Láti Wo Ayé Sàn
Àwọn àpá àti ìyàtọ̀ ni a lè yanjú àní kí a sì wò wọ́n sàn nígbàtí a bá nbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, Baba gbogbo wa, àti Jésù Krístì, Ọmọ Rẹ̀.
Arákùnrin àti arábìnrin, ní àkokò Ọdún Àjínde ológo, a di alábùkún gidi láti pàdé àti láti gba àmọ̀ràn àti ìdarí látọ́dọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
Ìtọ́nisọ́nà àti àwọn ìkọ́ni mímọ́ látọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run nrànwálọ́wọ́ láti yíká nínú ayé ìgbà ewu wọ̀nyí. Bí a ti sọtẹ́lẹ̀, “iná, àti afẹ́fẹ́,” “ogun, ìdágìrì ogun, àti ìsẹ́lẹ̀ ní onírurú ibi,” “àti onírurú ìwà-ìríra,”1 “árùn,”2 “ìyàn, àti àwọn àjàkálẹ̀-àrùn”3 npa àwọn ẹbí, ìletò, àní àti àwọn orílẹ̀-èdè run.
Òmíràn wà tí ó nda àgbáyé láàmú: àwọn ìkọlù lórí yín àti ẹ̀sìn òmìnira mi. Ìdàgbà ìrò yí nwá láti mú ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kúrò ní gbangba, ilé-ìwé, and ìsọ̀rọ̀ ará-ìlú. Àwọn alátakò òmìnira ẹ̀sìn nwá láti fi àwọn ìdènà lé orí fífi ìdánilójú àtọkànwá hàn. Àní wọ́n nṣe ọfíntótó wọ́n si nfi àwọn àṣà ìgbàgbọ́ ṣẹ̀sín.
Irú ìwà bẹ́ẹ̀ npààlà àwọn ènìyàn, dín-iyì àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ araẹni kù, dídára, ọ̀wọ̀, níti-ẹ̀mí, àti àláfíà ẹ̀rí ọkàn.
Kíni òmìnira ẹ̀sìn?
Ó jẹ́ òmìnira ìjọ́sìn ní gbogbo ìgbẹ́kalẹ̀: òmìnira ìkọ́rajọ, òmìnira ìsọ̀rọ̀, Òmìnira láti ṣe ìṣe kórí àwọn ìgbàgbọ́ araẹni, àti òmìnira fún àwọn ẹlòmíràn láti ṣe bákannáà. Òmìnira ẹ̀sìn nfi ààyè gbà wá láti pinnu fún ara wa ohun tí a gbàgbọ́, bí a ó ṣe gbé àti lṣ´ti ṣe ìṣe gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wa, àti ohun tí Ọlọ̀run nretí lọ́dọ̀ wa.
Àwọn akitiyan láti dín irú òmìnira ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ kù kò jẹ́ titun. Nínú gbogbo àkọọ́lẹ̀-ìtàn, àwọn ènìyàn ti jìyà gidigidi ní ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kò yàtọ̀.
Láti ìbẹ̀rẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n nwá Ọlọ́run ti fa-súnmọ́ Òjọ nítorí àwọn ìkọ́ni ẹ̀kọ́ tọ̀run rẹ̀, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, ìrònúpìwàdà, ètò ìdùnnú, àti Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa wa.
Àtakò, inúnibíni, àti pé ìjà kọlu wòlíì àkọ́kọ́ ọjọ́-ìkẹhìn wa, Joseph Smith, àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀.
Ní àárín ìrúkèrúdò nó 1842, Joseph tẹ àwọn kókó ìpìlẹ̀ mẹ́tàlá ti dídàgbà Ìjọ, pẹ̀lú ọ̀kan yí: “Àwa ní ẹ̀tọ́ ànfàní ti sísin Ọlọ́run Alágbára Jùlọ ní ìbámu sí ìdarí ẹ̀mí ọkàn tiwa, a sì gba gbogbo ènìyàn ní ààyè irú ànfàní kannáà, jẹ́ kí wọ́n ó sìn bí wọ́n ti fẹ́, níbití wọ́n fẹ́, tàbí oun tí wọ́n fẹ́.”4
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú, ìdásílẹ̀, àti tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Iyẹn ni àkójá òmìnira ẹ̀sìn.
Wòlíì Joseph Smith bákannáà wípé:
“Mo ní ìgboyà láti kéde níwájú Ọ̀run pé èmi ti ṣetán láti kú ní dídá ààbò bo àwọn ẹ̀tọ́ ti Presbyterian, Baptist, ọkùnrin rere kan ní èyíkéyí ẹ̀sìn míràn; fún irú ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ èyí tí yíò tẹ ẹ̀tọ́ àwọn … Ènìyàn Mímọ́ mọ́lẹ̀ yíò tẹ ẹ̀tọ́ àwọn Roman Catholic, tàbí èyíkèyí ẹ̀sìn míràn tí wọ́n lè mátilẹ̀ ní òkìkí àti àìlera jù láti dá ààbò bo arawọn.
