ṣe ìtọ́jú fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ti wọ́ọ̀dù rẹ̀.”7

Báwo ni àwọn bíṣọ́pù wa olùfẹ́ ọ̀wọ́n tí wọ́n sì nṣiṣẹ́ kára ṣe le mú ojúṣe yìí ṣẹ? Bí ẹ ṣe rántí, ní 2018 a ṣe àtúnṣe àwọn iyejú Oyè Àlùfáà Mẹ́lkísẹ́dẹ́kì lati ṣiṣẹ́ ní tímọ́-tímọ́ síi pẹ̀lú àwọn Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ kí àwọn iyejú àwọn alàgbà àti àwọn Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, ní abẹ́ ìdarí bíṣọ́pù, le ṣe ìrànlọ́wọ́ gbé àwọn ojúṣe pàtàkì tí ó ngba púpọ̀ àkókò rẹ̀ ní àtẹ̀hìnwá. Nínú àwọn ojúṣe wọ̀nyí ni iṣẹ́ ìhìnrere, áti iṣẹ́ tẹ́mpìlì àti ìtàn ẹbí ní wọ́ọ̀dù8—gẹ́gẹ́ bíi púpọ̀ ti síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ijọ ní wọ́ọ̀dù.

Àwọn ojúṣe ti bíṣọ́ọ̀pù

Bíṣọ́ọ̀bù kò le fi àwọn ojúṣe kan rán ẹlòmíràn, bíi ti fífun àwọn ọ̀dọ́ lókun, jíjẹ́ onídájọ́ ti gbogbo ènìyàn, síṣe ìtọ́jú àwọn aláìní, àti mímójútó ètò ìṣúná owó àti àwọn ohun ti ara. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ ju ohun tí a lè ti ní òye rẹ̀ sẹ́hìn lọ. Bí Alàgbà Jeffrey R. Holland ti ṣe àlàyé ní ọdún tí ó kọjá, nígbàti àwọn àtúnṣe sí àwọn iyejú Oyè Àlùfáà Mẹ̀lkísẹ́dẹ́kì di kíkéde: “Bíṣọ́pù sì dúró, ní tòótọ́, sí ipò àlùfáà gíga olùdarí ní wọ́ọ̀dù. Ìbárẹ́ tuntun yi [ti àwọn iyejú àwọn alàgbà àti àwọn Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́] yío jẹ́ kí ó ṣe àkóso lórí iṣẹ́ Oyè Àlùfáà Mẹ̀lkísẹ́dẹ́kì àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ láìsí pé ó ní láti ṣe iṣẹ́ ọ̀kankan nínú àwọn ẹgbẹ́ wọnnì.9

Fún àpẹrẹ, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ kan lati ààrẹ iyejú àwọn alàgbà kan, bí a bá ti yàn wọ́n, le kó ipa nlá kan ní dídámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà—bí ààrẹ Àwọn Ọdọ́mọbìnrin kan ti le ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin. Nígbàtí ó jẹ́ pé bíṣọpù nìkan ni ó le ṣiṣẹ́ bíi onídájọ́ gbogbo ènìyàn, àwọn olórí miràn wọ̀nyí ní ẹ̀tọ́ sí ìfihàn láti ọ̀run bákannáà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ìpèníjà tí kò bá nílò onídajọ́ gbogbo ènìyàn tàbí kí ó ní í ṣe sí èyíkéyìí ilòkulò.10

Èyíinì ko túmọ̀ sí pé ọ̀dọ́mọbìnrin kan kò le tàbí kò níláti bá bíṣọ́pù tàbí àwọn òbí rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ìfojúsùn wọn ni àwọn ọ̀dọ́! Ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pé olùdarí Àwọn Ọdọ́mọbìnrin kan le bá àwọn àìní ọ̀dọ́mọbìnrin kọ̀ọ̀kan pàdé ní ọ̀nà tí ó dára jùlọ. Bìṣọ́ọ́príkì ní àníyàn fún àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bíi ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, ṣùgbọ́n a mọ okun tí ó nwá láti inú níní alágbára, òṣìṣẹ́ takuntakun, àti ìfojúsí àwọn olórí àwọn Ọdọ́mọbìnrin tí wọ́n ní ìfẹ́ tí wọ́n sì ntọ́ni, láì gba ojúṣe àwọn àjọ ààrẹ kíláàsì ṣe ṣùgbọ́n tí wọ́n nran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti yege nínú àwọn ojúṣe wọnnì.

