Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìyípadà Ni Ìlépa Wa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


10:25

Ìyípadà Ni Ìlépa Wa

Kò sí ìró̩pò fún àkokò tí ẹ̀ nlò nínú àwọn ìwé-mímó̩, gbígbó̩ kí È̩mí Mímó̩ sò̩rò̩ sí yín tààrà.

Ó ti lé lọ́dún mẹ́ta péré báyìí, tí a ti jọ wà ní ìrìn àjò papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ti Ìjọ Olúwa. Ó jé̩ Oṣù Kẹwa 2018 nígbàtí Àjo̩ Ààre̩ Ìkínní àti Iyejú Àwọn Àpóstélì Méjìlá pè wá láti kọ nípa Jésù Krístì nípa s̩is̩e às̩àrò àwọn ìwé-mímó̩ ní àṣà titun àti onímísí, pè̩lú Wá, Tè̩lé Mi ohun-èlò bíi ìtó̩nisó̩nà wa.

Ní ìrìn-àjò èyíkéyìí, ódára láti dúró lé̩è̩kò̩ò̩kan láti ṣe àyè̩wò ìlo̩síwájú wa àti láti ri dájú pé a s̩ì ntè̩síwájú sí ibi-afé̩dé wa.

Ìyípadà Ni Ibi-afẹ́dé Wa

Wo ò̩rò̩ tí ó jinlè̩ yí láti ìfihàn sí Wá, Tẹ̀lé Mi::

“Àbájáde gbogbo ìkọ́ni àti ikẹkọ ìhìnrere ni láti mú ìyípadà wa sí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì jinlẹ̀. …

“… Irú ìkọ́ni ìhìnrere tí ó nfún ìgbàgbọ́ wa lókun tí ó sì ndarí sí iṣẹ́ ìyanu ti ìyípadà gbogbo rẹ̀ kìí ṣẹ̀lẹ̀ lẹ́ẹ̀kannáà. Ó gbòòrò kọjá iyàrá ìkàwé sínú ọkàn àti àwọn ilé wa. Ó gba fún ìsapá ojoojúmọ́ ní àìyẹsẹ̀ láti lóye àti láti gbé ìhìnrere náà. Ike̩ko̩ ìhìnrere tí ó darí sí ìyípadà tòótọ́ gba ìdarí Ẹ̀mí Mímọ́.”1

Ìyẹn ni iṣẹ́ ìyanu tí a nwá—nígbàtí ènìyàn kan bá ní ìrírí nínú àwọn ìwé mímọ́2 àti pé ìrírí yẹn jẹ́ ìbùkún nípasẹ̀ ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́. Irú àwọn ìrírí bé̩è̩ jé̩ àwọn òkúta ìpìlè̩ iyebíye fún ìyípadà wa sí Olùgbàlà. Àti gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Russell M. Nelson ṣe rán wa létí láìpẹ́, a gbọ́dọ̀ máa fi kún àwọn ìpìlẹ̀ ti-ẹ̀mí ní ìgbà gbogbo.3 Ìyípadà tí ó pé̩ ni ìlànà ìgbésí-ayé.4 Ìyípadà Ni Ibi-afẹ́dé Wa.

Láti wà ní ìmúnádóko jùlọ, àwọn ìrírí yín pè̩lú àwọn ìwé-mímó̩ gbọdò̩ jé̩ tìrẹ.5 Kíkà tàbí gbígbó̩ nípa àwọn ìrírí àti àwọn òye e̩lòmíràn lè ṣèrànwó̩, ṣùgbó̩n ìyẹn kìí yíò mú agbára ìyípadà kannáà wá. Kò sí ìró̩pò fún àkokò tí lò nínú àwọn ìwé-mímó̩, gbígbó̩ kí È̩mí Mímó̩ sò̩rò̩ sí yín tààrà.

Kíni È̩mí Mímó̩ NKó̩ Mi?

Ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí mo bá ṣí ìwé Wa, Tẹ̀lé Mi , Mo nkọ ìbéèrè yìí sí òkè ojú-ewé náà: “Kí ni Ẹ̀mí Mímọ́ nkọ́ mi ní ọ̀sẹ̀ yí bí mo ṣe nka àwọn orí wọ̀nyí?”

