Ìyípadà sí Ifẹ́ Ọlọ́run
Ìyìpadà araẹni wà pẹ̀lú ojúṣe láti pín ìhìnrere Jésù Krístì pẹ̀lú Ayé.
Mo dúpẹ́ fún ìpè alágbára ti wòlíì Ààrẹ Russell M. Nelson sí iṣẹ́-ìsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere àti Ààrẹ M. Russell Ballard Nelson àti Alàgbà Marcos A, Aidukaitis fún ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere ìmísí ti òní.
iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere kan sí Great Britain ní òpin ọdún tó kọjá gbà mí láàyè láti ronú lorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oníyebíye ti-ẹ̀mí tí ó jẹ́ ìpìnlẹ̀ sí ìpinnu mi láti sìn bí ojíṣẹ́ ìhìnrere kan.1 Nígbàtí mo wà ní ọmọ ọdún mẹẹdogun, arákùnrin mi àgbà, Joe, jẹ́ ọmọ ogún ọdún—ọjọ́ orí pípé láti sìn ní míṣọ̀n kan. Nítorí ìjà Korean, díẹ̀ gan ni a fi ààyè gbà làti sìn, ní United States. Ẹnìkan ṣoṣo ni a lè pè látinú wọ́ọ̀dù kọ̀ọ̀kan ní ọdún kan.2 Ó yà mí lẹ́nú nígbàtí bíṣọ́ọ̀pù wa ní kí Joe ṣàwárí ìṣeéṣe yí pẹ̀lú baba wa. Joe ti nmúra ìbèèrèfúnsẹ́ fún ilé-ìwé iṣẹ́ òògùn sílẹ̀. Baba wa, ẹnití kìí ṣe déédé nínú Ìjọ, ti ṣe ìmúrasílẹ̀ owó láti ràn án lọ́wọ́ kò sì sí ní ojúrere joe ní lílọ sí míṣọ̀n kan. Baba dá àbá pé Joe lè ṣe dídára si nípa lílọ sí ilé-ìwé iṣẹ́ òògùn. Èyí jẹ́ ọ̀ràn títóbi nínú ẹbí wa.
Nínú ìbánisọ̀rọ̀ olókìkí pẹ̀lú arákùnrin mi àgbà ọlọ́gbọ́n àti alápẹrẹ, a parí pé ìpinnu rẹ̀ lórí bóyá láti sin míṣọ̀n kí ó sì dáwọ́ ẹ̀kọ́ dúró dálè orí àwọn ìbèèrè mẹ́ta (1) Ṣé àtọ̀runwá ni Jésù Krístì? (2) Ṣé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Ìwé ti Mọ́mọ́nì? Àti pé (3) Ṣé Joseph Smith ni Wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò? Bí ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè mẹta wọ̀nyí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, ó hàn kedere pé Joe lè ṣe rere síi ní mímú ìhìnrere Jésù Krístì lọ sí ayé ju dída dókítà ní ọjọ́ tí ó ṣíwájú.3
Ní alẹ́ náà mo gbàdúrà taratara àti pẹ̀lú èrò-inú òtítọ́. Ẹ̀mí, nínú ọ̀nà alágbára àìlèsẹ́, tí fẹsẹ̀múlẹ̀ sí mi pé àwọn ìdáhùn sí gbogbo àwọn íbèère mẹta náà jẹ́ òtítọ́. Eléyìí jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ idanilẹkọ kan fún mi. Mo dámọ̀ pé gbogbo ìpinnu tí èmi yíò ṣe fún ìyókù ayé mi yíò lágbára nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí. Bákannáà mo mọ̀ pé èmi yíò sìn ní míṣọ̀n bí a bá fún mi ni ànfàní. Ní àkokò ìgbé-ayé iṣẹ́-ìsìn àti àwọn ìrírí ti-ẹ̀mí, mo ti wá láti ní òyè pé ìyípadà òtítọ́ ni èsì ìtẹ́wọ́gbà ìtara mímọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti pé a lè ní ìtọ́sọ́nà nínú àwọn ìṣe wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
Mo ti ní ẹ̀rí kan tẹ́lẹ̀ nípa àtọ̀runwá Jésù Krístì bí Olùgbàlà aráyé. Ní alẹ́ náà mo gba ẹ̀rí ti-ẹ̀mí nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì4 àti Wòlíì Joseph Smith.
Joseph Smith Jẹ́ Ohun-èlò ní Ọwọ́ Olúwa.
