Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ó jínde Pẹ̀lú Ìwòsàn Ní Ìyẹ́ Apá Rẹ̀: A Lè Ju Aṣẹ́gun Lọ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


12:15

Ó jínde Pẹ̀lú Ìwòsàn Ní Ìyẹ́ Apá Rẹ̀: A Lè Ju Aṣẹ́gun Lọ

A Lè Ju Aṣẹ́gun Lọ.

Jésù ti borí àwọn ìlòkulò ti ayé yi láti fún yín ní agbara kìí ṣe lati yè nìkan ṣugbọn ni ọjọ kan, nipasẹ Rẹ, lati bori ati paapaa láti ṣẹ́gun.

Marin, èmi ni Alàgbà Holland, àwọn ohunkan fẹ́ lọ sílẹ̀ látòkè.

A Lè Ju Aṣẹ́gun Lọ.

Gbogbo wa la ní ìyàlẹ́nu nípa ìtàn àbáláyé. A gbọ́ ìtàn àwọn aláìnífòyà olùṣàwárí àti àwọn ènìyàn lásán tí wọ́n lè ṣe àkóso láti pa ara wọn mọ́ láàyè sí ìlòdì àti ìfojúsọ́nà, a kò sì lè ṣàì ṣèrànwọ́ ṣùgbọ́n bi ara wa léèrè pé, “Ǹjẹ́ mo lè ṣe èyí bí?”

Mo ronú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nípa olùwákiri British Ernest Shackleton àti àwọn atukọ̀ ti ọkọ̀ ojú-omi rẹ̀ HMS Ìfaradà, rì nínú yìnyín Antarctic àti lẹ́hìnnáà tí ó dààmú lórí erékòṣù àgàn fún bíi ọdún méjì. Aṣáájú aláìlẹ́gbẹ́ Shackleton àti ìpinnu aláìlèṣeéṣe gba ẹ̀mí àwọn ọkùnrin rẹ̀ là, pẹ̀lú àwọn ipò tó le jù lọ.

Lẹ́hìnnáà mo ronú nípa àwọn atukọ̀ Àpóllò kẹtàlá tó nṣe ìpalára nípasẹ̀ ààyè láti gúnlẹ̀ lórí òṣùpá! Ṣùgbọ́n ìjàmbá ṣẹlẹ̀ nígbàtí tànkì afẹ́fẹ́ kan bú gbàmù, tí a sì nílati fi òpin sí rin-àjo náà. Láìní afẹ́fẹ́ púpọ̀, àwọn atukọ̀ ati aṣàkóso ìrìn-àjò ló ṣe àmúlò ọgbọ́n wọ́n sì mú gbogbo àwọn arìnlófurufú mẹtẹ̀tá wá sí ilẹ̀-ayé padà láìléwu.

Ó yàmílẹ́nu níti ìwàláàyè àgbàyanu àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ìdílé tí ogun fìyà jẹ, tí wọ́n fi ṣẹ́wọ̀n ní àgọ́, àti àwọn tí wọ́n di rẹfují tí wọ́n fi ìwà-akọni àti ìgboyà pa iná ìrètí mọ́ fún àwọn olùjìyà ẹlẹgbẹ́ wọ́n, tí wọ́n nfúnni ní oore ní ojú ìwà-íkà, tí wọ́n sì ngbìyànjú lọ́nàkọnà láti ràn àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti farada ọjọ́ kan díẹ̀ sí i.

Njẹ́ ìwọ tàbí èmi lè yè nínú eyikeyi àwọn ipò líle wọ̀nyí bí?

Bóyá àwọn kan nínú yín, bákannáà, yẹ̀ àwọn àkọsílẹ̀ ti àwọn tó wà láàyè wò, tí ọkàn yín sì kigbe jáde pé ẹ̀yin ni ẹ ngbé ìtàn ìwàláàyè lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìsisìyí gẹ́gẹ́bí olùfaragba ílòkulò, àìbìkítà, ìpániláya, ìwà-ipá ilé, tàbí èyíkéyìí irú ìjìyà bẹ́ẹ̀. Ẹ wà ní aarín ìgbìyànjú àìnírètí ti arayín láti yè nínú ipò kan tí ẹ mọ̀lára púpọ̀ bí ìjàmbà búburú àjálù ọkọ̀ ojú-omi tàbí iṣẹ́ ìlérí tí ó dédé dúró ní áìròtẹ́lẹ̀. Njẹ́ a lè gbà yín nínú ewu láeláé; njẹ́ ẹ̀yin yíò la ìtàn ìwàláàyè tiyín já?

