Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìfẹ́ Àtọ̀runwá nínú Ètò Bàbá.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ìfẹ́ Àtọ̀runwá nínú Ètò Bàbá.

Èrèdí ẹ̀kọ́ àti àwọn ìṣètò ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ ni láti múra àwọn ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀ fún ìgbàlà nínú ìjọba sẹ̀léstíà àti fún ìgbéga nínú ìpele rẹ̀ gíga jùlọ.

Ètò ìhìnrere jẹ́ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ti Bàbá Ọ̀run fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ hàn. Láti ní òye èyí, a gbọdọ̀ lépa láti ní òye ètò Rẹ̀ àti àwọn òfin Rẹ̀. Ó fẹ́ràn àwọn ọmọ Rẹ̀ púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo, Jésù Krístì, sílẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, láti jìyà àti láti kú fún wa. Nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a mú padàbọ̀sípò, a ní òye àrà ọ̀tọ̀ kan nípa ètò ti Baba wa Ọrun. Èyí fún wa ní ọ̀nà yíyàtọ̀ kan ní wíwo èrèdí ìgbé ayé-ikú, ìdájọ́ àtọ̀runwá tí ó tẹ̀lé e, àti àyànmọ́ ológo ìkẹhìn ti gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Mo féràn yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run Nígbàtí a bi Jésù léèrè pé, “Èwo ni àṣẹ nlá nínú òfin?” Ó kọ́ni pé fífẹ́ràn Ọlọ́run àti fífẹ́ràn àwọn ẹnìkejì wa ni àkọ́kọ́ nínú àwọn òfin nlá Ọlọ́run.1 Àwọn òfin wọnnì jẹ́ àkọ́kọ́ nítorípé wọ́n pè wá láti dàgbà níti ẹ̀mí nípa lílépa láti ṣe àpẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa. Ó wùmí kí gbogbo wa ó ní òye ẹ̀kọ́ àti àwọn ìlànà olùfẹ́ni tí Baba wa Ọrun àti ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ohun tí mo sọ níhin nwá láti ṣe àfọ̀mọ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run ti ṣe àlàyé ẹ̀kọ́ náà àti àwọn ìlànà onímìísí wọnnì.

1.

Èdè àìyédè tí ó wọ́pọ̀ nípa ìdájọ́ tí ó tẹ̀lé ayé-ikú ní ìgbẹ̀hìn ni pé àwọn ènìyàn rere nlọ sí ibikan tí a pè ní ọ̀run rere àti pé àwọn ènìyàn búburú nlọ sí ibi àìlópin kan tí a pè ní ọ̀run àpáàdì. Àwọn àṣìṣe èrò ti àwọn ibi ìdésí ìgbẹ̀hìn méjì péré yi jẹ́kí ó dàbí pé àwọn tí kò le pa gbogbo àwọn òfin mọ́ tí a nílò fún ọ̀run yío fi dandan ní àyànmọ́ fún ọ̀run àpáàdì.

Bàbá Ọ̀run olùfẹ́ni kan ní ètò dídárajù kan fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ẹ̀kọ́ tí a fihàn nípa Ìjọ Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀ sípò kọ́ni pé gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run—pẹ̀lú àwọn àyọsílẹ̀ tí ó kéré jọjọ láti jẹ́ gbígbèrò níhin—yío parí ní òpin nínú ìjọba ògo.2 “Ní ilé Baba mi ọ̀pọ̀ àwọn ìbùgbé ni ó wà,”3 ni Jésù kọ́ni. Láti inú ìfihàn òde òní a mọ̀ pé àwọn ìbùgbé wọnnì wà ní àwọn ìjọba ògo mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nínú Ìdájọ́ Ìgbẹ̀hìn ọ̀kọ̀ọ̀kan wa yío jẹ́ dídálẹ́jọ́ ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ wa àti àwọn ìfẹ́ inú ọkàn wa.4 Ṣaájú èyí, a ó nílò láti jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a kò ronúpìwàdà wọn. Àwọn ìwé mímọ́ ṣe kedere lórí èyí.5 Nígbànáà olódodo Onídajọ́ wa yío fún wa ní ìbùgbé nínú ọ̀kàn lára àwọn ìjọba ògo wọnnì. Báyi, bí a ti mọ̀ láti inú àwọn ìfihàn ti òde òní, gbogbo ènìyàn “yío jẹ́ dídálẹ́jọ́ … , àti pé olukúlùkù ènìyàn yío gba ilẹ̀ ọba tirẹ̀, ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ tirẹ̀, nínú àwọn ibùgbé tí a ti pèsè.”6

