Ìyípadà Nla Ọkàn
“Èmi Kò Ní Ohunkóhun Síi Láti Fún Ọ”
Ìyípadà nlá ti ọkàn yi kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀; ó gba ìgbàgbọ́, ìrònúpìwàdà, àti iṣẹ́ ti-ẹ̀mí léraléra láti ṣẹlẹ̀.
Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú
Ní ọjọ́ Jímọ̀, Ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n Oṣù Kẹwa, Ọdún 1588, lẹ́hìn tí ó ti pàdánù ìtọ́ka rẹ̀ láti jẹ́ síṣàkóso nípasẹ̀ atukọ̀ nìkan, ọkọ̀ ojú omi La Girona, tí ó jẹ́ ti Armada Nlá ti ìlú Spanish, kọlu àwọn àpáta ti Àmì Lacada ní Ìhà Àríwá Ireland.1
Ọkọ̀ ojú omi náà dojúdé. Ọ̀kan lára àwọn ẹni-tó dànù tí ó ńlàkàkà láti yè wọ òrùka wúrà tí aya rẹ̀ fún un ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn pẹ̀lú àkọlé náà pé, “Èmi kò ní ohunkóhun síi láti fún ọ.”2
“Èmi kò ní ohunkóhun sìi láti fún ọ”—gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan àti orúka kan pẹ̀lú àwòrán ọwọ́ kan tí ó di ọkàn mú, ìfarahàn ìfẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ ìyàwó sí ọkọ rẹ̀.
Àsopọ̀ Ìwé-mímọ́
Nígbàtí mo ka ìtàn yìí, ó ní ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ sí mi, mo sì ronú nípa ìbèèrè tí Olùgbàlà béèrè: “Ẹ̀yin yíò sì fi sílẹ̀ bíi ìrúbọ fún mi ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́.”3
“Bẹ́ẹ̀ni, a gba gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwọ ti sọ fún wa gbọ́…, tí ó ti ṣe ìyípadà ńlá nínú wa, tàbí nínú ọkàn wa, pé àwa kò ní ìtẹ̀sí láti ṣe búburú mọ́, bíkòṣe láti máa ṣe rere nígbà gbogbo.”4
Àsopọ̀ ti Araẹni
Ẹ jẹ́ kí nsọ ìrírí kan tí mo ní nígbàtí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá fún yín, ipa èyítí ó ṣì wà títí di òní olónìí.
Ìyá mi wípé, “Eduardo, yára kíá. A ti pẹ́ fún àwọn ìpàdé Ìjọ.”
“Màmá, Èmi yíò dúró pẹ̀lú bàbá lóni,” Mo dáhùn.
“Ṣé ó dá ọ lójú? O ní láti lọ sí ìpàdé ẹgbẹ́ iyejú àlùfáà rẹ,” ni ó sọ.
Mo fesi wipe, “Baba talaka! Òun ni a ó fi sílẹ̀ làti dá nìkan wa. Èmi yíò dúró pẹ̀lú rẹ̀ lóni.”
Bàbá kìí ṣe ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.
Màmá mi àti àwọn arábìnrin mi máa nlọ sí àwọn ìpàdé ọjọ́ Ìsinmi. Nítorínáà, mo lọ pàdé bàbá nílé iṣẹ́-ọwọ́ rẹ̀, níbití ó fẹ́ràn láti má a wà ní àwọn ọjọ́ Ìsinmi, àti gẹ́gẹ́bí mo ti sọ fún ìyá mi, mo lo àkókò díẹ̀, èyiinì, ìṣẹ́jú díẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti lẹ́hìn náà mo béèrè pé, “Bàbá, ṣé gbogbo nkan dára?”
Ó nbá iṣẹ́ àṣenọjú rẹ̀ nìṣó níti àtúnṣe àwọn rédíò àti aago, ó sì rẹ́rìn músẹ́ sí mi.
Lẹ́hìnnáà Mo sọ fún un pé, “Èmi yíò lọ ṣeré pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi.”
Bàbá, láì wòkè, sọ fún mi pé, “Òni ni ọjọ́ Àìkú. Ṣé kò yẹ fún ọ láti lọ sí ilé ìjọsìn? ”
“Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọn lóni Mo sọ fún Màmá Èmi kì yíò lọ,” Mo dáhùn. Bàbá tẹ̀síwájú nípa ìṣòwò rẹ̀, àti fún mi, èyí jẹ́ ìgbaniláàyè láti lọ.
Ní òwúrọ̀ náà eré bọ́ọ̀lù pàtàkì kan wà, àwọn ọ̀rẹ́ mi ti sọ fún mi pé wọ́n nílò mi, Èmi kò le pàdánù rẹ̀, àti pé a ní láti borí eré yẹn.
Ìpèníjà mi ni pé Mo ní láti kọjá ní iwájú ilé ìjọsìn láti lọ sí pápá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá náà.
