Fẹ́, Pín, Pè
Bí a ṣe fẹ, pín, àti pè, a njẹ́ ara ìṣẹ nlá àti ológo tí ó nmúra ayé sílẹ̀ fún ìpadabọ̀ ti Mèssíah rẹ̀.
Ròó pẹ̀lú mi, fún àkokò kan, dídúró lórí òkè ní Galilee, jijẹri ìyanu àti ògo àjínde Olùgbàlà tí ó nbẹ àwọn ọmọẹ̀hìn wò. Bí ó ti jẹ́ ìmísí-ọ̀wọ̀ láti yẹ gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wò níti-ara, èyí tí Ó npín pẹ̀lú wọn, àṣẹ ọ̀wọ̀ Rẹ̀ láti “lọ nítorínáà, kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè, rì wọn bọmi ní orúkọ Baba, àti Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́.”1 Dájúdájú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yíò fún wa lágbára, mísí, àti láti wọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lára, bí ó ti ṣe sí àwọn Àpóstélì Rẹ̀. Nítòótọ́, wọ́n fọkànsìn fún ìyókù àwọn ìgbé ayé wọn ní ṣíṣe èyí lásán.
Ní wíwuni, kìí ṣe àwọn Àpóstelì nìkan ni wọ́n gba àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sí ọkàn. Àwọn ọmọ Ìjọ ìṣíwájú, láti titunjùlọ sí dídara jùlọ, sa ipá nínú ìfifúnni nlá Olùgbàlà, pípín àwọn ìròhìn rere ti ìhìnrere pẹ̀lú àwọn tí wọ́n pàdé tí wọ́n sì mọ̀. Ìpinnu láti pín ẹ̀rí wọn nípa Jésù Krístì ran ìgbékalẹ̀ Ìjọ Rẹ̀ titun láti dàgbà si gidi.2
Àwa bákannáà, bí àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì, ni a pè láti gbọ́ ìfifúnni Rẹ̀ loni, bíi pé a wà lórí òkè Galilee bí ó ti kéde rẹ̀ lakọkọ. Ìfifúnni yí bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi ní 1830, nígbàtí Joseph Smith ya arákùnrin rẹ̀ Sámúẹ́lì sọ́tọ̀ bí òjíṣẹ́ ìhìnrere ìṣaájú ti Ìjọ Jésù Krístì. Láti ìgbà náà, jú míllíọ̀nù kan ààbọ̀ àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ti rin ìrìnàjò káàkiri ayé ní kíkọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ríri àwọn wọnnì tí wọ́n gba ìròhìn ayọ nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere bọmi.
Èyí ni ẹ̀kọ́ wa. Ìfẹ̀ wa tí a fẹ́ràn.
Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọdé wa dé àgbà ní àárín wa, a nlọ́ra fún àkokò nígbàtí a lè gbọ́ ìpè Olùgbàlà kí a sì pín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Ó dá mi lójú pé ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin ní ìmọ̀lára irú ìpènijà ìfúnni-lágbára láti ọ̀dọ̀ wòlíì wa ní àná bí ó ti pè wá láti múrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìṣìn ìhìnrere ìgbà-kíkún gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ti ṣe pẹ̀lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀.
Bíiti àwọn olùsáré ní ìbẹ̀rẹ̀ búlọ́kì, a dúró pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ìpè gbangba, kíkún pẹ̀lú ìfọwọ́sí wòlíì, fífàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje! Ìfẹ́ yí ni akọni àti onímísí; bákannáà, ẹ jẹ́ kí a yẹ ìbèèrè yí wò: kínìdí tí gbogbo wa kò fi bẹ̀rẹ̀ nísisìyí?
Ẹ lè bèèrè, “Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere láìní àlẹmọ́ orúkọ?” Tàbí a wí fun arawa pé “Àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ni a yà sọ́tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ yí. Èmi yíò fẹ́ láti ṣerànwọ́ ṣùgbọ́n bóyá lẹ́hìnwá nígbàtí aye bá tura díẹ̀.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, o rọrun jù bẹ́ẹ̀ lọ! Pẹ̀lú ìmoore, àṣẹ nlá Olùgbàlà ni a le ṣe yọrí nípasẹ̀ níní-òye àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ jẹ́jẹ́, ìrọ̀rùn tí a kọ́ ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan wa láti ọmọdé: fẹ́, pín, àti pè.