Olúwa ti yàn láti fi kékeré jùlọ hàn nípa méjì lára àwọn ìjọba ògo wọ̀nyí. Ní ìdàkejì, Olúwa ti fi púpọ̀ hàn nípa ìjọba ògo tí ó ga jùlọ, èyítí Bíbélì ṣe àpèjúwe rẹ̀ bíi “ògo òòrùn.”7

Nínú ògo ti “sẹ̀lẹ́stíà”8 àwọn ìpele, tàbí àtẹ̀gún mẹ́ta ni ó wà.9 Gíga jùlọ nínú àwọn wọ̀nyí ni ìgbéga nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, níbití a lè dàbí Baba wa àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Láti rànwálọ́wọ́ ṣe ìmúdàgbà àwọn ìwà bí ti Ọlọ́run àti ìyípadà nínú ìwà àdánidá tí ó ṣe dandan láti le rí agbára àtọ̀runwá wa, Olúwa ti fi ẹ̀kọ́ hàn Ó sì ti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àṣẹ tí ó dá lórí òfin ayérayé. Èyí ni ohun tí a nkọ́ni nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nítorípé èrèdí ẹ̀kọ́ àti àwọn ìlànà ti Ìjọ tí a múpadàbọ̀sípò yí ni láti pèsè àwọn ọmọ Ọlọ́run fún ìgbàlà nínú ògo ti sẹ̀lẹ́stíà àti, ní pàtàkì jùlọ, fún ìgbéga nínú ìpele rẹ̀ gíga jùlọ.

Àwọn májẹ̀mú tí a dá àti àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí sí àwọn olõtọ́ nínú àwọn tẹ́mpìlì Ọlọ́run ni kókó. Èyí ṣe àlàyé kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì wa káàkiri ayé, nípa èyí tí àwọn akọrin ti kọ̀rin tó larinrin gan. Àwọn míràn ní ìrújú sí àtẹnumọ́ yí, ní àìní òye pé àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà tẹ́mpìlì ntọ́ wa sí ìhà ṣíṣe àṣeyọrí ìgbéga. Èyí lè yéni nìkan nínú àkóonú ti òtítọ́ tí a fihàn nípa àwọn ìpele ògo mẹta . Nítorí ìfẹ́ nlá ti Baba wa Ọrun fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀, Ó ti pèsè àwọn ìjọba ògo míràn—bí Alàgbà Quentin L. Cook ti ṣe àlàyé ní àná—gbogbo èyítí ó jẹ́ ìyanu ju ohun tí a le ní òye rẹ̀ lọ.10

Ètùtù ti Jésù Krístì mú gbogbo èyí ṣeéṣe. Ó ti fihàn pé Òun “ṣe Baba lógo, Ó sì gba gbogbo àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ là.”11 Pé a fi ìgbàlà fúnni nínú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àwọn ìjọba ògo. A mọ̀ láti inú ìfihàn ti òde òní pé “gbogbo àwọn ìjọba ní òfin kan tí a fifúnni.”12 Pẹ̀lú Àpẹrẹ:

“Ẹni náà tí kò le gbé pẹ̀lú òfin ìjọba sẹ̀lẹ́stíà kì yíò le gbé nínú ògo sẹ̀lẹ́stíà.

“Àti ẹni náà tí kò le gbé pẹ̀lú òfin ìjọba tẹ̀rẹ́stríà kì yío le gbé pẹ̀lú ògo tẹ̀rẹ́stríà.

“Àti ẹni náà tí kò le gbé pẹ̀lú òfin ìjọba tẹ̀lẹ́stíà kì yío le gbé pẹ̀lú ògo tẹ̀lẹ́stíà.”13

Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, ìjọba ògo tí a ba gbà nínú Ìdájọ́ Ìkẹhìn yío jẹ́ pípinnu nípa àwọn àṣẹ tí a yàn láti gbé nípa rẹ̀ nínú ètò ìfẹ́ni Baba wa Ọ̀run. Ní abẹ́ ètò náà àwọn ìjọba púpọ̀ ló wà kí ó le jẹ́ pé gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ yío le jẹ́ yíyàn sí ìjọba kan níbití wọ́n le “gbé”.

ll.

Àwọn ìkọ́ni àti àwọn ìlànà ti Ìjọ Olúwa tí a múpadàbọ̀ sípò náà ṣe àmúlò àwọn òtítọ́ ayérayé wọ̀nyí ní ọ̀nà tí a le ní òye rẹ̀ ní kíkún nínú àkóónú ètò ìfẹ́ni ti Baba wa Ọrun nìkan fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.