Pẹ̀lú ìpinnu, mo sáré lọ sí ìhà pápá ìṣeré bọ́ọ̀lù náà, mo sì dára dúró níwájú ibi ìkọ̀sẹ̀ ńlá náà, ilé ìjọsìn. Mo sáré lọ sí ojú ọ̀nà ẹlẹ́sẹ ní òdì-kejì, níbití àwọn igi ńlá kan wà, mo sì pinnu láti sáré ní àárín wọn kí ẹnikẹ́ni má bàa rí mi níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ àkókò tí àwọn ọmọ ìjọ ńdé sí ìpàdé.
Mo dé ní àsìkò gẹ́gẹ́ fún ìbẹ̀rẹ̀ eré náà. Mo lè ṣeré kí nsì lọ sílé ṣíwájú kí ìyá mi tó délé.
Ohun gbogbo ti lọ dáradára; ẹgbẹ́ wa ti borí, inú mi sì dùn. Ṣùgbọ́n aré sísá mi dáradára náà sí ibi pápá kò lọ láìjẹ́ fífiyèsí nípasẹ̀ olùdámọ̀ràn ẹgbẹ́ àwọn diakoni.
Arákùnrin Félix Espinoza ti rí mi tí mò ńsáré láti igi dé igi, tí mo ńgbìyànjú kí a máṣe dá mi mọ̀.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀, arákùnrin Espinoza wá sí ilé mi ó sì bèèrè láti bá mi sọ̀rọ̀. Kò sọ ohunkóhun nípa ohun tí òun rí ní ọ́jọ́ Ìsnimi, bẹ́ẹ̀ ni kò béèrè lọ́wọ́ mi ìdí tí mo fi pàdánù ìpàdé mi.
Ó kàn fi ìwé kíkà ṣọwọ́ sí mi ó sì wípé, “Èmi yíò fẹ́ kí o kọ́ kílásì oyè-àlùfáà ní Ọjọ́-ìsinmi. Mo ti sámì sí ẹ̀kọ́ náà fún ọ. Kò ṣòro púpọ̀. Mo fẹ́ kí o kà á, àti pé èmi yíò sì kọjá wá lọ́jọ́ méjì láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ìmúrasílẹ̀ fún ẹ̀kọ́ náà. Lẹ́hìn tí ó ti sọ èyí, ó fi ìwé ìléwọ́ lé mi lọ́wọ́ ó sì lọ.
Èmi kò fẹ́ láti kọ́ kílàsì náà, sùgbọ́n Èmi kò nígboyà láti sọ fún un pé bẹ́ẹ̀kọ́. Mo tún ti gbèrò ní ọjọ́ Ìsinmi èyíinì, láti wà pẹ̀lú bàbá mi lẹ́ẹ̀kansi, ìtumọ̀, eré pàtàkì míran wà.
Arákùnrin Espinoza jẹ́ ènìyàn kan tí àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ràn.5 O ti ri ihinrere ti a mu pada sípò o si yi igbesi aye rẹ pada tabi, ni awọn ọrọ miiran, ọkan rẹ.
Nígbàtí ọ̀sán Sátidé dé, mo ronú pé, ó dára, bóyá lọ́la ni èmi yíò jí ṣàìsàn, àti pé èmi kì yíò lọ sí ilé-ìjọsìn. Kìí ṣe eré bọ́ọ̀lù ló ṣe àníyàn mi mọ́; Kíláàsì tí mo ní láti kọ́ ni, pàápàá ẹ̀kọ́ kan nípa ọjọ́ Ìsinmi.
Ọ̀jọ́ ìsinmi dé, Mo sì jí nínú ìlera pípé ju láéláé. Èmi kò ní awáwí—kò sí ọ̀nà àbáyọ.
Ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí èmi ó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n Arákùnrin Espinoza wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ọjọ́ náà sì ni ọjọ́ ìyípadà ọkàn nlá fún mi.
Láti ìgbà náà lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í pa ọjọ́ Ìsinmi mọ́ ní mímọ́, àti bí àkókò ti ńlọ, nínú àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson, ọjọ́ Ìsinmi ti di ìdùnnú.6
“Olúwa, mo fún ọ ní ohun gbogbo; Èmi kò ní ohunkóhun síi láti fún ọ.”