”Ójẹ́ ìfẹ́ òmìnira [tí ó] nmí sí ẹ̀mí mi—òmìnira ìlú àti ẹ̀sìn sí gbogbo ẹ̀yà ẹlẹ́ran ara.”5
Síbẹ̀, àwọn ọmọ Ìjọ ìṣíwájú ni a kọlù tí a sì lé lọ fún ọgọgọ́ọ̀rún máìlì, láti New York sí Ohio sí Missouri, níbití gómìnà ti pàṣẹ kí a “ṣe àwọn ọmọ ìjọ bí ọ̀tá kí a sì pa wọ́n tàbí lé wọn láti ìpínlẹ̀ sí ìpínlẹ̀.”6 Wọ́n sá lọ sí Illinois, ṣùgbọ́n ìdálóró náà tẹ̀síwájú. Àgbájọ ènìyàn pa Wòlíì Josèh, ní ríròpé pípaá yíò pa Ìjọ run kí ó sì fán àwọn onígbàgbọ́ ká. Ṣùgbọ́n àwọn onígbàgbọ́ dúróṣinṣin. Àtẹ̀lé Joseph, Brigham Young, darí ẹgbẹgbẹ̀rún nínú ìkólọ tipátipá máìlì ẹgbẹ̀rúnlémẹ́ta ìwọ̀-òòrùn sí ohun tí a mọ̀ nísisìyí bí Ìpínlẹ̀ Utah.7 Àwọn babanla mi wà lára àwọn àtìpó olùlànà ìṣaájú.
Láti ọjọ́ inúnibíni líle wọnnì, Ìjọ Olúwa ti dàgbà déédé sí bíi míllíọ̀nù mẹ́tàdínlógún ọmọ ìjọ, pẹ̀lú bí ìkọjá ìlàjì tí wọ́n ngbé ní ìtà United States.8
Ní Oṣù Kẹ́rin 2020 Ìjọ ṣe ayẹyẹ àjọ̀dún igba ọdún ti Ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere pẹ̀lú ìkéde kan sí àgbáyé, tí a ṣe nípasẹ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpostélì Méjìlá wa. Ó bẹ̀rẹ̀ pé, “A fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kéde pé Ọlọ́run nifẹ àwọn ọmọ Rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè ti ayé.”9
Olùfẹ́ wòlíì wa, Russell M. Nelson, ti fihàn síwájúsíi:
“Àwa gbàgbọ́ nínú òmìnira, inúrere, àti ìdára fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.
“Gbogbo wa jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ olùfẹ́ni Baba ní Ọ̀run. Ọmọ Rẹ̀, Olúwa Jésù Krístì, pe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ‘dúdú àti funfun, ẹnití ó wà nígbèkùn àti nínú òmínira, ọkùnrin àti obìnrin’ (2 Nefi 26:33).”10
Yẹ àwọn ọ̀nà mẹ́rin tí àwùjọ àti ẹnìkọ̀ọ̀kan fi njèrè látinú òminira wó pẹ̀lú mi.
Àkọ́kọ́ Òmìnira ẹ̀sìn bu-ọlá fún òfin kínní àti ìkejì nlá, ní gbígbé Ọlọ́run sí oókan ìgbé-ayé wa. A kà nínú Máttéù
“Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.”11
“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ yíò fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”4
Bóyá nínú ilé-ìjọsìn, sínágọ́gù, mọ́ṣáláṣí, tàbí abà tí òkè-onírin, àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì àti gbogbo àwọn onígbàgbọ́ irúkannáà lè fi ìfọkànsìn sí Ọlọ́run nípa ìjọsìn Rẹ̀ àti níní-ìfẹ́ láti sin àwọn ọmọ Rẹ̀ hàn.
Jésù Krístì ni àpẹrẹ pípé ti irú ìfẹ́ àti iṣẹ́ ìsìn. Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, ó tọ́jú àwọn aláìní,13 ó wo aláìsàn àti afọ́jú14 sàn.15 Ó bọ́ àwọn elébi,16 Ó ṣí apá Rẹ̀ fún àwọn ọmọdé,17 ó sì dáríji àwọn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí I, àní tí wọ́n kàn án mọ́ àgbélèbú.18
Àwọn ìwé-mímọ́ júwe pé Jésù “lọ ní ṣíṣe rere.”19 Bẹ́ẹ̀ni a gbọ́dọ̀ ṣe.
