Ọ̀rọ̀ Ìparí
Ìkàyẹ ẹnìkọ̀ọ̀kan bèèrè fún ìyípadà-ọkàn pípé ti inú àti ọkàn láti dàbí Olúwa sìi.
Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, bí a ṣe dé ìparí ípàdé àpapọ̀ onítàn yí, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa fún àwọn ọ̀rọ̀ ìmísí àti orin tí ó ti gbé wá ga. A ti gbádùn apèjẹ ti ẹ̀mí kan nítòótọ́.
A mọ̀ pé ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì yíò mú ìrètí àti ayọ̀ fún àwọn ènìyàn tí yíò gbọ́ tí yíò si gba ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Bákannáà a mọ̀ pé ilé kọ̀ọ̀kan le di ilé-ìṣọ́ ìgbàgbọ́ nítòótọ́, níbití àláfíà, ifẹ́, àti Ẹ̀mí Olúwa lè gbé.
Bẹ́ẹ̀ni, ayọrísí rere ti Ìmúpadàbọ̀sípò ni tẹ́mpìlì mímọ́. Àwọn ìlànà mímọ́ rẹ̀ àti májẹ̀mù ṣe kókó sí ìmúrasílẹ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ṣetán láti kí Olùgbàlà káàbọ̀ ní Bíbọ Ẹ̀ẹ̀kẹjì Rẹ̀. Lọ́wọ́lọ́wọ́ a ní àwọn tẹ̀mpìlì mẹ́fàlélọ́gọ́jọ tí a ti yàsímímọ́.
Ilé ṣíṣí ni a ó ṣe ṣíwájú ìyàsímímọ́ tẹ́mpìlì titun kọ̀ọ̀kan àti àtúnkọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́ tí kìí ṣe ti ìgbàgbọ́ wa ní rírìnká àwọn tẹ́mpìlì wọnnì à ó sì kọ́ nípa àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì. Àti pé díẹ̀ lára àwọn àlejò wọnnì yíò gba ìfọwọ́tọ́ láti nímọ̀ síi. Àwọn díẹ̀ yíò fi tòdodotòdodo bèèrè bí wọ́n ṣe lè yege fún àwọn ìbùkún ti tẹ́mpílì.
Gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ, a nílò láti múrasílẹ̀ láti dáhùn àwọn ìbèèrè wọn. A lè ṣàlàyé pé àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì wà fún ẹnikẹ́ni àti gbogbo ènìyàn tí yíò múrasílẹ̀ fúnrawọn. Ṣùgbọ́n kí wọ́n tó lè wọnú tẹ́mpìlì kan tí a ti yàsímímọ́, wọ́n ní láti yege. Olúwa nfẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣe àbápín àwọn ìbùkún tó wà nínú tẹ́mpìlì Rẹ̀. Òun ti darí ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe láti yege fún wíwọ ilé mímọ́ Rẹ̀.
Ibi dídára kan láti bẹ̀rẹ̀ irú ànfàní ìkọ́ni kan ni láti pè wọ́n sí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbẹ́ sí ìtà tẹ́mpìlì: “Ìwàmímọ́ sí Olúwa; Ilé ti Olúwa.” Ọ̀rọ̀ Ààrẹ Eyring loni àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn ti mísí wa láti di mímọ́ síi. Tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ibi mímọ́ kan; olùtọ́jú tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan ntiraka láti di mímọ́ síi.
Gbogbo ìnílò láti wọ tẹ́mpìlì ní íṣe pẹ̀lú ìwàmímọ́ araẹni. Láti yẹ ìmúrasílẹ̀ náà wò, ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó bá nfẹ́ láti gbádùn àwọn ìbùkún ti tẹ́mpìlì yíò ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò méjì: àkọ́kọ́ pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù kan, olùdámọ̀ràn bìṣọ́príkì, tàbí ààrẹ ẹ̀ká; ìkejì pẹ̀lú èèkan kan tàbí ààrẹ míṣọ̀n tàbí ọ̀kan lára àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀. Nínú àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wọnnì, onírurú àwọn ìbèèrè ni a ó bèèrè.
