Nínú Ìyanu Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀
Njẹ́ kí ìrántí ohun tí ojú wa ti rí tí ọkàn wa sì ti ní ìmọ̀lára mú kí ìyàlẹ́nu wa sí ẹbọ ètùtù ti Olùgbàlà pọ̀ si.
Mo ní ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, olùfẹ̀hìntì kòfẹ́sọ̀ unifásitì, amòye onkọ̀wé, àti, paríparí rẹ̀, olùfarajìn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì kan. Ó ti bẹ Ilẹ̀ Mímọ́ wò ní ìgbà dọ́sìnì láti kópa nínú àwọn ìpàdé àpapọ̀, ṣe ìwákiri ẹ̀kọ́, ó sì ndari àwọn ìrìnàjò. Gẹ́gẹ́bí ti rẹ̀, gbogbo ìgbà tí ó bá ṣèbẹ̀wò sí ilẹ̀ náà níbití Jésù ti rìn, ó níyanu nítorí láìṣiyèméjì òun ti kọ́ àwọn ohun titun, níní-ìyàlẹ́nu, wíwuni nípa Olùgbàlà, iṣẹ́-ìrànṣẹ́ ayé-ikú Rẹ̀, àti ìlú olùfẹ́ Rẹ̀. Ọ̀wọ̀ tí ọ̀rẹ́ mi nfihàn nígbàtí ó bá nsọ̀rọ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ti kọ́ nínú Ilẹ̀ Mímọ́ nranni; àti pé ìyanilẹ́nu yí ti jẹ́ ìpìlẹ̀ nínú àwọn àyọrísí nlá àti àwọn ìlépa ẹ̀kọ́ nínú ayé rẹ̀.
Bí mo ti nfetísílẹ̀ sí àwọn ìrírí rẹ̀ àti ìmọ̀lára ìwúrí rẹ̀, mo ti ronú lórí bí ìyanu ti-ẹ̀mí ti pọ̀ tó, kí nwí bẹ́ẹ̀, pé a lè àti pé a níláti ní ìmọ̀lára fún ìhìnrere tí Jésù Krístì àti pé ìyàtọ̀ tí ó lè mú wá nínú jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn wa àti nínú ìrìnàjò wa síwájú ìyè ayérayé. Ìyàlẹ́nu tí mo tọ́ka sí ni àìbàlẹ̀ ẹ̀dùn-ọkàn, ọ̀wọ̀, tàbí àrà tí ó wọ́pọ̀ sí gbogbo ẹnití wọ́n fi tọkàn-tọkàn gbé ayé wọn lé Olùgbàlà àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ àti tí wọ́n fi ìrẹ̀lẹ̀ dá wíwà Rẹ̀ nínú ayé wọn mọ̀. Irú ìmọ̀lára ìyanu kan, tí agbára Ẹ̀mí Mímọ́ nípasẹ̀ ìmísí, nwú ìwúrí sókè láti fi tayọ̀tayọ̀ gbé ìgbé-ayé ẹ̀kọ́ Krístì.1
Àwọn ìwé-mímọ́ wà pẹ̀lú onírurú àwọn àpẹrẹ bí a ṣe lè fi wíwúsókè yí hàn. Wólíì Ísáíàh, fún àpẹrẹ, fi ìjìnlẹ̀ ìmoore rẹ̀ hàn sí Olúwa nípasẹ̀ yíyayọ̀ rẹ̀ nínú Rẹ̀.2 Àwọn tí wọ́n gbọ́ tí Jésù nwàásù nínú sínágọ̀gù ní Cápánáùmù ní ìyànu fún ẹ̀kọ́ Rẹ̀ àti okun pẹ̀lú èyí tí Ó fi nkọ́ ọ.3 Ó jẹ́ iru ìmọ̀lára kannáà tí ó wọnú gbogbo ọkàn Joseph Smith kékeré bí òun ti nka àwọn orí ìkínní ti Jákọ́bù, tí ó darí rẹ̀ sí wíwá ọgbọ́n Ọlọ́run.5
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nígbàtí a bá wà nínu ọ̀wọ̀ ti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ nítòótọ́, a nní ìdùnnú si, a nní ìwúrí si fún iṣẹ́ Ọlọ́run, a sì ndá ọwọ́ Olúwa mọ̀ nínú ohun gbogbo. Ní àfikún, àṣàrò wa nípa àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nní ìtumọ̀ si, àdúra wa, mímọ̀ọ́mọ̀ sí; ìjọ́sìn wa, ìbọ̀wọ̀ si, iṣẹ́-ìsìn nínú ìjọba Ọlọ̀run, nní aápọn si. Gbogbo àwọn iṣe wọ̀nyí jẹ́ ìdásí sí ipá Ẹ̀mí Mímọ́ tó nfi ìgbà gbogbo wà ní ayé wa.6 Báyìí, ẹ̀rí wa nípa Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ yíò lókun, a ó pa Krístì mọ́ ní ààyè nínú wa,7 a ó sì gbé ìgbé ayé wa ní “mímulẹ̀ kí a sì gbésókè nínú rẹ, kí a sì dádúró nínú ìgbàgbọ́, … gbígbé níbẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣọpẹ́.”8 Nígbàtí a bá ngbé ní ọ̀nà yí, a ndi olùfaradà ti ẹ̀mí si àti olùdáàbòbò ní àtakò sí ṣíṣubú sínú pàkúté àìbìkítà ti-ẹ̀mí.