Èkejì Òmìnira ẹ̀sìn nmú ìfihàn ìgbàgbọ́, ìrètí, àti àláfíà mulẹ̀.
Bí ìjọ kan, a darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀sìn míràn ní dídá ààbò bo àwọn ènìyàn ti gbogbo ìgbàgbọ́ àti ìyílọ́kànpadà àti ẹ̀tọ́ wọn láti sọ̀rọ̀ ìdánilójú wọn. Èyí kò túmọ̀ sí pé a tẹ́wọ́gba ìgbàgbọ́ wọn, tàbí tiwọn àwa, ṣùgbọ́n a ní púpọ̀si ní ìwọpọ̀ ju bí a ti ní pẹ̀lú àwọn ẹnití ó nfẹ́ láti pa wá lẹ́nu mọ́.
Láìpẹ́ mo ṣojú Ìjọ nínú Ẹgbẹ́ Onírurú-ìgbàgbọ́ G20 Ọlọ́dọọdún ní Italy. A gbà mí níyànjú, àní gbé mi ga, nígbàtí mo pàdé pẹ̀lú ìjọba àti olórí ìgbàgbọ́ káàkiri àgbáyé. Mo mọ pé àwọn àpá àti ìyàtọ̀ ni a lè yanjú àní kí a sì wò wọ́n sàn nígbàtí a bá nbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, Baba gbogbo wa, àti Jésù Krístì, Ọmọ Rẹ̀. Olùwòsàn Nlá ti gbogbo ènìyàn ni Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.
Mo ní àkokò dídùnmọ́ni bí mo ti parí ọ̀rọ̀ mi. Àwọn olùsọ̀rọ̀ méje ìṣaájú kò tíì parí ní ọ̀nàkọnà ti àṣà ìgbàgbọ́ tàbí ní orúkọ Ọlọ́run. Bí mo ti nsọ̀rọ̀, mo ròó, “Ṣé kí nkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ yín kí nsì joko sílẹ̀, tàbí ṣé kí nparí ‘Ní orúkọ Jésù Krístì’?” Mo rántí ẹni tí mo jẹ́, àti pé mọ̀ pé Olúwa yíò fẹ́ kí nsọ orúkọ Rẹ̀ láti parí ọ̀rọ̀ mi. Nítorínáà mo ṣé. Wíwo ẹ̀hìn, ó jẹ́ ànfàní mi láti fi ìgbàgbọ́ mi hàn, àti pé tí mo bá ní òmìnira ẹ̀sìn láti jẹ́ ẹ̀rí mi nípa orúkọ Rẹ̀ mímọ́.
Ẹ̀kẹ́ta Ẹ̀sìn nmísí àwọn ènìyàn láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.
Nígbàtí tí a bá fún ẹ̀sìn ní ààyè àti òmìnira láti gbèrú, àwọn onígbàgbọ́ nṣe àwọn ìṣe akọni iṣẹ́-ìsìn jẹ́jẹ́ àti nígbàmíràn. Gbólóhùn Ọ̀rọ àtijọ́ ti Júù “tikkun olam,” ó túmọ̀ sí “láti túnṣe tàbí láti wo ayé sàn,” ni ó nhàn loni nínú àwọn akitiyan ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ gan. A ti parapọ̀ pẹ̀lú àwọn Arannilọ́wọ́ Catholic, tí a mọ̀ bí Caritas Gbogbogbò, Ìrànlọ́wọ́ Ìslámù, àti oyekóye àwọn Júù, Buddhist, Sikh, àti àwọn ìṣètò b Salvation Army and tíiti Ọmọ-ogun Ìgbàlà àti Ìpìlẹ̀ Krìstẹ́nì Káàkiri. Lápapọ̀ a nsin àwọn mí\llíọ́nù nínú àìní, láìpẹ jọjọ nípa ríran àwọn rẹfují ogun lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn abà, àpò sísùn, àti ìpèsè oúnjẹ,20 a sì npèsè àwọn abẹ̀rẹ àjẹsára, pẹ̀lú pólíò21 àti àrùn COVID.22 àwọn ìdárúkọ ohun tí a nṣe gùn, ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ni àwọn àìní.
Kò sí àníàní pé, àwọn ènìyàn onígbàgbọ́, tó nṣiṣẹ́ papọ̀, lè ṣe àwọn ìdásí pàtàkì. Ní àkokò kannáà, iṣẹ́-ìsìn kan-sí-ọ̀kan ní a kò kéde nígbàkugbà ṣùgbọ́n tí ó nyí ayé padà jẹ́jẹ́.