Díẹ̀ lára àwọn ìbèèrè wọnnì ní a ti tún-wò fún lílóye. Èmi ó fẹ́ràn láti tun wọn wò fún yín nísisìyí:
-
Ṣe ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àti ẹ̀rí kan nípa Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé; Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì; àti Ẹ̀mí Mímọ́?
-
Ṣé ẹ ní ẹ̀rí Ètùtù Jésù Krístì àti ojúṣe Rẹ̀ bí Olùgbàlà àti Olùràpadà yín?
-
Ṣe ẹ ní ẹ̀rí kan nípa Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì?
-
Ṣe ẹ ṣe ìmúdúró Ààrẹ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti bí ẹnìkanṣoṣo lórí ilẹ̀ ayé tí a fún láṣẹ láti lo gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà?
Ṣe ẹ ṣe ìmúdúró àwọn ọmọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.
Ṣe ẹ ṣe ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò àti àwọn olórí ìbílẹ̀ Ìjọ?
-
Olúwa ti wípé gbogbo àwọn ohun ni a níláti “ṣe nínú ìwẹ̀nùmọ́” níwájú Rẹ̀ (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 42:41).
Ṣé ẹ̀ ntiraka fún ìwà mímọ́ nínú àwọn èrò àti ìhùwàsí yín?
Ṣé ẹ̀ ngbọ́ran sí àṣẹ ìwàmímọ́?
-
Ṣé ẹ̀ ntẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Ìjọ Jésù Krístì nínú ìwà ìkọ̀kọ̀ àti gbangba yín pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹbí yín àti àwọn míràn?
-
Ṣé ẹ nṣàtìlẹhìn tàbí gbé àwọn ìkọ́ni, ìṣe, tàbí ẹ̀kọ́ tó lòdì sí àwọn ti Ìjọ Jésù Krísti ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kọ̀ọ̀kan wọnnì ga.
-
Ṣé ẹ̀ ntiraka láti pa Ọjọ́-ìsinmi mọ́ ní mímọ́, ní ilé àti ìjọ; ṣé ẹ̀ nlọ sí àwọn ìpàdé yín; tí ẹ̀ nmúrasílẹ̀ fún àti láti ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ; tí ẹ sì ngbé ìgbé ayé yín ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ àti òfin ìhìnrere?
-
Ṣé ẹ̀ ntiraka láti jẹ́ olotitọ nínú ohun gbogbo tí ẹ̀ nṣe?
-
Njẹ́ ẹ jẹ́ olùsan idamẹwa-kíkún?
-
Ṣé ẹ ní ìmọ̀ tí ẹ sì ngbọ́ran sí Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n?
-
Ṣé ẹ ní ojúṣe owó tàbí àwọn ohun míràn sí ọkọ tàbí ìyàwó àtijọ́ tàbí sí ọmọ?
Tí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, ṣe ẹ̀ nṣe àwọn ojúṣe wọnnì déédé?
-
Ṣé ẹ̀ npa àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá nínú tẹ́mpìlì mọ́, pẹ̀lú wíwọ ẹ̀wù tẹ́mpìlì bí a ti gbàṣẹ nínú ìfúnnilágbára ẹ̀bùn?
-
Njẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle kan wà nínú ayé yín tí ẹ nílò láti ṣàtúnṣe pẹ̀lú àwọn aláṣẹ oyèàlùfáà bí apákan ìrònúpìwàdà yín?
-
Ṣé ẹ ká ara yín yẹ láti wọnú ilé Olúwa àti láti kópa nínú àwọn ìlànà tẹ́mpìlì?
Lọ́la, àwọn àtúnkọ ìbèèrè ìkaniyẹ tẹ́mpìlì ni a ó pínká sọ́dọ̀ àwọn olórí Ìjọ káàkiri ayé.
