Iṣẹ́ Ìsìn Ìránṣẹ́ Ìhìnrere Bùkún Ayé Mi Títíláé
Mo gbàdúrà pé ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àti àwọn òbí yín yío rí ẹ ó sì mọ̀ bí iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere yío ṣe bùkún ayé yín títíláé.
O ṣeun, Ààrẹ Nelson, fún pípín ìmọ̀ràn náà lẹ́ẹ̀kansíi nípa iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere.
Ẹyin arákùnrin ati arábìnrin, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn bí mo ti nsọ̀rọ̀ nínú ìpàdé apapọ̀, ìríran nínú ojú mi òsì dédé gbàbọ̀dè lójijì nípa ohun kan tí a pè ní ìbájẹ́ màkúlà, èyítí ó burú síi lẹ́hìnwá tí ó sì ti jẹ́ kí nwà láìní ìríran tí ó wúlò nínú ojú náà.
Bí mo ti ntiraka pẹ̀lú ìpèníjà yí, mo nní ìmoore síi fún irú àwọn ìríran, èyí tí ìríran ojú-inú wà nínú rẹ̀. Bí mo ti bojú wẹ̀hìn lórí ìgbésí ayé mi, mo ti le rí àwọn ìrírí kan pàtó tí ó nmú ìyàtọ̀ pàtàkì wá. Ọkan lára àwọn ìrírí wọ̀nyí ni bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi kíkún bíi ọ̀dọ́ ọmọkùnrin ní England ti bùkún ayé mi tí ó sì tún àyànmọ́ mi ti ẹ̀mí ṣe.
Mo ti ronú lórí bí àwọn ìpèníja ti ọrọ̀ ajé tí ó so pọ̀ pẹ̀lú Ìrẹ̀wẹ̀sì Nlá ní 1930 dárí sí àyípadà àìlóríire fún àwọn òbí mi àti ẹbí wa. Baba mi di ẹnití ó fi gbogbo ara sí inú gbígba iṣẹ́ ọkọ̀ títà rẹ̀ là kí ó sì ṣe àtìlẹhìn fún ẹbí kan láàrìn ìgbà ìṣòro yí tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn òbí mi kò le lọ sí ilé ìjọsìn fún àkókò kan.
Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò wà nínú àwọn ìjọsìn ìjọ bí ẹbí, èyí kò dí mi lọ́wọ́ láti wà níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi.
Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, lílọ sí mísọ̀n wà ní apákan inú mi, ṣùgbọ́n kìí ṣe ohun tí mo máa nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òbí mi.
Nígbàtí mo wà ní kọ́lẹ́jì, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti èmi pinnu láti sìn ní àwọn mísọ̀n. Ní ṣíṣe ìbẹ̀wò pẹ̀lú bíṣọ́pù mi, mo fi ọwọ́ sí ìwé ìbèèrè fún ṣíṣe ìránṣẹ́ ìhìnrere mi nígbàtí àwọn òbí mi kò sí nílé. Nígbàtí àwọn obí mi padà dé, mo yà wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú ìròhìn pé a ti pè mí láti sìn ní Great Britain. Mo dúpẹ́ fún àtìlẹ́hìn wọn pẹ̀lú ìtara sí ìpinnu yí àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rere tí wọ́n rànmí lọ́wọ́ ní pinnu láti sìn.
Ìṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere mi pèsè mi sílẹ̀ láti jẹ́ ọkọ àti baba dídára síi àti láti ṣe àṣeyọrí nínú okòwò. Ó pèsè mi bákannáà fún iṣẹ́ ìsìn sí Olúwa nínú Ìjọ Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé.
Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 1985, a yàn mí láti sọ̀rọ̀ nínú abala ti oyè àlùfáà. Mo darí àwọn ọ̀rọ̀ mi sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin. Mo sọ̀rọ̀ nípa mímúra láti sìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere. Mo sọ pé, “Nínú gbogbo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti mo ti gbà nínú àwọn iṣẹ́ yíyàn mi nínú Ìjọ, kò sí èyí tí ó ṣe pàtàkì sími ju ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti mo gbà bi alàgbà ẹni ọdún mọ́kàndínlógún tí ó nsìn ní míṣọ̀n fún àkókò kíkún.”1
Olúwa mọ̀ yín. Nígbàtí ẹ bá nsìn ní míṣọ̀n yín, ẹ ó ní àwọn ìrírí tí yío ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀ Ọ́ dáradára síi. Ẹ ó dàgbàsókè ní ti ẹ̀mí nínú sísìn I. Ní orúkọ Rẹ̀, a ó rán yín ní àwọn iṣẹ lati sin àwọn ẹlòmíràn. Òun ó fún yín ní àwọn ìrírí pẹ̀lú àwọn ìṣílétí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Olúwa yío fún yín ní àṣẹ láti kọ́ni ní orúkọ Rẹ̀. Ẹ le fi hàn Án pé Ó le gbẹ́kẹ̀ lé yín Ó sì le gbé ara lé yín.
Ó lé díẹ̀ ní oṣù márun sẹ́hìn, Alàgbà Jeffrey R. Holland àti Alàgbà Quentin L. Cook, tí àwọn náà ti sìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere ní British Isles, darapọ̀ mọ́ mi ní ṣíṣe àbẹ̀wò sí àwọn ọmọ ìjọ àti àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní ilẹ̀ rírẹwà náà. Nígbàtí a wà níbẹ̀, mo ronú sẹ́hìn lórí àwọn ìrírí mi bíi ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Mo jẹrí pé míṣọ̀n mi ni ibití mo ti mọ̀ pé Baba mi Ọrun àti Olùgbàlà mi Jésù Krístì mọ̀ mí wọ́n sì fẹ́ràn mi.
Mo di alábùkún láti ní àwọn ààrẹ̀ míṣọ̀n oníyanu méjì, Selvoy J. Boyer àti Stainer Richards, lẹgbẹ pẹ̀lú àwọn ojúgbà olùfọnkànsìn wọn Glady Boyer àti Jane Richards. Ní wíwò padà sẹ́hìn, mo le ríi àní kedere síi pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé mi wọ́n sì fẹ́ràn mi. Wọ́n kọ́mi ní ìhìnrere. Wọ́n retí ohun púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. Wọ́n fún mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ yíyàn tó peni níjà àti àwọn ojúṣe jíjẹ́-olórí láti rànmí lọ́wọ́ láti dàgbà kí nsì múrasílẹ̀ fún ìgbé ayé iṣẹ́ ìsìn.
Mo ti ronú sẹ́hìn bákannáà lórí pípè láti ọwọ́ Ààrẹ Spencer W. Kimball láti ṣàkóso lórí Míṣọ̀n Canada Toronto pẹ̀lú ìyàwó mi ọ̀wọ́n, Barbara, àti àwọn ọmọ wa ní ẹ̀gbẹ́ wa. Ààrẹ Kimball pè wá láti sìn ní Oṣù Kẹrin 1974, ní kété lẹ́hìn tí ó fúnni ní ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ ìhìnrere onímísí rẹ̀ pẹ̀lú àkòrí “Nígbàtí Ayé Yío di Yíyípadà.”2 Nínú ọ̀rọ̀ náà, Ààrẹ Kimball ṣe àlàyé ìran rẹ̀ fún bí ìhìnrere yío ṣe di mímú lọ sí gbogbo agbáyé. Ó pè fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere púpọ̀ síi láti àyíká ayé. Ó ránwa létí nípa ìrétí Olúwa “pé gbogbo ènìyàn … gbé ohùn ìkìlọ̀ sókè sí àwọn olùgbé ayé.”3 Ìkọ́ni Ààrẹ Kimball nípa ìrètí fún àwọn ọ̀dọ́mọbkùnrin láti sìn ní míṣọ̀n di àkọlé kan nípa ìbárasọ̀rọ̀ nínú ilé yíká àgbáyé. Ìrètí náà kò tíì yípadà. Mo ní ìmoore pé Ààrẹ Nelson bákannáà fi ìdí ìrètí Olúwa múlẹ̀ ní òwúrọ̀ yi.
Ó ti fẹ́rẹ̀ tó ọdún mẹ́wàá láti ìgbà tí Ààrẹ Thomas S. Monson ti kéde dídín ọjọ́ orí ìránṣẹ́ ìhìnrere kù fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin.4 Ní ìwòye mi, ìdí àkọ́kọ́ pàtàkì fún ìyípadà yí ni láti fún púpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ wa síi ní ànfààní tó nyí ìgbé ayé padà láti sìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere.
Bíi Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì, nísisìyí mo pe ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin—àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n bá ní ìfẹ́ inú láti sìn ní míṣọ̀n kan—láti bẹ̀rẹ̀ nísisìyí láti máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí yín nípa sísìn ní míṣọ̀n kan. Bákannáà mo pè yín láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ yín nípa sísìn ní míṣọ̀n, àti pé bí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ yín kò bá ní ìdánilójú nípa sísìn, ẹ gbà wọ́n níyànjú láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú bíṣọ́pù wọn.
Ẹ ṣe ìpínnu sí ara yín àti sí Baba Ọrun pé ẹ ó sìn ní míṣọ̀n kan àti pé láti àkókò yí lọ ẹ ó tiraka láti ṣe ọkàn yín, ọwọ́ yín, àti àyà yín ní mímọ́ àti yíyẹ. Mo pè yín láti jéré ẹ̀rí tó fẹsẹ̀múlẹ̀ nípa ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadà bọ̀sípò.
Ẹyin baba àti ẹ̀yin ìyá àwọn ọ̀dọ́ dáradára wọ̀nyí, ẹ ní ipa pàtàkì nínú ìlànà ìmúrasílẹ̀ yí. Ẹ bẹ̀rẹ̀ lóni láti máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ yín nípa iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere. A mọ̀ pé ẹbí ni ipá tí ó jinlẹ̀ jùlọ ní ríran àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin wa lọ́wọ́ láti múra.
Bí ẹ bá sì wà nínú àlàfo ọjọ́ orí fún iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere ṣùgbọ́n tí o kò tíì sìn nítorí àjàkálẹ̀ àrùn tàbí àwọn ìdí míràn, mo pè yín láti sìn nísisìyí. Bá bíṣọ́pù rẹ sọ̀rọ̀, kí o sì múra lati sin Olúwa.
Mo gbà yín níyànjú ẹ̀yin bíṣọ́pù láti ran gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n ti súnmọ́ ọjọ́ orí ìránṣẹ́ ìhìnrere lọ́wọ́ láti múra láti sìn, mo sì gbà yín níyànjú bákannáà ẹ̀yin bíṣọ́pù láti ṣe ìdámọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ti dàgbà tó ṣùgbọ́n tí wọn kò tíì sìn. Pe ọ̀dọ́mọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti di ìránṣẹ́ ìhìnrere, àti bẹ́ẹ̀ náà ọ̀dọ́mọbìnrin kọ̀ọ̀kan tí ó bá ní ìfẹ́ inú láti sìn.
Sí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n nsìn lọ́wọ́lọ́wọ́, a dúpẹ́ lọ́wọ́ yín. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín ti jẹ́ àkókò àjàkálẹ̀ àrun jákèjádò àgbáyé. Bíi àbájáde, ìrírí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín kò dàbí ìrírí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tèmi tàbí àwọn ìrírí èyíkéyi àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n sìn ṣaájú 2020. Mo mọ̀ pé ó ti jẹ́ àìrọrùn. Ṣùgbọ́n nínú àwọn àkókò ìṣòro wọ́nyí, Olúwa ti ní iṣẹ́ kan fún yín láti ṣe, ẹyin sì ti ṣe é dáradára pẹ̀lú ìyanu. Fún àpẹrẹ, ẹ̀yin ti lo ìmọ̀ ẹ̀rọ ní àwọn ọ̀nà titun láti wá àwọn tí wọ́n ṣetán láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì. Bí ẹ ti sìn pẹ̀lú aápọn àti ní ìbámu sí àwọn ìleṣe yín, mo mọ̀ pé Olúwa ní inú dídùn sí akitiyan yín. Mo mọ̀ pé iṣẹ́ ìsìn yín yíò bùkún ayé yín.
Nígbàtí a bá dáa yín sílẹ̀ kúrò nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín, ẹ rántí pé a kò dáa yín sílẹ̀ kúrò nínú iṣẹ́ ṣííṣe nínú Ìjọ. Ẹ gbèrú síi nínú àwọn ìwà rere tí ẹ tí kọ́ ní míṣọ̀n yín, ẹ tẹ̀síwájú láti máa fún ẹ̀rí yín lókun, ẹ ṣiṣẹ́ kára, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ sì jẹ́ olùgbọ́ràn sí Olúwa. Ẹ bu ọlá fún àwọn májẹ̀mú ti ẹ ti dá. Ẹ tẹ̀síwájú láti máa bùkún kí ẹ sì máa sin àwọn ẹlòmíràn.
Mo gbàdúrà pé ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àti àwọn òbí yín yío rí ẹ ó sì mọ̀ bí iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere yío ṣe bùkún ayé yín títíláé. Njẹ́ kí ẹ le mọ̀ ní inú yín kí ẹ sì ní ìmọ̀lára nínú ọkàn yín agbára ìpè náà tí Olúwa fún ìránṣẹ́ ìhìnrere nlá àwọn ọmọkùnrin Mosíah. Ó wípé, “Ẹ jáde lọ … kí ẹ sì gbé ọ̀rọ̀ mi kalẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin níláti ní sùúrù nínú ìpamọ́ra àti àwọn ìpọ́njú, kí ẹ̀yin lè fi àwọn àpẹrẹ rere hàn jáde … nínú mi, èmi yíò sì ṣe yín ní ohun èlò ní ọwọ́ mi sí ìgbàlà àwọn ọkàn púpọ̀.”5
Njẹ́ kí Ọlọ́run bùkún àwọn ọ̀dọ́ Ìjọ láti ní ìfẹ́-inú àti láti sìn Ín ni àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ mi, èyí tí mo fúnni ní òwúrọ̀ yí ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.