Arábìnrin Cordon yío ṣe àbápín àfikún àwọn àyípadà dídùnmọ́ni fún àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní alẹ́ yi. Bíótilèríbẹ́ẹ̀, mo kéde pé nísisìyí àwọn ààrẹ Àwọn Ọdọ́mọbìnrin ni wọ́ọ̀dù yío máa jíhìn fún, wọn ó sì máa gbìmọ̀ràn tààrà pẹ̀lú bíṣọ́pù ti wọ́ọ̀dù. Ní àtẹ̀hìnwá, iṣẹ́ yi le jẹ́ fífi rán olùdámọ̀ràn kan, ṣùgbọ́n láti isisìyí lọ, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin yío jẹ́ ojúṣe tààrà ti ẹni náà tí ó ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìṣàkóso fún wọ́ọ̀dù. Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ yío tẹ̀síwájú láti máa jíhìn fún bíṣọ́pù tààrà.11

Ní àwọn ìpele gbogbogbò àti èèkàn, aó tẹ̀síwájú láti ní àwọn àjọ ààrẹ Àwọn Ọdọ́mọkùnrin Ní ìpele èèkàn, ọmọ ìgbìmọ̀ gíga kan ni yío jẹ́ ààrẹ Àwọn Ọdọ́mọkùnrin12 yío sì jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Oyè Àlùfáà ti Áárọ́nì–àti Àwọn Ọdọ́mọbìnrin, pẹ̀lú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ gíga tí a bá yàn sí ti àwọn Ọdọ́mọbìnrin àti Alákọbẹ̀rẹ̀. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí yío ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ ààrẹ Àwọn Ọdọ́mọbìnrin ti èèkàn nínú ìgbìmọ̀ yi. Pẹ̀lú olùdámọ̀ràn kan sí ààrẹ èèkàn bíi alága, ìgbìmọ̀ yí yío ní àlékún agbára nítorípé púpọ̀ àwọn ètò àti àwọn ìdárayá nínú ìkọ́ni tuntun ti Àwọn Ọmọdé àti Àwọn Ọ̀dọ́ yío jẹ́ ní ìpele èèkàn.

Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ gíga wọ̀nyí, ní abẹ́ ìdarí àjọ ààrẹ èèkàn, le ṣiṣẹ́ bíi ohun èlò sí bíṣọ́pù àti àwọn iyejú Oye Àlùfáà Áárọ́nì, ní ọ̀nà tí ó jọ iṣẹ́ ìsìn tí a npèsè láti ọwọ́ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ gíga fún iyejú àwọn alàgbà.

Bíi ọ̀rọ̀ tí ó jọ ara wọn, ọmọ ìgbìmọ̀ gíga miràn yío ṣiṣẹ́ bíi ààrẹ Ilé Ìwé Ọjọ́ Ìsinmi ti èèkan àti, bí a bá ṣe nílò, le ṣiṣẹ́ nínú ìgbìmọ̀ Oyè Àlùfáà Áárọ́nì–àti àwọn Ọdọ́mọbìnrin.13

Àfikún àwọn àyípadà ìṣe àmójútó ni aó ṣe àlàyé rẹ̀ síwájú nínú ìwífúnni tí a fi ránṣẹ́ sí àwọn olùdarí. Nínú àwọn àyípadà wọ̀nyí ni:

  • Ìpàdé ìgbìmọ̀ àjọ bíṣọ́pù àti àwọn ọ̀dọ́ ní aó rọ́pò pẹ̀lú ìgbìmọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ijọ.

  • Ọrọ̀ “Múṣúà” ni aó fi tì, yío sì di “ìdárayá àwọn Ọdọ́mọbìnrin,” “ìdárayá iyejú àwọn Olóyè Àlùfáà Áárọ́nì,” tàbí “ìdarayá àwọn ọ̀dọ́” yío sì máa wáyé ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ níbití ó bá ti ṣeéṣe.

  • Ètò ìsúná owó wọ́ọ̀dù fún ìdárayá àwọn ọ̀dọ́ ni a ó pín ní dọ́gba-dọ́gba ní ààrin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin, ní ìbámu sí iye ọ̀dọ́ ní ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Iye owó tí ó tó ni aó pèsè fún ìdárayá àwọn alákọ́bẹ̀rẹ̀.

  • Ní gbogbo àwọn ìpele—wọ́ọ̀dù, èèkàn, àti gbogbogbò—a ó máa lo ìjúwe “ẹgbẹ́” dípò ìjúwe “amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́.” Àwọn wọnnì tí wọ́n ndarí Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, ẹgbẹ́ Àwọn Ọdọ́mọbìnrin, ti Àwọn Ọdọ́mọkùnrin, ti Alákọ́bẹ̀rẹ̀, àti ti Ilé Ìwé Ọjọ́ Ìsinmi Gbogbogbò ni a ó mọ̀ bíi “Àwọn Òṣìṣẹ́ Gbogbogbò.” Àwọn wọnnì tí wọ́n ndarí ní àwọn ìpele wọ́ọ̀dù àti èèkàn ni a ó mọ̀ bíi “àwọn olóyè wọ́ọ̀dù” àti “àwọn òṣìṣẹ́ èèkàn.”14

Àwọn àtúnṣe tí a kéde loni le bẹ̀rẹ̀ bí àwọn ẹ̀ka, àwọn wọ́ọ̀dù, àwọn ẹkùn, àti àwọn èèkàn bá ti ṣetán, ṣùgbọ́n ó níláti wà ní lílò ní 1 Oṣù Kínní, 2020. Àwọn àtúnṣe wọ̀nyí, nígbàtí a bá dà wọ́n pọ̀ pẹ̀lú àwọn àtúnṣe ti àtẹ̀hìnwá, dúró fún akitiyan ti ẹ̀mí àti ìṣe àmójútó, tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ láti bùkún àti láti fi okun fún olukúlùkù ọkùnrin, òbìnrin, ọ̀dọ́, àti ọmọdé, ní ríran ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, bí a ti ntẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, mo ṣe ìlérí mo sì jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn àtúnṣe pípé wọ̀nyí, ní abẹ́ ìdarí ààrẹ àti wòlíì kan tí ó ní ìmísí, Russell M. Nelson, yío fi agbára àti okun fún olukúlùkù ọmọ Ìjọ. Àwọn ọ̀dọ́ wa yío ṣe ìmúdàgbà ìgbàgbọ́ nlá nínú Olùgbàlà, aó s wọ́n kúrò nínú àwọn ìdánwò ọ̀tá, wọn ó sì dúró ní ìmúrasílẹ̀ láti pàdé àwọn ìdojúkọ ìgbé ayé. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Russell M. Nelson, in “Wòlíì Ọjọ́-ìkẹhìn, Ìyàwó àti Àpọ́stélì Ṣe Àbápín Òye ti Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Gbogbogbò,” Newsroom, Oct. 30, 2018, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  2. Ní àfikún, ẹ ti ṣe àwọn ìtiraka ní pàtó láti lo orúkọ dídára ti Ìjọ bí a ti kọ́ni láti ọwọ́ Ààrẹ Russell M. Nelson àti láti rántí Olùgbàlà wa pẹ̀lú ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀.