Ní àfikún sí dídáhùn àwọn ìbèèrè wọnnì lotitọ, ó jẹ́ ìmọ̀ pé àgbà olùtọ́jú tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan yíò wọ ẹ́wù mímọ́ ti oyèàlùfáà sábẹ́ ẹ̀wu déédé wọn. Èyí jẹ́ alámì ti ìfarasìn inú kan láti tiraka lójoojúmọ́ láti dà bíi Olúwa síi. Bákannáà ó ránwa létí láti dúró lotitọ́ sí àwọn májẹ̀mú tí a ṣe lójoojúmọ́ àti láti rìn ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú lojoojúmọ́ ní ọ̀nà gígajùlọ àti mímọ́ jùlọ.
Fún àkokò díẹ̀, èmi yíò fẹ́ràn láti sọ̀rọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ wa. A gbà yín níyànjú láti yege fún ìkaniyẹ ìlo-òpin tẹ́mpìlì. A ó bi yín ní àwọn ìbèèrè wọnnì nìkan tó wúlò síi yín nínú ìmúrasílẹ̀ yín fún àwọn ìlànà ti arọ́pò ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀. A ní ìmoore gan an fún yíyẹ yín àti ìfẹ́ láti kópa nínú iṣẹ́ tẹ́mpìlì mímọ́. A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín.
Yíyẹ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti wọnú ilé Olúwa nfẹ́ ọ̀pọ̀ imúrasílẹ̀ ti ẹ̀mí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, kò sí ohun tí kò ṣeéṣe. Ní àwọn ọ̀nà kan, ó rọrùn láti kọ́ tẹ́mpìlì kan ju láti gbé àwọn èníyàn ga ní ìmúrasílẹ̀ fún tẹ́mpìlì. Yíyẹ ẹnìkọ̀ọ̀kan nfẹ́ ìyípadà ti inú àti ọkàn pátápátá sí dídàbíi Olúwa, láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè òtítọ́, láti jẹ́ àpẹrẹ dídárasi, àti láti di ẹni mímọ́jùlọ.
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé irú iṣẹ́ ìmúrasílẹ̀ bẹ́ẹ̀ nmú àwọn àìlónkà ìbùkún wá nínú ayé yí àti àwọn ìbùkún àìlègbà fún ayé tó mbọ̀, pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú ẹbí yín káàkiri gbogbo ayé àìlópin nínú ipò “àìparí ìdùnnú láéláé.”1
Nísisìyí èmi yíò fẹ́ràn láti yípadà sí àkórí míràn: àwọn ètò fún ọdún tó mbọ̀. Ní ìgbàìrúwé ti ọdún 2020, yíò jẹ́ igba ọdún gééré látìgbà tí Joseph Smith ti ní ìrírí alárà tí a mọ̀ sí Ìran Àkọ́kọ́. Ọlọ́run Bàbá àti Olólùfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, farahàn sí Joseph, ọ̀dọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn fàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbòsípò ti ìhìnrere Jésù Krístì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀, yékéyéké bí a ṣe sọ́tẹ́lẹ̀ nínú Bíbẹ́lì Mímọ́.2
Nígbànáà ni àtẹ̀lé àwọn ìbẹ̀wò látọ̀dọ̀ àwọn olùránṣẹ́ tọ̀run, pẹ̀lú Mórónì, Jòhánnù Onírìbọmi, àti àwọn Àpọ́stélì Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù. Àwọn míràn tẹ̀le, pẹ̀lú Mósè, Ẹ́líásì, àti Elijah. Ẹnìkọ̀ọ̀kan mú àṣẹ tọ̀run wá láti bùkún àwọn ọmọ Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé lẹ́ẹ̀kansi.