Rírígbà
Báwo la ṣe lè rí ìyípadà ọkàn ńlá náà gbà? A ti fi lélẹ̀ àti níkẹhìn ó wáyé:
-
Nígbàtí a bá ka àwon ìwé-mímọ́ láti gba ìmọ̀ tí yíò mú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì lókun, èyí tí yíò dá ìfẹ́ láti yípadà sílẹ̀.7
-
Nígbàtí a bá nmú ìfẹ́ náà dàgbà nípa àdúrà àti ààwẹ̀.8
-
Nígbàtí a bá ṣe ìṣe, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí a ti kọ́ tàbí gbà, tí a sì dá májẹ̀mú láti fi ọkàn wa lé E lọ́wọ́, bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn ènìyàn ọba Bẹ́ńjámínì.9
ìdámọ̀ àti Májẹ̀mú
Báwo ni a ó ṣe mọ̀ pé ọkàn wa nyí padà?10
-
Nígbàtí a bá fẹ́ tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn nínú ohun gbogbo.11
-
Nígbàtí a bá fi ìfẹ́, ìbọ̀wọ̀, àti àkíyèsí bá àwon ẹlòmíràn lò.12
-
Nígbàtí a bá ri pé àwọn ìwà bí ti Krístì ndi ara ìṣesí wa.13
-
Nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára itosona ti Emi Mimo lémọ́lémọ́ síi.14
-
Nígbàtí a bá pa òfin tí ó ti ṣòro fún wa láti gbọ́ràn si tẹ́lẹ̀ mọ́ àti lẹ́hìnnáà tí a tẹ̀síwájú lati gbé ìgbé ayé rẹ̀.15
Nígbàtí a bá tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sí ìmọ̀ràn àwọn olórí wa tí a sì fi ìdùnnú pinnu láti tẹ̀lé e, a kò ha ti ní ìrírí ìyípadà ọkàn nlá bí?
“Olúwa, mo fún ọ ní ohun gbogbo; Èmi kò ní ohunkóhun síi láti fún ọ.”
Ìtọ́jú àti Àwọn Ànfàní
Báwo ni a ṣe lè ṣètọ́jú ìyípadà nlá náà?
-
Nígbàtí a bá ngba oúnjẹ Olúwa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí a sì nse àtúnṣe májẹ̀mú láti gba orúkọ Krístì sórí wa, láti rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo, àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.16
-
Nígbàtí a bá yí ìgbé ayé wa sí ìhà tẹ́mpìlì.17 Wíwá sí tẹ́mpìlì déédé yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti ṣètọ́jú ọkan titun bí a ṣe nṣe nkópa nínú àwọn ìlànà.
-
Nígbàtí a bá fẹ́ràn tí a sì sin àwọn aladugbo wa nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́-ìránṣẹ́ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere.18
Nígbànáà fún ayọ̀ nlá wa, ìyípadà àtinúwá náà yíò lókun yío sì tànká títí yíò fi pọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ rere.19
Ìyípadà nlá ti ọkàn yi nmú ìmọ̀lára òmìnira, igbekele, ati alafia wá fún wa.20
Ìyípadà nlá ti ọkàn yi kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀; ó gba ìgbàgbọ́, ìgboyà, àti iṣẹ́ ẹ̀mí ìgbà gbogbo láti ṣẹlẹ̀. Ó máa ńbẹ̀rẹ̀ nígbàtí a bá fẹ́ láti fi ìfẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́, ó sì máa nfarahàn nígbàtí a bá wọ inú tí a sì pa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́.
Ìṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan yi ní ipa rere lórí àwa àti lórí àwọn ènìyàn tó wà láyiká wa.
Nínú àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson, “Ronú kíákíá bí àwọn ìjà olóró jákèjádò ayé—àti àwọn tí ó wà nínú ìgbésí ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa—yíò tètè yanjú tí gbogbo wa bá yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì àti láti gbọ́ àwọn ìkọ́ni rẹ̀.”21 Iṣe ti títẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ Olùgbàlà yí ndarí sí ìyípadà nlá ti ọkàn.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, ẹ̀yin ọ̀dọ́, àti ẹ̀yin ọmọdé, bí a ṣe nkópa nínú ìpàdé àpapọ̀ ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí, ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì wa, tí yíò ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wọ inú ọkàn wa láti ní ìrírí ìyípadà nlá kan.
Fún àwọn wọnnì tí wọn kò tíì darapọ̀ mọ́ Ìjọ Olúwa tí a mú padàbọ̀sípò, mo pè yín láti fetí sí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere pẹ̀lú ìfẹ́ àtọkànwá láti mọ ohun tí Ọlọ́run nretí láti ọ̀dọ̀ yín kí ẹ sì ní ìyípadà àtinúwá náà.22
Lóni ni ọjọ́ láti pinnu láti tẹ̀lé Olúwa Jésù Krístì. “Olúwa, mo fún ọ, ní ọkàn mi; Èmi kò ní ohunkóhun síi láti fún ọ.”
Gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe rí òrùka náà padà láti inú ọkọ̀ ojú omi tó rì, nígbàtí a bá fi ọkàn wa fún Ọlọ́run, a ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn òkun ríru ti ayé yìí, àti nínú ètò náà a ó tún wa ṣe a ó si sọ wá di ọ̀tun nípasẹ̀ Ètùtù ti Kristi a ó sì di “àwọn ọmọ Kristi,” jíjẹ́ ti-ẹ̀mí “tí a bí nípa Rẹ̀.”23 Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.