  3. “Àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ni a nrán jáde ‘lati ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà rẹ̀ fún ìgbàlà ọkàn àwọn ènìyàn’ (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 138:56). Iṣẹ́ ìgbàlà yi ní ìṣẹ́ ìránṣẹ́ ọmọ ìjọ nínú, mímú àwọn tí wọ́n yipadà dúró, mímú àwọn tí kò ṣe déédé padà, iṣẹ́ tẹmpili ati ìtàn ẹbi, ati kíkọ́ni ní ìhìnrere. Bìṣọ́príkì ndarí iṣẹ́ yìí nínú wọ́ọ̀dù, pẹ̀lú àtìlẹ́hìn láti ọ̀dọ̀ àwọn miràn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù”(Handbook 2: Administering the Church, 5.0, ChurchofJesusChrist.org).

  4. Bíi olùdarí, a fẹ́ràn àwọn ọmọ Ijọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fún ìṣerere yín àti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn. A gbé oríyìn fún ẹnikọ̀ọ̀kan yín, ẹ̀yin ìyá, ẹ̀yin bàbá, ẹ̀yin ọ̀dọ́, àti ẹ̀yin ọmọdé tí ẹ nrìn ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú—tí e sì nṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìfọkànsìn àti ayọ̀.

  5. Ní 2019, àwọn díákónì ẹni-ọdún-mọ́kànlá bẹ̀rẹ̀ sí pín oúnjẹ Olúwa, àti ẹni-ọdún-mọ́kànlá àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọkunrin gba àwọn ìwé ìkaniyẹ́ lílò fún ìgbà díẹ̀. Ní ọdun tí ó kọjá, Ààrẹ Nelson pe àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin wa níjà láti jẹ́ ara àwọn ọmọ ogun ọ̀dọ́ kan láti ṣe àkójọ àwọn Israẹlì tí wọ́n ti fọ́nka ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú (wo “Ìrètí Ísráẹ́lì” [iṣẹ́ ìsìn kári ayé fún àwọn ọ̀dọ́, 3 Oṣù Kẹfà, 2018], HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org). Ìfèsì náà ti dàbí ere ìtàgé.

    Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún nsìn nísisìyí ní ọ̀nà àra ọ̀tọ̀ àti ni àwọn ọjọ́ orí tí ó kéré jù. Láti 6 Oṣù Kẹwáà, 2012, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ti kún ojú òsùnwọ̀n láti sìn ní ẹni ọjọ́ orí ọdún méjìdínlógún, àti ọ̀dọ́mọbìnrin ní ẹni ọjọ́ orí ọdún mọ́kàndínlógún

  6. “Bákannáà ojúṣe ààrẹ lórí Oyè Àlùfáà Áárẹ́nì ni láti ṣe àkóso lórí àwọn àlùfáà, kí ó sì jókòó nínú ìgbìmọ̀ pẹ̀lú wọn, láti kọ́ wọn ní àwọn ojúṣe ipò iṣẹ́ wọn. … Ààrẹ yi níláti jẹ́ bíṣọpù; nítorí èyí ni ọ̀kan nínú àwọn ojúṣe oyè àlùfáà yi” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:87–88).

  7. Àwọn àgbà adarí ní a ó pè bákannáà bíi olùrànlọ́wọ́ sí iyejú Oyè Àlùfáà Áárọ́nì, láti ṣe àtilẹ́hìn pẹ̀lú àwọn ètò àti ìdárayá àti láti wà níbi àwọn ìpàdé iyejú kí àjọ bíṣọ́pù ó le rí ààyè máa bẹ kíláàsì Àwọn Ọdọ́mọbìnrin àti àwọn ìdárayá wọn wò àti Alákọbẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. A le pe àwọn olùrànlọ́wọ́ díẹ̀ láti ṣe àtilẹ́hìn pẹ̀lú ètò kan ní pàtó bíi ìpàgọ́; a le pe àwọn míràn fún ìgbà pípẹ́ láti ran àwọn olùdámọ̀ràn ti ìyejú lọ́wọ́. Ọkùnrin àgbà méjì yío máa wà ní ibi ìpàdé iyejú, ètò, tàbí ìdárayá wọn nígbà gbogbo. Nígbàtí àwọn ojúṣe àti orúkọ ipò yío yipadà, a kò retí dídínkù nínú iye àwọn àgbà ọkùnrin tí yío ṣiṣẹ́ àti àtìlẹhìn ní àwọn iyejú Oyè Àlùfáà Áárọ́nì.