Tìyanutìyanu, bákannáà a ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Ẹ̀rí ti Jésù Krístì Míràn, ẹnìkejì ìwé mímọ́ sí Bíbélì Mímọ́. Àwọn ìfihàn tí a tẹ̀ jáde nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Majẹ̀mú àti Péálì Olówó Iyebíye bákannáà ti fún ìmọ̀ wa nípa àwọn òfin Ọlọ́run àti òtítọ́ ayérayé ní ọ́rọ̀ nlá.
Àwọn kọ́kọ́rọ́ àti ibi-iṣẹ́ oyèàlùfáà ni a ti mú padàsípò, pẹ̀lú àwọn ibi-iṣẹ́ Àpọ́stélì, Àádọ́rin, bàbánlá, àlùfáà gíga, alàgbà, bíṣọ́ọ̀pù, àlùfáà, olùkọ́ni, àti díákónì. Àwọn obìnrin tí wọ́n fẹ́ràn Olúwa sìn bí akọni nínú Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, Alakọbẹrẹ, àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, Ilé-ẹ̀kọ́ Ọjọ́-ìsinmi, àti àwọn ìpè Ìjọ míràn—gbogbo jẹ́ àwọn ara pàtàkì Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Báyìí, ọdún 2020 ni a ó yàn bí igba ọdún àjọyọ̀. Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹrin tó mbọ̀ yíò yàtọ̀ sí gbogbo ìpàdé àpapọ̀ tí a ti ṣe. Ní oṣù mẹ́fà tó mbọ̀, mo nírètí pé gbogbo ọmọ ìjọ àti gbogbo ẹbí yíò múrasílẹ̀ fún ìpàdé ápapọ̀ araọ̀tọ̀ tí yíò ṣàjọyọ̀ àwọn ìpìlẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere gan an.
Ẹ lè fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìmúrasílẹ̀ yín nípa kíka àkọsílẹ̀ Joseph Smith nípa Ìran Àkọ́kọ́ lọ́tun bí a ṣe kọ́ sínú Péálì Olówó Iyebíye. Ìlépa fún àṣàrò wa fún ọdún tó mbọ̀ ni Wá, Tẹ̀lé Mi ni Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ẹ lè fẹ́ láti jíròrò àwọn ìbèèrè pàtàkì bí irú,”Báwo ni ìgbé ayé mi yíò ṣe yàtọ̀ tí a bá mú ìmọ̀ tí mo jèrè látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì kúrò?” tàbí “Báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tẹ̀lé Ìran Àkọ́kọ́ ṣe mú yàtọ̀ wá fún mi àti àwọn olólùfẹ́ mi?” Bákannáà, pẹ̀lú àwọn fídíò Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí ó nwà nísisìyí, ẹ lè fẹ́ láti fi wọ́n sínú àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan yín àti ẹbí.
Ẹ yan àwọn ìbèèrè ti arayín. Ẹ yàwòrán ètò tiyín. Ẹ ri ara yín sínú ìmọ́lẹ̀ ológo ti ìmúpadàbọ̀sípò. Bí ẹ ti nṣeé, ìpàdé àpapọ̀ Oṣù Kẹrin tó mbọ̀ kò ní jẹ́ alárinrin nìkan; yíò jẹ́ àìlègbàgbé.
Nísisìyí ní ìparí, mo fi ìfẹ́ mi sílẹ̀ pẹ̀lú yín àti ìbùkún kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín le nídùnnú si àti di mímọ́ si pẹ̀lú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó nkọjá lọ. Ní báyìí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ dájú pé ìfihàn ntẹ̀síwájú nínú Ìjọ àti pé yíò tẹ̀síwájú lábẹ́ ìdarí Olúwa títí “tí èrò Ọlọ́run yíò fi wá sí ìmúṣẹ, àti tí Jehofa Nla yíò sọ pé iṣẹ́ ti ṣe.”3
Ni mo bùkún yín bẹ́ẹ̀, títẹnumọ́ ìfẹ́ mi fún yín, pẹ́lú ẹ̀rí mi pé Ọlọ́run wà láàyè! Jésù ni Krístì. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀ àti pé àwa ni ènìyàn Rẹ̀. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín