Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ẹ̀kọ́ Látinú Kànga
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Àwọn Ẹ̀kọ́ Látinú Kànga

A lè yàn láti yípadà sí Olùgbàlà ní òní fún okun àti ìwòsàn tí yíò mú kí gbogbo ohun tí a rán wa wá síbí láti ṣe wá sí ìmúṣẹ.

E wò bó ti jẹ́ ayọ̀ láti péjọ pẹ́lú ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní abala ti àwọn obìnrin nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yí!

Mo dàgbà ní ìwọ̀-oòrùn New York mo sì lọ sí ẹ̀ka kékeré ti Ìjọ níwọ̀n bíi ogun máìlì sí ilé wa. Bí mo ti joko ní kíláàsì ilé-ẹ̀kọ́ Ọjọ́-ìsinmi ní ìsàlẹ̀ ilé-ìjọsìn àyágbé wa àtijọ́ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi Patti Jo, èmì kò lè rò láéláé pé mo lè jẹ́ ara arábìnrin àgbáyé ti àwọn míllíọ́nù obìnrin

Ọdún marun sẹ́hìn ọkọ̀ mi, Bruce, ṣàìsàn líle nígbàtí à nsìn pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ ní Agbègbè Ìlà-oòrùn Europe. A padà sílé, ó sì kọjá lọ ní àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́hìnnáà. Ayé mi yípadà mọ́jú ọjọ́ kan. Mò nṣọ̀fọ̀ mo sì nní ìmọ̀lára àìlera àti ìpalára, Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa láti darí ipa-ọ̀nà mi: “Kíni Ẹyin yíò fẹ́ kí Nṣe?”

Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́hìnnáà, mò nwo àwọn ìfìwéránṣẹ́ mi nígbàtí mo rí àwòrán kékeré nínú kátálọ́gì tí ojú mi lọ sí. Bí mo ti wòó dáadáa, mo damọ̀ pé ó jẹ́ iṣẹ́ ayàwòrán ti arábìnrin ará Samaria pẹ̀lù Jésù ní ibi kangà. Ní àkokò náà, ẹ̀mí sọ̀rọ̀ sí mi kedere pé: “èyí ni ohun tí ó yẹ kí o ṣe.” Olùfẹ́ni Baba Ọ̀run npè mi láti wá sọ́dọ̀ Olùgbàlà kí a sì kẹkọ.

Èmi yíò fẹ́ láti pín pẹ̀lú yín àwọn ẹ̀kọ́ mẹta tí mò nkọ́ bí mo ti ntẹ̀síwájú láti mu nínu kànga ti “omi ìyè Rẹ̀.”1

Àkọ́kọ́: Àwọn Ipò Wa tó Kọjá àti ti Ìsisìyí Kò Pinnu Ọjọ́-ọ̀la Wa

Ẹ̀yin arábìnrin, mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín nní ìmọ̀lára bí mo ti ní, àìní-ìdánilójú bí ẹ ó ti dojúkọ ìṣòro ìpènijà àti àdánù—àdánù nítorí ìgbé-ayé yín kò farahàn ní ọ̀nà tí ẹ ti ní ìrètí fún, gbàdúrà fún, àti ṣètò fún.

Bíótiwù kí àwọn ipò wa rí, ayé wa jẹ́ mímọ́ ó sì ní ìtumọ̀ àti èrèdí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa jẹ́ olùfẹ́ ọmọbìnrin Ọlọ́run, tí a bí pẹ̀lú ìwàtọ̀run nínú ẹ̀mí wa.

Olùgbàlà wa Jésù Krístì, nípasẹ̀ irúbọ ètùtù Rẹ̀, mu ṣeéṣe fún wa láti gba ìwẹ̀numọ́ kí a sì ní ìwòsàn, tí ó nmú wa ní ìmúṣẹ èrèdí wa ní ayé láìka àwọn ìpinnu àwọn ọmọ ẹbí, ipò ìgbeyàwó wa, ìlera ti-ara tàbí ti-ọpọlọ, tàbí ipòkípò míràn sí.