Bí mo ṣe ns̩e às̩àrò àwọn Ìwé Mímọ́, mo máa nronú lé lórí léraléra. Láì kùnà, àwọn ìmísí ti è̩mí nwá, àti pé mo ṣàkíyèsí wọn nínú ìwé àfọwó̩kọ mi.

Nísisìyí, báwo ni mo ṣe mọ ìgbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ nkọ́ mi? Ó dára, ó maa nṣẹlè̩ ní àwọn ò̩nà kékeré tí ó sì rọrùn. Nígbà míràn ẹsẹ ìwé mímọ́ kan yíò dà bí ẹni pé ó fo kúrò ní ojú ewé náà sí àfiyèsí mi. Ní àwọn ìgbà míràn, mo nní ìmò̩lára bí ọkàn mí ti ní ìmó̩lè̩ pè̩lú òye tí ó gbòòrò nípa ìlànà ìhìnrere kan. Mo tún ní ìmọ̀lára ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà tí ìyàwó mi, Anne Marie, àti èmi nsọ̀rọ̀ nípa ohun tí a nkà. Àwọn ìwòye rè̩ nígbàgbogbo npe È̩mí.

Wòlíì àti Ìrékọjá náà

Lọ́dún yìí a nkọ́ nípa Májẹ̀mú Láéláé—ìwé mímọ́ tó nfi ìmọ́lẹ̀ kún ọkàn wa. Nígbàtí a nka Májè̩mú Láéláé, mo ní ìmọ̀lára bí e̩nipé mo nlo àkokò pè̩lú àwọn ìtó̩só̩nà tí ó ṣeé gbé̩kè̩lé: Adam, Efa, Enoku, Noa, Abraham, àti ò̩pò̩lọpò̩ àwọn míràn.

Ní ọ̀sẹ̀ yìí, nígbà tí a nka Ẹ́ksódù orí 7–13, a kọ́ bí Olúwa ṣe dá àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nídè kúrò nínú ọ̀pọ̀ sé̩ntúrì ìgbèkùn ní Egypt. A kà nípa àjàkálẹ̀ àrùn mẹ́sàn—àwọn ìfihàn agbára Ọlọ́run mẹ́sàn tó fani lọ́kàn mọ́ra—tí Fáráò jẹ́rìí sí láìní ìrọ́nú ọkàn rẹ̀.

Nígbànáà ni Olúwa sọ fún wòlíì rẹ̀, Mósè, nípa ìyọnu ìdá mẹ́wàá—àti bí e̩bí kọ̀ọ̀kan ní Ísráẹ́lì ṣe lè múrasílẹ̀ fún un. Gẹ́gẹ́bí ara ààtò-ìsìn tí wọ́n pè ní Ìrékọjá, àwọn ọmọ Ísráẹ́lì gbọ́dọ̀ fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ. Lẹ́hìnnáà, wọ́n ní láti fi ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn sàmì sí àwọn e̩nu ilẹ̀kùn ilé wọn. Olúwa ṣèlérí pé gbogbo ilé tí a fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí ni yíò wà ní ààbò lọ́wọ́ àjàkálẹ̀-àrùn tó nbọ̀ wá.

Àwọn ìwé mímọ́ sọ pé, “Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè” (Ẹ́ksódù 12:28). Ohunkan wà tí ó lágbára púpò̩ nínú ò̩rò̩ ìgbọràn tí ó rọrùn yẹn.

Nítorí pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì tẹ̀lé ìmọ̀ràn Mósè tí wọ́n sì ṣe ìṣe nínú ìgbàgbọ́, a gba wọn là kúrò nínú àjàkálẹ̀ àrùn náà, nígbà tó sì yá, wọ́n dá wọn sílẹ̀ lóko ẹrú.

Nítorínáà, kí ni Ẹ̀mí Mímọ́ kọ́ mi nínú àwọn orí wọ̀nyí ní ọ̀sẹ̀ yí?

Ìwọ̀nyí ni àwọn èrò tí ó wá sí ọkàn mi:

  • Olúwa ṣis̩é̩ nípasè̩ wòlíì Rè̩ láti dáàbòbò àti láti gba àwọn ènìyàn Rè̩ là.