Ìfẹ́
Ohun àkọ́kọ́ tí a lè ṣe ni láti nifẹ bí Krístì ti fẹ̀ni.
Ọkàn wa wúwo pẹ̀lú ìjìyà àwọn ènìyàn àti àìfọkànbalè tí a rí káàkiri ayé ní àárín àwọn ìgbà ìrúkèrúdò wọ̀nyí. Bákannáà, a lè ní ìmísí nípasẹ̀ ìtújáde àánú àti rírannilọ́wọ́ tí a ti júwe làti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbigbogbo nínú ìtiraka wọn láti nawọ́ jáde sí àwọn tí a pààlà fún—àwọn tí a fọ́nká kúrò ní ilé wọn, yapa kúrò nínú àwọn ẹbí wọn, tàbí ní ìrírí àwọn ọ̀ràn ìkorò àti àìnírètí.
Láìpẹ́, àwọn orísun ìròhìn jíhìn bí ẹgbẹ́ àwọn ìyá ní Poland, nínú àníyàn fún àwọn ẹbí tó nsálọ, fi àwọn akẹ́rù kíkún sílẹ̀ lórí pẹpẹ ibùdókọ̀ reluwé nínú ìlà afínjú, ní ṣíṣetán wọ́n sì ndúró fún àwọn ìyá àti ọmọ rẹfují tí yíò nílò wọn ní sísọdá ààlà bí wọ́n ti nsọ̀kalẹ̀ nínú reluwé kan. Dájúdájú, Baba wa Ọ̀run rẹrin lórí àwọn ìṣe ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́ àìní-ìmọtaraẹni-nìkan bí irú ìwọ̀nyí, fún bí a ṣe ngbé àjàgà arawa, a “nmú àṣẹ Krístì ṣẹ.”4
Nígbàkugbà tí a bá fi ifẹ́ ìwà bí Krístì hàn sí aladugbo wa, à nwàásù ìhìnrere—àní bí a kò bá fọhùn ọ̀rọ̀ kanṣoṣo.
Ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn ni ìsọ̀rọ̀ dídán nìpa òfin nlá kejì láti fẹ́ràn ọmọnìkejì wa;5 ó fi ètò àtúnṣe Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó nṣiṣẹ́ nínú ẹ̀mí ti arawa hàn. Nípa jíjúwe ìfẹ́ Krístì sí àwọn ẹlòmíràn, a lè mú kí àwọn tí wọ́n rí iṣẹ́ rere wa fi “ògo fún Baba [wa] èyí tí nbẹ ní ọ̀run.”6
A nṣe èyí láìretí ohunkóhun ní ìpadàbọ̀.
Ìrètí wa, bẹ́ẹ̀ni, ni pé wọn yíò gba ìfẹ́ wa àti ọ̀rọ̀ wa, bíotilẹ̀jẹ́pé bí wọ́n ti dáhùn kò sí ní àrọ́wọ́tó wa.
Ohun tí a ṣe àti ẹnití a jẹ́ dájúdájú ni.
Nípasẹ̀ ìfẹ́ bíiti Krístì fún àwọn ẹlòmíràn, a nwààsù pẹ̀lú ìsọ̀rọ̀ ológo. Àwọn ohun-ìní Igbé ayé-yíyípadà ti ìhìnrere Krístì, a sì nkópa pàtàkì nínú imúṣẹ ìfifúni nlá Rẹ̀.
Pín
Ohun keji tí ẹ lè ṣe ní láti pín.
Ní àwọn oṣù ìṣíwájú ti àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19, Arákùnrin Wisan láti Thailand ní ìmọ̀lára ìṣílétí láti pín àwọn ìmọ̀làra rẹ̀ àti ìtẹ̀mọ́ra nípa ohun tí ó nkọ́ nínú àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì rẹ̀ lórí àkọsílẹ̀ ìròhìn àwùjọ. Nínú ọ̀kan lára àwọn àlẹ̀mọ́ araẹni rẹ̀ nípàtàkì, ó pín ìtàn nípa àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere Ìwé ti Mọ́mọ́nì méjì, Ámúlẹ́kì àti Álmà.
Arákùnrin rẹ̀, Winai, bíótilẹ̀jẹ́pé ó fìdímúlẹ̀ nínú àwọn ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn rẹ̀, ní ìfọwọ́tọ́ nípa àlẹ̀mọ́ náà ó sì fèsì, ó bèèrè ní àìròtẹ́lẹ̀ pé, “Ṣe mo lè rí ìwé náà ní Thai?”