Ẹ̀rí yín yíò gba okun nígbàtí ẹ bá mọ̀ nínú ọkàn yín nípasẹ̀ àwọn àdúrà yín pé Wòlíì Joseph Smith jẹ́ ohun-èlò ní ọwọ́ Olúwa. Ní ọdún mẹ́jọ sẹ́hìn, ọ̀kan lára ìfúni-níṣẹ mi nínú àwọn Àpóstélì Méjìlá ni láti yẹ̀wò àti ka gbogbo àwọn ìwé àti ìwé-àṣẹ àti ìwáàdí olókìkí tí ó darí sí àtẹ̀jáde àwọn àpò-iwé Ènìyàn Mímọ́.5 Ẹ̀rí mi àti ìfẹràn Wòlíì Joseph Smith ti ní okun títóbi ó sì gbòòrò lẹ́hìn kíka nípa ìmísí yékéyéké ìgbé ayé rẹ̀ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti-wòlíì ìṣíwájú-ayé.
Ìyírọ̀padà-èdè Ìwé ti Mọ́mọ́nì nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí Ìmúpadàbọ̀sípò.6 Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni a kọ dáradára, sínú léraléra, ó sì wà pẹ̀lú àwọn èsì sí àwọn ìbèèrè nlá ti ayé. Ó jẹ́ ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Joseph Smith jẹ́ olódodo, ó kún fún ìgbàgbọ́, àti ohun-èlò ní ọwọ́ Olúwa ní mímú jáde Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
Àwọn ìfihàn àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú pèsè àwọn kọ́kọ́rọ́, ìlànà, àti májẹ̀mú tí ó ṣeéṣe fún ìgbàlà àti ìgbéga. Kìí ṣe pé wọ́n gbé àwọn ohun pàtàkì tí a nílò jáde láti gbé Ìjọ kalẹ̀ nìkàn ṣùgbọ́n bákannáà wọ́n pèsè ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ tí ó fi ààyè gbà wá láti ní òye èrèdí ìgbé-ayé kí ó sì fún wa ní ìwò ayéraye.
Ọ̀kan lára àwọn onírurú àpẹrẹ ti ojúṣe ti-wòlíì Joseph Smith ní a ri nínú Ìpín kẹrìndínlọ́gọ́rin ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú Ó jẹ́ àkọsílẹ̀ kíkún ti ìràn ọ̀run, pẹ̀lú àwọn ìjọba ti ògo, eyí tí Joseph àti Sidney Rigdon di alábùkún láti gbà ní Ọjọ́ Kẹrìndínlógún Oṣù Kejì, 1832. Ní ìgbà náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìjọ nkọ́ni pé Ètùtù Olùgbàlà kò ní pèsè ìgbàlà fún púpọ̀jù àwọn ènìyàn. A gbàgbọ́ pé díẹ̀ ni a ó gbàlà àti pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ni a ó parun sí àpáàdì àti ìdálẹ́bi, pẹ̀lú ìpalára àìlópin “ti ó burújùlọ àti lílèjù tí a kò lè sọ.”7
Ìfihàn tí ó wà nínú ìpín kẹrìndínlọ́gọ́rin npèsè ìran ológo ti àwọn ipele ògo níbití àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ti àwọn ọmọ Baba Ọ̀run tí wọ́n jẹ́ akọni ní ipò ìṣaájú-ayé ni a bùkún jinlẹ̀-jinlẹ̀ ní títẹ̀lẹ́ ìdájọ́ ìkẹhìn.8 Ìran ti ipele ògo mẹ́ta, èyí kíkéréjùlọ tí ó “ju gbogbo o`ye lọ,”9 ni ó jẹ́ ìgbéṣubú tààrà nípa àṣìṣe ẹ̀kọ́ alágbára ìgbànáà ṣùgbọ́n tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò jẹ́ píparun sí àpáàdì àti ìdálẹ́bi.