Ìdáhùn náà ni bẹ́ẹ̀ni. Ẹ lè yè. Nítòótọ́ a ti gbà yín là tẹ́lẹ̀; ẹ̀yin ti rí ìgbàlà tẹ́lẹ̀—láti ọ̀dọ̀ Ẹni náà tí ó ti jìyà ìrora tí ẹ̀yin njìyà gan-an, tí ó sì ti farada ìrora náà tí ẹ̀ nfaradà.1 Jésù ti borí àwọn ìlòkulò ti ayé yi2 láti fún yín ní agbara kìí ṣe lati nìkan ṣugbọn ni ọjọ kan, nipasẹ Rẹ, lati bori ati paapaa láti ṣẹ́gun—láti dìde pátápátá kọjá ìrora náà, ìnira náà, ìpọ́njú náà, àti ríri wọn ní ìrọ́pò nípa àlàáfíà.

Àpósítélì Páùlù béèrè pé:

“Tani yíò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Krístì? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà, tàbí inúnibíbi, tàbí ìyàn, tàbí ìhòho, tàbí ewu, tàbí idà? …

“Rárá, nínú gbogbo nkan wọ̀nyí, àwa ṣì ju aṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ ẹnití ó fẹ́ wa.”3

Àwọn Ìlérí fún Ísráẹ́lì Onímájẹ̀mú

Ẹ ó rántí ìgbàtí Ààrẹ Russell M. Nelson fúnni ní ìfipè wọ̀nyí nínú ìpàdé àpapọ̀. Ó wípé: “Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ yín … , mo gba yín níyànjú láti ṣe àkójọ gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣèlérí pé Òun yíò ṣe fún Ísráẹ́lì onímájẹ̀mú. Mo ronú pé yíò yà yín lẹ́nu!”4

Níhin ni díẹ̀ nínú àwọn ìlérí alàgbára àti ìtùnú ti ìdílé wa ti rí. Ẹ fi ojú inú wò ó pé Olúwa nsọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí yín—sí ẹ̀yin tí ẹ wà láàyè—nítorí wọ́n fún yín:

Má bẹ̀rù.5

Èmi mọ ìbànújẹ́ yín, Mo sì wá láti gbà yín.6

Èmi kì yíò fi yín sílẹ̀.7

Orúko mi nbẹ lára yín àti pé àwon ángẹ́lì mí sì ní àṣẹ lórí yín.8

Èmi yíò ṣe àwọn ìyanu láarín yín.9

Ẹ bá mi rìn; ẹ kọ́ nípa mi; Èmi yíò fún yín ní ìsinmi.10

Mo wà láarín yín.11

Ẹyin jẹ́ tèmi.12

Sí Àwon Tí Wọ́n Wà Láàyè

Pẹ̀lú àwọn ìdánilójú púpọ̀ wọ̀nyí ní ọkàn, mo fẹ́ sọ̀rọ̀ tààrà sí àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀lára pé kò sí ọ̀nà àbáyọ nínú ìtàn ìwàláàyè tiwọn nítorí ìwà ìkà ti àwọn ẹlòmíràn. Tí èyí bá jẹ́ ìtàn ìwàláàyè yín, a sọkún pẹ̀lú yín. À fẹ́ fún yín láti borí ìdàrudàpọ̀, itìjú, àti ìbẹ̀rù, a sì nṣe àfẹ́rí fun yín, nipasẹ Jesu Kristi, lati ṣẹ́gun.

Láti Olùfaragbà sí Wíwàláàyè sí Aṣẹ́gun

Tí ẹ bá ti ní ìrírí èyíkéyi írú ìlòkulò, ìwà-ipá, tàbí ìnilára, ẹ lè ni èrò pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀bi yín lọ́nàkọnà àti pé ó yẹ kí ẹ rú ìtìjú àti ẹ̀bi tí ẹ lérò. Ẹ lè ti ní àwọn èrò bíi:

  • Èmi ìbá ti dẹ́kun eyi.

  • Ọlọ́run kò fẹ́ràn mi mọ́.

  • Kò sí ẹnití yíò fẹ́ràn mi láéláé.

  • Mo ti bàjẹ́ kọjá àtúnṣe.

  • Ètùtù Olùgbàlà wúlò sí àwọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n kìí ṣe sí èmi.

Àwọn érò àṣìṣe àti àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí lè jẹ́ ìdènà sí wíwá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àwọn olórí, tàbí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n, àti nítorínáà ẹ ndánìkan tiraka. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ ti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ẹ fọkàn tán, ẹ ṣì lè máa jà pẹ̀lú àwọn èrò ìtìjú àní àti ìkórìíra araẹni. Ipa ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí lè dúró fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ẹ nírètí pé lọ́jọ́ kan ẹ̀yin yíò ní ìrọ̀rùn, ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ ọjọ́ náà kò tíì dé.