Wisan fi ọgbọ́n ṣètò fún ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì láti fi ṣọwọ́si nípasẹ̀ àwọn arábìnrin òjíṣẹ́ ìhìnrere méjì, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí nkọ́ arákùnrin rẹ̀.
Wisan darapọ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ orí-afẹ́fẹ́, nínú èyí tí ó ti pín àwọn ìmọ̀lára rẹ̀ nìpa Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Winai kọ́ láti gbàdúrà àti láti ṣe àṣàrò pẹ̀lú ẹ̀mí wíwá-òtítọ́, láti tẹ́wọ́gbà àti láti gbá òtítọ́ mọ́ra. Làárín oṣù, Winai ṣe ìrìbọmi
Wisan lẹ́hìnnáà wípé, “A ní ojúṣe láti jẹ́ ohun-èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, a sì gbọ́dọ̀ ṣetán fún Un láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ ní ọ̀nà Rẹ̀ nígbàgbogbo nípasẹ̀ wa.” Iṣẹ́ ìyanu ẹbí wọn nwá nítorí Wisan kàn pín ìhìnrere ní ọ̀nà ti ara àti àdánidá.
Gbogbo wa npín àwọn ohunkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. À nṣe é léraléra. A npín irú eré-ìtàgé àti oúnjẹ tí a fẹ́ràn, àwọn ohun pípanilẹ́rini tí a rí, àwọn ibi tí a bẹ̀wò, ère tí a mọyì, àwọn àyọsọ tí a ní ìmísí nípa.
Báwo ni a ṣe lè fikún ìtò àwọn ohun tí a ti pín tẹ́lẹ̀ nípa ohun tí a nifẹ nípa ìhìnrere Jésù Krístì.
Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ṣàlàyé pé: “Bí ẹnìkan bá bèèrè nípa òpin-ọ̀sẹ̀ yín, ẹ máṣe lọ́ra láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ẹ ní ìrírí ní ìjọ. Sọ díẹ̀ nípa àwọn ọmọ tí wọ́n dúró ní iwájú ìjọ tí wọn sì kọrin pẹ̀lú ìyára bí wọ́n ṣe ngbìyànjú láti dàbí Jésù. Sọ̀rọ̀ nípa ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ tí wọ́n nlo àkokó ní ríran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ ní àwọn ilé ìsinmi láti to àwọn àkọọ́lẹ̀-ìtàn araẹni wọn jọ.”7
Pípín kìí ṣe nípa “títa” ìhìnrere. Ẹ kò ní láti kọ ìwàásù tàbí bá ẹnìkan wí fún àwọn ìgbèrò tí kò tọ́.
Nígbàtí ó bá di iṣ̣ẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere, Ọlọ́run kò nílò yín láti jẹ́ ṣẹ̀rífù Rẹ̀, bákannáà, Ó nbèèrè kí a jẹ́, olùpín Rẹ̀.
Nípa pípín àwọn ìrírí dídára wa nínú ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, a kópa ní mímú ìfifúnni nlá Olùgbàlà ṣẹ.
Ìpè
Ohun kẹta tí ẹ lè ṣe ní láti pè.
Arábìnrin Mayra ni olùyípada àìpẹ́ láti Ecuador. Ayọ̀ rẹ̀ nínú ìhìnrere gòkè ní kété lẹ́hìn ìrìbọmi rẹ̀ bí ó ṣe pe àwọn ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ ní àyíká rẹ nípasẹ̀ àkọ́silẹ̀ ìròhìn àwùjọ. Àwọn ọmọ ẹbí Mayra àti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n rí àlẹ̀mọ́ rẹ̀ fèsì pẹ̀lú àwọn ìbèèrè. Mayra sopọ̀ mọ́ wọn, ó npè wọ́n sí ilé rẹ̀ nígbàkugbà láti pàdé pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere papọ̀.
Àwọn òbí Mayra, tẹ̀gbọ́n-tàbúrò rẹ̀, àntí rẹ̀, àwọn ìbátan méjì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ṣe ìrìbọmi nítorí òun fi ìgboyà pè wọ́n láti “wá láti rí,” “wá láti sìn,” àti “wá láti wà darapọ̀.” Nípasẹ̀ àwọn ìpè ti-ara àti àdánidá rẹ̀, àwọn ogún ènìyàn tẹ́wọ́gba ìpè rẹ̀ láti ṣe ìrìbọmi láti jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì. Èyí wá nítorí Arábìnrin Mayra pe àwọn ẹlòmíràn jẹ́jẹ́ láti ní ìrírí ayọ̀ tí òun ní ìmọ̀lára rẹ̀ bí ọmọ Ìjọ.