  8. Russell M. Nelson, “Witnesses, Aaronic Priesthood Quorums, and Young Women Classes,” Liahona, Nov. 2019, 39, emphasis added; see also Ezra Taft Benson, “To the Young Women of the Church,” Ensign, Nov. 1986, 85.

  9. A ngba àwọn bíṣọ́pù níyànjú bákannáà láti lo àkókò síi pẹ̀lú àwọn ọmọ ijọ ọ̀dọ́-àgbà ànìkangbé àti àwọn ẹbí ti arawọn.

  10. Jeffrey R. Holland, general conference leadership meeting, Apr. 2018; see also “Effective Ministering,” ministering.ChurchofJesusChrist.org. Alàgbà Holland kọni pé àwọn ojúṣe tí bíṣọ́pù kò le fi rán ẹlòmíràn ni síṣe àkóso lóri àwọn iyejú Oyè Àlùfáà Áárọ́nì àti ti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin, jíjẹ́ onídájọ́ ti gbogbo ènìyàn, mímójútó ètò ìṣúná owó àti àwọn ohun ti ìgbà ìsisìyí ti Ìjọ, àti síṣe ìtọ́jú àwọn aláìní. Àwọn ajọ ààrẹ ti iyeju àwọn alàgbà àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, àti àwọn ẹlòmíràn le gba ojúṣe fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere, iṣẹ́ tẹ́mpìlì àti ìtàn ẹbí, bí ìkọ́ni ti dára tó ní wọ́ọ̀dù, àti síṣe àmójútó àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ìjọ.

  11. Ní àfikún sí àwọn ipò tí ó le nílò àwọn kọ́kọ́rọ́ ti onídajọ́ gbogbo ènìyàn, àwọn bíṣọ́pù nílati dá sí àwọn ọ̀rọ̀ èyíkéyìí ìlòkulò ní ìbámu pẹ̀lú àkóso Ìjọ.

  12. Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ti èèkàn yío tẹ̀síwájú láti máa jíhìn tààrà fún ààrẹ èèkàn.

  13. A lè pe àwọn olùdámọ̀ràn ti ààrẹ Àwọn Ọdọ́mọkùnrin ti èèkàn làti inú àwọn ọmọ ijọ ní èèkàn tàbí, bí a ṣe nílò, ó le jẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ gíga tí a yàn fún Àwọn Ọdọ́mọbìnrin àti ọmọ ìgbìmọ̀ gíga tí a yàn fún Alákọbẹ̀rẹ̀.

  14. Arákùnrin tí ó nṣin bíi ààrẹ Ilé Ẹkọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ní ojúṣe pàtàkì fún ohun-èlò àwọn ọ̀dọ́ ní àwọn Ọjọ́ Ìsinmi méjì nínú oṣù kọ̀ọ̀kan

  15. Àwọn àjọ ààrẹ ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, àwọn Ọdọ́mọbìnrin, àwọn Ọdọ́mọkùnrin, Ilé Ẹkọ́ Ọjọ́ Ìsinmi, àti Alákọ́bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ìpele gbogbogbò àti èèkàn jẹ́ Àwọn Olóyè Gbogbogbò tàbí àwọn olóyè èèkàn. Ní ìpele wọ́ọ̀dù, bìṣọ́príkì ndarí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorínáà àwọn olùdámọ̀ràn ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kìí ṣe olóyè wọ́ọ̀dù.