Nígbàtí ẹ bá damọ̀ pé Joseph Smith jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ní ẹ̀kọ́ tó lópin, àti díẹ̀ tàbí àìsí ìmòye ti àwọn èdè kílásíkà látinú èyí tí a ti yí ọ̀rọ̀ Bíbélì padà, òun jẹ́ ohun-èlò ní ọwọ́ Olúwa nítòótọ́. Nínú ẹsẹ kẹtàdínlógún ti ìpín kẹrìndínlọ́gọ́rin, ó ní ìmísí láti lo ọ̀rọ̀ aláìṣòótọ́” dípò ti dálẹ́bi tí a lò nínú Ìhìnrere Jòhánnù.10
Ó dùnmọ́ni pé ọdún marundinlaadọta lẹ́hìnnáà olórí ìjọ Ánglíkàn àti akẹkọ amòye kílásíkà oníwé-ẹ̀rí,10 Frederic W. Farrar, ẹnití ó lo àwọn ọdún ní kíkọ Ìgbé-ayé Krístì,11 tẹnumọ pé ìtumọ̀ ìdálẹ́bi nínú Ẹ̀yà Bíbélì ti Ọba Jákọ́bù ni èsì àwọn àṣìṣe ìyírọ̀padà-èdè látinú Hébérù àti Greek sí Èdè-gẹ̀ẹ́sì.12
Ní ọjọ́ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ṣe àgbàtọ́ èròngbà pé àbájáde fún ẹ̀ṣẹ̀ níláti wà. Wọ́n ṣe àtìlẹhìn àìbìkítà gbígba ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ra láìsí ìrònúpìwàdà. Ìfihàn ẹ̀kọ́ wa kò kọ èrò pé púpọ̀ àwọn ènìyàn yíò gba ìdálẹ́bi ayérayé sí àpáàdì àti ìdálẹ́bi nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ṣe ìgbékalẹ̀ pé ìrònúpìwàdà araẹni ni àṣẹ ìmúyẹ láti ṣe àbápín Ètùtù Olùgbàlà kí a sì jogún ìjọba sẹ̀lẹ́stíà.14 Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Joseph Smith jẹ́ ohun-èlò òtítọ́ ní ọwọ́ Olúwa ní mímú Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀ jáde wá.
Nítorí Ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere Jésù Krístì, a ní òye pàtàkì ti méjèèjì ìrònúpìwàdà àti “àwọn iṣẹ́ òdodo.”15 A ní ìmọ̀ ìbonibọ́lẹ̀ pàtàkì ti Ètùtù Olùgbàlà àti àwọn ìlànà àti májẹ̀mú ìgbàlà Rẹ̀, pẹ̀lú àwọn tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì.
“Iṣẹ́ òdodo” njáde látinú àti pé wọ́n jẹ́ àbájáde ìyípadà. Ìyípadà òtítọ́ ni a nmú wá nípa ìtẹ́wọ́gbà mímọ̀ àti ìfarajìn tí ó tẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run.14 Àṣeyẹ àwọn àyọrísí àti ìbùkún tí ó nṣàn látinú ìyípadà jẹ́ òtítọ́ àti àláfíà pípẹ́-títí àti ìdánilójú ìgbẹ̀hìn araẹni15—bí àwọn ìjì ti ayé yí tilẹ̀ wà.
Ìyípadà sí Olùgbàlà nyí ìwà-ẹ̀dá ènìyàn padà sínú ìyàsímìmọ́, àtúnbí, ẹnì mímọ́—ẹ̀dá titun nínú Jésù Krístì.17
Ọ̀pọ̀ Ni A Pamọ́ kúrò nínú Òtítọ́ Nítorí Wọ́n Kò Mọ Ibití Wọn Ó ti Ríi
Kíni àwọn ojúṣe tí ó nṣàn látinú ìyípadà? Nínú ẹ̀wọ̀n Liberty, Wòlíì Joseph ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a “pamọ́ kúrò nínú òtítọ́ nítorí wọn kò mọ ibití wọn ó ti rí i.”18
Nínú ọ̀rọ̀-ìṣaájú Olúwa sí Ẹ̀kọ́ àti àwọn Majẹ̀mú, ìkéde àwòrán-nlá ti èrò Olúwa fún wa ní a gbé jáde. Ó kéde,“Nítorínáà, Èmi Olúwa, ní mímọ àwọn ewu tí yíò wá sí órí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, ké pe ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, mo sì sọ̀rọ̀ sí i láti ọ̀run, mo sì fún un ní àwọn òfin.” Ó pàṣẹ síwájú si,“Kí a lè kéde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi láti ẹnu aláìlágbára àti òpè sí àwọn òpin ayé.”19 Ìyẹn pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún. Ìyẹn pẹ̀lú ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa. Èyí níláti jẹ́ ìdojúkọ sí gbogbo ẹni tí a ti bùkún pẹ̀lú ìyípadà sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Olùgbàlà fi oore-ọ̀fẹ́ pè wá láti jẹ́ ohùn Rẹ̀ àti ọwọ́ Rẹ̀.20 Ìfẹ́ Olùgbàlà yíò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ìtọ́nisọ́nà wa. Olùgbàlà kọ́ àwọn ọmọẹ̀hìn, “Nítorínáà ẹ lọ, kí ẹ sì kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè.”21 Àti sí Joseph Smith, Ó kéde, “Wàásù ìhìnrere mi sí gbogbo ẹ̀dá tí kò ì tíì gbà á.”22
Ní ọ̀ṣẹ̀ kan lẹ́hìn ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Kirtland ní Ọjọ́ kẹta, oṣù kẹrin, 1836, èyí tí ó jẹ́ Ọjọ́-ìsinmi Àjínde àti Ìrékọjá bákannáà. Olúwa farahàn nínú ìran títóbí sí Joseph àti Oliver Cowdery. Olúwa tẹ́wọ́gba tẹ́mpìlì náà ó sì kéde pé.”Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìbùkún èyí tí yíò tú jáde sórí àwọn ènìyàn mi.”20
Lẹ́hìn tí ìran yìí parí, Mósè fi ara hàn “ó sì fi … àwọn kọ́kọ́rọ́ ti kíkójọ Ísráẹ́lì láti ìpín mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, àti dídarí àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá láti ilẹ̀ àríwá.”24
Ààrẹ Russell M. Nelson, olùfẹ́ wòlíì wa ní òní ẹnití ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ kannáà mú, tí a kọ́ni ní òwúrọ̀ yí: “Ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin ni a ti pamọ́ fún àkokò yí nígbàtí ìlérí ìkójọ ti Ísráẹ́lì ni o nṣẹlẹ̀. Bí ẹ ti nsìn ní àwọn míṣọ̀n, ẹ nkó ojúṣe tí ó ṣe kókó nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí yì!”24
Fún àṣẹ Olùgbàlà láti pín ìhìnrere láti di ara ẹni tí a jẹ́, a nílò láti dà olùyípadà sí ìfẹ́ Ọlọ́run, a nílò láti fẹ́ràn àwọn aladugbo wa, pín ìmuípadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì, kí a sì pe gbogbo ènìyàn láti wá kí wọ́n sì ri. Bí ọmọ Ìjọ, a ṣìkẹ́ ìdáhùn Wòlíì Joseph sí John Wentworth, onkọ̀wé Democrat Chicago, ní 1842. Ó nbèèrè àlàyé nípa Ìjọ. Joseph parí ìdáhùn rẹ̀ nípa lílo “Òṣùwọ̀n Òtítọ́” bí ọ̀rọ̀-ìṣaájú sí àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ kẹtàlá. Òṣùwọ̀n nfi, ọ̀nà ìbámu kan hàn, ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣeyọrí.
“Kò sí ọwọ́ àìmọ́ tí ó lè dá iṣẹ́ náà dúró ní lilọsíwájú; inúnibíni lè jà, àgbájọ enìyànkénìyàn lè papọ̀, àwọn ọmọ-ogun lè kórajọ, olùṣátá lè borúkọjẹ́, ṣùgbọ́n òtítọ́ Ọlọ́run yíò lọ síwájú tìgboyàtìgboyà, tọlátọlá, ìgbáraléaraẹni, títí tí a fi wọnú gbogbo agbègbè, bẹ gbogbo ibi gíga wò, gbá gbogbo orílẹ̀-èdè, àti dún ní gbogbo ètítítí tí gbogbo èrò Ọlọ́run a fi di mímúṣẹ, àti tí Jèhófàh Nlá yíò wípé iṣẹ́ ti parí.”26
Èyí ti jẹ́ ìpè aápọn fún àwọn ìran Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, nípàtàkì àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere. Nínú ẹ̀mí “Òṣùwọ̀n ti Òtítọ́,,” a ṣọpẹ́ pé ní àárín àjàkálẹ̀-ààrùn àgbáyé àwọn onígbàgbọ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere ti pín ìhìnrere. Ẹ̀yin òjíṣẹ́ ìhìnrere, a ní ìfẹ́ yín! Olúwa ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa pín ìhìnrere Rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Ìyìpadà araẹni wa pẹ̀lú ojúṣe láti pín ìhìnrere Jésù Krístì pẹ̀lú Ayé.
Àwọn ìbùkún ti pípín ìhìnrere pẹ̀lú àlékún ìyípadà wa sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti jíjẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa.27 A nbùkún àwọn ẹlòmíràn láti ní ìrírí “ìyípadà nlá” ọkàn.”28 Ayọ̀ ayérayé wà nítòótọ́ ní ṣíṣe ìrànwọ́ láti mú àwọn ọkàn wá sọ́dọ̀ Krístì.29 Ṣíṣe iṣẹ́ fún ìyípadà ararẹni àti àwọn ẹlòmíràn ni iṣẹ́ akọni.30 Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.