Irú àìbìkítà bẹ́ẹ̀ nwá nípasẹ̀ ìsọnù díẹ̀díẹ̀ ti ìdùnnú wa láti ṣiṣẹ́ kíkún nínú ìhìnrere Olúwa. Gbogbo rẹ̀ nbẹ̀rẹ̀ nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára pé a níláti gba gbogbo ìmọ̀ àti àwọn ìbùkún tó ṣeéṣe fún ìdùnnú wa nínú ayé yí. Ìgbàmọ́ra yí, kí a sọ bẹ́ẹ̀, nfa kí a mú àwọn ìhìnrere yẹpẹrẹ, àti nígbànáà lọ, kí a wọ ewu ti pípatì ìwọnú déédéé àwọn pàtàkì ìhìnrere Jésù Krístì9 àti àwọn májẹ̀mú tí a ti ṣe. Ní àyọrísí, a njìnnà ara wa díẹ̀díẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Olúwa; rírẹ agbára wa sílẹ̀ láti “Gbọ́ Tirẹ̀,”10 dida aláìnáání àti àìnítara sí iṣẹ́ títóbijùlọ Rẹ̀. Iyèméjì nípa àwọn òtítọ́ ẹ̀rí wa tí a ti gbà tẹ́lẹ̀ nwọ inú àti ọkàn wa, ó nmú wa ní ìpalára sí àwọn àdánwò ọ̀tá.11
Olùṣọ́ Aiden Wilson Tozer, ònkọ̀wé mímọ̀ àti akọni Krìstẹ́nì, kọ pé, “Ìtẹ́lọ́rùn ni ọ̀tá búburú ti gbogbo ìdàgbà ti-ẹ̀mí.”11 Njẹ́ èyí kìí ṣe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn Néfì ní kété lẹ́hìn ìbí Krístì? Wọ́n “bẹ̀rẹ̀sí dínkù àti dínkù ní ìyanu sí àmì tàbí ìyalẹ́nu láti ọ̀run,” ní ṣíṣe iyèméjì nínú “[àìgbàgbọ́] gbogbo èyí tí wọ́n ti gbọ́ tí wọ́n sì ti rí.” Báyìí ni Sátánì “nfọ́ wọn lójú tí ó sì ndarí wọn kúrò ní gbígbàgbọ́ pé ẹ̀kọ́ Krístì jẹ́ ohun píponú àti òfo.”13
Ẹ̀yin olùfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, nínú ìfẹ́ pípé àìlópin àti mímọ ìwà-ẹ̀dá ènìyàn wa,14 Olùgbàlà ti gbé ọ̀nà kalẹ̀ fún wa láti yẹra ṣíṣubú sínú pàkúté àìbìkítà ti-ẹ̀mí. Ìpè Olùgbàlà fún wa ní ojú ìwòye tí ó gbòòrò, ní pàtàkì ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò ayé dídíjú nínú èyí tí a ngbé: “Kọ́ nípa mi, kí o sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi; ma rin ninu iwa tutu Ẹ̀mi mi, ẹ̀nyin o si ni alafia ninu mi.”14 Bí a ti ntẹ́wọ́gba ìpè yí láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, a njúwe ìrẹ̀lẹ̀ wa, ìfẹ́ wa láti gba ẹ̀kọ́, àti ìrètí wa láti dàbíi Rẹ̀ sì.16 Bákannáà ìpè yí wà pẹ̀lú sìsìn Ín àti ṣíṣé iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ọlọ́run “pẹ̀lú gbogbo ọkàn, okun, inú àti agbára [wa].”16 Ní kókó ìlàkàkà wa nínú ìrìnàjò yí ni, bẹ́ẹ̀ni, àwọn òfin méjì nlá: láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run wa àti fífẹ́ràn aladúgbò wa bí arawa.18
Èyí ni ara ìwà àtọ̀runwá Jésù tí ó sì hàn nínú gbogbo ohun tí ó ṣe ní ìgbà iṣẹ́-ìránṣẹ́ ilẹ̀-ayé Rẹ̀.19 Nítorínáà, nígbàtí a bá mọ̀ọ́mọ̀ tí a sì ya arawa sọ́tọ̀ sí wíwò Ó tí a sì nkọ́ látinú àpẹrẹ pípé Rẹ̀,20 à nwá láti mọ̀ Ọ́ dáradára si. À ndàgbà nínú ìwúrí àti ìfẹ́ láti fi òṣùwọ̀n ìgbẹ̀hìn sínú ayé wa nípa bí a ṣe níláti gbé ìgbé-ayé, àpẹrẹ tí a níláti gbekalẹ̀, àti àwọn òfin tí a níláti tẹ̀lé. Bákannáà a njèrè àfikún lílóye, ọgbọ́n, ìwà àtọ̀runwá, àti oore-ọ̀fẹ́ síwájú Ọlọ́run àti àwọn aladugbo wa.21 Mo lè mu dá yín lójú pé okun wa láti ní ìmọ̀lára agbára Olùgbàlà àti ìfẹ́ ayé wa, gbígbéga ìgbàgbọ́ wa, ìfẹ́ wa láti ṣe ìṣe ti òdodo, àti ìwúrí láti sìn Ìn àti àwọn ẹlòmíràn yíò pọ̀si.22 Ní àfikún, ìmoore wa fún àwọn ìbùkún àti ìpènijà tí à nní ìrírí nínú ayé-ikú yíò múlẹ̀ yíò sì di ara ìjọ́sìn òtítọ́ wa.23