Báyi, a bu ọlá fún agbára òmìnira ẹnìkọ̀ọ̀kan. Púpọ̀ mọ̀ nípa àwọn aápọn nlá Ìjọ yi láti gbárùkù ti òmìnira ẹ̀sìn. Àwọn aápọn wọ̀nyí jẹ́ mímú ètò Bàbá wa Ọ̀run tẹ̀síwájú. A nlépa láti ran gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́—kìí ṣe àwọn ọmọ ijọ tiwa nìkan—láti gbádùn òmìnira iyebíye láti yàn

Bákannáà, wọ́n máa nbi wá nígbà míràn ìdí tí a fi nrán àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere sí àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀, àní láàrin ibití àwọn Krístíánì pọ̀ sí. Wọ́n máa nbi wá bákannáà ìdí tí a nṣe àtìlẹ́hìn púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn tí kìí ṣe ọmọ Ìjọ wa láì so èyí pọ̀ mọ́ àwọn aápọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa. A nṣe èyí nítorípé Olúwa ti kọ́ wa láti bọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ bíi àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, a sì fẹ́ pín ọ̀pọ̀ ìní wa ní ti ẹ̀mí àti ti ara pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.

Ẹ̀kọ́ ayérayé bákannáà npèsè ìwòye yíyàtọ̀ kan lóri àwọn ọmọdé. Nípasẹ̀ ìwòye yi a ri bíbí àti títọ́jú àwọn ọmọdé bíi apákan ètò àtọ̀runwá náà. Ó jẹ́ ayọ̀ àti ojúṣe mímọ́ ti àwọn tí a fún ní agbára láti kópa nínú rẹ̀. Nítorínáà, a pàṣẹ fúnwa láti kọ́ àti láti jà fún àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ àti àwọn ìṣe tí ó pèsè àwọn àyíká tó dárajùlọ fún ìdàgbàsókè àti ìdùnnú àwọn ọmọdé ní àbẹ́ ètò Ọlọ́run.

lll.

Ní ìparí, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni a mọ̀ dáradára bíi Ìjọ tí ó fi ẹbí sí ààrin gbùngbùn. Ṣùgbọ́n ohun tí kò yéni tó ni òtítọ́ pé bí a ṣe fi ẹbí sí ààrin gbùngbùn kò pin sí àwọn ìbáṣepọ̀ ayé-ikú. Àwọn ìbáṣepọ̀ ayerayé náà jẹ́ kókó sí ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Ìjọ tí a mú padàbọ̀sípò náà ni láti ran gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti yege fún ohun tí Ọlọ́run fẹ́ bíi àyànmọ́ ìgbẹ̀hìn wọn. Nípa ìràpadà tí a pèsè nípasẹ̀ Ètùtù ti Krístì, gbogbo ènìyàn le rí ìyè ayérayé (ìgbéga nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà), èyítí Ìyá Éfà kéde pé “Ọlọ́run fifún gbogbo àwọn olùgbọràn.”14 Èyí ju ìgbàlà lọ. Ààrẹ Russell M. Nelson ti ránwa létí pé, “nínú ètò ayérayé ti Ọlọ́run, ìgbàlà jẹ́ nkan ti ẹnìkọ̀ọ̀kan; [ṣùgbọ́n] ìgbéga jẹ́ nkan ti ẹbí.”14

Ohun tó ṣe kókó sí wa ni ìfihàn ti Ọlọ́run pé ìgbéga le jẹ́ rírí nípasẹ̀ ìṣòtítọ́ nìkan sí àwọn májẹ̀mú ìgbeyàwó ayérayé láàrin ọkùnrin kan àti obìnrin kan.15 Pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ni ìdí ti a fi nkọ́ni pé “lákọ-lábo jẹ́ kókó ìrísí ti ìdánimọ̀ àti èrèdí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣaájú ayé-ikú, ní ayé-ikú, àti ní ayérayé.”16

Èyí bákannáà jẹ́ ìdí tí Olúwa fi nílò Ìjọ Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò láti tako àwọn ìtẹ́mọ́ ti àwùjọ àti ti òfin láti pẹ̀hìndà kúrò nínú ẹ̀kọ́ ti ìgbeyàwó láàrin ọkùnrin kan àti obìnrin kan, àti láti tako àwọn ìyàtọ̀ tí nrúni lójú ní àárín àwọn ọkùnrin àti obìnrin tàbí dàláàmú tàbí ṣe àtúnṣe lákọ-lábo.