  • Ìgbàgbó̩ àti ìrè̩lè̩ làti tè̩lé wòlíì ṣaájú is̩é̩ ìyanu ààbò àti ìtúsílè̩.

  • Ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí e̩nu ilẹ̀kùn jẹ́ àmì òde ti ìgbàgbọ́ inú nínú Jésù Kristi, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run.

Wòlíì àti Àwo̩n Ìlérí Olúwa

Mo ní ìwúrí pè̩lú íjọra ní àárín ò̩nà tí Olúwa bùkún àwọn ènìyàn Rè̩ nínú àko̩sílè̩ Májè̩mú Láéláé yí àti ò̩nà ti Ó tún nbùkún àwọn ènìyàn Rè̩ lónìí.

Nígbàtí wòlíì alààyè Olúwa, Ààrẹ Nelson, fi Wá, Tẹ̀lé Mi hàn wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́, ó pè wá láti yí àwọn ilé wa padà sí àwọn ibi mímọ́ ti ìgbàgbọ́ àti gbùngbun àwọn ibi ìkẹkọ ìhìnrere.

Lé̩hìnnáà ó ṣèlérí àwọn ìbùkún mé̩rìn pàtó:

  1. àwọn ọjó̩ Ìsinmi yín yíò jé̩ aládùn,

  2. inú àwọn ọmọ yín yíò dùn láti kó̩ àti láti gbé ìgbé ayé àwọn ìkọ́ni ti Olùgbàlà,

  3. ipa ò̩tá ní ìgbésí-ayé yín àti ní ilé yín yíò dínkù, àti pé

  4. àwon ìyípadà nínú ẹbí yín yíò jẹ̀ kíakíá àti mímúdúró. ”6

Níbàyí, a kò ní àwọn ìwé-àko̩sílè̩ èyíkéyíì láti ò̩dò̩ àwọn wò̩nniì tí wó̩n ní ìrírí Ìréko̩já pè̩lú Mósè ní Egypt. Síbè̩síbè̩, a ni ò̩pò̩lo̩pò̩ àwọn ìjé̩risí láti ò̩dò̩ Àwọn Ènìyàn Mímó̩ tí wó̩n, ní ìgbàgbó̩ dídó̩gba, wọ́n ntè̩lé ìmò̩ràn Ààre̩ Nelson lónìí àti gbígba àwọn ìbùkùn ìlérí náà.

Nihin ni àwọn irú ẹ̀rí díẹ̀ bẹ́ẹ̀:

Ìyá e̩bí kékere kan sọ pé: “A nsọ̀rọ̀ nípa Krístì a sì nyọ̀ nínú Kri´stì nínú ilé wa. Sí mi ìyẹn ni ìbùkún nla jùlọ—pé àwọn ọmọ mi lè dàgbà pẹ̀lú àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ìhìnrere wọ̀nyí ní ilé tí ó nmú wọn súnmọ́ Olùgbàlà.”7

Arákùnrin àgbà kan pe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ nípasẹ̀ Wá, Tẹ̀lé Mi “okùn tí ó kún fún ìmọ́lẹ̀ tọ̀run tí ó rànwálọ́wọ́ láti rí ẹ̀kọ́ ìhìnrere tí ó ṣe pàtàkì fún àlááfìà ẹ̀mí wa.”8

Ìyàwó ọ̀dọ́ kan ṣàlàyé àwọn ìbùkún tó wà nínú ìgbéyàwó rẹ̀ pé: “Mo ti túbọ̀ mọ ohun tó wà lọ́kàn ọkọ mi, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún un bí a ṣe nṣe àṣàrò papọ̀.”9

Ìyá ti ẹbí títóbi kan ṣe àkíyèsí bí àwọn ìgbìyànjú rẹ̀ láti kọ́ ẹbí rẹ̀ fi yípadà. Ó dárúkọ pé: “Wíwo ẹ̀hìn, ó dàbí ẹnìpé èmi ntẹ dùrù pẹ̀lú ìbọ̀wọ́ yìnyín lọ́wọ́. Mò nlọ nípasẹ̀ àwọn ìṣísẹ̀padà, ṣùgbọ́n àwọn orin kò tọ́ rárá. Báyìí àwọn ìbọ̀wọ́ wà ní pípa, nígbàtí orin mi kò jẹ́ pípé, mo gbọ́ ìyàtọ̀ náà. Wá, Tẹ̀lé Mi tí fún mí ní ìran, agbára, ìdojúkọ, àti èrèdí.”10

Ọkọ ọ̀dọ́ kan sọ pé: “Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ilé ti túbọ̀ ṣe kedere sí i látìgbà tí mo ti sọ Wá, Tẹ̀lé Mi di déédéé nínú àwọn òwúrọ̀ mi. Ṣíṣe àṣàrò máa njẹ́ kí nronú púpọ̀ sí i nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún mi, bíi tẹ́mpìlì, ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú ìyàwó mi, àti ìpè mi. Mo dúpẹ́ pé ilé mi jẹ́ ibi mímọ́ níbi tí Ọlọ́run ti jẹ́ àkọ́kọ́.”11

Arábìnrin kan ṣe àjọpín pé: “Àwọn ìrírí tí mo ní lójoojúmọ́ pẹ̀lú Wá, Tẹ̀lé Mi kì í fi bẹ́ẹ̀ yẹ fún àfiyèsí, ṣùgbọ́n bí àkokò ti nlọ mo lè rí bí a ṣe nyí mi padà nípa ṣíṣe àṣàrò ìwé mímọ́ ní ìdojúkọ, déédéé. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ máa nfún mi nírẹ̀lẹ̀, ó nkọ́ mi, ó sì nyí mi padà díẹ̀díẹ̀.”12

Òjíṣẹ́ ìhìnrere tó padàbọ̀ kan ròhìn pé: “Ètò Wá, Tẹ̀lé Mi ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ ìpele àṣàrò ìwé mímọ́ tí mo ṣe lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ̀n mi, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti lọ kúrò nínú ọgbọ́n ìfàmìsí àṣàrò ìwé-mímọ́ láti ní àwọn abala sísùnmọ́ni ti mímọ Ọlọ́run.”13

Arákùnrin kan sọ pé: “Mo ní ìmọ̀lára wíwá Ẹ̀mí Mímọ́ sí i nínú ìgbésí-ayé mi mo sì ní ìmọ̀lára ìtọ́sọ́nà ìṣípayá Ọlọ́run nínú ṣíṣe àwọn ìpinnu. Mo ní àwọn ìjíròrò jíjinlẹ̀ síi nípa ẹ̀wà nínú ẹ̀kọ́ rírọrùn ti Krístì àti Ètùtù Rẹ̀.”14

Ọmọ ọdún méje kan ṣe àbápín pé: “Mo máa tó ṣèrìbọmi láìpẹ́, àti pé Wá, Tẹ̀lé mi nmúra mí sílẹ̀. Èmi àti ẹbí mi máa nsọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe ìrìbọmi, èmi kò sì ní ìmọ̀lára ara gbígbọ̀n nípa ṣíṣe ìrìbọmi báyìí. Wá, Tẹ̀lé Mi ṣèrànwọ́ fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti wá sínú ọkàn mi, àti pé inú mi ndùn nígbàtí mo bá ka àwọn ìwé-mímọ́.”15

Àti nígbẹ̀hìn, látọ̀dọ̀ ìyá tí ó ní ọ̀pọ̀ ọmọ: “Bí a ṣe nṣáṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Ó ti ran ẹbí wa lọ́wọ́ láti kúrò nínú àníyàn sí agbára; láti ìdánwò àti ìpèníjà sí ìtúsílẹ̀; láti inú ìjà àti àtakò sí ìfẹ́ àti àlááfìà; àti láti inú ipa ọ̀tá wá sí ipa Ọlọ́run.”16

Ìwọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ àtẹ̀lé Krístì ti gbé ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run sí ẹnu ọ̀nà ilé wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Wọ́n nṣe àfihàn ìfarasìn inú wọn láti tẹ̀lé Olùgbàlà. Ìgbàgbọ́ wo̩n ṣaájú iṣẹ́-ìyanu náà. Ó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu ẹnìkan tó ní ìrírí nínú àwọn ìwé-mímọ́ àti pé ìrírí yẹn jẹ́ bíbùkún nípasẹ̀ ipá ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Nígbà tí a bá nṣàṣàrò àwọn ìwé-mímọ́, kò sí ìyàn ti ẹ̀mí ní ilẹ̀ náà. Gẹ́gẹ́bí Néfì ti sọ, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì fẹ́ dì í mú ṣinṣin, wọn kì yíò ṣègbé láé; bẹ̃ni ìdánwò àti àwọn ọfà iná èṣù kò lè borí wọn sí ìfọ́jù, láti tọ́ wọn kúrò sí ìparun” (1 Néfì 15:24).

Láyé àtijọ́, bí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ṣe tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Olúwa fún wọn nípasẹ̀ wòlíì Mósè, a bùkún wọn pẹ̀lú ààbò àti òmìnira. Lónìí, bí a ṣe ntẹ̀lé ìdarí Olúwa tí a fifúnni nípasẹ̀ wòlíì wa alààyè, Ààrẹ Nelson, bákannáà ni a bùkún wa pẹ̀lú ìyípadà nínú ọkàn wa àti ààbò nínú ilé wa.

Mo jẹ̀rí pé Jésù Krístì wà láàyè. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀, tí a mú padàbọ̀sípò nípa Wòlíì Joseph Smith. Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè ti Olúwa lónìí. Mo nifẹ rẹ̀ mo sì ṣe ìmúdúro rẹ. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún olúkúlùkù àti àwọn Ẹbí: Májẹ̀mú Láéláé 2022, vii.

  2. “Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ojúṣe fún ìdàgbàsókè ti-ẹ̀mí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa” (Russell M. Nelson, “Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀,” Liahona, Oṣù Kọkànlá 2018, 8).

  3. Wo Russell M. Nelson, “Tẹ́mpìlì àti Ìpìlẹ̀ Ti-ẹ̀mí Rẹ,” Liahona, Nov. 2021, 93–96.

  4. Èyí jẹ́ ìdí pàtàkì tí Ààrẹ Nelson fi rọ̀ wá láti “fi àkokò fún Olúwa! Ẹ mú kí ìpìlẹ̀ ẹ̀mí yín dúró ṣinṣin kí ó sì le kojú ìdánwò àkokò nípa síṣe àwọn nkan wọnnì tí yío fi ààyè gba Ẹmí Mímọ́ lati wà pẹ̀lú yín nígbàgbogbo” (“Wá Ààyè Fún Olúwa,” Liahona, Nov. 2021, 120).

  5. “Láìbìkítà ohun tí àwọn míràn lè sọ tàbí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó lè mú ẹ̀rí tí ó wá sí ọkàn àti àyà rẹ nípa ohun tí ó jẹ́ òtítọ́” (Russell M. Nelson, “Ìfihàn Fún Ìjọ, Ìfihàn Fún Ìgbé-ayé Wa,” Liahona, May 2018, 95).

  6. Wo Russell M. Nelson, “Dída Àpẹrẹ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Liahona, Nov. 2018, 113–14. Ààrẹ Nelson tún ìpè yí sọ ní Oṣù Kẹ́rin tó kọjá: “Ìfarajìn yín láti mú ilé yín jẹ́ kókó ibi mímọ́ ti ìgbàgbọ́ kò gbọdọ̀ dópin láé. Bí ìgbàgbọ́ àti ìwà mímọ́ ti ndínkù nínú ayé tó nṣubú yi, ìnílò yín fún àwọn ibi mímọ́ nlékún. Mo rọ̀ yín láti tẹ̀ síwájú láti sọ ilé rẹ di ibi mímọ́ nítòótọ́ ‘àti pé kí a má ṣípd’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 87:8; àtẹnumọ́ àfikún] látinú àfojúsùn pàtàkì náà” (“Ohun Ti À Nkọ́ Tí A Kò Ní Gbàgbé Láéláé,” Liahona, May 2021, 79).

  7. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni; bákannáà wo 2 Néfì 25:26.

  8. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  9. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  10. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  11. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  12. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  13. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni

  14. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  15. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  16. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.