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, gbogbo ohun wọ̀nyí nfún ìyanu ti-ẹ̀mí wa lókun nípa ìhìnrere àti pé ó ntì wá láti fi tayọ̀tayọ̀ pa àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Olúwa mọ́—àní ní àárín àwọn àdánwò àti ìpènijà tí à nní ìrírí. Bẹ́ẹ̀ni, fún àwọn àbájáde wọ̀nyí láti ṣẹlẹ̀, a nílò làti ri arawa pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti èro-inú òdodo nínú àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà,24 titiraka láti fi àwọn ìhùwàsí Rẹ̀ sí ọ̀nà ẹ̀mí wa.25 Ní àfikún, a nílò láti fà súnmọ́ Ọ nípasẹ̀ ìrònùpìwàdà wa,26 wíwá ìdáríjì Rẹ̀ àti agbára ìràpadà Rẹ̀ nínú ayé wa àti pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Olúwa Fúnrarẹ̀ ṣe ìlérí pé Òun yíò darí àwọn ipa ọ̀nà wa bí a o bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, jíjẹ́wọ́ Rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọ̀nà wa àti kí a máṣe gbáralé níní-ìmọ̀ ti arawa.28
Ọkùnrin kan tí mo bá pàdé láìpẹ́, ẹnití orúkọ rẹ̀ njẹ́ Wes tí ó wa nijoko nínú ìpàdé àpapọ̀ loni, tẹ́wọ́gba ìpè Krístì láti kọ́ nípa Rẹ̀ àti nípa ìhìnrere Rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìrírí ọ̀wọ̀ nípa ìfẹ́ Rẹ̀ lẹ́hìn ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ti jíjìnnà ararẹ̀ kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Ó wí fún mi pé ní ọjọ́ kan ó ní ìfarakàn ní Ojúìwé nípasẹ̀ òjíṣẹ́ ìhìnrere kan, Alàgbà Jones, ẹnití a fún níṣẹ́ ránpẹ́ sí agbègbè Wes ṣíwájú lílọ sí ìbi ìfúnni-niṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní míṣọ̀n Panama. Nígbàtí Alàgbà Jones rí àwòrán ojú Wes, àní ní mímọ́ ṣíwájú pé òun ti jẹ́ ọmọ Ìjọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ó ní ìmọ̀lára ìtọ́nisọ́nà ti Ẹ̀mí Mímọ́ ó sì mọ̀ pé òun níláti farakan Wes kíákíá. Ó tètè ṣe ìṣe lórí ìtẹ̀mọ́ra yí. Wes ní ìyanu nípasẹ̀ ìfarakàn àìròtẹ́lẹ̀ yí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ndamọ̀ pé Olúwa ni ìfura nípa òun bíótilẹ̀jẹ́pé òun jìnnà kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
Láti ìgbà náà lọ, Wes àti àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere bẹ̀rẹ̀ sí nbárasọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́. Alàgbà Jones àti ojúgbà rẹ̀ pèsè àwọn ìṣe iṣẹ̀-ìsìn àti àwọn ọ̀rọ̀ tí-ẹ̀mí tí ó ran Wes lọ́wọ́ láti gba ọ̀wọ̀ Olùgbàlà rẹ̀ àti ìhìnrere Rẹ̀. Ó ntún rírú iná ẹ̀rí rẹ̀ nípa òtítọ́ àti ìfẹ́ Olùgbàlà fún un ṣe. Wes ní ìmọ̀lára àláfíà tí ó nwá láti ọ̀dọ̀ Olùtùnú tí ó sì njèrè okun tí ó nílò láti padà sínú agbo. Ó wí fún mi pé ìrírí yí nmú ẹ̀dùn-ọkàn àti ẹ̀mí ìyè rẹ̀ padà wá ó sì nran án lọ́wọ́ láti mú àwọn ìmọ̀lára ìkorò tí ó ti kórajọ ní àwọn ọdún nítorí àwọn ìrírí ìṣòrò tí ó ti là kọjá.