Ìlòkulò náà kò ṣe, kìí ṣe, kì yíò sì jẹ́ ẹ̀bi yín láéláé, ohun èyíówù tí onílòkulò tàbi ẹnikẹ́ni míràn lè ti sọ ní ìlòdì. Nígbàtí ẹ̀yin bá ti jẹ́ olùjìyà ti ìkà, èèwọ̀ ìbálòpọ̀, tàbí ìwà ìbajẹ́ míràn, kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ nílò láti ronúpìwàdà; ẹ̀ kò ṣe ohunkankan.

Ẹ kò dínkù ní yíyẹ tàbi níní yelórí tàbi dínkù ní fífẹ́ bi ẹ̀dá ènìyàn, tàbí bí ọmọbìnrin tabi ọmọkùnrin Ọlọ́run, nítorí ohun tí ẹlòmíràn ti ṣe sí yín.

Ọlọ́run kò rí yín, tàbí kí Òun ri bẹ́ẹ̀ láéláé, bí ẹnikan tí a níláti kẹ́gàn nísisìyí. Ohunkóhun yiówù tó ti ṣẹlẹ̀ sí yín, Òun tijú yín, tàbí já a yín kulẹ̀. Ó nífẹ yín ní ọ̀nà tí ẹ kò tíì ṣàwárí síbẹ̀síbẹ̀. Ẹ̀yin náà yíò sì ṣàwárí rẹ̀ bí ẹ ṣe ngbẹ́kẹ̀lé àwọn ìlérí Rẹ̀ àti bí ẹ ṣe nkọ́ láti gbà Á gbọ́ nígbàtí Ó sọ pé ẹ jẹ́ “iyebíye ní ojú [Òun].”13

Ẹ̀yin kò sí ní àsọyé nípa àwọn ohun ìṣẹ̀lẹ̀ búburú wọ̀nyí tí a ti ṣe sí yín. Ẹ̀yin náà, nínú òtítọ́ ologo, ti ṣàlàyé nípasẹ̀ ìdánimọ̀ yín wíwà ti-ayérayé bí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Ọlọ́run àti nípasẹ̀ àṣepé Aṣẹ̀dá yín, ìfẹ́ àìlópin àti fiìpè sí gbogbo ènìyàn àti ìwòsàn pípé.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè dàbí ohun àìṣeéṣe, ní ìmọ̀lára àìṣeéṣe, ìwòsàn wá nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu ti agbára ìràpadà ti Ètùtù Jesu Kristi, ẹnití ó jí dìde “pẹ̀lú ìwòsàn ní ìyẹ́ apá rẹ̀.”14

Olùgbàlà aláànú wa, tí ó ṣẹ́gun lórí òkùnkùn àti ìwà ìbàjẹ́, ní agbára láti ṣàtúnṣe gbogbo àṣìṣe, òtítọ́ ìfúnni-níyè fún àwọn wọnnì tí a ṣẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ẹlòmíràn.”15

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé Olùgbàlà ti sọ̀kalẹ̀ sísàlẹ̀ gbogbo àwọn ohun, àní ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí yín. Nítorí èyí, Ẹ mọ rẹ́gi bí ẹ̀rù gidi àti ìtìjú ti rí lára àti bí ìmọ̀lára ìkọ̀sílẹ̀ àti bíbàjẹ́ ti rí.16 Làti inú ìjìnlẹ̀ ìjìyà ètùtù Rẹ̀, Ó fúnni ní ìrètí tí ẹ rò pé ẹ ti pàdánù láèláé, agbára tí ẹ gbàgbọ́ pé ẹ̀yin kò lè ní láéláé, àti ìwòsàn tí ẹ̀yin kò lérò pé ó ṣeéṣe.

Ìwà Ìlòkulò Ni A Dálẹ́bi Pátápátá látẹnu Oluwa ati awọn Woli Rẹ

Kò sí ibì kankan fún irú ìlòkulò èyíkéyìí—nípa ti ara, ìbálòpọ̀, ẹ̀dùn-ọkàn, tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu—ní ilé èyíkéyìí, orílẹ̀-èdè èyíkéyìí, tàbí àṣà èyíkéyìí. Ko si ohun ti iyawo, ọmọ, tabi ọkọ lè ṣe tàbí sọ tí ó mú wọn “yẹ” fún lílù. Kò sí ẹnikẹ́ni, ní orílẹ̀-èdè tàbí àṣà ìbílẹ̀ èyíkéyìí, rí tó “nbéèrè fún” ìfìràn tàbí ìwà ipá láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn tí ó wà ní ọlá-àṣẹ tàbí láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan tí ó tóbi tí ó sì lágbára.