Àwọn ipò Ìjọ tí a múpadàbọ̀sípò lórí àwọn kókó ìpìlẹ̀ wọ̀nyí máa nfi léraléra rú àtakò sókè. Èyí yé wa. Ètò Baba wa Ọrun fi ààyè gba “àtakò nínú ohun gbogbo,”18 àti pé àtàkò ti Sátánì tí ó le jùlọ máa nfojúsùn sí ohunkóhun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ sí ètò náà. Ní àyọrísí, ó nwá láti tako ìlọsíwájú sí ìgbéga nípa dída ìgbeyàwó rú, mú irẹ̀wẹ̀sì bá ọmọbíbí, tàbí da ọ̀rọ̀ lákọ-lábo rú. Ṣùgbọ́n, àwa mọ̀ pé nígbàtí ó bá pẹ́ èrèdí àti ètò àtọ̀runwá ti olùfẹ́ni Baba wa Ọrun kì yío di yíyípadà. Àwọn ipò ti ara ẹni le yípadà, ètò Ọlọ́run sì fi dánilójú pé ní ìgbẹ̀hìngbẹ́hín, àwọn olódodo tí wọ́n bá pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́ yío ní ànfààní láti yege fún gbogbo ìbùkún tí a ṣèlérí.19

Ìkọ́ni àrà ọ̀tọ̀ kan tí ó níyelórí láti rànwálọ́wọ́ múrasílẹ̀ fún ìyè ayérayé, “títóbijù nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run,”17 ni ìkéde kan lórí ẹbí ti 1995.18 Àwọn ìkéde rẹ̀, bẹ́ẹni, yàtọ̀ sí àwọn òfin lọ́wọ́lọ́wọ́ kan, àwọn ìṣe, àti ìpolongo, bí irú àjọgbélé àti ìgbéyàwó ẹ̀yà kannáà. Àwọn tí wọn kò ní òye kíkún nípa ètò ìfẹ́ni ti Baba fún àwọn ọmọ Rẹ̀ le rí ìkéde ẹbí yi bíi ohun tí kò ju ọ̀rọ̀ ìlànà tó ṣeé yí padà kan lọ. Ní ìdàkejì, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìkéde ẹbí, tí a dá sílẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ tí kò lé parẹ́, ṣe ìtumọ̀ irú àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí níbití abala pàtàkì jùlọ ti ìdàgbàsókè ayérayé wa ti le wáyé.

Èyí ni àkóónú fún àràọ̀tọ̀ ẹ̀kọ́ àti àwọn ìlànà Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a múpadàbòsípò.

IV.

Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ àti àwọn ipò ní ayé-ikú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ gbé pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀. Bíi atẹ̀lé Krístì tí ó níláti fẹ́ràn àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, a níláti gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tí wọn kò gbàgbọ́ bí àwa ti ṣe. Gbogbo wa ni ọmọ olùfẹ́ni Baba Ọrun kan. Fún gbogbo wa, Ó ti ní àyànmọ́ ìyè lẹ́hìn ikú àti, ní ìgbẹ̀hìn, ìjọba ògo kan. Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo wa ó tiraka fún àwọn ìbùkún Rẹ̀ gíga jùlọ tí ó ṣeéṣe nípa pípa àwọn òfin, àwọn májẹ̀mú, àti àwọn ìlànà Rẹ̀ gíga jùlọ mọ́, gbogbo èyí tí ó mú kí àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ Rẹ̀ ó máa jẹ́ kíkọ́ jákèjádò àgbáyé. A gbọ́dọ̀ lépa láti pín àwọn òtítọ́ ayérayé wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbèsè ìfẹ́ tí a jẹ sí gbogbo àwọn ọmọnìkejì wa, a ngba àwọn ìpinnu wọn ní gbogbo ìgbà. Bí wòlíì inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan ti kọ́ni, a gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú, ní níní “ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti gbogbo ènìyàn.”19

Bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ nínú ìpàdé àpapọ̀ wa tí ó kọjá, “Kò tíì sí àkókò kan láé nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn àgbáyé nígbàtí ìmọ̀ Olùgbàlà wa jẹ́ kókó àti wíwúlò ti ara-ẹni sí ọkàn gbogbo ènìyàn. … Ẹkọ́ mímọ́ ti Krístì kún fún agbára. Ó nṣe àyípadà ìgbé ayé olukúlùkù ẹnití ó ní òye rẹ̀ tí ó sì nlépa láti mú un lò nínú ìgbé ayé rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin.20

Njẹ́ kí gbogbo wa le mú ẹ̀kọ́ mímọ́ náà lò nínú ìgbé ayé tiwa, ni mo gbàdúrà ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