Gbé obìnrin tó wa níibi kànga yẹ̀ wò. Báwo ni ìgbé-ayé rẹ̀ ti rí? Jésù mọ̀ pé ó ti ní ọkọ marun àti pé kò ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú èyí tí ó ngbé pẹ̀lú lọ́wọ́lọ́wọ́ Àti síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìṣòrò ayé rẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ìkéde gbangba àkọ́kọ́ Olùgbàlà pé Òun ni Mèsíàh wà fún un. Ó wípé, “Èmi ni ẹni náà tí ó nba ọ sọ̀rọ̀.”2

Ó di ẹlẹri alágbára kan, ó nkéde sí àwọn wọnnì nínú ilú rẹ̀ pé Jésù ni Krístì náà. “Àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ara Samaria ní ìlú náà gbàgbọ́ nínú rẹ̀ nítorí ó sọ nípa obìnrin náà.”3

Àwọn ipò rẹ̀ àtẹ̀hìnwá àti ìsisìyí kò pinnu ọjọ́-ọ̀la rẹ̀. Bíi tirẹ̀, a lè yàn láti yípadà sí Olùgbàlà ní òní fún okun àti ìwòsàn tí yíò mú kí gbogbo ohun tí a rán wa wá síbí láti ṣe wá sí ìmúṣẹ.

Èkejì: Agbára Náà Wà Nínú Wa

Nínú ẹsẹ mímọ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, Olúwa gba àwọn obìnrin àti Ọkùnrin níyànjú lati “ṣiṣẹ́ taratara nínú èrò rere, kí wọ́n sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nípa ìfẹ́ arawọn, kí wọ́n sì mú òdodo púpọ̀ wá sí ìmúṣẹ; nítorí agbára náà wà nínú wọn.”5

Ẹ̀yin arábìnrin agbára náà wà nínú wa láti mú òdodo púpọ̀ wá sí ìmúṣẹ!

Ààrẹ Nelson kọ́ wa, “Gbogbo obìnrin àti ọkùnrin tí wọ́n dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run tí wọ́n sì npa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́, tí wọ́n sì nkópa ní yíyẹ́ nínú àwọn ìlànà oyèàlùfáà, ni ààyè tààrà sí agbára Ọlọ́run.”19

Mo ti wá mọ̀ pé bí a ti ntiraka bu ọlá fún àwọn májẹ̀mú wa mímọ́ tí a dá ní ìrìbọmi àti nínú tẹ́mpìlì mímọ́, Olúwa yíò bùkún wa “pẹ̀lú ìwòsàn Rẹ̀, agbára ìfúnni-lókun” àti pẹ̀lú “òye ti-ẹ̀mí àti àwọn ìtagìrì [tí a kò] ní rí tẹ́lẹ̀.”7

Ẹ̀kẹ́ta: “Nínú Ohun Kékeré Ni Èyí Ti Ó Tóbi Ti Nwá”10

Nínú ìwàásù ní orí òkè, Jésù kọ́ àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ni iyọ̀ayé”11 Ẹ̀yin sì ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”12 Lẹ́hìnnáà Ó fi dídàgbà ìjọba ọ̀run wé ìwúkàrà, “èyí tí obìnrin kan mú, tí ó sin sínú òṣùwọ̀n ìyèfun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ fi di wíwú.”13

  • Iyọ̀

  • Ìwúkàrà.

  • Ìmọ́lẹ̀

Àní níní oye kékeré gan, ni ọ̀kọ̀ọ̀kan npa ohungbogbo lára ní àyíká wọn. Olùgbàlà npè wá láti lo agbára Rẹ̀ láti jẹ́ iyọ̀, ìwúkàrà, àti ìmọ́lẹ̀.

Iyọ̀

O jẹ́ ìyàlẹ́nu irú ìyàtọ̀ tí gbígbọn iyọ̀ nṣe nínú adùn ohun tí à njẹ. Àti síbẹ̀síbẹ̀ iyọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun-èlò rírọrùnjùlọ̀ tí kò sì wọ́n.

Nínú ìwé àwọn Ọba kejì, a kà nípa “ọmọbìnrin kékeré kan”14 tí a mú nípasẹ̀ àwọn Syrian tí ó sì di ìránṣẹ́ sí ìyàwó Náámánì, ọ̀gágun àwọn ọmọ-ogun Syrian. Ó wà bí iyọ̀; ó jẹ́ ọ̀dọ́, tí kò níyì níti ayé, àti pé ayé rẹ̀ bí ẹrú ní orílẹ̀-èdè àjèjì ní kedere kìí ṣe ohun tí ó ti nírètí fún.

Bákannáà, ó sọ ẹ̀là ọ̀rọ̀ méjip pẹ̀lú agbára Ọlọ́run, ní jíjẹ́-ẹ̀rí sí ìyàwó Naaman: “Bí Ọlọ́run Olúwa mi bá ti wà pẹ̀lú wòlíì tí ó wà ní Samaria! nítorí oun ìbá ti tọ́jú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”13

Àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni a sọ fún Náámánì, ẹnití ó gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fi ààyè gbàá láti rí ìwòsàn méjèèjì níti-ara àti níti-ẹ̀mí.