Àwọn tó nloni nílòkulò tí wọ́n sì nwá ọ̀nà láti fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ búburú wọn pamọ́ lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Sùgbọ́n Olúwa, tí ó ri ohun gbogbo, mọ ìṣe àti èrò inú àti èrò ti ọkàn.17 Òun ni Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo, àti pé ìdájọ́ òdodo Rẹ̀ ni a ó fúnni.18

Pẹ̀lú ìyanu, Olúwa bákannáà jẹ́ Ọlọ́run aláànú sí àwọn tí ó ronúpìwàdà nítòótọ́. Àwọn onílòkulò—pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti lo arawọn nílòkulò fúnrawọn nígbàkan rí—tí wọ́n jẹ́wọ́, tí wọ́n kọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun nínú agbára wọn láti san ẹ̀san àti ìmúpadà, ní ààyè sí ìdáríjì nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu ti Ètùtù ti Krístì.

Fún àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn èké kàn, agbára tí a kò lè sọ nípa àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí nmú ìwẹ̀nùmọ́ ti ararẹ̀ wá. Ṣùgbọ́n àwọn bákannáà ni a bùkún fún nípasẹ̀ ìjìyà ìṣẹ́gun ti Olùgbàlà fún wọn àti ìmọ̀ pé òtítọ́ yíò lékè nígbẹ̀hìn.

Ṣùgbọ́n àwọn aláìrònúpìwàdà onílòkulò yíò dúró níwájú Olúwa láti jíhìn fún ẹ̀ṣẹ̀ búburú wọn.

Olúwa Fúnrarẹ̀ mu hàn kedere nínú ìdálẹ́bi Rẹ̀ nípa ìlòkulò èyíkéyìí: “Ṣùgbọ́n ẹnití ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀ … , ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọrùn rẹ̀, kí a sì rì í sínú ọ̀gbun omi okun.”19

Ìparí.

Àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́ gan-an—àti fún ọ̀ràn náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti farada àìṣèdájọ́ òdodo níti ìgbésí ayé—ẹ lè ní ìbẹ̀rẹ̀ titun àti àkọ̀tun titun. Ní Gẹtisémánì àti ní Kálfárì, Jésù “gbé … gbogbo ìrora àti ìjìyà sórí Ararẹ̀ láé tí ẹ̀yin àti èmi làkọjá rí,”20 Ó sì ti borí gbogbo rẹ̀! Pẹ̀lú apá nínà síta, Olùgbàlà fúnni ní ẹ̀bùn ìwòsàn. Pẹ̀lú ìgboyà, sùúrù, àti idojúkọ òtítọ́ lórí Rẹ̀, láìpẹ́ púpọ̀ ẹ le wá láti gba ẹ̀bùn yìí ní kíkún. Ẹ lè jẹ́kí ìrora yín lọ kí ẹ sì fi sílẹ̀ ní ẹsẹ̀ Rẹ̀.

Olùgbàlà yín kéde jẹ́jẹ́ pé, “Olè kò wá bíkòṣe láti jalè, àti láti pa, àti láti parun: Èmi wá kí [ẹ̀yin] lè ní ìyè, àti kí [ẹ] lè ní púpọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀.”21 Ẹ jẹ́ wíwàláàyè, ẹ lé níwòsàn, àti pé ẹ lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé wípé pẹ̀lú agbára àti ore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì, ẹ yíò borí ẹ ó sì ṣẹgun.

Jésù ṣe àmọ̀já nínú ohun tí ó dàbí ẹnipé kò ṣeéṣe. Ó wá síhìn-ín láti mú kí ohun tí kò ṣeéṣe ṣeéṣe, tí kò ṣeé ràpadà di ríràpadà, láti mú aláìníwòsàn láradá, láti mú àwọn ohun tí kòtọ́ tọ́, láti ṣèlérí fún aláìní-ìlérí.22 Àti pé Ó dára nípa rẹ̀ gan. Ní òtítọ́, Ó jẹ́ pípé nínú rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, Olùwòsàn wa, àmín.

Fún àlàyé díẹ̀ síi àti àwọn ohun-èlò, wo “Ìlòkulò” nínu abala Ìrànlọ́wọ́ Ìyè ChurchofJesusChrist.org àti nínú áàpù Ìkówépamọ́ Ìhìnrere.