Ọgọgọ́ọ̀rún àwọn ìfipè wà tí a lè nà sí àwọn ẹlòmíràn. A lè pè àwọn ẹlòmíràn láti “wá láti rí” ìjọ́sìn oúnjẹ Olúwa, ìṣe wọ́ọ̀dù kan, fídíò ayélujára tí ó ṣe àlàyé ìhìnrere Jésù Krístì. “Wá láti rí” lè jẹ́ ìfipè kan láti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì tàbí bẹ tẹ́mpìlì titun wò ní ìgbà ṣíṣí ilé rẹ̀ ṣíwájú ìyàsímímọ́ rẹ̀. Nígbàmíràn ìpè ni ohunkan tí a nnà sínú—ìpè kan sí arawa, tó nfún wa ní ìfura àti ìran ti àwọn ànfàní yíyí wa ká láti gbé ìgbésẹ̀ lórí wọn.
Ní ọjọ́ díjítà wa, àwọn ọmọ ìjọ npín àwọn ọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ìròhìn àwùjọ léraléra. Àwọn ọgọgọ́ọ̀rún, bí kìí bá ṣe ẹgbẹgbẹ̀rún, ti àwọn ohun ìgbéga tí ẹ lè rí ní yíyẹ fún pípín. Àkóónú yí fúnni ní àwọn ìfipè láti “wá látii rí,” “wá láti sìn,” àti “wá láti wà pẹ̀lú.”
Bí a ṣe npe àwọn ẹlòmíràn láti kọ́ nípa ìhìnrere Jésù Krístì, à ndi ara ìpè Olùgbàlà láti gbàsíṣẹ́ nínú iṣẹ́ fífúnni Rẹ̀.
Íparí
Ẹ̀yin olùfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, a ti sọ̀rọ̀ ní òní nípa àwọn ohun mẹ́ta jẹ́jẹ́—àwọn ohun ìrọ̀rùn—tí ẹnikẹ́ni lè ṣe. Àwọn ohun tí ẹ lè ṣe! Bóyá ẹ ti nṣe wọ́n tẹ́lẹ̀—àní láìsí mímọ̀ pé ẹ̀ ṣé
Mo pè yín láti yẹ àwọn ọ̀nà tí ẹ lè fi ní ìfẹ́, pín, àti pè wá. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó ní ìmọ̀lára ìwọn ti ayọ̀ mímọ̀ pé ẹ ngbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ olùfẹ́ Olùgbàlà wa.
Ohun tí èmi nrọ̀ yín láti ṣe kìí ṣe ètò titun. Ẹ ti gbá àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ wọ̀nyí tẹ́lẹ̀. Èyí kìí ṣe “ohun nlá tó kàn” tí Ìjọ nní kí ẹ ṣe. Àwọn ohun mẹ́ta wọ̀nyí kàn jẹ́ nínà nípa ẹnití a jẹ́ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.
Kò sí àmìn orúkọ tàbí lẹ́tà tí a nílò.
Kò sí ìpè iṣẹ́ tí a nílò.
Bí àwọn ohun mẹ́tà wọ̀nyí ṣe ndi ara àdánidá ti ẹnití a jẹ́ àti bí a ṣe ngbé, wọn yíò di àfọwọ́yí, ìfihàn àìnípá ìfẹ́ òtítọ́.
Bíiti àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì tí wọ́n kórajọ papọ̀ láti kẹkọ látọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní Galilee ní ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́hìn, àwa pẹ̀lú lè dìmọ́ àṣẹ Olùgbàlà kí a sì lọ sí gbogbo ayé ní wíwàásù ìhìnrere.
Bí a ṣe nifẹ, pín, àti pè, a njẹ́ ara ìṣẹ nlá àti ológo tí ó nmúra ayé sílẹ̀ fún ìpadabọ̀ ti Mèssíah rẹ̀.
Kí a lè gbọ́ ìpè Olùgbàlà kí a sì gba iṣẹ́ nínú ìfifúnni nlá Rẹ̀ ni àdúrà mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.