Nígbàkugba a ndojúkọ àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n pàrọwà sí Náámánì láti wẹ̀ nínú odò Jọ́dánì, bí wòlíì Elisha ti darì, ṣùgbọ́n Náámánì kì bá ti wà ní ẹnu-ọ̀nà Elisha láìsí “ọmọbìnrin kékeré kan.”

Ẹ lè jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí ní ìmọ̀lára àìjẹ́pàtàkì, ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ́ bí iyọ̀ nínú ẹbí tín, ní ilé-ìwé, àti ní ìletò yín.

Ìwúkàrà.

Njẹ́ ó ti jẹ́ búrẹ́dì rí láìsí ìwúkàrà? Báwo ni ẹ ó ṣe júwe rẹ̀? Rírọ̀? Wúwo? Líle? Pẹ̀lú oye ìwúkàrà kékeré nìkan, búrẹ́dì ndìde, ó nfẹ́ láti di fífúyẹ́ si àti rírọ̀ si.

Nígbàtí a bá pe agbára Ọlọ́run sínú ayé wa, a lè rọ́pò “ẹ̀mí wúwo”16 pẹ̀lú àwọn ìwò ìmísí tí ó ngbé àwọn ẹlòmírán ga tí wọ́n sì nfún àwọn ọkàn ní ààyè láti rí ìwòsàn.

Láìpẹ́ ọ̀rẹ́ mi kan wà lórí ibùsùn ní òwúrọ̀ Kérésìmesì, ní ìbòmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìkorò. Àwọn ọmọ rẹ̀ bẹ̀ẹ́ láti dìde; ṣùgbọ́n ó kún fún ìrora ti ìyapa rẹ̀ tí ó wà nílẹ̀. Ó sùn sórí ibùsùn ó nsọkún, ó ntú ẹ̀mí rẹ̀ jáde nínú àdúrà sí Baba Ọ̀run, ó nwí fún Un nípa àìnírètí rẹ̀.

Bí ó ti parí àdúrà rẹ̀, Ẹ̀mí ṣí i létí pé Ọlọ́run mọ ìrora rẹ̀. Ó kún fún àánú fún un. Ìrírí mímọ̀ yí fi ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ hàn ó sì fun un ní ìrètí pé òun kò dánìkan ṣe ọ̀fọ̀. Ó dìde, lọ sóde, ó sì kọ́ ọkùnrin-yìnyín pẹ̀lu àwọn ọmọ rẹ̀, ní rírọ́pò ìwúwo ti òwúrọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rín àti ayọ̀.

Ìmọ́lẹ̀

Oye ìmọ́lẹ̀ mélò ni ó gbà láti tú òkùnkùn ká nínú yàrá kan? Ìtànṣán kékerè kan. Àti pé ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà lè jáde látinú agbára Ọlọ́run nínú yín.

Àní bíótilẹ̀jẹ́pé ẹ lè ní ìmọ̀lára àdàwà bí àwọn ìjì ayé ṣe njà, ẹ lè tàn ímọ́lẹ̀ sínú òkùnkùn àìgbọ́yé, ìdàmú, àti àìgbàgbọ́. Ìmọ́lẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú Krístì le dúroṣinṣin kì ó sì dájú, ní dídarí àwọn wọnnì ní àyíká yín sí ààbò àti àláfíà.

Ẹ̀yin arábìnrin, a lè yí ọkàn padà kí a sì bùkún ìgbé-ayé bí a ti nfúnni ní iyọ̀ díẹ̀, ẹ̀kún-ṣíbí ìwúkàrà, àti ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ kan.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Olùgbàlà ni iyọ̀ nínú ayé wa, Ó npè láti tọ́ ayọ̀ àti ìfẹ́ Rẹ̀ wò.17 Òun ni ẹnití ó jẹ́ ìwúkàrà nígbàtí ayé wa bá le, Ó nmú ìrètí wa fún wa fún wa18 Ó sì ngbé àwọn ẹrù-wúwo wa kúrò19 nípasẹ̀ agbára ìfẹ́ àìláfiwé àti ìràpadà.20 Òun ni ìmọ́lẹ̀ wa,21 Ó ntan ìmọ́lẹ̀ sí ipa-ọ̀nà wa padà sílé.

Mo gbàdúrà pé kí a lè wá sọ́dọ̀ Olùgbàlà, bíi ti obìnrin ibi kànga, kí a sì mu omi ìyè Rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ènìyàn Samaria, a le kéde nígbànáà pé, “Nísisìyí a gbàgbọ́, … nítorí àwa tìkarawa ti gbọ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Krístì, Olùgbàlà arayé.”22 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