Bí aláròjinlẹ̀ pròfẹ́sọ̀ ọ̀rẹ́ mi tí mo dárúkọ tẹ́lẹ̀ ti ṣe àkíyèsí, ohun ìyanu àti ìfanimọ́ra kan wà nígbàgbogbo láti kọ́ nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀.29 Olúwa ti ṣe àwọn ìlérí ìyànu tí ó nà sí gbogbo àwọn wọnnì, pẹ̀lú wa, tí wọ́n nwá láti kọ́ nípa Rẹ̀ kí wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sínú ìgbé-ayé wọn. Sí Enoch Ó wípé, “Kíyèsi Ẹ̀mí mi [yíò wà] ní orí rẹ, nítorínáà gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni èmí yíò dáláre; àwọn òkè yíò sì sá níwájú rẹ, àwọn odò yíò sì yà kùrò ní ipa ọ̀nà wọn; ìwọ yíò sì gbé nínú mi, àti èmi nínú rẹ.”30 Nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ọba Bẹ́njámìn, Ó kéde, “A ó máa pè yín ní ọmọ Krístì, ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, àti ọmọ rẹ̀ lóbìnrin; nítorí ẹ kíyèsĩ, ní òní yí ni ó ti bí nyín nínú ẹ̀mí; nítorítí ẹ̀yin wípé ọkàn nyín ti yípadà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorínã, a bí nyín nínú rẹ ẹ̀yin sì ti di ọmọ rẹ̀ ní ọkùnrin àti ní óbìnrin.”29
Nítorínáà, bí a ṣe nfi òtítọ́ àti ìtẹramọ́ ìtiraka láti kọ́ nípa Olùgbàlà tí a sì ntẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀, mo ṣe ìlérí fún yín, ní orúkọ Rẹ̀, pé àwọn ìhùwàsí àtọ̀runwá Rẹ̀ yíò jẹ́ kíkọsílẹ̀ ní inú àti ọkàn wa,32 tí a ó dàbíi Rẹ̀ si, a ó sì rìn pẹ̀lú Rẹ̀.33
Ẹ̀yin olùfẹ́ arákùnrin àti aràbìnrin, mo gbàdúrà pé a ó dúró nínú ọ̀wọ̀ ti Jésù Krístì àti ìfẹ́ pípé, àìlópin, àṣeparí Rẹ̀. Njẹ́ kí rírántí ohun tí ojú wa ti rí, àti tí ọkàn wa ti ní ìmọ̀lára mú kì ìyanu wa nínú ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà pọ̀si, èyí tí ó lè wò wá sàn nípa àwọn ọgbẹ́ ti-ẹ̀mí àti ẹ̀dùn-ọkàn kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti súnmọ́ Ọ si. Njẹ́ kí a níyanu nínú àwọn ìlérí nlá tí Baba ní nínú ọwọ́ Rẹ̀ àti èyí tí Òun ti múrasílẹ̀ fún àwọn ẹnití ó gbàgbọ́:
“Ìjọba náà jẹ́ tiyín àti pé àwọn ìbùkún èyíinì jẹ́ tiyín, àwọn ọ̀rọ̀ ayérayé jẹ́ tiyín.
Ẹnití ó bá gba ohun gbogbo pẹ̀lú ọpẹ́ ni a ó ṣe lógo.”34
Jésù ni Olùràpadà ayé, èyí sì ni Ìjọ Rẹ̀. Mo jẹ́rí nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní ìmísí-ìyanu, mímọ̀, àti orúkọ ọlánlá ti Olùgbàlà wa Jésù Krístì, àmín.