Mo ronú nípa àpẹrẹ ní Lúkù nígbàtí Jésù Krístì nawọ́ jáde sí opó Náìn. Jésù, pẹ̀lú ẹgbẹ́ àtẹ̀lé kan, wá síbi ọ̀wọ́ ìsìnkù ti ọmọkanṣoṣo ti opó náà. Láìsí rẹ̀, òun ndojúkọ ẹ̀dùn-ọkàn, ti-ẹ̀mí, àní àti ìparun ìṣúná-owó. Jésù, ní rírí ojú omijé rẹ̀, wípé, “Má sọkún mọ́.”27 Nígbànnáà Ó fi ọwọ́ tọ́ àga pósí tí ó gbé ara náà, àwọn tí ó rùú sì dúró jẹ́.
“Ọ̀dọ́mọkùnrin,” Ó pàṣẹ, “mo wí fún ọ, Dìde.
“Ẹni tí ó kú náà sì dìde joko, ó bẹ̀rẹ̀ sí ohùn ífọ̀. [Jésù] sì fàá lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.”28
Jíjí òkú dìde jẹ́ iṣẹ́-ìyanu, ṣùgbọ́n gbogbo ìṣe ìwàrere àti àníyàn fún ẹnìkan tí ó nlàkàkà ni ọ̀nàmájẹ̀mú tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bákannáà lè “[lọ] ní ṣíṣe rere,” ní mímọ̀ pé “Ọlọ́run [wà] pẹ̀lú [wa].”29
Àti ẹ̀kẹ́rin Àwọn ìṣe òmìnira ẹ̀sìn bí rírẹ́pọ̀ àti agbára kíkórapọ̀ fún iyì àtúnṣe àti ìwamímọ́.
Ní inú Májẹ̀mú Titun a kà nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyípadà kúrò lọ́dọ̀ Jésù Krístì, ìráhùn ti ẹ̀kọ́ Rẹ̀, “Èyí jẹ́ ìsọ̀rọ̀ líle; tani ó lè gbọ́ ọ?”31
Ìgbe náà ni a ṣì ngbọ́ ní òní láti ẹnu àwọn ẹnití wọ́n nwá láti mú ẹ̀sìn kúrò nínú ìwàásù àti ipá. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀sìn kò bá sí níbẹ̀ láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú títún ìwà ṣe àti làjá ní àwọn ìgbà líle, tani yíò ṣe? Tani yíò kọ́ni ní ìṣòtítọ́, ìmoore, ìdáríjì, àti sùúrù? Tani yíò fi ifẹ́-àìlẹ́gbẹ́, àánú, àti inúrere hàn fún àwọn tí a gbàgbé àti àwọn tí a tẹ̀mọ́lẹ̀? Tani yíò gba àwọn tí wọ́n yàtọ̀ mọ́ra síbẹ̀ tí wọ́n lẹtọ bí gbogbo ènìyàn ti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run? Tani yíò la apá wọn sí àwọn tí ó wà nínú àìní àti láti máṣe wá ẹ̀san? Tani yíò bọ̀wọ̀ fún àláfíà àti ìgbọ́ran sí àwọn òfin títóbi ju àwọn àṣà ti ọjọ́? Tani yíò fèsì sí ẹ̀bẹ̀ Olùgbàlà “Lọ, kí o sì ṣe bákannáà”?32
A yíò ṣé! Bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a ó ṣé.
Mo pè yín láti ṣe olùborí èrèdí òmìnira ẹ̀sìn. Ó jẹ́ ìfihàn ìfúnni-Ọlọ́run ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ti agbára òmínira.
Òmìnira ẹ̀sìn nmú ìbámu wá sí àwọn ìmòye tí ó ndíje. Dídára ẹ̀sìn, àrọ́wọ́tó rẹ̀, àti àwọn ìṣe ìfẹ́ ojojúmọ́ èyí tí ẹ̀sìn nmísí npọ̀si nìkan nígbàtí a bá dá ààbò bo òmìnira láti fihàn àti láti ṣe ìṣe lórí àwọn kókó ìgbàgbọ́.
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè Ọlọ́run. Mo jẹri pé Jésù Krístì ndarí tí ó sì ntọ̀ Ìjọ yí sọ́nà. Ó ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, a kàn án mọ́ agbélèbú, Ó sì jínde ní ọjọ́ kẹta. Nítorí Rẹ̀, a lè gbé lẹ́ẹ̀kansi fún gbogbo àìlopin, àti àwọn ẹnití wọ̀n fẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè wà pẹ̀lú Baba wa ní Ọ̀run. Òtítọ́ yí ni mo kéde sí gbogbo ayé. Mo fi ìmoore hàn fún òmìnira láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.